ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20
Ohun Tí Ìwé Ìfihàn Sọ Pé Ó Máa Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Ọ̀tá Ọlọ́run
“Wọ́n sì kó wọn jọ sí ibi tí wọ́n ń pè ní Amágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—ÌFI. 16:16.
ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni ìwé Ìfihàn sọ pé Sátánì ń ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run?
ÌWÉ Ìfihàn sọ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́run, wọ́n sì ti lé Sátánì kúrò lọ́run. (Ìfi. 12:1-9) Àlàáfíà dé bá àwọn tó wà lọ́run nígbà tí wọ́n lé Sátánì kúrò níbẹ̀, àmọ́ ìyẹn dá wàhálà sílẹ̀ fún aráyé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Sátánì ń gbéjà ko àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn láyé.—Ìfi. 12:12, 15, 17.
2. Kí ló máa mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?
2 Kí ló máa mú ká jẹ́ olóòótọ́ bí Sátánì tiẹ̀ ń gbéjà kò wá? (Ìfi. 13:10) Ohun tó máa jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ ni pé ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ nínú ìwé Ìfihàn, àpọ́sítélì Jòhánù sọ díẹ̀ lára àwọn ohun rere tá a máa gbádùn láìpẹ́. Ọ̀kan lára ohun rere náà ni pé Ọlọ́run máa pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run. Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tí ìwé Ìfihàn sọ nípa àwọn ọ̀tá náà àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.
“ÀWỌN ÀMÌ” TÍ BÍBÉLÌ FI ṢÀLÀYÉ ÀWỌN Ọ̀TÁ ỌLỌ́RUN
3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àmì tí ìwé Ìfihàn lò?
3 Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìfihàn sọ fún wa pé “àwọn àmì” ni wọ́n máa fi ṣàlàyé àwọn ohun tá a máa kà nínú ìwé náà. Ìyẹn ni pé èdè àpèjúwe ni wọ́n máa lò. (Ìfi. 1:1) Èdè àpèjúwe ni ìwé Ìfihàn fi ṣàlàyé àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Ó pe àwọn kan ní ẹranko ẹhànnà. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù rí “ẹranko kan tó ń jáde látinú òkun, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje.” (Ìfi. 13:1) Lẹ́yìn ìyẹn, ó rí “ẹranko míì tó ń jáde látinú [ilẹ̀].” Ẹranko yẹn ń sọ̀rọ̀ bíi dírágónì, ó sì mú kí “iná wá láti ọ̀run.” (Ìfi. 13:11-13) Lẹ́yìn náà, ó tún rí ẹranko míì tó yàtọ̀, ìyẹn “ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò,” tí aṣẹ́wó kan jókòó sórí ẹ̀. Àwọn ẹranko ẹhànnà mẹ́ta yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká mọ ohun tí wọ́n jẹ́.—Ìfi. 17:1, 3.
4-5. Báwo ni ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 7:15-17 ṣe jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn àmì náà?
4 Ká tó lè mọ àwọn ọ̀tá yìí, ó yẹ ká mọ ìtumọ̀ èdè àpèjúwe tí ìwé Ìfihàn lò fún wọn. Ọ̀nà tó dáa jù láti gbà mọ̀ wọ́n ni pé kí Bíbélì fúnra ẹ̀ ṣàlàyé. Àwọn ìwé míì nínú Bíbélì ṣàlàyé ọ̀pọ̀ èdè àpèjúwe tí wọ́n lò nínú ìwé Ìfihàn. Bí àpẹẹrẹ, wòlíì Dáníẹ́lì lá àlá kan, ó rí ‘ẹranko ńlá mẹ́rin tó jáde látinú òkun.’ (Dán. 7:1-3) Dáníẹ́lì sọ ohun tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ. Ó sọ pé àwọn ẹranko ńlá mẹ́rin yìí ṣàpẹẹrẹ “ọba” mẹ́rin tàbí ìjọba mẹ́rin. (Ka Dáníẹ́lì 7:15-17.) Torí náà, àlàyé tó yéni dáadáa yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹranko tí ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ wọn náà gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso.
