ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7
Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Jàǹfààní Tó O Bá Ń Ka Bíbélì
“Kí lo kà níbẹ̀?”—LÚÙKÙ 10:26.
ORIN 97 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì ni Jésù fi mú Ìwé Mímọ́?
BÁWO ló ṣe máa rí lára ẹ ká sọ pé o wà níbi tí Jésù ti ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Ó dájú pé inú ẹ máa dùn gan-an bí Jésù ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ láìwo ìwé rárá! Kódà, inú Ìwé Mímọ́ ni Jésù ti fa ọ̀rọ̀ tó sọ yọ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi àtàwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kẹ́yìn kó tó kú.b (Diu. 8:3; Sm. 31:5; Lúùkù 4:4; 23:46) Yàtọ̀ síyẹn, ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ka Ìwé Mímọ́, tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹ̀, tó sì ṣàlàyé ẹ̀ ní gbangba.—Mát. 5:17, 18, 21, 22, 27, 28; Lúùkù 4:16-20.
2. Bí Jésù ṣe ń dàgbà, kí ló jẹ́ kó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
2 Ọ̀pọ̀ ọdún kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló ti máa ń ka Ìwé Mímọ́, tó sì máa ń gbọ́ báwọn míì ṣe ń kà á. Ó dájú pé á máa gbọ́ bí Màríà àti Jósẹ́fù ṣe ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ nínú ilé.c (Diu. 6:6, 7) Ó dá wa lójú pé gbogbo ọjọ́ Sábáàtì ni Jésù àti ìdílé ẹ̀ máa ń lọ sínú sínágọ́gù. (Lúùkù 4:16) Kò sí àní-àní pé Jésù máa ń tẹ́tí sílẹ̀ gan-an bí wọ́n ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá débẹ̀. Nígbà tó yá, Jésù náà kọ́ bá á ṣe máa dá ka Ìwé Mímọ́ fúnra ẹ̀. Torí náà, ohun tí Jésù ń ṣe yìí jẹ́ kó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, kó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kó sì máa darí gbogbo nǹkan tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12) péré? Ṣe lẹnu ya gbogbo àwọn olùkọ́ tó mọ Òfin Mósè dáadáa nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù “nítorí òye tó ní àti bó ṣe ń dáhùn.”—Lúùkù 2:46, 47, 52.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Táwa náà bá ń ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, a máa mọ̀ ọ́n, àá sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àmọ́, kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ jàǹfààní bá a ṣe ń ka Bíbélì? A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Jésù sọ fáwọn tó mọ Òfin dáadáa, ìyẹn àwọn akọ̀wé òfin, àwọn Farisí àtàwọn Sadusí. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn máa ń ka Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, àmọ́ ohun tí wọ́n ń kà ò ṣe wọ́n láǹfààní kankan. Jésù sọ nǹkan mẹ́ta tí ò jẹ́ kí wọ́n jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n ń kà. Ohun tí Jésù sọ fún wọn yẹn máa jẹ́ ká rí (1) bá a ṣe lè túbọ̀ lóye ohun tá à ń kà, (2) bá a ṣe lè wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye, (3) ká sì jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.
GBÌYÀNJÚ LÁTI LÓYE OHUN TÓ Ò Ń KÀ
4. Kí ni Lúùkù 10:25-29 kọ́ wa nípa bó ṣe yẹ ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
4 Ó yẹ ká lóye ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní jàǹfààní kankan nínú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nígbà tó ń bá “ọkùnrin kan tó mọ Òfin dunjú” sọ̀rọ̀. (Ka Lúùkù 10:25-29.) Nígbà tí ọkùnrin yẹn béèrè pé kí lòun máa ṣe kóun lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, Jésù darí ẹ̀ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì bi í pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?” Ọkùnrin yẹn dáhùn ìbéèrè Jésù dáadáa, ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. (Léf. 19:18; Diu. 6:5) Àmọ́ ẹ kíyè sí ìbéèrè tí ọkùnrin yẹn bi Jésù lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Ta ni ọmọnìkejì mi gan-an?” Ohun tí ọkùnrin yẹn ń sọ ni pé òun ò lóye ohun tí òun kà. Torí náà, kò mọ bó ṣe máa lo ohun tó kà nínú Ìwé Mímọ́ nígbèésí ayé ẹ̀.
Máa ṣiṣẹ́ kára kó o lè túbọ̀ lóye ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì
5. Tá a bá gbàdúrà, tá ò sì yára jù nígbà tá à ń ka Ìwé Mímọ́, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká lóye ohun tá à ń kà?
