ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18
“Sá Eré Ìje Náà Dé Ìparí”
“Mo ti sá eré ìje náà dé ìparí.”—2 TÍM. 4:7.
ORIN 129 A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣe?
ṢÉ WÀÁ gbà láti sá eré kan tó o mọ̀ pé ó nira, pàápàá lásìkò tó ò ń ṣàìsàn tàbí tó ti rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu? Ó dájú pé o ò ní gbà. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ là ń sá eré ìje. (Héb. 12:1) Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, bóyá ara wa mókun tàbí kò mókun, gbogbo wa pátá la gbọ́dọ̀ sá eré náà, ká sì fara dà á dópin tá a bá fẹ́ rí èrè tí Jèhófà ṣèlérí gbà.—Mát. 24:13.
2. Kí nìdí tí ẹnu Pọ́ọ̀lù fi gba ọ̀rọ̀ tó sọ nínú 2 Tímótì 4:7, 8?
2 Ẹnu Pọ́ọ̀lù gba ọ̀rọ̀ tó sọ torí pé òun alára ti “sá eré ìje náà dé ìparí.” (Ka 2 Tímótì 4:7, 8.) Àmọ́, eré ìje wo ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ gan-an?
KÍ NI ERÉ ÌJE NÁÀ?
3. Eré ìje wo ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?
3 Àwọn ìgbà kan wà tí Pọ́ọ̀lù lo àwọn eré tí wọ́n máa ń ṣe nílẹ̀ Gíríìsì àtijọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. (1 Kọ́r. 9:25-27; 2 Tím. 2:5) Kódà nínú ìwé tó kọ sáwọn ìjọ kan, ó fi ìgbésí ayé àwa Kristẹni wé ti àwọn sárésáré. (1 Kọ́r. 9:24; Gál. 2:2; Fílí. 2:16) Ìgbà tẹ́nì kan bá ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tó sì ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ eré ìje náà. (1 Pét. 3:21) Ìgbà tí Jèhófà bá fún onítọ̀hún ní èrè ìyè àìnípẹ̀kun ló tó sá eré náà dópin.—Mát. 25:31-34, 46; 2 Tím. 4:8.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Báwo ni ìgbésí ayé àwa Kristẹni ṣe jọra pẹ̀lú tàwọn tó ń sáré ọlọ́nà jíjìn? Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n fi jọra. Ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára wọn. Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ gba ọ̀nà tó tọ́, ìkejì, a gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ ibi tá à ń lọ ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà àti ìkẹta, a gbọ́dọ̀ lè fara da àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó yọjú.
GBA Ọ̀NÀ TÓ TỌ́
5. Ojú ọ̀nà wo ni gbogbo wa gbọ́dọ̀ gbà, kí sì nìdí?
5 Kí àwọn sárésáré tó lè rí ẹ̀bùn eré ìje náà gbà, wọ́n gbọ́dọ̀ gba ojú ọ̀nà táwọn tó ṣètò eré ìje náà ní kí wọ́n gbà. Lọ́nà kan náà, káwa Kristẹni tó lè rí èrè ìyè àìnípẹ̀kun gbà, a gbọ́dọ̀ tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Kristi fi lélẹ̀. (Ìṣe 20:24; 1 Pét. 2:21) Àmọ́, Sátánì àtàwọn tó ń ṣèfẹ́ rẹ̀ kò fẹ́ ká máa tọ ọ̀nà yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n fẹ́ ká máa ṣe bíi tiwọn. (1 Pét. 4:4) Wọ́n ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ pé ìgbésí ayé wa kò nítumọ̀, pé tiwọn ló sàn jù torí pé àwọn wà lómìnira. Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ kì í ṣòótọ́.—2 Pét. 2:19.