5 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn àmì tí ìwé Ìfihàn lò. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá rí bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn àmì náà. A máa bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn ẹranko ẹhànnà yẹn. Àkọ́kọ́, a máa mọ ohun tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ. Lẹ́yìn náà, a máa mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Níparí ẹ̀, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn nǹkan yìí ṣe kàn wá.
BÁ A ṢE MỌ ÀWỌN Ọ̀TÁ ỌLỌ́RUN
6. Kí ni ẹranko ẹhànnà olórí méje tí Ìfihàn 13:1-4 sọ ṣàpẹẹrẹ?
6 Kí ni ẹranko ẹhànnà olórí méje náà? (Ka Ìfihàn 13:1-4.) A kíyè sí pé ẹranko náà dà bí àmọ̀tẹ́kùn, àmọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi ti bíárì, ẹnu rẹ̀ jọ ti kìnnìún, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. Gbogbo nǹkan yìí làwọn ẹranko mẹ́rin tó wà nínú Dáníẹ́lì orí 7 ní. Àmọ́ nínú ìwé Ìfihàn, ẹranko kan ṣoṣo ló ní gbogbo nǹkan yìí kì í ṣe ẹranko mẹ́rin. Ẹranko ẹhànnà kan ṣoṣo yẹn ò ṣàpẹẹrẹ ìjọba kan ṣoṣo tàbí ìjọba alágbára kan tó ń ṣàkóso gbogbo ayé. Jòhánù sọ pé ó ń ṣàkóso lórí “gbogbo ẹ̀yà, èèyàn, ahọ́n àti orílẹ̀-èdè.” Ẹranko yìí lágbára ju ìjọba orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lọ. (Ìfi. 13:7) Torí náà, ẹranko ẹhànnà yìí ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ìjọba alágbára tó ṣàkóso ayé jálẹ̀ ìtàn aráyé.b—Oníw. 8:9.
7. Kí ni orí kọ̀ọ̀kan nínú orí méje tí ẹranko ẹhànnà náà ní ṣàpẹẹrẹ?
7 Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan orí méje náà ṣàpẹẹrẹ? Ìfihàn orí 17 ṣàlàyé ère ẹranko ẹhànnà tó wà nínú Ìfihàn orí 13. Ìfihàn 17:10 sọ pé: “Ọba méje ló wà: Márùn-ún ti ṣubú, ọ̀kan wà, ọ̀kan yòókù kò tíì dé; àmọ́ nígbà tó bá dé, ó gbọ́dọ̀ wà fúngbà díẹ̀.” Nínú gbogbo ìjọba ayé tí Sátánì ti lò, Bíbélì fi méje lára wọn wé “orí” torí pé wọ́n lágbára gan-an. Àwọn ìjọba alágbára yẹn ló ń ṣàkóso ayé, wọ́n sì ń pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú. Nígbà ayé àpọ́sítélì Jòhánù, márùn-ún lára wọn ti ṣàkóso parí. Àwọn ni: Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà àti Páṣíà àti Gíríìsì. Ìjọba kẹfà ìyẹn Róòmù ṣì ń ṣàkóso lọ́wọ́ nígbà tí Jòhánù rí ìran náà. Ìjọba wo ló máa wá jẹ́ ìjọba keje tó máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn tàbí orí keje?
8. Ìjọba wo ni orí keje lára ẹranko ẹhànnà náà ṣàpẹẹrẹ?
8 A máa rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìwé Dáníẹ́lì ti jẹ́ ká mọ orí keje tó kẹ́yìn lára ẹranko ẹhànnà náà. Ìjọba wo ló ń ṣàkóso ayé lásìkò òpin yìí, ìyẹn ní “ọjọ́ Olúwa”? (Ìfi. 1:10) Àpapọ̀ ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti ìjọba Amẹ́ríkà ni. À ń pè é ní Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé. Torí náà, a lè sọ pé òun ni orí keje lára ẹranko ẹhànnà tó wà nínú Ìfihàn 13:1-4.
