Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀rẹ́ Kan Bá Wọ Gàù?
Sherrie, ọmọ ọdún 14, sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi tí mo fẹ́ràn jù lọ sú lọ kúrò nínú ètò Kristian. Ó bà mí nínú jẹ́. Mo ti sapá gidigidi láti ràn án lọ́wọ́!”a
ẸNÌ kan tí ó sún mọ́ ọ ha ti wọ gàù rí bí tàbí kí ó bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé àṣà ìgbésí ayé tí kò tọ̀nà? Johnny sọ pé: “Mo sún mọ́ Chris. Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni wá. Ní ọjọ́ kan, ó sá lọ kúrò nílé. Èyí mú mi dààmú, mo sì fẹ́ láti sá tẹ̀ lé e. Mo wakọ̀ ní gbogbo òru, mo sì ń wá a kiri.”
Bibeli kìlọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ìkìmọ́lẹ̀ gíga yóò wà lórí àwọn ènìyàn, àtèwe àtàgbà. (2 Timoteu 3:1-5) Nítorí náà, kò ní láti dààmú wa nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ nígbà míràn pé Kristian ọ̀dọ́ kan ṣi ẹsẹ̀ gbé. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan tí o bìkítà nípa rẹ̀, o lè ní onírúurú ìmọ̀lára, bẹ̀rẹ̀ láti orí ìbànújẹ́ àti ìyọ́nú dé orí ìbínú. O fẹ́ ran ọ̀rẹ́ rẹ lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n báwo ní o ṣe lè ṣe é?
‘Mo Lè Gbà á Là’
Bibeli sọ pé: “Ẹni tí ó yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò ninu ìṣìnà ọ̀nà rẹ̀ yoo gba ọkàn [ẹlẹ́ṣẹ̀ náà] là kúrò lọ́wọ́ ikú yoo sì bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (Jakọbu 5:20) Ṣùgbọ́n èyí ha túmọ̀ sí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹrù iṣẹ́ rẹ? Kò pọn dandan. Àwọn òbí ọ̀rẹ́ rẹ ni wọ́n ni lájorí ẹrù iṣẹ́ bíbójú tó o. (Efesu 6:4) Bibeli tẹ̀ síwájú láti sọ nínú Galatia 6:1 pé: “Ẹ̀yin ará, bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nipa rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ tóótun nipa ti ẹ̀mí ẹ gbìyànjú lati tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà ninu ẹ̀mí ìwàtútù.” Àwọn alábòójútó ìjọ ní pàtàkì tóótun nígbà tí ó bá di irú ọ̀ràn yìí. Nípa báyìí, wọ́n wà ní ipò tí ó dára jù láti ṣèrànwọ́ jù ọ́ lọ.
O gbọ́dọ̀ mọ̀ pé, gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ kan, o ní ìrírí tí kò tó nǹkan nínú ìgbésí ayé. (Fi wé Heberu 5:14.) Nítorí náà, mọ̀wọ̀n ara rẹ nínú ọ̀ràn yìí, kí o sì yẹra fún fífi gọ̀gọ̀ fa ohun tí ọwọ́ rẹ kò tó. (Owe 11:2) Gbé ọ̀ràn ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Rebekah yẹ̀ wò. Ó gbìyànjú láti ran ọ̀rẹ́kùnrin kan tí ó jẹ́ ìbátan rẹ̀ tí ó ti kó wọnú ìlòkulò oògùn lọ́wọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Ohun tí ó gbé ìkìmọ́lẹ̀ ka orí mi ni pé ó ń finú hàn mí, kò sì fi han àwọn òbí rẹ̀. Mo gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́, ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Ó rọrùn fún mi nígbà tí mo mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé n kò lè ṣe ohunkóhun . . . n kò lè jẹ́ olùgbàlà rẹ̀.” Nígbà náà, Rebekah rọ̀ ọ́ láti wá ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbà títóótun.
Matthew ọ̀dọ́ wà ní ipò tí ó fara jọra, ṣùgbọ́n ó tètè mọ ìwọ̀n ara rẹ̀. Ó sọ nípa ọ̀rẹ́ kan tí ó wọ gàù pé: “Yóò gbé ìṣòro rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ fún un pé kí ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Mo lóye ju pé kí ń máa gbé ẹrù ìṣòro rẹ̀ lọ.”