6. Kí lo rí kọ́ látinú ìrírí Brian?
6 Kì í pẹ́ tẹ́ni tó bá ń fara wé àwọn èèyàn ayé èṣù yìí fi máa ń mọ̀ pé wọn ò lómìnira rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹrú Sátánì ni wọ́n. (Róòmù 6:16) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Brian. Àtikékeré làwọn òbí rẹ̀ ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì jẹ́ kó mọ ọ̀nà tó yẹ kó máa rìn. Àmọ́ nígbà tó di ọ̀dọ́, ó ronú pé òun ò ní gbádùn ara òun tóun bá ń tọ ọ̀nà tí wọ́n kọ́ òun. Brian pinnu pé ìgbésí ayé táwọn èèyàn inú ayé ń gbé lòun á máa gbé. Ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé ṣe ni irú òmìnira tí mò ń wá yìí máa jẹ́ kí n sọ ìwàkiwà di bárakú. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mò ń mu ọtí àmujù, mo sì ń ṣe ìṣekúṣe. Láàárín ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn oògùn olóró tó tún le ju àwọn tí mò ń lò tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì di bárakú fún mi. . . . Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ta oògùn olóró kí n lè máa rí owó ra àwọn nǹkan tó ti di bárakú fún mi yìí.” Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Brian bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò. Ó yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2001. Ní báyìí, ṣe ni inú ẹ̀ ń dùn torí pé ó ń rìn ní ọ̀nà tó tọ́.b
7. Bó ṣe wà nínú Mátíù 7:13, 14, ọ̀nà méjì wo ló wà níwájú wa?
7 Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tọ ọ̀nà tó tọ́! Sátánì fẹ́ kí gbogbo wa ṣíwọ́ rírìn lójú ọ̀nà tó há èyí “tó lọ sí ìyè” ká sì bọ́ sí ọ̀nà gbòòrò, ìyẹn ọ̀nà tí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ayé yìí ń rìn. Ọ̀nà gbòòrò yìí làwọn èèyàn mọ̀ jù, ó sì rọrùn láti rìn. Àmọ́ Bíbélì sọ pé ó “lọ sí ìparun.” (Ka Mátíù 7:13, 14.) Tá a bá fẹ́ máa rìn nìṣó lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè ká má sì kúrò níbẹ̀, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ká sì máa tẹ́tí sí i.
TẸJÚ MỌ́ IBI TÓ Ò Ń LỌ MÁ SÌ JẸ́ KÍ OHUNKÓHUN GBÉ Ẹ ṢUBÚ
8. Bí sárésáré kan bá ṣubú, kí ló máa ṣe?
8 Àwọn tó máa ń kópa nínú eré ọlọ́nà jíjìn máa ń tẹjú mọ́ ọ̀kánkán ibi tí wọ́n ń lọ kí wọ́n má bàa ṣubú. Àmọ́, ẹni tí wọ́n jọ ń sáré lè gbé wọn ṣubú láìmọ̀ọ́mọ̀ tàbí kí wọ́n já sí kòtò tàbí gegele. Tó bá tiẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ṣubú, ṣe ni wọ́n máa ń dìde tí wọ́n á sì tún máa sáré lọ. Kì í ṣe ohun tó gbé wọn ṣubú ló máa ń gbà wọ́n lọ́kàn bí kò ṣe bí wọ́n ṣe máa sáré náà parí tí wọ́n á sì gba èrè náà.
9. Tá a bá kọsẹ̀ tàbí ṣubú, kí ló yẹ ká ṣe?
9 Nínú eré ìje tá à ń sá, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kọsẹ̀, tá a sì máa ń ṣàṣìṣe lọ́rọ̀ àti níṣe. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn tá a jọ ń sáré ìje náà ló ṣe ohun tó dùn wá. Kò sí kírú ẹ̀ má ṣẹlẹ̀. Aláìpé ni gbogbo wa, bẹ́ẹ̀ la sì jọ wà lójú ọ̀nà tó há èyí tó lọ sí ìyè. Torí náà, kò sí bá ò ṣe ní máa “kọ lu” ara wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ìgbà míì wà tá a máa “ní ìdí láti fẹ̀sùn kan ẹlòmíì.” (Kól. 3:13) Àmọ́ dípò ká máa ronú nípa ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa, ẹ jẹ́ ká tẹjú mọ́ èrè tó wà níwájú. Tẹ́nì kan bá mú wa kọsẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá dìde, àá sì máa bá eré ìje náà lọ. Tá a bá bínú tá ò sì sáré mọ́, a ò ní lè parí eré ìje náà, a ò sì ní rí èrè gbà. Yàtọ̀ síyẹn, a lè fa ìdíwọ́ fáwọn míì tó ń gbìyànjú láti sáré lójú ọ̀nà tó há náà.