9. Kí ni ẹranko ẹhànnà tó ní “ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn” náà ṣàpẹẹrẹ?
9 Ìfihàn orí 13 tún sọ fún wa pé orí keje, ìyẹn Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé ń ṣe bí ẹranko ẹhànnà tó ní “ìwo méjì bí ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ bíi dírágónì.” Ẹranko yìí “ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, kódà ó ń mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé lójú aráyé.” (Ìfi. 13:11-15) Ìfihàn orí 16 àti 19 pe ẹranko ẹhànnà yìí ní “wòlíì èké.” (Ìfi. 16:13; 19:20) Dáníẹ́lì náà sọ ohun tó jọ ọ́, ó ní Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé “máa runlérùnnà.” (Dán. 8:19, 23, 24, àlàyé ìsàlẹ̀) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló ṣe bọ́ǹbù átọ́míìkì méjì tí wọ́n yìn láti fòpin sí ogun náà. Torí náà, a lè sọ pé Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé “mú kí iná wá láti ọ̀run sí ayé.”
10. Kí ni “ère ẹranko náà” ṣàpẹẹrẹ? (Ìfihàn 13:14, 15; 17:3, 8, 11)
10 Lẹ́yìn náà, Jòhánù rí ẹranko ẹhànnà míì. Ó jọ ẹranko olórí méje yẹn gan-an, àmọ́ ní tiẹ̀, àwọ̀ rírẹ̀dòdò ló ní. Ó pè é ní “ère ẹranko,” ó sì sọ pé òun ni “ọba kẹjọ.”c (Ka Ìfihàn 13:14, 15; 17:3, 8, 11.) Bíbélì sọ pé “ọba” yìí wà tẹ́lẹ̀, nígbà tó yá kò sí mọ́, àmọ́ lẹ́yìn náà, ó tún wà. Ẹ ò rí i pé àlàyé yìí bá ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé mu gẹ́lẹ́! Kódà, òun ló ń ti àwọn ìjọba ayé lẹ́yìn. Nígbà tó wà tẹ́lẹ̀, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni wọ́n ń pè é. Lẹ́yìn ìyẹn, kò sí mọ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Nígbà tó yá, ó tún pa dà wá, ó sì ń jẹ́ Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé.
11. Kí làwọn ẹranko ẹhànnà yẹn ń ṣe, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù wọn?
11 Àwọn ìjọba tó dà bí ẹranko ẹhànnà yẹn máa ń parọ́ káwọn èèyàn lè ta ko Jèhófà àtàwa èèyàn ẹ̀. Jòhánù sọ pé ṣe ló máa dà bíi pé wọ́n kó “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé” jọ sí ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn ogun “ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìfi. 16:13, 14, 16) Àmọ́ kò sídìí fún wa láti bẹ̀rù. Torí pé Jèhófà Ọlọ́run wa alágbára máa gbèjà gbogbo àwọn tó ń ti ìjọba ẹ̀ lẹ́yìn, á sì gbà wọ́n.—Ìsík. 38:21-23.
12. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko náà?
12 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko náà? Ìfihàn 19:20 sọ pé: “A sì mú ẹranko náà pẹ̀lú wòlíì èké tó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì níwájú rẹ̀, èyí tó fi ṣi àwọn tó gba àmì ẹranko náà lọ́nà àti àwọn tó jọ́sìn ère rẹ̀. A ju àwọn méjèèjì láàyè sínú adágún iná tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.” Torí náà, nígbà táwọn ìjọba tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run yìí ṣì ń ṣàkóso lọ́wọ́, Ọlọ́run máa pa wọ́n run ráúráú.
13. Ìṣòro wo làwọn ìjọba kan máa ń dá sílẹ̀ fún gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́?
