ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39
Tó O Bá Ní Ìwà Tútù, Wàá Di Alágbára
“Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn.”—2 TÍM. 2:24.
ORIN 120 Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ìbéèrè wo làwọn èèyàn lè bi wá níbiiṣẹ́ tàbí nílé ìwé?
BÁWO ló ṣe máa ń rí lára ẹ tẹ́ni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ ilé ìwé ẹ bá bi ẹ́ nípa ohun tó o gbà gbọ́? Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́? Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ lára wa lẹ̀rù máa ń bà. Àmọ́, irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká mọ ohun tẹ́ni náà ń rò àtohun tó gbà gbọ́. Ìyẹn sì lè ṣí àǹfààní sílẹ̀ láti wàásù fún un. Nígbà míì, àwọn kan máa ń béèrè ìbéèrè torí pé wọn ò fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́ tàbí torí kí wọ́n lè bá wa jiyàn. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu. Ìdí ni pé wọ́n ti sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ohun tá a gbà gbọ́ fáwọn kan. (Ìṣe 28:22) Ìdí míì ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “kìígbọ́-kìígbà,” tí wọ́n sì “burú gan-an” là ń gbé báyìí.—2 Tím. 3:1, 3.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ oníwà tútù?
2 O lè máa ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, kí n sì sọ̀rọ̀ tó tura tẹ́nì kan bá fẹ́ bá mi jiyàn nípa ohun tí mo gbà gbọ́?’ Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ìwà tútù ni. Ẹni tó bá níwà tútù kì í tètè bínú, ó máa ń kó ara ẹ̀ níjàánu tí wọ́n bá múnú bí i tàbí tí kò bá mọ ohun tó máa sọ. (Òwe 16:32) Ká sòótọ́, kò rọrùn láti jẹ́ oníwà tútù. Àmọ́ báwo lo ṣe lè ní ìwà tútù? Tẹ́nì kan bá ní kó o ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́, báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìwà tútù? Tó o bá sì jẹ́ òbí, báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pẹ̀lú ìwà tútù? Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.
BÓ O ṢE LÈ NÍ ÌWÀ TÚTÙ
3. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹni tó níwà tútù kì í ṣe ojo? (2 Tímótì 2:24, 25)
3 Àwọn tó bá níwà tútù kì í ṣe ojo. Ó gba sùúrù gan-an ká tó lè hùwà jẹ́jẹ́ tí wọ́n bá múnú bí wa. Ìwà tútù jẹ́ ọ̀kan lára “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22, 23) Nígbà míì, wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìwà tútù” fún ẹṣin kan tó burú, àmọ́ tí wọ́n ti kápá ẹ̀. Fojú inú wo ẹṣin kan tó burú gan-an, àmọ́ tó ti wá ń ṣe jẹ́jẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹṣin náà ti ń ṣe jẹ́jẹ́, ó ṣì lágbára. Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ oníwà tútù, síbẹ̀ ká jẹ́ alágbára? Ká sòótọ́, kì í ṣe ohun tá a lè dá ṣe fúnra wa. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ká sì sọ fún un pé kó jẹ́ ká níwà tútù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti fi hàn pé èyí ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti fi hàn pé a níwà tútù nígbà táwọn èèyàn ta kò wá tàbí tí wọ́n múnú bí wa, ìyẹn sì ti jẹ́ káwọn èèyàn ní èrò tó tọ́ nípa wa. (Ka 2 Tímótì 2:24, 25.) Báwo lo ṣe lè níwà tútù, kó o sì fi hàn pé o kì í ṣe ojo?
4. Kí la kọ́ lára Ísákì nípa bá a ṣe lè níwà tútù?
4 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i pé ìwà tútù máa ń ṣeni láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ísákì. Nígbà tó pàgọ́ sí agbègbè Gérárì ní Filísínì, àwọn Filísínì tó wà lágbègbè yẹn jowú ẹ̀, wọ́n sì dí àwọn kànga tí bàbá ẹ̀ gbẹ́ pa. Dípò kí Ísákì bá wọn jà, ńṣe ló kó àwọn ará ilé ẹ̀ kúrò lágbègbè yẹn lọ sí agbègbè míì tó jìnnà, ó sì gbẹ́ àwọn kànga míì síbẹ̀. (Jẹ́n. 26:12-18) Síbẹ̀, ṣe làwọn Filísínì tún sọ pé àwọn làwọn ni omi inú àwọn kànga náà. Láìka gbogbo èyí sí, Ísákì ò bá wọn jà. (Jẹ́n. 26:19-25) Kí ló jẹ́ kó níwà tútù bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yẹn fẹ́ mọ̀ọ́mọ̀ múnú bí i? Ohun tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ lára Ábúráhámù bàbá ẹ̀ tó máa ń wá àlàáfíà àti Sérà ìyá ẹ̀ tó ní “ìwà jẹ́jẹ́ àti ìwà tútù.”—1 Pét. 3:4-6; Jẹ́n. 21:22-34.
5. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè kọ́ àwọn ọmọ wọn béèyàn ṣe ń níwà tútù?
5 Ẹ̀yin òbí, ó dájú pé ẹ̀yin náà lè kọ́ àwọn ọmọ yín pé ìwà tútù máa ń ṣeni láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Maxence tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17). Àwọn tó máa ń bínú gan-an wà nílé ìwé ẹ̀, ó sì tún máa ń bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé lóde ìwàásù. Torí náà, àwọn òbí ẹ̀ kọ́ ọ pé ó yẹ kó níwà tútù. Wọ́n sọ pé: “Maxence ti wá rí i pé ó rọrùn láti gbaná jẹ, àmọ́ ẹni tó bá ń kó ara ẹ̀ níjàánu kì í tètè bínú.” Inú wa dùn pé Maxence ti kọ́ béèyàn ṣe ń níwà tútù.
6. Báwo ni àdúrà ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ níwà tútù?
6 Kí la lè ṣe tí wọ́n bá múnú bí wa, irú bíi kẹ́nì kan sọ ohun tí ò dáa nípa Jèhófà àbí Bíbélì? Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè fọgbọ́n dá ẹni náà lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Àmọ́, tá a bá rí i pé ọ̀nà tá a gbà dá ẹni náà lóhùn ò dáa tó ńkọ́? A lè gbàdúrà nípa ẹ̀, ká sì ronú nípa bá a ṣe máa dáhùn dáadáa nígbà míì. Jèhófà máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè kó ara wa níjàánu, ká sì níwà tútù.
7. Tá a bá mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí, báwo nìyẹn ò ṣe ní jẹ́ ká gbaná jẹ? (Òwe 15:1, 18)
7 Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tí ò ní jẹ́ ká gbaná jẹ. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè jẹ́ ká rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà. (Jòh. 14:26) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìlànà tó wà nínú ìwé Òwe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ oníwà tútù. (Ka Òwe 15:1, 18.) Ìwé Bíbélì yẹn tún jẹ́ ká mọ àǹfààní tá a máa rí tá ò bá gbaná jẹ nígbà tí wọ́n bá múnú bí wa.—Òwe 10:19; 17:27; 21:23; 25:15.
ÌJÌNLẸ̀ ÒYE MÁA JẸ́ KÁ NÍWÀ TÚTÙ
8. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa ìdí tẹ́nì kan fi béèrè ìbéèrè nípa ohun tá a gbà gbọ́?
8 Nǹkan míì tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni ìjìnlẹ̀ òye. (Òwe 19:11) Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye ò ní bínú tí wọ́n bá ní kó ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn èèyàn bá bi wá ní ìbéèrè, wọn kì í sọ ìdí tí wọ́n fi béèrè ìbéèrè náà. Ìyẹn fi hàn pé a lè má mọ ìdí tí ẹni náà fi béèrè ìbéèrè yẹn. Ó lè jẹ́ pé ó fẹ́ ta kò wá tàbí kó jẹ́ pé nǹkan kan ń jẹ ẹ́ lọ́kàn ló fi béèrè ìbéèrè náà. Torí náà, á dáa ká fara balẹ̀ wádìí ká tó dáhùn.—Òwe 16:23.
9. Kí ni Gídíónì ṣe tó fi hàn pé ó ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìwà tútù nígbà táwọn ọkùnrin Éfúrémù wá bá a?
9 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Gídíónì ṣe nígbà táwọn ọkùnrin Éfúrémù wá bá a. Wọ́n fìbínú béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé kí nìdí tí ò fi pe àwọn nígbà tó kọ́kọ́ fẹ́ lọ bá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jà. Àmọ́ kí nìdí tí wọ́n fi ń bínú? Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbéraga ló wọ̀ wọ́n lẹ́wù? Èyí ó wù ó jẹ́, Gídíónì fi hàn pé òun ní ìjìnlẹ̀ òye. Ó mọ ohun tó ń bí wọn nínú, ó sì dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Kí ni wọ́n wá ṣe? Ìbínú wọn rọlẹ̀, “ara wọn [sì] balẹ̀.”—Oníd. 8:1-3.
