ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 11
Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lè Mú Kó O Fara Da Ìṣòro
“Ọlọ́run . . . ń fúnni ní ìfaradà.”—RÓÒMÙ 15:5.
ORIN 94 A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Irú àwọn ìṣòro wo làwa èèyàn Jèhófà máa ń kojú?
ṢÉ ÀWỌN ìṣòro kan wà tó ń bá ẹ fínra báyìí? Ṣé ẹnì kan nínú ìjọ ló ṣe ohun tó dùn ẹ́? (Jém. 3:2) Bóyá ẹnì kan níbi iṣẹ́ rẹ tàbí ọmọ ilé ìwé rẹ kan ló ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ò ń sin Jèhófà. (1 Pét. 4:3, 4) Ó sì lè jẹ́ pé àwọn ará ilé ẹ ló ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o má lọ sípàdé mọ́, kó o má sì wàásù mọ́. (Mát. 10:35, 36) Bí ìṣòro náà bá dójú ẹ̀ tán, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìṣòro yòówù kó máa bá ẹ fínra, Jèhófà máa fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ kó o lè fara dà á.
2. Àǹfààní wo ni Róòmù 15:4 sọ pé a máa rí tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
2 Jèhófà rí i dájú pé àpẹẹrẹ àwọn tó fara da ìṣòro wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ ohun tó wà nínú Róòmù 15:4. (Ka Róòmù 15:4.) Torí náà, tá a bá ń ka irú àwọn àkọsílẹ̀ yìí, á tù wá nínú, á sì jẹ́ ká nírètí. Àmọ́ o, kì í ṣe ká kàn máa ka Bíbélì, tá a bá máa jàǹfààní, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohun tá à ń kà wọ̀ wá lọ́kàn, kó sì yí èrò wa pa dà. Bí àpẹẹrẹ, kí la lè ṣe tá a bá ń wá ìtọ́sọ́nà nípa bá a ṣe lè fara da ìṣòro kan? A lè ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin tó tẹ̀ lé e yìí: (1) Máa gbàdúrà, (2) Máa fojú inú wo nǹkan, (3) Máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà àti (4) Máa fi ohun tó o kà sílò. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.b Lẹ́yìn náà, àá lo ìgbésẹ̀ mẹ́rin yìí láti kẹ́kọ̀ọ́ lára Ọba Dáfídì àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.
3. Kí ló yẹ kó o ṣe kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, kí sì nìdí?
3 (1) Máa gbàdúrà. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jàǹfààní látinú ohun tó o fẹ́ kà. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń ronú ohun tó o máa ṣe sí ìṣòro kan, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ìlànà táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Fílí. 4:6, 7; Jém. 1:5.
4. Kí lá jẹ́ kó o túbọ̀ lóye àwọn ìtàn inú Bíbélì?
4 (2) Máa fojú inú wo nǹkan. Jèhófà fún wa ní ẹ̀bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ni pé a lè fojú inú wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bá ò tiẹ̀ sí níbẹ̀. Kó o lè túbọ̀ lóye ìtàn Bíbélì kan, fojú inú wò ó pé o wà níbẹ̀ àti pé ìwọ gangan ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀ sí. Ṣe bí ẹni pé ò ń rí ohun tí ẹni náà ń rí, o sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀.
5. Báwo lo ṣe lè máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà?
5 (3) Máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà. Ó ṣe pàtàkì kó o máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà àti bó o ṣe lè fi ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò. Ìyẹn á jẹ́ kó o rí bó ṣe tan mọ́ ohun tó o mọ̀ tẹ́lẹ̀, á sì jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ohun tó ò ń kà. Tó o bá ń ka Bíbélì láìronú lórí ẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni tó kó èlò ọbẹ̀ sórí tábìlì láìsè é. Àmọ́ tó o bá ń ronú lórí ohun tó o kà, ṣe ló dà bí ìgbà tó o fi èlò náà se ọbẹ̀ aládùn. Kó o lè ronú lórí ohun tó ò ń kà, o lè bi ara ẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí lẹni tí mò ń kà nípa ẹ̀ yìí ṣe kó lè yanjú ìṣòro ẹ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́? Báwo làwọn nǹkan tí mo kọ́ nínú ìtàn yìí ṣe lè mú kí n fara da ìṣòro mi?’
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn nǹkan tá a kà sílò?