5 Àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tó yẹ ká máa ṣe ká lè túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí máa ràn wá lọ́wọ́. Kọ́kọ́ gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Ká tó lè lóye ohun tá à ń kà nínú Bíbélì, àfi ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè pọkàn pọ̀. Lẹ́yìn náà, má yára jù tó o bá ń ka Bíbélì. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lóye ohun tó ò ń kà. O lè túbọ̀ jàǹfààní tó o bá ń kà á sókè tàbí tó ò ń fojú bá Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ lọ. Bó o ṣe ń gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn ẹ̀ sílẹ̀ yẹn, tó o sì ń fojú bá a lọ nínú Bíbélì ẹ, wàá lóye ẹ̀, wàá rántí ẹ̀, wàá sì túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì. (Jóṣ. 1:8) Tó o bá ti ka Bíbélì tán, tún gbàdúrà sí Jèhófà, kó o dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó fún ẹ ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀, kó o sì ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ohun tó ò ń kọ́ sílò.
6. Tó o bá ń ka Bíbélì, kí nìdí tó fi yẹ kó o bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan, kó o sì ṣàkọsílẹ̀? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Àbá méjì míì rèé táá jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì. Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè nípa ohun tó o kà. Tó o bá ń ka ìtàn Bíbélì kan, bi ara ẹ pé: ‘Àwọn wo ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ wọn níbí yìí? Ta ló sọ ọ̀rọ̀ yìí? Ta ló ń bá sọ̀rọ̀, kí sì nìdí tó fi sọ ohun tó sọ? Ibo ni nǹkan náà ti ṣẹlẹ̀, ìgbà wo sì ni?’ Tó o bá bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí, á jẹ́ kó o ronú jinlẹ̀, ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì á sì túbọ̀ yé ẹ. Yàtọ̀ síyẹn, máa ṣe àkọsílẹ̀ bó o ṣe ń ka Bíbélì. Tó o bá ń ṣàkọsílẹ̀, á jẹ́ kó o kọ èrò ẹ sílẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kí ohun tó ò ń kà túbọ̀ yé ẹ. Á tún jẹ́ kó o rántí àwọn ohun tó o kà. O lè kọ àwọn ìbéèrè tó wá sí ẹ lọ́kàn sílẹ̀ àti ìwádìí tó o ṣe. Ṣàkópọ̀ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ibi tó o kà, kó o sì kọ bó o ṣe máa lò ó sílẹ̀ àti bí nǹkan tó o kà yẹn ṣe rí lára ẹ. Irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kó o rí i pé torí tìẹ gan-an ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ ohun tó wà nínú Bíbélì sílẹ̀.
7. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń ka Bíbélì, kí sì nìdí? (Mátíù 24:15)
7 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a nílò ànímọ́ pàtàkì kan tá a bá fẹ́ lóye ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ànímọ́ náà ni ìfòyemọ̀. (Ka Mátíù 24:15.) Kí ni ìfòyemọ̀? Ìfòyemọ̀ ni kí ẹnì kan rí bí ọ̀rọ̀ kan ṣe tan mọ́ ọ̀rọ̀ míì tàbí bí ọ̀rọ̀ kan ṣe yàtọ̀ sí òmíì, kó sì tún lóye ohun tí ò hàn síta. Bákan náà, Jésù tún jẹ́ ká mọ̀ pé a nílò ìfòyemọ̀ ká tó lè rí i pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ. A tún nílò ànímọ́ yìí ká lè jàǹfààní púpọ̀ látinú gbogbo ohun tá à ń kà nínú Bíbélì.
8. Báwo la ṣe lè fòye mọ ohun tá à ń kà nínú Bíbélì?
8 Jèhófà máa ń jẹ́ káwa ìránṣẹ́ ẹ̀ ní ìfòyemọ̀. Torí náà, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní ànímọ́ pàtàkì yìí. (Òwe 2:6) Àmọ́ kí lo lè ṣe táá fi hàn pé o fẹ́ kí Jèhófà dáhùn àdúrà ẹ? Ronú jinlẹ̀ nípa nǹkan tó o kà, kó o sì wo bó ṣe tan mọ́ àwọn nǹkan tó o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Kíyẹn lè rọrùn fún ẹ, o lè ṣèwádìí nínú àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ìwé ìwádìí yìí máa jẹ́ kó o lóye àwọn nǹkan tó o kà nínú Bíbélì, kó o sì mọ bó o ṣe lè fi sílò nígbèésí ayé ẹ. (Héb. 5:14) Tó o bá ń fòye mọ ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì, á túbọ̀ yé ẹ.
WÁ ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ IYEBÍYE BÓ O ṢE Ń KA BÍBÉLÌ
9. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo làwọn Sadusí ò gbà gbọ́?
