ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Máa Ń Ro Ti Jèhófà Tí Mo Bá Ń Ṣèpinnu
ILÉ tó rẹwà ní agbègbè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù nílùú Caracas, lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà ni mò ń gbé. Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí mò ń lọ síbi iṣẹ́ lọ́dún 1984, mò ń ronú lórí àpilẹ̀kọ kan tí mo kà nínú Ilé Ìṣọ́. Àpilẹ̀kọ yẹn sọ̀rọ̀ nípa ojú táwọn èèyàn fi ń wò wá. Bí mo ṣe ń wo àwọn ilé tó wà nítòsí, mo bi ara mi pé: ‘Ojú wo ni àwọn aládùúgbò fi ń wò mí? Ṣé ojú òṣìṣẹ́ báǹkì kan tó ti rọ́wọ́ mú ni wọ́n fi ń wò mí àbí wọ́n ń rí mi bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó kàn ń fi iṣẹ́ báǹkì gbọ́ bùkátà ìdílé ẹ̀?’ Ohun tí mo rí pé ó jẹ́ ìdáhùn kò tẹ́ mi lọ́rùn, torí náà mo pinnu láti ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀.
May 19, 1940 ni wọ́n bí mi ní ìlú Amioûn, lórílẹ̀-èdè Lebanon. Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìdílé wa kó lọ sí ìlú Tripoli. A nífẹ̀ẹ́ ara wa, à ń láyọ̀, a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Èmi ni àbígbẹ̀yìn nínú ọmọ márùn-ún tí àwọn òbí wa bí, obìnrin mẹ́ta àti ọkùnrin méjì ni wá. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí àwọn òbí wa ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìpàdé àti bí wọ́n ṣe máa ran àwọn míì lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà, kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa di olówó.
A ní àwọn ẹni àmì òróró mélòó kan nínú ìjọ wa. Ọ̀kan lára wọn ni Arákùnrin Michel Aboud tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa. Ìlú New York ló ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, òun ló sì mú òtítọ́ wá sí orílẹ̀-èdè Lebanon lọ́dún 1921. Mo rántí bí wọ́n ṣe ran àwọn arábìnrin méjì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́wọ́, ìyẹn Anne àti Gwen Beavor. A wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, inú mi dùn gan-an nígbà tí mo rí Anne lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn náà, mo tún rí Gwen tí òun àti ọkọ ẹ̀ Wilfred Gooch jọ ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú London, lórílẹ̀-èdè England.
IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ LEBANON
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò pọ̀ lórílẹ̀-èdè Lebanon nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́. Síbẹ̀, a máa ń fìtara wàásù fáwọn míì, a ò sì dẹwọ́ láìka bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan ṣe ń ta kò wá. Kódà, mo ṣì rántí àwọn nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀ dáadáa.
Lọ́jọ́ kan, èmi àti Sana ẹ̀gbọ́n mi jọ ń wàásù nílé kan. Ni àlùfáà kan bá wá sílé tá a ti ń wàásù, ó jọ pé ẹnì kan ló pè é. Ni àlùfáà náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bú Sana ẹ̀gbọ́n mi. Kódà, ó tì í látorí àtẹ̀gùn sísàlẹ̀, ó sì ṣèṣe gan-an. Bí ẹnì kan ṣe pe àwọn ọlọ́pàá nìyẹn, wọ́n sì ṣètò bí ẹ̀gbọ́n mi ṣe rí ìtọ́jú tó yẹ. Wọ́n wá mú àlùfáà náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá, ibẹ̀ ni wọ́n ti rí i pé ìbọn wà lọ́wọ́ ẹ̀. Ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá wá bi í pé: “Ṣé àlùfáà ni ìwọ yìí ṣá, àbí ọ̀gá àwọn ọmọọ̀ta?”