10. Kí la lè ṣe tá ò fi ní jẹ́ “ohun ìkọ̀sẹ̀” fáwọn míì?
10 Ohun kan tá a lè ṣe tá ò fi ní jẹ́ “ohun ìkọ̀sẹ̀” fáwọn tá a jọ ń sáré ìje ìyè yìí ni pé ká ṣe tán láti gba èrò wọn nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀ dípò tá a fi máa rin kinkin mọ́ èrò tiwa. (Róòmù 14:13, 19-21; 1 Kọ́r. 8:9, 13) Kókó yìí ló mú ká yàtọ̀ sí àwọn sárésáré inú ayé. Ṣe ni wọ́n máa ń bára wọn díje tí olúkúlùkù á sì máa wá bí òun á ṣe gbégbá orókè. Tara wọn nìkan ni wọ́n máa ń rò. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń ti àwọn míì kó lè jẹ́ pé àwọn ló máa wà níwájú. Àmọ́ àwa Kristẹni kì í bára wa díje. (Gál. 5:26; 6:4) Ohun tó jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ ká lè jọ sá eré náà dópin ká sì jọ rí èrè ìyè náà gbà. Ìdí nìyẹn tá a fi ń sa gbogbo ipá wa ká lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé ká máa “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe [tiwa] nìkan.”—Fílí. 2:4.
11. Kí lohun míì tó máa ń jẹ àwọn sárésáré lógún, kí sì nìdí?
11 Ní àfikún sí wíwo ọ̀kánkán ibi tí wọ́n ń lọ, ohun míì tó máa ń jẹ àwọn sárésáré lógún ni bí wọ́n ṣe máa sáré náà dé òpin. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n ń lọ náà ṣì lè jìnnà, wọ́n á máa fojú inú wo bí wọ́n á ṣe sá eré náà parí tí wọ́n á sì gba ẹ̀bùn. Ẹ̀bùn tí wọ́n máa gbà yẹn máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ eré náà láìṣàárẹ̀.
12. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa?
12 Nínú eré ìje ìyè tá à ń sá yìí, Jèhófà fi dá wa lójú pé òun máa san èrè ńlá fún wa tá a bá sáré náà dópin. Ó ṣèlérí pé òun á fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun yálà ní ọ̀run tàbí nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ìwé Mímọ́ sọ bí ọjọ́ iwájú náà ṣe máa rí ká lè mọ bí ìgbésí ayé wa ṣe máa dùn tó. Tá a bá ń ronú nípa èrè ọjọ́ iwájú yìí, tí ohunkóhun bá tiẹ̀ mú wa kọsẹ̀ a ò ní jẹ́ kó dí wa lọ́wọ́ àtisáré náà dópin.
MÁA BÁ ERÉ ÌJE NÁÀ LỌ LÁÌKA ÀWỌN ÌṢÒRO TÓ O NÍ SÍ
13. Àǹfààní wo la ní táwọn sárésáré ò ní?
13 Onírúurú ìṣòro làwọn sárésáré ilẹ̀ Gíríìsì àtijọ́ máa ń ní. Bí àpẹẹrẹ, ó lè rẹ̀ wọ́n, ara sì lè máa ro wọ́n. Àmọ́ gbogbo ohun tí wọ́n gbára lé kò ju ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà àti okun tí wọ́n ní. Bíi tiwọn, àwa náà gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe máa sá eré ìje ìyè náà. Àmọ́ a ní àǹfààní kan táwọn sárésáré yẹn ò ní. A lè gbára lé Jèhófà tó jẹ́ orísun agbára tí kò láfiwé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé Jèhófà máa dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nìkan, á tún mú ká túbọ̀ lágbára!—1 Pét. 5:10.
14. Báwo lọ̀rọ̀ inú 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10 ṣe lè mú ká fara da ìṣòro?
14 Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni Pọ́ọ̀lù kojú. Yàtọ̀ sí pé àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ burúkú sí i tí wọ́n sì ṣenúnibíni sí i, àwọn ìgbà kan wà tó rẹ̀ ẹ́ tó sì tún fara da ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ara rẹ̀.’ (2 Kọ́r. 12:7) Àmọ́ dípò tó fi máa jẹ́ káwọn ìṣòro yẹn mú kóun juwọ́ sílẹ̀, ṣe ló kà á sí àǹfààní láti túbọ̀ gbára lé Jèhófà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.) Torí pé Pọ́ọ̀lù gbára lé Jèhófà tí kò sì juwọ́ sílẹ̀, Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti fara da gbogbo ìṣòro tó ní.
15. Tá a bá fara wé Pọ́ọ̀lù, àǹfààní wo la máa rí?
15 Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ burúkú sí wa tàbí kí wọ́n ṣenúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́. Nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá tàbí ká máa ṣàìsàn. Àmọ́ tá a bá fara wé Pọ́ọ̀lù, àá ka àwọn ìṣòro yẹn sí àǹfààní láti túbọ̀ gbára lé Jèhófà pẹ̀lú ìdánilójú pé á ràn wá lọ́wọ́.