9 Àwọn Sadusí mọ ohun tó wà nínú ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa, àmọ́ wọn ò gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú ẹ̀ gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tí Jésù sọ nígbà táwọn Sadusí ta kò ó lórí ọ̀rọ̀ àjíǹde. Jésù bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?” (Máàkù 12:18, 26) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Sadusí ti ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ìbéèrè tí Jésù bi wọ́n fi hàn pé wọn ò gba ẹ̀kọ́ pàtàkì kan gbọ́, ìyẹn ẹ̀kọ́ àjíǹde.—Máàkù 12:27; Lúùkù 20:38.d
10. Kí ló yẹ ká máa kíyè sí tá a bá ń ka Bíbélì?
10 Kí lo kọ́ nínú ohun tó o kà? Gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì kan tàbí ìtàn Bíbélì tá a kà ló yẹ ká kíyè sí. Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tá a ti mọ̀ nìkan ló yẹ ká máa kíyè sí, ó tún yẹ ká máa kíyè sí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ àtàwọn ìlànà tó fara sin nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a kà.
11. Báwo lo ṣe lè fi ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:16, 17 wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye inú Bíbélì?
11 Báwo lo ṣe lè wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó o bá ń ka Bíbélì? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí 2 Tímótì 3:16, 17 sọ. (Kà á.) Kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ pé ‘gbogbo Ìwé Mímọ́ ló wúlò’ fún (1) kíkọ́ni, (2) bíbáni wí, (3) mímú nǹkan tọ́ àti fún (4) títọ́nisọ́nà. O ṣì lè jàǹfààní àwọn nǹkan mẹ́rin yẹn, kódà látinú àwọn ìwé Bíbélì tí o kì í sábà kà. Ronú nípa ohun tí ìtàn náà kọ́ ẹ nípa Jèhófà, ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé àtàwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe ń bá wa wí. Tó o bá ń ka Bíbélì, wo àwọn ìwà tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ní kó o yẹra fún, kó o sì pinnu pé o ò ní hu irú àwọn ìwà yẹn mọ́ kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Wo bí ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe lè mú kó o mú nǹkan tọ́, ìyẹn ni pé kó o fi ṣàtúnṣe èrò tí ò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi ran ẹnì kan tó o pàdé lóde ìwàásù lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, wo bí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà ṣe lè tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè máa fojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́rin yìí, wàá rí àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ jàǹfààní nínú Bíbélì tó ò ń kà.
JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN MÚ KÓ O ṢÀTÚNṢE TÓ YẸ
12. Kí nìdí tí Jésù fi bi àwọn Farisí pé, ‘Ṣé ẹ ò tíì kà á ni?’
12 Jésù tún bi àwọn Farisí pé, ‘Ṣé ẹ ò tíì kà á ni?’ kó lè fi hàn pé wọn ò lóye ohun tí wọ́n ń kà nínú Ìwé Mímọ́. (Mát. 12:1-7)e Lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, ṣe làwọn Farisí fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé wọ́n rú òfin Sábáàtì. Torí náà, Jésù tọ́ka sí àpẹẹrẹ méjì látinú Ìwé Mímọ́, ó sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Hósíà kó lè fi hàn pé àwọn Farisí yẹn ò lóye òfin Sábáàtì, wọn ò sì lójú àánú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Farisí yẹn ń ka Ìwé Mímọ́, kí nìdí tí wọn ò fi jẹ́ kó yí èrò wọn pa dà? Ìdí ni pé wọ́n ń gbéra ga, bí wọ́n sì ṣe máa fi dá àwọn ẹlòmíì lẹ́jọ́ ni wọ́n máa ń wá tí wọ́n bá ń ka Ìwé Mímọ́. Ìwà burúkú tí wọ́n ní yìí ni ò jẹ́ kí wọ́n lóye ohun tí wọ́n ń kà.—Mát. 23:23; Jòh. 5:39, 40.
13. Èrò wo la gbọ́dọ̀ ní tá a bá ń ka Bíbélì, kí sì nìdí?
13 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ ní èrò tó tọ́ tá a bá ń ka Bíbélì. Kò yẹ ká ṣe bíi tàwọn Farisí, ó yẹ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì ṣe tán láti gba ẹ̀kọ́. Ó tún yẹ ká jẹ́ ‘kí ìwà tútù mú kí ọ̀rọ̀ fìdí múlẹ̀ nínú wa.’ (Jém. 1:21) Tá a bá ní ìwà tútù, àá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí ìwà wa pa dà. Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, tá ò sì fi ohun tá à ń kà nínú Bíbélì dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, ìgbà yẹn la máa kọ́ bá a ṣe lè fàánú àti ìfẹ́ hàn.