6 (4) Máa fi ohun tó o kà sílò. Jésù sọ pé tá ò bá fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ṣe la dà bí ọkùnrin kan tó kọ́ ilé ẹ̀ sórí iyẹ̀pẹ̀. Ó ṣiṣẹ́ kára lóòótọ́, àmọ́ àṣedànù ló ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ilé náà máa wó tí ìjì bá jà, tí àgbàrá omi sì rọ́ lù ú. (Mát. 7:24-27) Lọ́nà kan náà, tá a bá gbàdúrà, tá a fojú inú wo ohun tá à ń kà, tá a sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí àmọ́ tá ò fi ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò, ṣe la kàn fi àkókò wa ṣòfò. Tá a bá wá kojú àdánwò tàbí inúnibíni, a ò ní lè dúró. Lọ́wọ́ kejì, tá a bá kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì fohun tá a kọ́ sílò, àá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ọkàn wa máa balẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á sì lágbára. (Àìsá. 48:17, 18) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì, ká sì wo bá a ṣe lè lo àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́rin yìí láti fa àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ yọ.
KÍ LO LÈ KỌ́ LÁRA ỌBA DÁFÍDÌ?
7. Ìtàn Bíbélì wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?
7 Ṣé ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan ti dalẹ̀ rẹ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò ìtàn Ábúsálómù ọmọ Ọba Dáfídì. Ó dalẹ̀ bàbá rẹ̀, ó sì gbìyànjú láti gbàjọba mọ́ ọn lọ́wọ́.—2 Sám. 15:5-14, 31; 18:6-14.
8. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́?
8 (1) Gbàdúrà. Bó o ṣe ń ronú nípa ìtàn náà, sọ ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ ṣe sí ẹ fún Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. (Sm. 6:6-9) Sọ ohun tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ gan-an, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ìlànà táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro náà.
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárín Dáfídì àti Ábúsálómù?
9 (2) Fojú inú wo ohun tó ò ń kà. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn yìí, kó o sì fojú inú wo bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára Dáfídì. Nǹkan bí ọdún mẹ́rin ni Ábúsálómù ọmọ Dáfídì fi ń fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (2 Sám. 15:7) Nígbà tí àsìkò tó lójú Ábúsálómù, ó rán àwọn amí lọ sí gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì káwọn èèyàn náà lè sọ ọ́ di ọba. Kódà, ó fa ojú Áhítófẹ́lì tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn àti ọ̀rẹ́ Dáfídì mọ́ra, ìyẹn náà sì dara pọ̀ mọ́ ọn láti dìtẹ̀ sí Dáfídì. Lẹ́yìn náà, Ábúsálómù kéde pé òun ti di ọba, ó sì gbìyànjú láti pa Dáfídì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ṣeé ṣe kára Dáfídì má yá lásìkò yẹn. (Sm. 41:1-9) Nígbà tí Dáfídì gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn alátìlẹ́yìn Ábúsálómù kojú àwọn ọmọ ogun Dáfídì, àmọ́ àwọn ọmọ ogun Dáfídì ṣẹ́gun, wọ́n sì pa Ábúsálómù.
10. Kí ni ìṣòro náà lè mú kí Dáfídì ṣe?
10 Fojú inú wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe máa rí lára Dáfídì. Ó nífẹ̀ẹ́ Ábúsálómù, ó sì fọkàn tán Áhítófẹ́lì. Àmọ́, àwọn méjèèjì dalẹ̀ rẹ̀, kódà wọ́n gbìyànjú láti pa á. Ohun tí wọ́n ṣe yìí dun Dáfídì gan-an. Dáfídì lè ronú pé àwọn ọ̀rẹ́ òun tó kù ti dara pọ̀ mọ́ Ábúsálómù, kó má sì fọkàn tán wọn mọ́. Tó bá jẹ́ pé irú èrò tí Dáfídì ní nìyẹn, ó lè fẹ́ sá kúrò nílùú lóun nìkan, kó má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀ lé òun. Ó tún lè ro ara ẹ̀ pin, kó sì gbà pé ó ti tán fún òun. Àmọ́, Dáfídì ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣe ohun tó mú kó borí ìṣòro náà. Àwọn nǹkan wo ló ṣe?
