Kí Ni Ẹranko Ẹhànnà Olórí Méje Inú Ìṣípayá Orí Kẹtàlá Dúró Fún?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹranko ẹhànnà olórí méje tí Ìṣípayá 13:1 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ dúró fún àpapọ̀ ètò ìṣèlú àgbáyé.
Ó ní ọlá àṣẹ, ó ní agbára, ó sì ní ìtẹ́ kan, gbogbo èyí fi hàn pé ó jẹ́ ètò ìṣèlú.—Ìṣípayá 13:2.
Ó ń ṣàkóso lórí “gbogbo ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n àti orílẹ̀-èdè,” torí náà ó ju ìjọba orílẹ̀-èdè kan lọ.—Ìṣípayá 13:7.
Ó láwọn ohun tó jọra pẹ̀lú àwọn ẹranko ẹhànnà mẹ́rin tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì 7:2-8. Bí àpẹẹrẹ, ara rẹ̀ rí bíi ti àmọ̀tẹ́kùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ jọ ti béárì, ẹnu rẹ̀ dà bíi ti kìnnìún, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. Àwọn ẹranko ẹhànnà tí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì mẹ́nu bà dúró fún àwọn ọba kan ní pàtó tàbí àwọn ìjọba kan tó ṣàkóso tẹ̀ léra lórí àwọn ilẹ̀ ọba. (Dáníẹ́lì 7:17, 23) Torí náà, ẹranko ẹhànnà inú ìwé Ìṣípayá orí kẹtàlá dúró fún àjọ ìṣèlú kan tí àwọn ìjọba tó para pọ̀ wà nínú rẹ̀.
Ó jáde wá “láti inú òkun,” ìyẹn látinú aráyé oníjàgídíjàgan tó jẹ́ orísun àwọn ìjọba èèyàn.—Ìṣípayá 13:1; Aísáyà 17:12, 13.
Bíbélì sọ pé orúkọ ẹranko ẹhànnà náà tàbí nọ́ńbà orúkọ rẹ̀, ìyẹn 666, jẹ́ “nọ́ńbà ènìyàn.” (Ìṣípayá 13:17, 18) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá orí kẹtàlá dúró fún ètò tó ń lọ láàárín ọmọ aráyé, kì í ṣe láàárín àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tàbí ẹ̀mí èṣù.
Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn orílẹ̀-èdè ò fohùn ṣọ̀kan lé lórí, síbẹ̀ gbogbo wọn pinnu láti máa ṣàkóso fúnra wọn dípò kí wọ́n jẹ́ kí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso. (Sáàmù 2:2) Ní Amágẹ́dọ́nì, wọ́n tún máa kóra jọ láti bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run tí Jésù Kristi máa ṣáájú jagun, àmọ́ ìparun ni ogun yìí máa yọrí sí fún àwọn orílẹ̀-èdè.—Ìṣípayá 16:14, 16; 19:19, 20.
“Ìwo mẹ́wàá àti orí méje”
Bíbélì máa ń lo àwọn nọ́ńbà kan lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Bí àpẹẹrẹ, ẹẹ́wàá àti eéje máa ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó pé pérépéré. Ohun pàtàkì tó lè jẹ́ ká mọ ohun tí “ìwo mẹ́wàá àti orí méje” ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá orí kẹtàlá túmọ̀ sí ni “ère ẹranko ẹhànnà náà” tí ìwé Ìṣípayá tún sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. (Ìṣípayá 13:1, 14, 15; 17:3) Bíbélì sọ pé orí méje ẹranko ẹhànnà aláwọ̀ rírẹ̀dòdò yìí túmọ̀ sí “ọba méje,” tàbí àwọn ìjọba.—Ìṣípayá 17:9, 10.
Lọ́nà kan náà, orí méje ẹranko ẹhànnà inú Ìṣípayá 13:1 dúró fún ìjọba méje, ìyẹn àwọn ìjọba ayé tó lágbára gan-an bí ìtàn ṣe sọ, tí wọ́n sì mú ipò iwájú nínú ṣíṣe inúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn ni Íjíbítì, Ásíríà, Bábílónì, Mídíà òun Páṣíà, Gíríìsì, Róòmù, àti Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà. Tá a bá wá sọ pé ìwo mẹ́wàá náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo orílẹ̀-èdè tó ti dòmìnira, yálà wọ́n kéré tàbí wọ́n tóbi, nígbà náà adé dáyádémà tó wà lórí ìwo kọ̀ọ̀kan fi hàn pé orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóò máa ṣàkóso nígbà kan náà pẹ̀lú agbára ayé tó bá jẹ́ olórí lákòókò yẹn.