ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 52
Bó O Ṣe Lè Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
“Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró.”—SM. 55:22.
ORIN 33 Ju Ẹrù Rẹ Sọ́dọ̀ Jèhófà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?
OJOOJÚMỌ́ la máa ń kojú ìṣòro, a sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro náà. Àmọ́, ó lè má rọrùn láti yanjú àwọn ìṣòro yìí tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. Torí náà, kò yẹ ká fàyè gba ìrẹ̀wẹ̀sì. Tá a bá fàyè gbà á, a ò ní ní ìgboyà láti kojú àwọn ìṣòro wa, a ò sì ní láyọ̀. Òwe 24:10 sọ pé: “Tí o bá rẹ̀wẹ̀sì ní ọjọ́ wàhálà, agbára rẹ ò ní tó nǹkan.” Òótọ́ ni, tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, a lè má ní okun tàbí agbára láti fara da àwọn ìṣòro wa.
2. Kí ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Onírúurú nǹkan ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, ó lè jẹ́ ìṣòro ara ẹni tàbí àwọn nǹkan míì. Lára wọn ni àìpé wa, àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa àti àìsàn. A tún lè rẹ̀wẹ̀sì tí ọwọ́ wa ò bá tẹ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá tàbí tí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ò bá méso jáde. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì.
ÀÌPÉ ÀTI KÙDÌẸ̀-KUDIẸ WA
3. Kí ni ò ní jẹ́ ká ro ara wa pin nítorí àìpé wa?
3 Tá ò bá ṣọ́ra, a lè ro ara wa pin nítorí àìpé àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. Kódà, ìyẹn lè mú ká ronú pé kì í ṣe irú wa ni Jèhófà máa jẹ́ kó wọnú ayé tuntun. Irú èrò yìí léwu gan-an. Ojú wo ló yẹ ká fi máa wo àìpé wa? Bíbélì sọ pé “gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀” àfi Jésù nìkan. (Róòmù 3:23) Àmọ́ o, kì í ṣe pé Baba wa ọ̀run ń wá ibi tá a kù sí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò retí pé ká jẹ́ ẹni pípé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún ń mú sùúrù fún wa. Ó rí bá a ṣe ń sapá, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ká má sì ro ara wa pin.—Róòmù 7:18, 19.
4-5. Báwo lohun tó wà nínú 1 Jòhánù 3:19, 20 ṣe ran àwọn arábìnrin méjì kan lọ́wọ́ tí ìrẹ̀wẹ̀sì ò fi bò wọ́n mọ́lẹ̀?
4 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Deborah àti Maria.b Nígbà tí Deborah wà ní kékeré, àwọn ìdílé ẹ̀ kì í rí tiẹ̀ rò rárá, wọn kì í sì í gbóríyìn fún un. Ìyẹn wá mú kó máa ro ara ẹ̀ pin. Kódà kó jẹ́ àṣìṣe kékeré ló ṣe, ṣe ló máa ń ronú pé kò sí nǹkan ire tóun mọ̀ ọ́n ṣe láyé òun. Irú ìṣòro yìí ni Maria náà ní, ńṣe làwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ máa ń dójú tì í ṣáá. Ìyẹn mú kó máa ronú pé òun ò wúlò. Kódà lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó máa ń ronú pé kì í ṣe irú òun ló yẹ kó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
5 Síbẹ̀, àwọn arábìnrin yìí ò fi Jèhófà sílẹ̀. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Ohun kan ni pé wọ́n gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà, wọ́n sì fi gbogbo ìṣòro wọn lé e lọ́wọ́. (Sm. 55:22) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n rí i pé Baba wa ọ̀run mọ ohun tí ojú wa ti rí sẹ́yìn, ó sì mọ báwọn nǹkan yẹn ṣe máa ń bà wá nínú jẹ́. Bákan náà, Baba wa ọ̀run máa ń rí ibi tí a dáa sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò wúlò.—Ka 1 Jòhánù 3:19, 20.
6. Èrò wo lẹnì kan tó ń ṣe àṣìṣe kan náà lè ní nípa ara ẹ̀?
6 Ẹnì kan tó ti ń sapá láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ kan lè tún ṣe àṣìṣe kan náà, ìyẹn sì lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí tínú ẹ̀ ò ní bà jẹ́. (2 Kọ́r. 7:10) Àmọ́, kò yẹ ká ro ara wa pin ká wá máa ronú pé: ‘Mi ò wúlò rárá. Bóyá ni Jèhófà á lè dárí jì mí.’ Irú èrò yìí ò tọ̀nà rárá, tá ò bá sì ṣọ́ra, ó lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. Ẹ rántí ohun tó wà nínú Òwe 24:10 pé agbára wa máa kéré jọjọ tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. Dípò tá a fi máa ro ara wa pin, ṣe ló yẹ ká gbàdúrà sí Jèhófà, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú wa kí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ lè pa dà gún régé. (Àìsá. 1:18) Tí Jèhófà bá rí i pé o ronú pìwà dà tọkàntọkàn, á dárí jì ẹ́. Láfikún sí i, tọ àwọn alàgbà lọ, wọ́n á fìfẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kọ́fẹ pa dà nípa tẹ̀mí.—Jém. 5:14, 15.
7. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tó bá ń ṣòro fún wa láti ṣe ohun tó tọ́?
7 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Jean-Luc lórílẹ̀-èdè Faransé máa ń sọ fún àwọn tó ń sapá láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ wọn pé: “Ẹni tí Jèhófà kà sí olódodo kì í ṣe ẹni tí kì í ṣàṣìṣe. Àmọ́, ó jẹ́ ẹni tó máa ń banú jẹ́ tó bá ṣàṣìṣe tó sì máa ń ronú pìwà dà.” (Róòmù 7:21-25) Torí náà, má ṣe ro ara ẹ pin tó o bá láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan tó ò ń bá yí. Ká máa rántí pé, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run nípasẹ̀ ìràpadà ni Jèhófà ń wò mọ́ wa lára tó fi kà wá sí olódodo, kì í ṣe nípa iṣẹ́ rere èyíkéyìí tá a ṣe.—Éfé. 1:7; 1 Jòh. 4:10.
8. Àwọn wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá rẹ̀wẹ̀sì?
8 Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lè ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n máa tẹ́tí sí wa nígbà tá a bá ń tú ọkàn wa jáde, wọ́n sì máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ táá gbé wa ró. (Òwe 12:25; 1 Tẹs. 5:14) Arábìnrin Joy lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tóun náà máa ń rẹ̀wẹ̀sì sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ará, ìrẹ̀wẹ̀sì ì bá ti bò mí mọ́lẹ̀. Báwọn ará ṣe ràn mí lọ́wọ́ mú kó dá mi lójú pé Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Kódà, wọ́n ti jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè fún àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí.” Àmọ́ o, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn ará wa lè má mọ̀gbà tá a nílò ìṣírí. Torí náà, ó lè gba pé ká sún mọ́ àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tá à ń bá yí.
TÁ A BÁ Ń ṢÀÌSÀN
9. Ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ló wà nínú Sáàmù 41:3 àti 94:19?
9 Jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá wa tá a bá ń ṣàìsàn, pàápàá tó bá jẹ́ àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lè má wò wá sàn lọ́nà ìyanu, ó ń tù wá nínú, ó sì ń fún wa lókun ká lè fara da àìsàn tó ń ṣe wá. (Ka Sáàmù 41:3; 94:19.) Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú kí àwọn ará ìjọ wá bá wa ṣe iṣẹ́ ilé tàbí kí wọ́n bá wa ra àwọn nǹkan tá a nílò. Ó lè mú kí wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú wa, ó sì lè mú ká rántí àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká rántí bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun níbi tá ò ti ní máa ṣàìsàn, tí kò sì ní sí ìrora èyíkéyìí mọ́.—Róòmù 15:4.
10. Kí ni Isang ṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì ò fi bò ó mọ́lẹ̀ lẹ́yìn tó ní ìjàǹbá ọkọ̀?
10 Isang tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ìjàǹbá ọkọ̀, ìyẹn sì mú kó rọ lẹ́sẹ̀. Dókítà tó ń tọ́jú ẹ̀ sọ fún un pé kò ní lè rìn mọ́ láé. Isang sọ pé: “Ẹ̀dùn ọkàn bá mi, ìbànújẹ́ sì dorí mi kodò.” Àmọ́ ṣé ìrẹ̀wẹ̀sì yẹn wá bò ó mọ́lẹ̀? Rárá o! Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi ò dákẹ́ àdúrà, ìgbà gbogbo la sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A tún pinnu pé àá máa dúpẹ́ oore tí Jèhófà ṣe fún wa, títí kan ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun.”
11. Kí ni Cindy ṣe tó mú kó láyọ̀ nígbà tó ń ṣàìsàn tó le?
11 Àwọn dókítà sọ fún Cindy tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò pé àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí ló ní. Kí ló ṣe tí ò fi rẹ̀wẹ̀sì? Ní gbogbo àsìkò tó fi ń gba ìtọ́jú, ó pinnu pé òun á máa wàásù lójoojúmọ́. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń wàásù fáwọn míì mú kí n gbọ́kàn kúrò lórí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún mi àti ìrora tí mo ní. Bí mo ṣe máa ń ṣe é nìyí: Tí mo bá ń bá àwọn dókítà tàbí àwọn nọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀, mo máa ń béèrè àlàáfíà wọn àti ti ìdílé wọn. Màá wá bi wọ́n pé, kí nìdí tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ yìí ni wọ́n yàn láàyò. Ohun tí wọ́n bá sọ ló máa jẹ́ kí n mọ ohun tí mo lè bá wọn sọ táá wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi gan-an, wọ́n á sì sọ pé ó ṣọ̀wọ́n kí aláìsàn tó béèrè àlàáfíà àwọn. Kódà, àwọn kan fún mi ní àdírẹ́sì ilé wọn àti nọ́ńbà fóònù wọn. Torí náà, ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira fún mi yìí, Jèhófà mú kí n láyọ̀. Kódà, ó ya èmi fúnra mi lẹ́nu!”—Òwe 15:15.