Ìgbà míì tí mo tún rántí ni ìgbà tí ìjọ wa gba mọ́tò láti lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ tí a kì í ṣe déédéé. À ń gbádùn iṣẹ́ náà gan-an, àfìgbà tí àlùfáà tó wà ládùúgbò yẹn gbọ́ pé a wà níbẹ̀, ló bá lọ kó àwọn ọmọọ̀ta jọ. Wọ́n halẹ̀ mọ́ wa, kódà wọ́n ju òkò lù wá, bàbá mi sì ṣèṣe. Mo rántí pé ẹ̀jẹ̀ bo gbogbo ojú wọn. Ni ìyá mi bá mú wọn lọ sídìí mọ́tò, àwa tó kù sì tẹ̀ lé wọn. Mi ò lè gbàgbé ohun tí ìyá mi sọ bí wọ́n ṣe ń nu ojú bàbá mi. Wọ́n sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́ dárí jì wọ́n, torí wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”
Mo tún rántí ìgbà kan tá a lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí wa nílùú wa. Nígbà tá a débẹ̀, a rí Bíṣọ́ọ̀bù kan nílé bàbá bàbá mi. Bíṣọ́ọ̀bù náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi. Ó wá dájú sọ mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni mí nígbà yẹn. Ó ní: “Ìwọ, kí ló dé tó ò tíì ṣèrìbọmi?” Mo sọ fún wọn pé ọmọdé ṣì ni mí àti pé mo gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n sì nígbàgbọ́ tó lágbára kí n tó ṣèrìbọmi. Torí pé wọn ò fara mọ́ ohun tí mo sọ, wọ́n lọ fẹjọ́ sun bàbá bàbá mi pé mo rí àwọn fín.
Irú àwọn ìrírí yìí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ìdí ni pé àwọn ọmọ ìlú Lebanon máa ń kóni mọ́ra, wọ́n sì máa ń ṣaájò èèyàn gan-an. Torí náà, a máa ń rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ dáadáa lóde ẹ̀rí, a sì ní ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
A KÓ LỌ SÓRÍLẸ̀-ÈDÈ MÍÌ
Nígbà tí mo wà nílé ìwé, arákùnrin kan láti Fẹnẹsúélà wá ṣèbẹ̀wò sí Lebanon. Ìjọ wa ni wọ́n máa ń wá, báwọn àti Wafa ẹ̀gbọ́n mi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn nìyẹn. Nígbà tó yá, wọ́n ṣègbéyàwó, wọ́n sì kó lọ sí Fẹnẹsúélà. Wafa máa ń kọ lẹ́tà sí wa, ó sì máa ń sọ fún bàbá mi ṣáá pé kí gbogbo wa máa kó bọ̀ ní Fẹnẹsúélà. Ó fẹ́ ká wá torí pé àárò wa ń sọ ọ́. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, a kó lọ sí Fẹnẹsúélà!
Ọdún 1953 la kó lọ sílùú Caracas, lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà, a sì ń gbé nítòsí ilé ààrẹ orílẹ̀-èdè. Torí pé mo ṣì kéré nígbà yẹn, inú mi máa ń dùn tí mo bá rí ọkọ̀ bọ̀gìnnì tó ń gbé ààrẹ orílẹ̀-èdè kọjá. Ara àwọn òbí mi ò tètè mọlé torí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan wọn ló yàtọ̀ sí tiwa. Bí àpẹẹrẹ, èdè àti àṣà wọn yàtọ̀, ó sì pẹ́ kí oúnjẹ àti ojú ọjọ́ wọn tó bá àwọn òbí mi lára mu. Kódà, ara wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọlé ni nígbà tí àjálù burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí wa.
ÀJÁLÙ KAN ṢẸLẸ̀
Bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn. Ó yà wá lẹ́nu gan-an torí pé koko lara wọn le, kódà, àìsàn ò dá wọn gúnlẹ̀ rí. Àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ní àrùn jẹjẹrẹ, torí náà wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn. Ó dùn mí gan-an pé ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n kú.
Mi ò lè ṣàlàyé bọ́rọ̀ yẹn ṣe rí lára wa, torí pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13) péré ni mí nígbà yẹn. Ikú bàbá mi bá wa lójijì, gbogbo nǹkan sì tojú sú wa. Ó pẹ́ kí màmá mi tó gbà pé bàbá mi ti kú. Àmọ́ nígbà tó yá, a gba kámú, Jèhófà sì ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á. Nígbà tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ girama lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), ó wù mí gan-an pé kí n ran ìdílé wa lọ́wọ́.
