Báwo Lo Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ṣèlérí pé: “Ẹni tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ máa wà láàyè títí láé.” (1 Jòhánù 2:17, Bíbélì Holy Bible—Easy-to-Read Version) Kí ni Ọlọ́run fẹ́ kó o ṣe?
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti Jésù, Ọmọ rẹ̀. Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Kí ni ‘gbígba ìmọ̀’ Ọlọ́run àti Jésù ní nínú? A lè mọ̀ wọ́n tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń fi ohun tá a kọ́ níbẹ̀ ṣèwà hù nígbèésí ayé wa.a Bíbélì jẹ́ ká mọ bí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa tó fún wa ní ìwàláàyè, ṣe ń ronú. (Ìṣe 17:24, 25) Bíbélì tún sọ fún wa nípa Jésù, Ọmọ rẹ̀, ẹni tó fi “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun” kọ́ni.—Jòhánù 6:67-69.
Lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Jésù wá sáyé láti “ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà.” (Mátíù 20:28) Ẹbọ ìràpadà Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn èèyàn láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.b (Sáàmù 37:29) Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Fi sọ́kàn pé ó ju pé kéèyàn kàn sọ pé òun gba Jésù gbọ́ lọ. A gbọ́dọ̀ ‘lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,’ ìyẹn ni pé ká yàn láti máa fi àwọn ohun tó kọ́ wa ṣèwà hù, ká sì máa ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀.—Mátíù 7:21; Jákọ́bù 2:17.
Jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run lágbára. Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun, ká sì di ọ̀rẹ́ òun. (Jákọ́bù 2:23; 4:8) Títí ayé ni Ọlọ́run máa wà. Kò lè kú láé, ó sì fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ òun náà wà láàyè títí láé. Ọlọ́run sọ ohun tó fẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń wá a nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Kí ọkàn-àyà yín wà láàyè títí láé.”—Sáàmù 22:26.
Àṣìlóye Táwọn Èèyàn Ní Nípa Wíwà Láàyè Títí Láé
Àṣìlóye: Ìsapá ẹ̀dá èèyàn máa mú ìyè àìnípẹ̀kun wá.
Òtítọ́: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú tó ti bá ìmọ̀ ìṣègùn jẹ́ ká rí i pé àwọn onímọ̀ ìṣègùn lè mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn sí i, irú ìsapá bẹ́ẹ̀ ò lè mú ìyè àìnípẹ̀kun wá. Ọlọ́run nìkan ló lè fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, torí òun nìkan ni “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9) Ó ṣèlérí pé òun máa “gbé ikú mì títí láé”, òun á sì fún gbogbo èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Aísáyà 25:8; 1 Jòhánù 2:25.
Àṣìlóye: Àwọn tó bá wá láti ẹ̀yà kan pàtó nìkan ló máa wà láàyè títí láé.
Òtítọ́: Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Àwọn èèyàn láti gbogbo ẹ̀yà àti ilẹ̀ lóríṣiríṣi tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lè gbé títí láé.
Àṣìlóye: Téèyàn bá wà láàyè títí láé, ayé máa súùyàn.
Òtitọ́: Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì fẹ́ ká máa láyọ̀ ló sọ pé òun máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jákọ́bù 1:17; 1 Jòhánù 4:8) Ó mọ̀ pé tá a bá máa láyọ̀, ó yẹ ká máa ṣiṣẹ́ tó nítumọ̀. (Oníwàásù 3:12) Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn tó bá wà láàyè títí láé ní ayé máa ní iṣẹ́ tó nítumọ̀, tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn tó máa ṣe àwọn àtàwọn èèyàn wọn láǹfààní.—Aísáyà 65:22, 23.
Bákan náà, títí lọ làwọn tó bá wà láàyè títí láé á máa kọ́ ohun tuntun nípa Ẹlẹ́dàá wọn àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tó dá. Ọlọ́run dá a mọ́ àwa èèyàn pé kó máa wù wá láti wà láàyè títí láé, ká sì máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní lè “rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” (Oníwàásù 3:10, 11) Torí náà, gbogbo ìgbà ni àwọn tó bá wà láàyè títí láé á máa rí ohun tuntun kọ́, tí wọ́n á sì máa rí ohun tó dùn mọ́ wọn ṣe.
a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò tá a pè ní Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?”