10. Kí ló máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa dáhùn ìbéèrè àwọn tó ní ká ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́? (1 Pétérù 3:15)
10 Ó ṣeé ṣe kẹ́ni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí ọmọ ilé ìwé wa bi wá pé kí nìdí tá a fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì kan? A máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti jẹ́ kẹ́ni náà rí i pé ohun tí Bíbélì sọ ló tọ̀nà, bá a sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún ẹni náà. (Ka 1 Pétérù 3:15.) Dípò ká máa ronú pé ẹni náà ń ta kò wá, ṣe ló yẹ ká rí i bí àǹfààní láti dáhùn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Ohun yòówù kó mú kẹ́nì kan béèrè ìbéèrè, ó yẹ ká fara balẹ̀ dá a lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Ohun tá a bá sọ lè mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà. Kódà tẹ́nì kan bá rín wa fín tàbí tó sọ̀rọ̀ àbùkù sí wa, ó ṣì yẹ ká dá a lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́.—Róòmù 12:17.
11-12. (a) Kí ló yẹ ká ronú nípa ẹ̀ ká tó dáhùn ìbéèrè tó le? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Sọ àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá béèrè ìbéèrè, ó lè jẹ́ kẹ́nì kan fara balẹ̀ tẹ́tí sí wa.
11 Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lè bi wá pé kí nìdí tó fi jẹ́ pé a kì í ṣe ọjọ́ ìbí? Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé ẹ̀sìn wa ò gbà wá láyè láti gbádùn ara wa? Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa rò pé bá ò ṣe kí í bá wọn ṣe àwọn ayẹyẹ kan ò ní jẹ́ káwọn ará ibiṣẹ́ máa ṣe nǹkan pa pọ̀, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn? Tó bá jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀ tá a bá jẹ́ kó mọ̀ pé a mọyì bó ṣe ń sapá láti jẹ́ kára tu àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ká jẹ́ kó mọ̀ pé àwa náà fẹ́ kí ìfẹ́ wà láàárín àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe ká láǹfààní láti ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ìbí fún un.
12 A tún lè kọ́kọ́ béèrè àwọn ìbéèrè kan tẹ́nì kan bá bi wá láwọn ìbéèrè tó le. Ọmọ ilé ìwé wa kan lè sọ pé káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí èrò wa pa dà nípa àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Torí náà, ó yẹ ká béèrè pé kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ṣé torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ ni àbí ṣé ó lè jẹ́ pé ọ̀rẹ́ ẹ̀ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan jẹ́ abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀? Ṣé ó ronú pé a kórìíra àwọn abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ ni? Á dáa ká jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo èèyàn la máa ń fìfẹ́ hàn sí, a sì mọ̀ pé kálukú ló máa pinnu ohun tóun máa fayé òun ṣe.b (1 Pét. 2:17) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fún wa láǹfààní láti jẹ́ kó mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà àti pé àwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣe wá láǹfààní tá a bá tẹ̀ lé e.
13. Tẹ́nì kan bá sọ pé òmùgọ̀ làwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà, báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́?
13 Tẹ́nì kan bá ta ko ohun tá a gbà gbọ́, kò yẹ ká gbà pé a mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. (Títù 3:2) Bí àpẹẹrẹ, tí ọmọ ilé ìwé ẹ kan bá sọ pé òmùgọ̀ làwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà ńkọ́? Ṣé ó yẹ kó o rò pé ó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, ó sì mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó má tíì ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà rí. Dípò tí ẹ̀ẹ́ fi máa jiyàn nípa ohun tí ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì sọ nípa ọ̀rọ̀ náà, ṣé o lè fún un ní ohun kan tó máa ṣèwádìí nípa ẹ̀ táá jẹ́ kó ronú jinlẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kó lọ ka ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá lórí ìkànnì jw.org. Tó bá yá, ó lè fẹ́ jíròrò àpilẹ̀kọ tó kà tàbí fídíò tó wò níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé tá a bá ṣàlàyé fún wọn lọ́nà yìí, tá a sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ó lè mú kí wọ́n yí èrò wọn pa dà.
14. Báwo ni Niall ṣe lo ìkànnì wa láti ran ọmọ kíláàsì ẹ̀ lọ́wọ́ kó lè tún èrò ẹ̀ ṣe nípa ohun tí ò dáa tó gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
14 Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Niall lo ìkànnì wa láti tún èrò àwọn èèyàn ṣe nípa ohun tá a gbà gbọ́. Ó sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni ọmọ kíláàsì mi kan máa ń sọ pé ìdí tí mi ò fi gba ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì gbọ́ ni pé ìwé kan lásán ni mo gbà gbọ́ dípò kí n gba òtítọ́ gbọ́.” Nígbà tí ọmọ kíláàsì Niall ò jẹ́ kó ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́, ó ní kó lọ sórí ìkànnì jw.org, kó sì wo abala “Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì.” Nígbà tó yá, Niall kíyè sí i pé ó jọ pé ọmọ náà ti ka àwọn àpilẹ̀kọ yẹn, ó sì fẹ́ káwọn jíròrò nípa ẹni tó dá àwọn nǹkan. Táwa náà bá ń ṣe bíi ti Niall, àwọn èèyàn á túbọ̀ máa tẹ́tí sí wa.