Àsìkò yẹn ni Sana ẹ̀gbọ́n mi fẹ́ Rubén Araujo tó ti lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tó sì ti pa dà sí Fẹnẹsúélà. Àwọn méjèèjì wá kó lọ sílùú New York. Nígbà tí ìdílé wa pinnu pé mo máa lọ sí yunifásítì, mo kó lọ sí New York lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ wọn, mo sì ń lọ sílé ìwé níbẹ̀. Àwọn méjèèjì ràn mí lọ́wọ́ gan-an láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nígbà tí mò ń gbé lọ́dọ̀ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a ní àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ìjọ Brooklyn Spanish tí mo dara pọ̀ mọ́. Méjì lára wọn ni Milton Henschel àti Frederick Franz tí wọ́n ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn.
Nígbà tó kù díẹ̀ kí n parí ọdún àkọ́kọ́ ní yunifásítì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe. Mo ronú gan-an lórí àwọn àpilẹ̀kọ tí mo kà nínú Ilé Ìṣọ́ nípa ohun tó yẹ káwa Kristẹni fi ìgbésí ayé wa ṣe. Mo rí bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní ìjọ wa ṣe ń láyọ̀, ó sì wù mí kémi náà nírú ayọ̀ yẹn, àmọ́ mi ò tíì ṣèrìbọmi. Torí náà, mo pinnu láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣèrìbọmi ní March 30, 1957.
MO ṢE ÀWỌN ÌPINNU PÀTÀKÌ
Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, mo rí i pé ó yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó wù mí gan-an láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ kò rọrùn fún mi. Báwo ni mo ṣe fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tí mo ṣì wà ní yunifásítì? Bí mo ṣe ń kọ lẹ́tà sílé làwọn náà ń kọ lẹ́tà sí mi pa dà, mo ṣàlàyé fún wọn pé mo fẹ́ kúrò ní yunifásítì kí n pa dà sí Fẹnẹsúélà, kí n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
June 1957 ni mo pa dà sí Caracas. Àmọ́ nígbà tí mo délé, mo rí i pé nǹkan ò rọrùn fún ìdílé wa. Mo wá rí i pé ó di dandan kémi náà ṣiṣẹ́ kí n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Mo ríṣẹ́ sí báǹkì kan, àmọ́ ó ṣì wù mí gan-an pé kí n ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ó ṣe tán, ìdí tí mo fi pa dà sí Fẹnẹsúélà nìyẹn. Mo wá pinnu pé màá ṣe méjèèjì pọ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ṣiṣẹ́ ní báǹkì tí mo sì tún ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ọwọ́ mi máa ń dí gan-an, síbẹ̀ mò ń láyọ̀!
Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo fẹ́ arábìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Sylvia lorúkọ ẹ̀, orílẹ̀-èdè Jámánì ló sì ti wá. Òun àtàwọn òbí ẹ̀ ni wọ́n jọ kó wá sí Fẹnẹsúélà. Nígbà tó yá, a bímọ méjì, orúkọ wọn ni Mike àti Samira. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀dọ̀ wa ni màmá mi ń gbé, àwa la sì ń bójú tó wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní láti fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ kí n lè bójú tó ìdílé mi, mo ṣì ń fìtara wàásù. Èmi àti ìyàwó mi máa ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbàkigbà tí àyè ẹ̀ bá yọ.
MO ṢE ÌPINNU PÀTÀKÌ MÍÌ
Àwọn ọmọ mi ṣì wà nílé ìwé nígbà tóhun tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀. Kí n sòótọ́, owó ń wọlé fún mi dáadáa, àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì sì ń bọ̀wọ̀ fún mi. Síbẹ̀, òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni mo fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ mí sí, kì í ṣe òṣìṣẹ́ báǹkì. Ohun tí mo rò lọ́jọ́ yẹn ò kúrò lọ́kàn mi. Torí náà, èmi àtìyàwó mi sọ̀rọ̀ nípa owó tó ń wọlé àti bá a ṣe ń náwó. Tí mo bá fi iṣẹ́ báǹkì sílẹ̀, wọ́n máa fún mi lówó ìfẹ̀yìntì tó jọjú. Torí pé a ò jẹ gbèsè, a ṣírò ẹ̀ pé tá a bá dín ìnáwó wa kù, owó yẹn á tó wa ná fún ọdún mélòó kan.
Kò rọrùn láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, àmọ́ ìyàwó mi àti màmá mi tì mí lẹ́yìn. Bó ṣe di pé mo tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan sí i nìyẹn. Inú mi dùn gan-an! Ṣe ló dà bíi pé gbogbo ètò ti tò. Àmọ́, kò pẹ́ sígbà yẹn ni ohun kan ṣẹlẹ̀ tó ya gbogbo wa lẹ́nu.
