Ṣé Òtítọ́ Ṣì Lérè?
Ǹjẹ́ o ti kíyè sí pé ó ṣòro fáwọn èèyàn níbi gbogbo láyé láti máa sòótọ́? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn èèyàn àti èrò wọn ni wọ́n fi máa ń pinnu ohun tó jóòótọ́, dípò kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé kò síbi tá a yíjú sí láyé yìí tá ò ní rí i pé òótọ́ ti sọnù.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí kì í ṣe nǹkan tuntun. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì (2,000) sẹ́yìn, Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ Gómìnà Róòmù kàn fẹ́ gbọ́ tẹnu Jésù, ó wá bi Jésù pé: “Kí ni òtítọ́?” (Jòhánù 18:38) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbéèrè ẹ̀ ṣe pàtàkì, kò dúró gbọ́ ìdáhùn. Wàá rí ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè yìí, ìyẹn á sì jẹ́ kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe nínú ayé tí òótọ́ ti sọnù yìí.
Ṣé òtítọ́ ṣì wà lónìí?
Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “òtítọ́” láti tọ́ka sí ohun tó jẹ́ òótọ́ délẹ̀délẹ̀ àti ohun tó jẹ́ mímọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófàa Ọlọ́run ni orísun òtítọ́ nígbà tó pè é ní “Ọlọ́run òtítọ́.” (Sáàmù 31:5) Òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, ó sì fi òtítọ́ yìí wé ìmọ́lẹ̀ tó ń tọ́ wa sọ́nà nínú ayé tó ṣókùnkùn yìí.—Sáàmù 43:3; Jòhánù 17:17.
Báwo lo ṣe lè rí òtítọ́?
Ọlọ́run ò fẹ́ ká kàn gba òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì gbọ́ láì ronú jinlẹ̀, tàbí ká gbà á gbọ́ torí bí nǹkan ṣe rí lára wa. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó rọ̀ wá pé ká lo agbára ìrònú wa. (Róòmù 12:1) Ó fẹ́ ká mọ òun ká sì nífẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú “gbogbo èrò” wa. Bákan náà, ó gbà wá níyànjú pé ká rí i pé òtítọ́ tá a kọ́ nínú Bíbélì dá wa lójú.—Mátíù 22:37, 38; Ìṣe 17:11.
Tá ló kọ́kọ́ parọ́?
Bíbélì sọ pé ọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run ni irọ́ ti bẹ̀rẹ̀. Abájọ tí Jésù fi pè é ní “baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Ó parọ́ mọ́ Ọlọ́run nígbà tó ń bá Adámù àti Éfà tó jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 13, 17-19; 5:5) Látìgbà yẹn ni Sátánì ti ń tan irọ́ kálẹ̀ tó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwọn èèyàn má bàa mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.—Ìfihàn 12:9.
Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń parọ́ gan-an lónìí?
Sátánì ń lo agbára ẹ̀ láti darí àwọn èèyàn kó sì ṣí wọ́n lọ́nà, ní pàtàkì lákòókò wa yìí tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1, 13) Irọ́ ló kún inú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn lónìí. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lákòókò wa yìí àwọn èèyàn “á fi àwọn olùkọ́ yí ara wọn ká, kí wọ́n lè máa sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́,” ‘wọn ò sì ní fetí sí òtítọ́ mọ́’.—2 Tímótì 4:3, 4.
Kí nìdí tí òtítọ́ fi ṣe pàtàkì?
Káwọn èèyàn tó lè fọkàn tán ara wọn, ó ṣe pàtàkì kí wọ́n máa bára wọn sọ òótọ́. Kò lè sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tàwọn èèyàn ò bá fọkàn tán ara wọn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn tó ń jọ́sìn [Ọlọ́run] sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ìyẹn fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí ìjọsìn wa dá lórí òtítọ́. Tó o bá fẹ́ mọ bí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ṣe lè jẹ́ kó o mọ irọ́ tí àwọn ẹlẹ́sìn fi n kọ́ni lónìí àtohun tó o lè ṣe kí wọ́n má baà kó èèràn ràn ẹ́, ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Irọ́ Tí Kò Jẹ́ Káwọn èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.”
Kí nìdí tí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó o mọ òtítọ́?
Ọlọ́run fẹ́ kó o wà láàyè títí láé, àmọ́ kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe wàá kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run nínú Bíbélì. (1 Tímótì 2:4) Wàá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà rẹ̀ tó dá lórí ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, tó o sì ń fi wọ́n sílò. (Sáàmù 15:1, 2) Ọlọ́run rán Jésù wá sí ayé, káwa èèyàn lé mọ òtítọ́. Ohun tí Ọlọ́run sì fẹ́ ni pé, ká máa tẹ́tí sáwọn ẹ̀kọ́ Jésù.—Mátíù 17:5; Jòhánù 18:37.
Ṣé Ọlọ́run máa fòpin sí irọ́ pípa?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run kórìíra kéèyàn máa parọ́, kò sì fẹ́ ká máa tan àwọn míì jẹ. Ó sọ pé òun máa pa àwọn tí ò yéé parọ́ run. (Sáàmù 5:6) Lẹ́yìn náà, á mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Ètè tó ń sọ òtítọ́ máa wà títí láé.”—Òwe 12:19.
a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Ka àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?”