14. Báwo la ṣe lè mọ̀ bóyá à ń jẹ́ kí Bíbélì yí èrò wa pa dà? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ìwà tá à ń hù sáwọn èèyàn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò wa pa dà. Torí pé àwọn Farisí ò jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n máa ń “dá àwọn tí kò jẹ̀bi lẹ́bi.” (Mát. 12:7) Lọ́nà kan náà, ìwà tá à ń hù sáwọn èèyàn máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá à ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò wa pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó mọ́ wa lára láti máa sọ nípa ìwà tó dáa táwọn ẹlòmíì ní, àbí ibi tí wọ́n kù sí la máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? Ṣé a máa ń fàánú hàn, ṣé a sì máa ń dárí ji àwọn èèyàn, àbí ṣe la máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, tá a sì ń dì wọ́n sínú? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá ò ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yí èrò ẹ, ìṣe ẹ àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ pa dà.—1 Tím. 4:12, 15; Héb. 4:12.
A MÁA LÁYỌ̀ TÁ A BÁ Ń KA Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
15. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jésù tó bá ń ka Ìwé Mímọ́?
15 Jésù nífẹ̀ẹ́ Ìwé Mímọ́ gan-an, kódà Sáàmù 40:8 sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó ní: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ni inú mi dùn sí, òfin rẹ sì wà nínú mi lọ́hùn-ún.” Torí pé Jésù nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà, ó fayọ̀ sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Táwa náà bá ń jẹ́ kí ohun tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wá lọ́kàn, tá a sì ń fi sílò, àwa náà máa láyọ̀, a ò sì ní fi Jèhófà sílẹ̀.—Sm. 1:1-3.
16. Kí lo máa ṣe báyìí kó o lè túbọ̀ jàǹfààní bó o ṣe ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Wo àpótí náà “Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Lóye Ohun Tó Ò Ń Kà.”)
16 Ohun tí Jésù sọ àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀ ti jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká wá bá a ṣe máa jàǹfààní púpọ̀ sí i tá a bá ń ka Bíbélì. A máa túbọ̀ lóye ohun tá à ń kà nínú Bíbélì tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń fara balẹ̀ ka Bíbélì, tá à ń béèrè àwọn ìbéèrè tó yẹ, tá a sì ń ṣàkọsílẹ̀. Ó tún yẹ ká máa fòye mọ ohun tá à ń kà nínú Bíbélì, ká máa ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀, ká sì ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Tá a bá ń walẹ̀ jìn nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá ò kì í fi bẹ́ẹ̀ kà ká lè rí àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tó wà níbẹ̀, àá túbọ̀ lóye Bíbélì. Ó sì tún yẹ ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ká ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ bá a ṣe ń kà á. Torí náà, tá a bá ń fi gbogbo àbá yìí sílò bá a ṣe ń ka Bíbélì, àá jàǹfààní nínú ohun tá à ń kà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Bàbá wa ọ̀run.—Sm. 119:17, 18; Jém. 4:8.
ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
a Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la máa ń gbìyànjú láti ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn míì náà máa ń ka Bíbélì, àmọ́ ohun tí wọ́n ń kà ò fi bẹ́ẹ̀ yé wọn. Bó ṣe rí fún àwọn kan nígbà ayé Jésù náà nìyẹn. Àmọ́, tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù sọ fáwọn tó ń ka Bíbélì, a máa túbọ̀ jàǹfààní táwa náà bá ń kà á.
b Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, tí Jèhófà sì fẹ̀mí mímọ́ yàn án, Jèhófà jẹ́ kó rántí àwọn nǹkan tó ti kọ́ lọ́run kó tó wá sáyé.—Mát. 3:16.
c Màríà mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa, ó sì máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹ̀. (Lúùkù 1:46-55) Ó jọ pé Jósẹ́fù àti Màríà ò lówó tí wọ́n lè fi ra àwọn Ìwé Mímọ́ tiwọn. Ó dájú pé wọ́n á máa tẹ́tí sílẹ̀ gan-an tí wọ́n bá ń ka Ìwé Mímọ́ nínú sínágọ́gù, kí wọ́n lè máa rántí ẹ̀ tó bá yá.
d Wo àpilẹ̀kọ náà, “Sún Mọ́ Ọlọ́run—‘Ọlọ́run Àwọn . . . Alààyè Ni’” nínú Ilé Ìṣọ́ February 1, 2013.
e Tún wo Mátíù 19:4-6, níbi tí Jésù ti bi àwọn Farisí pé: “Ṣé ẹ ò kà á pé?” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kà nípa bí Jèhófà ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, wọn ò lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo ìgbéyàwó.
f ÀWÒRÁN:Nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn àti àwòrán jáde ṣe àwọn àṣìṣe kan. Síbẹ̀, àwọn arákùnrin tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ gbóríyìn fún un lẹ́yìn ìpàdé dípò kí wọ́n bá a wí torí àwọn àṣìṣe tó ṣe.