Bí O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Èyí kò túmọ̀ sí pé o kò lè ṣe ohunkóhun láti ṣèrànwọ́. Púpọ̀ sinmi lórí bí ọ̀ràn náà bá ti rí. Ọ̀rẹ́ rẹ lè fẹ́ láti máa finú hàn ọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, ìwọ yóò fẹ́ láti ṣètìlẹyìn, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀. (Owe 18:24; 21:13) Tàbí ó lè jẹ́ pé ó ti ń tẹ̀ lé àṣà ìgbésí ayé tí kò tọ̀nà. Yóò jẹ́ ohun yíyẹ láti lo ìdánúṣe, kí o sì sọ fún un pé, bí o tilẹ̀ bìkítà nípa rẹ̀, o kò lè tẹ́wọ́ gba ohun tí ó ń ṣe.
Nínú ipò ọ̀ràn míràn, ó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ kan tí ó jẹ́wọ́ pé òún ti lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́ wíwúwo. Ó tilẹ̀ lè gbìyànjú láti mú ọ ṣèlérí pé ìwọ kò ní sọ fún ẹnì kankan. Ṣùgbọ́n Bibeli sọ pé: “Máṣe . . . jẹ́ alájọpín ninu ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹlòmíràn; fi ààbò pa ara rẹ mọ́ ní oníwàmímọ́.” (1 Timoteu 5:22) Bí ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ṣàìsàn gidigidi, tí ó sì nílò ìrànlọ́wọ́ ìṣègùn, ìwọ kì yóò ha fi dandan lé e pé ìwọ yóò gbé e lọ sí ọ̀dọ̀ dókítà? Bákan náà, bí òún bá ti kó sínú ìwà àìtọ́ wíwúwo, òún nílò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí. Láti pa ọ̀ràn náà mọ́ ní àṣírí lè ṣekú pa á nípa tẹ̀mí—o sì lè nípa búburú lórí ìjọ. Nítorí náà, o ní ẹrù iṣẹ́ láti rí i dájú pé, a sọ fún àwọn alàgbà ìjọ.—Fi wé Lefitiku 5:1.
Caroline ọ̀dọ́ mú ìdúró onígboyà nípa ọ̀rẹ́ oníwà wíwọ́ kan tí ó ń purọ́ fún àwọn òbí rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo fún un ní ọ̀sẹ̀ méjì láti fi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà. Mo sọ fún un pé, bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Èyí kò rọrùn fún mi láti ṣe.” Johnny, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, fi irú ìgboyà kan náà hàn. Johnny sọ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé ó ń gbé pẹ̀lú ọmọdébìnrin kan. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mìíràn wà níbẹ̀ pẹ̀lú tí wọ́n ń mu ọtí àti sìgá.” Johnny pe ọ̀rẹ́ rẹ̀ jáde, ó sì dámọ̀ràn tìgboyàtìgboyà pé kí ó wá ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà nínú ìjọ.
Ọ̀rẹ́ rẹ lè mọrírì ìsapá rẹ, ó sì lè má mọrírì rẹ̀. Bibeli sọ fún wa pé, nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n Josefu lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà ‘mú ìròyìn búburú wọn wá fún bàbá wọn.’ Dájúdájú, èyí kò bù kún ìfùsì rẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ní tòótọ́, ‘wọ́n kórìíra rẹ̀.’—Genesisi 37:2-4.
Ti Ṣíṣe Bí Ẹni Pé Kò Sí Láburú Kankan Ńkọ́?
Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ yóò jin ìsapá rẹ láti ṣèrànwọ́ lẹ́sẹ̀ bí o bá ń bá ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ nìṣó bí ẹni pé kò sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nínú 1 Korinti 15:33, aposteli Paulu kìlọ̀ fún àwọn Kristian lòdì sí kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn oníwà àìtọ́. Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò wulẹ̀ kó bá ọ ni!
Mollie ọ̀dọ́ kẹ́kọ̀ọ́ èyí lọ́nà líle koko, nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Sally bẹ̀rẹ̀ sí í dájọ́ àjọròde níkọ̀kọ̀. Kì í ṣe kìkì pé Sally kéré jù láti ṣègbéyàwó nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń ròde pẹ̀lú àwọn ọmọdékùnrin tí wọn kì í ṣe Kristian. Mollie dágunlá sí ipò ọ̀ràn náà, ó sì ń bá a nìṣó láti máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Mollie sọ pé: “Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Sally ṣètò fún èmi àti ọmọdékùnrin ayé kan, a sì jọ ròde.” Ó dùn mọ́ni pé, Mollie rí ìrànwọ́ gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ, kí ipò ọ̀ràn náà tóó burú jù.