16. Kí lo lè ṣe ká tiẹ̀ ní ara rẹ ò le?
16 Ṣé ìdùbúlẹ̀ àìsàn lo wà tàbí kẹ̀kẹ́ arọ ni wọ́n fi ń tì ẹ́ kiri? Ṣé orúnkún rẹ ni kì í jẹ́ kó o rìn bó o ṣe fẹ́ àbí o kì í ríran dáadáa? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ wàá lè bá àwọn ọ̀dọ́ tí ara wọn ń ta kébékébé sáré? Ó dájú pé o lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tó ti dàgbà tára wọn ò sì le ló ń sáré lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Agbára wọn nìkan kò tó láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Wọ́n ń rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà bí wọ́n ṣe ń gbádùn àwọn ìpàdé ìjọ látorí fóònù tàbí fídíò. Wọ́n ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn bí wọ́n ṣe ń wàásù fáwọn ìbátan wọn, àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì.
17. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn aláìlera?
17 Má ṣe jẹ́ kí àìlera rẹ mú kó o rẹ̀wẹ̀sì débi tí wàá fi ronú pé bóyá ni wàá lè fara da eré ìje náà dópin. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ gan-an torí pé o nígbàgbọ́ nínu rẹ̀, ó sì mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe látọdún yìí wá. Àsìkò yìí gan-an lo nílò ìrànwọ́ rẹ̀, kò sì ní pa ọ́ tì láé. (Sm. 9:10) Kódà, ṣe lá túbọ̀ sún mọ́ ẹ. Gbọ́ ohun tí arábìnrin kan tó ń ṣàìsàn sọ, ó ní: “Bí àwọn àìsàn tó ń ṣe mí ṣe ń pọ̀ sí i, mo wá rí i pé bẹ́ẹ̀ ni àǹfààní tí mo ní láti wàásù túbọ̀ ń dín kù. Àmọ́ mo mọ̀ pé ìwọ̀nba tí mò ń ṣe ń múnú Jèhófà dùn, ìyẹn sì ń fún èmi náà láyọ̀.” Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì, rántí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ. Máa rántí àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, kó o sì fi ọ̀rọ̀ tó sọ sọ́kàn pé: “Mò ń láyọ̀ nínú àìlera, . . . torí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, ìgbà náà ni mo di alágbára.”—2 Kọ́r. 12:10.
18. Àwọn ìṣòro tó nira wo làwọn kan ń kojú?
18 Ìṣòro míì làwọn kan lára àwọn tá a jọ ń sá eré ìje ìyè yìí ní. Àwọn nìkan ló mọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí, àwọn míì ò mọ̀ ọ́n torí pé ìṣòro náà kò hàn sójú táyé. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àníyàn ló bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìṣòro táwọn ará wa yìí ní nira? Ìdí ni pé tẹ́nì kan bá kán lápá tàbí tó wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ, àwọn èèyàn á rí i, wọ́n á sì lè ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, ó lè má hàn lójú ẹni tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ìdààmú ọkàn pé onítọ̀hún níṣòro. Bí ọ̀rọ̀ ẹni tó kán lápá tàbí tó dá lẹ́sẹ̀ ṣe rí náà nìṣòro wọn rí, àmọ́ torí pé àwọn èèyàn ò rí ìṣòro tí wọ́n ní, wọ́n lè má ràn wọ́n lọ́wọ́.
19. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Méfíbóṣétì?
19 Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn èèyàn ò lóye àìsàn tó ń ṣe ẹ́, àpẹẹrẹ Méfíbóṣétì máa fún ẹ níṣìírí. (2 Sám. 4:4) Ó ní àìlera tó ń bá yí, yàtọ̀ síyẹn Ọba Dáfídì tún dá a lẹ́jọ́ láìgbọ́ tẹnu ẹ̀. Kì í ṣe Méfíbóṣétì ló fà á táwọn ìṣòro yẹn fi dé bá a. Síbẹ̀, kò jẹ́ káwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i yẹn mú kó ṣinú rò, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn nǹkan rere tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ̀ ló gbájú mọ́. Ó mọyì oore tí Dáfídì ti ṣe fún un sẹ́yìn. (2 Sám. 9:6-10) Torí náà, nígbà tí Dáfídì dá a lẹ́jọ́ láìgbọ́ tẹnu ẹ̀, Méfíbóṣétì fòye gbé ohun tó ṣẹlẹ̀. Kò jẹ́ kí àṣìṣe tí Dáfídì ṣe mú kí òun ṣinú rò. Kò sì dá Jèhófà lẹ́bi nítorí ohun tí Dáfídì ṣe. Ohun tó gbà á lọ́kàn ni bó ṣe máa ṣètìlẹyìn fún ọba tí Jèhófà yàn sípò. (2 Sám. 16:1-4; 19:24-30) Jèhófà jẹ́ kí wọ́n kọ ìtàn Méfíbóṣétì sílẹ̀ sínú Ìwé Mímọ́ ká lè rí ẹ̀kọ́ kọ́.—Róòmù 15:4.