Ẹ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ YÍN NÍ OHUN TÍ WỌ́N MÁA SỌ
15. Báwo làwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́ táwọn ọmọ ilé ìwé wọn bá ní kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́?
15 Ó yẹ kẹ́yin òbí kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́ tí wọ́n bá ní kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (Jém. 3:13) Àwọn òbí kan máa ń fi dánra wò nígbà ìjọsìn ìdílé. Wọ́n máa ń jíròrò àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi àwọn ọmọ wọn nílé ìwé, wọ́n á sọ bí wọ́n ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè náà àti bí wọ́n ṣe máa sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́.—Wo àpótí náà “Ìdánrawò Máa Ran Ìdílé Yín Lọ́wọ́.”
16-17. Báwo ni ìdánrawò ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́?
16 Táwọn ọ̀dọ́ bá ń ṣe ìdánrawò bí wọ́n ṣe máa ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ìyẹn á jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ dá wọn lójú. Ìwé àjákọ fún àwọn ọ̀dọ́ wà ní abala “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” lórí ìkànnì jw.org. Wọ́n ṣe ìwé yẹn lọ́nà táá jẹ́ kí ohun táwọn ọ̀dọ́ gbà gbọ́ dá wọn lójú, wọ́n á sì lè dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé bá jọ lo ìwé àjákọ náà, wọ́n á kọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́.
17 Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Matthew sọ bí ìdánrawò ṣe ran òun lọ́wọ́. Tí Matthew àtàwọn òbí ẹ̀ bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé, wọ́n máa ń ṣèwádìí nípa àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi í nílé ìwé. Ó sọ pé: “A máa ń ronú nípa àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀, àá wá fi àwọn ohun tá a kọ́ nígbà tá a ṣèwádìí nípa wọn dánra wò. Tó bá dá mi lójú pé òótọ́ lohun tí mo gbà gbọ́, ọkàn mi máa ń balẹ̀, ó sì máa ń rọrùn fún mi láti ṣàlàyé ẹ̀ fáwọn èèyàn lọ́nà pẹ̀lẹ́.”
18. Kí ni Kólósè 4:6 sọ pé ká máa ṣe?
18 Òótọ́ kan ni pé kì í ṣe gbogbo èèyàn tá a fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ fún ló máa gba ohun tá a sọ. Àmọ́ tá a bá fọgbọ́n ṣàlàyé lọ́nà pẹ̀lẹ́, àá lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Kólósè 4:6.) A lè fi bá a ṣe ń ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ wé bí ẹnì kan ṣe ń ju bọ́ọ̀lù sí ẹlòmíì. A lè rọra ju bọ́ọ̀lù náà, a sì lè fagbára jù ú. Tá a bá rọra jù ú, ó ṣeé ṣe kẹ́ni tá a jù ú sí rí i mú, ká sì jọ máa gbádùn eré náà lọ. Lọ́nà kan náà, tá a bá fọgbọ́n ṣàlàyé lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn gbọ́ wa, kí wọ́n sì fẹ́ ká máa bá ìjíròrò náà lọ. Àmọ́ ṣá o, tá a bá rí i pé ẹnì kan ń bá wa jiyàn tàbí pé ó ń ta ko ohun tá a gbà gbọ́, kò pọn dandan ká máa bá ìjíròrò náà lọ. (Òwe 26:4) Àmọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ò wọ́pọ̀ torí ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa fetí sí wa.
19. Kí ló máa jẹ́ ká ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́?
19 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti rí i pé tá a bá níwà tútù, ó máa ṣe wá láǹfààní. Táwọn èèyàn bá bi ẹ́ ní ìbéèrè tó le tàbí tí wọ́n ta kò ẹ́, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ lókun kó o lè dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́. Máa rántí pé tó o bá dáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, ọ̀rọ̀ náà ò ní di àríyànjiyàn. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá níwà tútù, tó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn, ìdáhùn ẹ lè mú káwọn kan yí èrò tí wọ́n ní nípa Bíbélì àti nípa wa pa dà. Torí náà, ó yẹ ká “ṣe tán nígbà gbogbo láti gbèjà” ohun tá a gbà gbọ́, àmọ́ ká “máa fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìwà tútù máa fún wa lágbára!
ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn àbá tá a lè tẹ̀ lé táwọn èèyàn bá múnú bí wa tàbí tí wọ́n sọ pé ká fi dandan ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ àti bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìwà tútù.
b Wo ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú àpilẹ̀kọ náà “Ṣé Bíbélì Fàyè Gbà Á Pé Kí Ọkùnrin Fẹ́ Ọkùnrin?” nínú Jí! No. 4, 2016.
c Wàá rí àwọn àbá tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org ní abala “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” àti “Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”