12-13. Báwo ni àwọn kan tó ń ṣàìsàn tàbí tí wọn ò lè jáde nílé ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, àṣeyọrí wo ni wọ́n sì ṣe?
12 Ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí tí ò lè jáde nílé torí pé ìwọ̀nba ni wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn ló ti wá ọ̀nà láti wàásù. Àpẹẹrẹ kan ni ti arábìnrin kan tó ń jẹ́ Laurel lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ní onírúurú ìṣòro. Ó ní àrùn jẹjẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ṣe iṣẹ́ abẹ, kòkòrò sì bo ara ẹ̀. Kódà, ẹ̀rọ ló fi ń mí fún odindi ọdún mẹ́tàdínlógójì (37)! Àmọ́ àwọn ìṣòro yìí ò ní kó má wàásù. Bó ṣe ń wàásù fáwọn nọ́ọ̀sì náà ló ń wàásù fáwọn tó ń tọ́jú rẹ̀ nínú ilé. Kí lèyí yọrí sí? Ó kéré tán, àwọn mẹ́tàdínlógún (17) ló ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!c
13 Alàgbà kan lórílẹ̀-èdè Faransé tó ń jẹ́ Richard sọ àwọn nǹkan tí àwọn tí kò lè jáde nílé àtàwọn tí wọ́n wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó lè ṣe. Ó sọ pé: “Mo máa ń sọ fún wọn pé kí wọ́n ní ibì kan tí wọ́n lè pàtẹ àwọn ìwé wa sí. Ìpàtẹ ìwé yìí máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra, ìyẹn sì lè mú kí wọ́n béèrè ìbéèrè. Èyí máa ń mú kó ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí kò lè jáde nílé láti máa wàásù.” Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tí ò lè jáde nílé lè kọ lẹ́tà tàbí kí wọ́n fi tẹlifóònù wàásù.
TÁ Ò BÁ NÍ ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN TÓ WÙ WÁ
14. Kí la rí kọ́ lára ohun tí Ọba Dáfídì ṣe?
14 A lè má ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan nínú ìjọ tàbí ní àyíká bóyá nítorí ọjọ́ orí wa, ìlera wa tàbí àwọn nǹkan míì. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Ọba Dáfídì. Ó wu Dáfídì gan-an pé kó kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n sọ fún un pé òun kọ́ ló máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà, kò rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kọ́wọ́ ti ẹni tí Jèhófà yàn. Kódà, ọ̀pọ̀ wúrà àti fàdákà ló fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún wa.—2 Sám. 7:12, 13; 1 Kíró. 29:1, 3-5.
15. Báwo ni Arákùnrin Hugues ṣe borí ìrẹ̀wẹ̀sì?
15 Àìsàn tó ń ṣe Arákùnrin Hugues lórílẹ̀-èdè Faransé ló mú kó fi iṣẹ́ alàgbà sílẹ̀. Kódà, ó ṣòro fún un gan-an láti ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé. Ó sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, ìrẹ̀wẹ̀sì mú mi, mo sì ronú pé mi ò wúlò. Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá rí i pé á dáa kí n mohun tí agbára mi gbé, ìyẹn sì jẹ́ kí n máa láyọ̀ bí mo ti ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Torí náà, mo pinnu pé mi ò ní bọ́hùn bíi ti Gídíónì àtàwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, wọn ò juwọ́ sílẹ̀.”—Oníd. 8:4.
16. Kí la rí kọ́ lára àwọn áńgẹ́lì?
16 Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ jẹ́ fún wa. Nígbà ìṣàkóso Ọba Áhábù, Jèhófà pe àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n rò pé àwọn á lè gbà tan ọba burúkú náà. Onírúurú àbá làwọn áńgẹ́lì yẹn mú wá. Àmọ́ Jèhófà wá yan ọ̀kan lára wọn, ó sì sọ fún un pé àbá tiẹ̀ máa yọrí sí rere. (1 Ọba 22:19-22) Ṣé àwọn áńgẹ́lì yòókù wá rẹ̀wẹ̀sì, bóyá kí wọ́n máa ronú pé, ‘Ká ní mo mọ̀ ni, mi ò bá ti dákẹ́.’ Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ronú bẹ́ẹ̀. Onírẹ̀lẹ̀ làwọn áńgẹ́lì, bí wọ́n sì ṣe máa gbógo fún Jèhófà ló jẹ wọ́n lógún.—Oníd. 13:16-18; Ìfi. 19:10.
17. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé a ò ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá?
17 Mọyì àǹfààní tá a ní pé à ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà, a sì ń kéde Ìjọba rẹ̀. A lè ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan lónìí, ká má sì ní in mọ́ lọ́la. Àmọ́, kì í ṣe àwọn àǹfààní yìí ló mú ká ṣeyebíye lójú Jèhófà. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, Jèhófà máa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, àwọn ará náà sì máa nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó o sì mọ̀wọ̀n ara ẹ. Máa ronú lórí àpẹẹrẹ àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn nínú Bíbélì. Múra tán láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ará ní gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe.—Sm. 138:6; 1 Pét. 5:5.
TÍ ÌPÍNLẸ̀ ÌWÀÁSÙ YÍN Ò BÁ MÉSO JÁDE
18-19. Kí lá jẹ́ kó o láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ bí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ò bá tiẹ̀ méso jáde?
18 Ǹjẹ́ a rígbà kan tó o rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ò méso jáde tàbí nítorí pé ẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ bá àwọn èèyàn nílé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o láyọ̀? Wàá rí àwọn àbá tó o lè fi sílò nínú àpótí tá a pè ní “Ohun Táá Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Méso Jáde.” Ó tún ṣe pàtàkì ká ní èrò tó tọ́ nípa iṣẹ́ ìwàásù wa. Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
19 Fi sọ́kàn pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká kéde orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ fáwọn èèyàn. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn díẹ̀ ló máa rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè. (Mát. 7:13, 14) Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ ìwàásù mú ká láǹfààní láti máa bá Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́. (Mát. 28:19, 20; 1 Kọ́r. 3:9; Ìfi. 14:6, 7) Bákan náà, Jèhófà ló máa ń fa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀. (Jòh. 6:44) Torí náà, tẹ́nì kan ò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa nígbà àkọ́kọ́, ó lè tẹ́tí sí wa nígbà míì.
20. Kí ni Jeremáyà 20:8, 9 sọ tó lè mú ká borí ìrẹ̀wẹ̀sì?
20 A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wòlíì Jeremáyà. Àwọn èèyàn tí Jèhófà rán an sí kò tẹ́tí sí i rárá àti rárá. Ṣe làwọn èèyàn náà ń bú u, tí wọ́n sì ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́ “láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.” (Ka Jeremáyà 20:8, 9.) Ìgbà kan wà tó rẹ̀wẹ̀sì tó sì ronú pé òun ò ní sọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́. Àmọ́, kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé “ọ̀rọ̀ Jèhófà” dà bí iná tó ń jó nínú Jeremáyà, kò sì lè pa á mọ́ra! Bó ṣe máa rí lára tiwa náà nìyẹn tá a bá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà lọ́kàn wa. Èyí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayọ̀ wa á máa pọ̀ sí i, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa á sì túbọ̀ méso jáde.—Jer. 15:16.
21. Báwo la ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì láìka ohun yòówù kó fà á?
21 Deborah tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Irinṣẹ́ tó lágbára ni ìrẹ̀wẹ̀sì jẹ́ lọ́wọ́ Sátánì.” Àmọ́, Jèhófà lágbára ju Sátánì àtàwọn nǹkan ìjà ogun ẹ̀ lọ. Torí náà, ohun yòówù kó mú kó o rẹ̀wẹ̀sì, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Á jẹ́ kó o lè fara da àìpé àti kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ, á dúró tì ẹ́ tó o bá ń ṣàìsàn. Á jẹ́ kó o lè máa fi ojú tó tọ́ wo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run, á sì jẹ́ kó o láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ fún Jèhófà Baba rẹ ọ̀run. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé lọ́lá ìtìlẹyìn Jèhófà, wàá borí ìrẹ̀wẹ̀sì.
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
a Gbogbo wa la máa ń rẹ̀wẹ̀sì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan pàtó tá a lè ṣe tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. A tún máa rí i pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c O lè ka ìtàn ìgbésí ayé Laurel Nisbet nínú Jí! January 22, 1993.
d ÀWÒRÁN: Ìgbà kan wà tí arábìnrin kan rẹ̀wẹ̀sì, àmọ́ ó ronú nípa ohun tó ti ṣe sẹ́yìn nínú ìjọsìn Jèhófà, ó sì gbàdúrà. Ó dá a lójú pé Jèhófà ò gbàgbé ohun tóun ṣe sẹ́yìn àtèyí tóun ń ṣe báyìí.