ÌBÙKÚN TÁ Ò LÉRÒ!
Lọ́jọ́ kan, dókítà wa sọ fún wa pé ìyàwó mi tún ti lóyún. Ó ya àwa méjèèjì lẹ́nu gan-an! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn ayọ̀ ni, mo tún ronú ipa tó máa ní lórí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mo fẹ́ ṣe. Kò pẹ́ tá a fi gba kámú, tá a sì ń fayọ̀ retí ọmọ tuntun náà. Àmọ́ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí mo fẹ́ ṣe ńkọ́?
Lẹ́yìn tá a jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a fẹ́ ṣe, a pinnu pé kí n ṣì ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. April 1985 la bí Gabriel ọmọ wa. Síbẹ̀, mo fiṣẹ́ báǹkì sílẹ̀ mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní June 1985. Nígbà tó yá, mo di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Àmọ́, ẹ̀ka ọ́fíìsì jìnnà sí Caracas tá à ń gbé, kódà ó tó nǹkan bí ọgọ́rin (80) kìlómítà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọjọ́ méjì sí mẹ́ta ni mo fi máa ń lọ síbẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀.
A TÚN KÓ LỌ SÍBÒMÍÌ
Ìlú La Victoria ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wà, torí náà a pinnu pé ká kó lọ síbẹ̀ ká lè wà nítòsí Bẹ́tẹ́lì. Ìyípadà ńlá ni, mo sì mọyì bí ìdílé mi ṣe tì mí lẹ́yìn. Ohun tí wọ́n ṣe wú mi lórí gan-an. Baha ẹ̀gbọ́n mi mú màmá wa sọ́dọ̀. Lásìkò yẹn, Mike ti gbéyàwó, àmọ́ Samira àti Gabriel ṣì wà pẹ̀lú wa. Bí ò tiẹ̀ rọrùn, wọ́n fi àwọn ọ̀rẹ́ wọn sílẹ̀ ní Caracas. Yàtọ̀ síyẹn, kò rọrùn fún ìyàwó mi torí pé ìlú ńlá la ti kó wá sí ìgbèríko. Bákan náà, gbogbo wa la ṣe àwọn àyípadà kan torí pé ibi tá à ń gbé báyìí kéré síbi tá à ń gbé tẹ́lẹ̀. Kí n sòótọ́, ọ̀pọ̀ ìyípadà la ṣe nígbà tá a kó kúrò ní Caracas lọ sí La Victoria.
Àmọ́, nǹkan tún yí pa dà. Gabriel gbéyàwó, Samira sì ń dá gbé. Nígbà tó di 2007, wọ́n ní kémi àtìyàwó mi máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, ibẹ̀ la sì wà títí di báyìí. Alàgbà ni Mike ọmọ wa àgbà, aṣáájú-ọ̀nà sì lòun àtìyàwó rẹ̀ Monica. Alàgbà ni Gabriel náà, Ítálì sì ni òun àti Ambra ìyàwó rẹ̀ wà. Bákan náà, aṣáájú-ọ̀nà ni Samira, ó sì tún ń ṣiṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì látilé.
MI Ò KÁBÀÁMỌ̀ ÀWỌN ÌPINNU TÍ MO ṢE
Ọ̀pọ̀ ìpinnu ni mo ti ṣe nígbèésí ayé mi, síbẹ̀ mi ò kábàámọ̀. Kódà, tí n bá láǹfààní láti tún ìpinnu ṣe, àwọn ìpinnu yẹn kan náà ni màá ṣe. Mo mọyì gbogbo àǹfààní tí Jèhófà ti fún mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. Àwọn ohun tí mo ti rí látọdún yìí wá jẹ́ kí n rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú Jèhófà. Ìpinnu èyíkéyìí tá a bá ṣe, yálà ó rọrùn tàbí kò rọrùn, ó dájú pé Jèhófà máa fún wa ní àlàáfíà “tó kọjá gbogbo òye.” (Fílí. 4:6, 7) Èmi àtìyàwó mi ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wa ní Bẹ́tẹ́lì, a sì gbà pé Jèhófà ti bù kún àwọn ìpinnu wa torí pé ìfẹ́ rẹ̀ la fi síwájú nígbèésí ayé wa.