20. Ìṣòro wo làwọn kan ní, kí ló sì yẹ kó dá wọn lójú?
20 Ìṣòro tàbí àníyàn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan ní tún yàtọ̀. Ìṣòro náà ni pé ara wọn kì í balẹ̀ tí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń nira fún wọn tí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn, síbẹ̀ wọ́n máa ń wá sáwọn ìpàdé, àpéjọ àyíká àti ti agbègbè. Kì í rọrùn fún wọn láti bá ẹni tí wọn ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀, síbẹ̀ wọ́n máa ń lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì ń wàásù fáwọn èèyàn. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn, máa rántí pé ó ti ṣe àwọn kan bẹ́ẹ̀ rí. Bákan náà, àwọn kan wà láàárín wa tí wọ́n ṣì ń bá irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ yí. Fi sọ́kàn pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀. Bó o ṣe ń bá a lọ láìbọ́hùn jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà ń tì ẹ́ lẹ́yìn àti pé òun ló ń fún ẹ lágbára tó o nílò.c (Fílí. 4:6, 7; 1 Pét. 5:7) Bó o ṣe ń bá a lọ láti máa jọ́sìn Jèhófà láìka ti àìlera tàbí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní sí, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà ń dùn sí ẹ.
21. Kí ni gbogbo wa pátá máa lè ṣe lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà?
21 A mà dúpẹ́ o pé ìyàtọ̀ wà láàárín eré táwọn sárésáré ń sá àtèyí tí Pọ́ọ̀lù sọ pé àwa Kristẹni ń sá. Bí àpẹẹrẹ, lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹnì kan péré lára àwọn sárésáré ló máa ń gba ẹ̀bùn. Àmọ́ gbogbo ẹni tó bá fara da eré ìje ìyè yìí dópin ló máa gba ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 3:16) Ní ti àwọn sárésáré inú ayé, gbogbo wọn lara wọn gbọ́dọ̀ le, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ wọ́n lè má rí ẹ̀bùn náà gbà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ wa la ní àìlera tá à ń bá yí, síbẹ̀ à ń fara dà á. (2 Kọ́r. 4:16) Torí náà, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, gbogbo wa pátá la máa sá eré ìje ìyè yìí dópin!
ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà
a Ọ̀pọ̀ àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń fara da onírúurú ìṣòro bíi hẹ́gẹhẹ̀gẹ ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn tó le koko tó sì ń tánni lókun. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo wa ni nǹkan máa ń tojú sú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Torí náà, ó lè má rọrùn fún wa láti sáré. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí gbogbo wa ṣe lè fara dà á lẹ́nu eré ìje ìyè tá à ń sá, èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2013.
c Tó o bá tún ń fẹ́ ìmọ̀ràn lórí bó o ṣe lè borí àníyàn àtàwọn ìrírí tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, wo ètò ti oṣù May 2019 lórí ìkànnì jw.org®. Wo abẹ́ OHUN TÁ A NÍ > JW BROADCASTING®.
d ÀWÒRÁN: Bí arákùnrin àgbàlagbà yìí ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òun dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù mú kó lè máa bá eré ìje ìyè náà nìṣó.
e ÀWÒRÁN: A lè mú àwọn míì kọsẹ̀ tá a bá ń rọ̀ wọ́n ṣáá pé kí wọ́n túbọ̀ mu ọtí tàbí táwa ò bá lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ọtí mímu.
f ÀWÒRÁN: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé ìwòsàn ni arákùnrin yìí wà, ó ń bá eré ìje ìyè náà nìṣó bó ṣe ń wàásù fáwọn tó ń tọ́jú rẹ̀.