13 Kí ló yẹ ká ṣe? Àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. (Jòh. 18:36) Tá a bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú ayé yìí. Àmọ́ ìyẹn kì í rọrùn rárá torí pé àwọn ìjọba máa ń fẹ́ ká ti àwọn lẹ́yìn ní gbogbo ọ̀nà. Àwọn tó bá ṣe ohun tí wọ́n sọ máa gba àmì ẹranko ẹhànnà náà. (Ìfi. 13:16, 17) Àmọ́ inú Jèhófà ò ní dùn sí ẹnikẹ́ni tó bá gba àmì náà, kò sì ní jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Ìfi. 14:9, 10; 20:4) Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká má dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá tí ìjọba bá tiẹ̀ ń fúngun mọ́ wa lójú méjèèjì!
Ẹ̀TẸ́ LÓ MÁA GBẸ̀YÌN AṢẸ́WÓ ŃLÁ NÁÀ
14. Ohun ìyanu wo ni Ìfihàn 17:3-5 sọ pé Jòhánù rí lẹ́yìn náà?
14 Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé ohun tí òun rí lẹ́yìn ìyẹn ‘ya òun lẹ́nu gan-an.’ Kí ló rí? Ó rí obìnrin kan tó ń gun ọ̀kan lára àwọn ẹranko ẹhànnà náà. (Ìfi. 17:1, 2, 6) Bíbélì sọ pé “aṣẹ́wó ńlá” ni, ó sì pè é ní “Bábílónì Ńlá.” Òun ni “àwọn ọba ayé” bá “ṣe ìṣekúṣe.”—Ka Ìfihàn 17:3-5.
15-16. Ta ni “Bábílónì Ńlá,” báwo la sì ṣe mọ̀?
15 Ta ni “Bábílónì Ńlá”? Obìnrin yẹn ò lè jẹ́ ètò òṣèlú torí Bíbélì sọ pé ó bá àwọn olórí olóṣèlú ayé ṣe ìṣekúṣe. (Ìfi. 18:9) Kódà, ó máa ń darí àwọn alákòóso, ìyẹn ni pé ó ń gùn wọ́n. Bákan náà, kò lè jẹ́ ètò ìṣòwò jẹgúdújẹrá ayé yìí. Ìdí ni pé ètò ìṣòwò ni Bíbélì pè ní “àwọn oníṣòwò ayé.”—Ìfi. 18:11, 15, 16.
16 Nínú Bíbélì, “aṣẹ́wó” tàbí “alágbèrè” ni wọ́n máa ń pe àwọn tó bá sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run àmọ́ tí wọ́n ń lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà tàbí tí wọ́n ń bá ayé ṣọ̀rẹ́. (1 Kíró. 5:25; Jém. 4:4) Àmọ́ “oníwà mímọ́” tàbí “wúńdíá” ni Bíbélì pe àwọn tó ń fi òótọ́ inú sin Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 11:2; Ìfi. 14:4) Ìlú Bábílónì àtijọ́ ni ojúkò ìjọsìn èké nígbà yẹn. Torí náà, Bábílónì Ńlá ní láti ṣàpẹẹrẹ gbogbo ìjọsìn èké. Kódà, òun ni àpapọ̀ gbogbo ẹ̀sìn èké ayé.—Ìfi. 17:5, 18; wo àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì jw.org. Àkòrí ẹ̀ ni “Kí Ni Bábílónì Ńlá?”
17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì Ńlá?
17 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì Ńlá? Ìfihàn 17:16, 17 dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Ìwo mẹ́wàá tí o rí àti ẹranko náà, máa kórìíra aṣẹ́wó náà, wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá. Torí Ọlọ́run ti fi sí ọkàn wọn láti ṣe ohun tí òun fẹ́.” Jèhófà máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè lo ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ìyẹn Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé láti pa gbogbo ẹ̀sìn èké ayé run pátápátá.—Ìfi. 18:21-24.