11. Kí ni Dáfídì ṣe sí ìṣòro náà?
11 (3) Ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà. Kí lo rí kọ́ nínú ìtàn náà? Dáhùn ìbéèrè yìí, “Kí ni Dáfídì ṣe kó lè borí ìṣòro náà?” Dáfídì ò bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n jìnnìjìnnì, kó wá kánjú ṣèpinnu láìronú. Lọ́wọ́ kejì, kò jókòó gẹlẹtẹ torí pé ẹ̀rù ń bà á kó má sì gbé ìgbésẹ̀ kankan. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó ní káwọn ọ̀rẹ́ òun ran òun lọ́wọ́, ó sì gbé ìgbésẹ̀ láìjáfara lórí ìpinnu tó ṣe. Òótọ́ ni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dun Dáfídì gan-an, kò banú jẹ́ débi táá fi kórìíra gbogbo èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì fọkàn tán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́?
12 Báwo ni Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́? Tó o bá ṣèwádìí, wàá rí i pé Jèhófà fún Dáfídì lókun láti fara da ìṣòro náà. (Sm. 3:1-8; àkọlé) Bákan náà, Jèhófà mú kí àwọn ìpinnu tí Dáfídì ṣe yọrí sí rere. Ó sì ran àwọn tó dúró ti Dáfídì lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà.
13. Báwo lo ṣe lè fara wé Dáfídì tí ẹnì kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an? (Mátíù 18:15-17)
13 (4) Fi àwọn ohun tó o kà sílò. Bi ara ẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fara wé Dáfídì?’ Ó ṣe pàtàkì kó o tètè gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú ìṣòro náà. Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ lá pinnu bó o ṣe máa fi ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Mátíù orí 18 sílò. (Ka Mátíù 18:15-17.) Àmọ́ kò yẹ kó o kánjú ṣèpinnu nígbà tó o ṣì ń bínú. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o ní sùúrù, kó sì fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi yanjú ọ̀rọ̀ náà. Má ṣe tìtorí ohun tó ṣẹlẹ̀ pa àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Òwe 17:17) Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni kó o tẹ̀ lé.—Òwe 3:5, 6.
KÍ LO LÈ KỌ́ LÁRA PỌ́Ọ̀LÙ?
14. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ táá mú kó o ronú lórí 2 Tímótì 1:12-16; 4:6-11, 17-22?
14 Ṣé àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ ń ta kò ẹ́ torí pé ò ń sin Jèhófà? Ṣé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lò ń gbé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kó o ka 2 Tímótì 1:12-16 àti 4:6-11, 17-22.c Inú ẹ̀wọ̀n ni Pọ́ọ̀lù wà nígbà tó kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí.
15. Kí lo lè gbàdúrà fún?
15 (1) Gbàdúrà. Kó o tó ka àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, sọ ìṣòro ẹ fún Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó mọ bó ṣe rí lára ẹ. Sọ ohun tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe fún ẹ gan-an. Lẹ́yìn náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ìlànà tó wà nínú ìtàn Pọ́ọ̀lù táá jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè yanjú ìṣòro náà.
16. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù?
16 (2) Fojú inú wo ohun tó ò ń kà. Fojú inú wò ó pé ìwọ lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ṣẹlẹ̀ sí. Inú ẹ̀wọ̀n ló wà nílùú Róòmù. Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n nìyí, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ó dá a lójú pé wọ́n máa pa òun. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan ti pa á tì, kò sì lókun mọ́ lákòókò yẹn.—2 Tím. 1:15.
17. Kí ni ìṣòro náà lè mú kí Pọ́ọ̀lù ṣe?
17 Pọ́ọ̀lù lè ronú pé ká sọ pé òun ò lo ara òun tó bẹ́ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó ṣeé ṣe kóun má sí lẹ́wọ̀n. Ó ṣeé ṣe kó máa bínú sí àwọn ará tó wà ní Éṣíà torí wọ́n pa á tì, kó má sì fọkàn tán àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó kù mọ́. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ló jẹ́ kó lè fara dà á, kó sì gbà pé Jèhófà máa san òun lẹ́san?
18. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe sí ìṣòro náà?
18 (3) Ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kà. Dáhùn ìbéèrè yìí, “Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe sí ìṣòro tó ní?” Kódà nígbà tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé wọ́n máa pa òun, ohun tó ṣe pàtàkì sí i jù ni bó ṣe máa fògo fún Jèhófà. Bákan náà, ó tún ń ronú nípa bó ṣe lè fún àwọn míì níṣìírí. Kò fi mọ síbẹ̀ o, ó tún máa ń gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo. (2 Tím. 1:3) Dípò kó máa banú jẹ́ torí àwọn tó pa á tì, ṣe ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí àwọn ọ̀rẹ́ tó dúró tì í, tó sì ràn án lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù máa ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (2 Tím. 3:16, 17; 4:13) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó dá a lójú pé Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ òun, wọn ò pa òun tì, wọ́n sì máa san òun lẹ́san lọ́jọ́ iwájú.
19. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́?
19 Jèhófà ti sọ fún Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí i. (Ìṣe 21:11-13) Báwo ni Jèhófà ṣe ràn án lọ́wọ́? Jèhófà dáhùn àdúrà Pọ́ọ̀lù, nígbà tó sì yá, ó fún un lágbára. (2 Tím. 4:17) Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà máa san òun lẹ́san fún iṣẹ́ takuntakun tóun ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Bákan náà, Jèhófà mú kí àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù ràn án lọ́wọ́.
20. Kí ni Róòmù 8:38, 39 sọ pé ó jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù lè fara da ìṣòro? Báwo la ṣe lè fara wé e?
20 (4) Fi ohun tó o kà sílò. Bi ara ẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù?’ Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa náà mọ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́. (Máàkù 10:29, 30) Ká lè jẹ́ olóòótọ́ lójú àdánwò, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a lè ṣe ni pé ká máa fògo fún Jèhófà. Torí náà, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé, kò sì sóhun tí ẹnikẹ́ni lè ṣe táá mú kó pa wá tì.—Ka Róòmù 8:38, 39; Héb. 13:5, 6.
KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ MẸ́NU KÀN
21. Kí ló ran Aya àti Hector lọ́wọ́ láti borí ìṣòro tí wọ́n ní?
21 Ìṣòro yòówù ká ní, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Bí àpẹẹrẹ, aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Aya ní Japan sọ pé ìtàn Jónà ló mú kóun borí ìbẹ̀rù tóun ní láti wàásù níbi térò pọ̀ sí. Àpẹẹrẹ míì ni ti ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Hector ní Indonesia. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí ẹ̀ ò sin Jèhófà, ó sọ pé àpẹẹrẹ Rúùtù ran òun lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kóun sì fayé òun sìn ín.
22. Kí lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ jàǹfààní látinú àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì tàbí ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn”?
22 Ibo lo ti lè rí àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro? Àwọn fídíò àtàwọn àtẹ́tísí tó dá lórí ìtàn Bíbélì àti ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn” máa jẹ́ kí àwọn ìtàn Bíbélì túbọ̀ ṣe kedere sí ẹ.d Kó o tó gbádùn èyíkéyìí lára àwọn ìtẹ̀jáde tá a fara balẹ̀ ṣètò yìí, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o rí àwọn ẹ̀kọ́ tó o lè fi sílò. Fojú inú wò ó pé ìwọ gangan ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀ sí. Ronú jinlẹ̀ lórí ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe sí ìṣòro wọn àti bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ẹ̀. Lẹ́yìn náà, wo bó o ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò nígbèésí ayé ẹ. Dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. O sì lè fi hàn pé o mọyì ohun tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ tíwọ náà bá ń wá bó o ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́, kó o sì fún wọn níṣìírí.
23. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa nínú Àìsáyà 41:10, 13?
23 Nǹkan ò rọrùn rárá nínú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso yìí. Kódà, ìṣòro náà máa ń wọni lọ́rùn nígbà míì. (2 Tím. 3:1) Àmọ́ kò yẹ ká bẹ̀rù tàbí ká máa ṣàníyàn torí pé Jèhófà mọ ohun tá à ń bá yí. Jèhófà ṣèlérí fún wa pé òun máa fi ọwọ́ ọ̀tún òun dì wá mú tá a bá ṣubú. (Ka Àìsáyà 41:10, 13.) Ó dá wa lójú hán-ún pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, á lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti fún wa lókun tá a nílò ká lè fara da ìṣòro èyíkéyìí ká sì borí wọn.
ORIN 96 Ìṣúra Ni Ìwé Ọlọ́run
a Ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ inú Bíbélì ló fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bó o ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà táá mú kó o túbọ̀ jàǹfààní ohun tó ò ń kà.
b Onírúurú ọ̀nà la lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O tún lè rí àwọn àbá míì tó o bá wo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ àkòrí náà “Bíbélì.” Wo ìsọ̀rí náà “Bí O Ṣe Lè Ka Bíbélì Kí O sì Lóye Rẹ̀.”
c Ẹ má ṣe ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ níjọ yín.
d Wo “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—Àwọn Ọkùnrin àti Obìnrin Tó Wà Nínú Bíbélì” lórí jw.org/yo. (Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÌGBÀGBỌ́ NÍNÚ ỌLỌ́RUN.)