Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Nígbà ayé Jésù, owó orí wo làwọn èèyàn máa ń san?
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti máa ń san owó kí wọ́n lè fi ti ìjọsìn mímọ́ lẹ́yìn. Àmọ́ nígbà ayé Jésù, owó orí táwọn Júù ń san ti pọ̀ débi pé ó mú kí nǹkan nira gan-an fún wọn.
Òfin Ọlọ́run sọ pé àwọn ọkùnrin Júù gbọ́dọ̀ máa san ààbọ̀ ṣékélì (ìyẹn dírákímà méjì) láti ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn ní ilé Jèhófà. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, owó yẹn ni wọ́n máa fi ń bójú tó tẹ́ńpìlì tí Hẹ́rọ́dù kọ́ àtàwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú níbẹ̀. Àwọn Júù kan bi Pétérù bóyá Jésù máa ń san owó orí yẹn. Jésù sì jẹ́ kó ṣe kedere pé kò burú láti ṣe bẹ́ẹ̀, kódà ó sọ ibi tí Pétérù ti máa rí owó tí wọ́n á fi san owó orí náà.—Mát. 17:24-27.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì tún máa ń san ìdá mẹ́wàá irè oko wọn àti owó iṣẹ́ tí wọ́n bá gbà. (Léf. 27:30-32; Nọ́ń. 18:26-28) Àmọ́, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn nígbà ayé Jésù wá fi dandan lé e pé àwọn èèyàn náà gbọ́dọ̀ san ìdá mẹ́wàá lórí gbogbo irè oko wọn títí kan “ewéko míńtì, dílì àti kúmínì.” Jésù ò sọ pé káwọn èèyàn má ṣe san ìdá mẹ́wàá, àmọ́ ó jẹ́ kó hàn gbangba pé alágàbàgebè làwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí torí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é.—Mát. 23:23.
Lásìkò yẹn náà, àwọn Júù tún ní láti san owó orí lórí onírúurú àwọn nǹkan fún àwọn ará Róòmù tó ń ṣàkóso wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó nílẹ̀ máa ń san owó orí, ó sì lè jẹ́ irè oko wọn ni wọ́n á fi san án. Kódà, ìdá mẹ́rin sí ìdá márùn-ún irè oko wọn ni wọ́n máa ń gbà. Yàtọ̀ síyẹn, Júù kọ̀ọ̀kan tún máa ń san owó orí. Owó orí yìí làwọn Farisí wá bi Jésù nípa ẹ̀. Jésù wá sọ ohun tó yẹ ká máa ṣe nípa owó orí, ó ní: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Mát. 22:15-22.
Wọ́n tún máa ń san owó orí lórí àwọn ọjà tí wọ́n kó wọ̀lú tàbí àwọn ọjà tí wọ́n ń kó lọ sílùú míì. Wọ́n máa ń gba owó orí yìí láwọn etíkun, lórí afárá, ní oríta, lẹ́nu ibodè ìlú tàbí lọ́jà.
Owó orí tí ìjọba Róòmù ń gbà lọ́wọ́ àwọn Júù pọ̀ gan-an, ìyẹn sì mú kí nǹkan nira fún wọn. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Tacitus sọ pé nígbà tí Jésù wà láyé, ìyẹn lásìkò Tìbéríù Olú Ọba Róòmù, “àwọn ará Síríà àti Jùdíà bẹ̀bẹ̀ pé kí ìjọba Róòmù dín owó orí táwọn ń san kù torí ó wọ àwọn lọ́rùn.”
Ọ̀nà tí ìjọba Róòmù fi ń gba owó orí tún mú kí nǹkan nira gan-an fáwọn Júù. Ẹni tó máa san owó tó pọ̀ jù fún ìjọba ni ìjọba máa ń gbéṣẹ́ fún pé kó lọ gba owó orí lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Ẹni tí wọ́n bá gbéṣẹ́ yìí fún tún máa wá gba àwọn míì tó máa lọ gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn, gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn ló sì máa ń fi owó kún owó náà kí wọ́n lè yọ èrè tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, olórí àwọn agbowó orí ni Sákéù, ó sì ṣeé ṣe kó ní àwọn míì tó ń ṣiṣẹ́ fún un. (Lúùkù 19:1, 2) Gbogbo èyí mú kí nǹkan nira fáwọn Júù, abájọ tí wọ́n fi kórìíra àwọn tó máa ń gba owó orí lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì máa ń fojú burúkú wò wọ́n.