18. Kí la máa ṣe tá ò fi ní ti Bábílónì Ńlá lẹ́yìn lọ́nàkọnà?
18 Kí ló yẹ ká ṣe? “Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run” ló yẹ ká máa ṣe. (Jém. 1:27) A ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kọ́ èké láyè, a ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àwọn àjọ̀dún tó wá látinú ìbọ̀rìṣà. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú ayé lónìí tàbí àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí Bábílónì Ńlá ń ṣe. Nǹkan míì tá a máa ṣe ni pé ká máa pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n “jáde kúrò nínú [Bábílónì Ńlá],” kí wọ́n má bàa gbà nínú ẹ̀bi rẹ̀ níwájú Ọlọ́run.—Ìfi. 18:4.
ỌLỌ́RUN MÁA DÁ OLÓRÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ Ẹ̀ LẸ́JỌ́
19. Ta ni “dírágónì ńlá aláwọ̀ iná” náà?
19 Ìwé Ìfihàn tún sọ̀rọ̀ nípa “dírágónì ńlá aláwọ̀ iná” kan. (Ìfi. 12:3) Dírágónì yìí bá Jésù àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jà. (Ìfi. 12:7-9) Ó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì ń fún àwọn ẹranko ẹhànnà náà lágbára. (Ìfi. 12:17; 13:4) Ta ni dírágónì náà? Òun ni “ejò àtijọ́ náà, ẹni tí à ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” (Ìfi. 12:9; 20:2) Òun ló ń ti gbogbo àwọn ọ̀tá Jèhófà lẹ́yìn.
20. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí dírágónì náà?
20 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí dírágónì náà? Ìfihàn 20:1-3 sọ pé áńgẹ́lì kan máa sọ Sátánì sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, tó dà bí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí Sátánì bá wà lẹ́wọ̀n, kò ní “ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà fi máa parí.” Níkẹyìn, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù máa pa run títí láé torí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa jù wọ́n “sínú adágún iná àti imí ọjọ́.” (Ìfi. 20:10) Ẹ fojú inú wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ò bá sí mọ́. Ayé yìí á mà dáa gan-an o!
21. Kí nìdí tí ohun tá a kà nínú ìwé Ìfihàn fi yẹ kó máa múnú wa dùn?
21 Ẹ wo bó ti ń mórí wa wú tó pé a mọ ìtumọ̀ àwọn àmì tó wà nínú ìwé Ìfihàn! Kì í ṣe pé a mọ àwọn ọ̀tá Jèhófà nìkan, a tún ti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bẹ́ẹ̀ ni, “aláyọ̀ ni ẹni tó ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tó ń gbọ́” ọ! (Ìfi. 1:3) Àmọ́, àwọn ohun rere wo làwa èèyàn Ọlọ́run máa gbádùn nígbà táwọn ọ̀tá Ọlọ́run bá pa run? A máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ kẹta.
ORIN 23 Jèhófà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso
a Àmì ni ìwé Ìfihàn fi ṣàpèjúwe àwọn tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. Ìwé Dáníẹ́lì sì jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn àmì náà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa fi àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Dáníẹ́lì wé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jọ wọ́n nínú ìwé Ìfihàn. Ìyẹn máa jẹ́ ká lè dá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run mọ̀. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.
b Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé ẹranko ẹhànnà olórí méje náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ìjọba alágbára tó ṣàkóso ayé ni pé ó ní “ìwo mẹ́wàá.” Bíbélì sábà máa ń lo nọ́ńbà náà mẹ́wàá láti fi hàn pé ohun kan pé pérépéré.
c Ère ẹranko ẹhànnà yìí yàtọ̀ sí ẹranko ẹhànnà àkọ́kọ́ torí pé àwọn ìwo rẹ̀ kò ní “adé dáyádémà.” (Ìfi. 13:1) Ìdí ni pé àtinú àwọn ọba “méje náà” ló ti wá, àwọn ló sì ń fún un lágbára tó ń lò.—Wo àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì jw.org, àkòrí ẹ̀ ni “Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Aláwọ̀ Rírẹ̀dòdò Tó Wà Nínú Ìṣípayá orí Kẹtàdínlógún?”