Bákan náà, Lynn gbọ̀jẹ̀gẹ́ lọ́nà tí ó léwu, kí ó ba lè pa ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú ọmọdébìnrin kan tí ń jẹ́ Beth. Lynn sọ pé: “Mo rò pé mo lè gbà á là, ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe. Mo lọ sí àwọn àpèjẹ alẹ́ pẹ̀lú rẹ̀. Mo mọ̀ pé kò tọ́, ṣùgbọ́n n kò fẹ́ bà á nínú jẹ́. Ìṣòro rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bò mí mọ́lẹ̀. N kò sọ nǹkan kan nípa ọ̀ràn náà, ní ríronú pé ìṣòro náà yóò tán, ṣùgbọ́n, ó tóbi sí i.” Ọ̀ràn ìbànújẹ́ ṣojú Lynn wáí. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ Beth ni ọkùnrin ọ̀dọ́ tí ó ń bá ròde ṣekú pa.
Rírọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ọ̀rẹ́ kan lè dà bí ohun tí ó bójú mu. Ṣùgbọ́n, bí ọ̀rẹ́ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í rì sínú alagbalúgbú omi, ìwọ pẹ̀lú yóò ha bẹ́ sínú rẹ̀ bí? Ẹ̀yin méjèèjì yóò wulẹ̀ kú sínú omi ni. Ohun tí ó bá ọgbọ́n mú láti ṣe yóò jẹ́ láti ju ohun kan tí yóò dáàbò bo ìwàláàyè rẹ̀ sí i. Bákan náà, o ní láti pèsè ìrànwọ́ láti ọ̀kánkán.—Juda 22, 23.
Jíjìnnà sí ọ̀rẹ́ rẹ pọn dandan bí a bá lé e jáde nínú ìjọ. Àṣẹ Bibeli ni pé kí a “jáwọ́ dídarapọ̀ ninu ìbákẹ́gbẹ́pọ̀” pẹ̀lú ẹni yẹn. (1 Korinti 5:11) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o bìkítà nípa ẹni yẹn, o lè ràn án lọ́wọ́ jù lọ nípa fífi ìdúró ṣinṣin hàn sí Jehofa, kì í ṣe nípa títẹ̀ lé e lọ sínú ìwà àìtọ́. (Orin Dafidi 18:25) Ìdúró aláìgbọ̀jẹ̀gẹ́ rẹ lè jẹ́ ohun náà gan-an tí yóò ràn án lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìdúróṣinṣin rẹ yóò mú ìdùnnú bá Jehofa.—Owe 27:11.
Ẹrù Tí Ó Pọ̀ Jù
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, gbogbo ìgbìyànjú ẹnì kan láti ṣèrànwọ́ lè já sí pàbó. Rebekah sọ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Mo gbìyànjú láti kàn sí i kí n sì ràn án lọ́wọ́. Mo tilẹ̀ kọ̀wé sí i, ṣùgbọ́n kò dá èsì padà.” Caroline rí i pé, lẹ́yìn gbígbìyànjú fún ọ̀pọ̀ oṣù láti ran ọ̀rẹ́ kan tí ń fa ìjọ̀ngbọ̀n lẹ́sẹ̀ lọ́wọ́, “ó bẹ̀rẹ̀ sí í sú òun.”
Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé “olúkúlùkù wa ni yoo ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọrun.” (Romu 14:12) Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti gbé àwọn ẹrù ìnira tàbí ìṣòro ara ẹni rẹ̀, nípa pípèsè ìrànwọ́ ṣíṣeé múlò, ìwọ kò wulẹ̀ lè gbé “ẹrù” ẹlòmíràn ni—ìyẹn ni, ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ sí Ọlọrun. Bibeli sọ pé: “Olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Galatia 6:5) Ìwọ kọ́ ni yóò jíhìn fún àwọn yíyàn tí ọ̀rẹ́ rẹ bá ṣe.
Bí ó ti wù kí ó rí, wíwo ọ̀rẹ́ kan tí ń ba ìgbésí ayé ara rẹ̀ jẹ́ máa ń bani nínú jẹ́. Ọkùnrin ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Mike sọ nípa ọ̀rẹ́ kan tí ó pàdánù pé: “Ó bà mí nínú jẹ́ gidigidi. Mo sún mọ́ Mark àti àwọn òbí rẹ̀ gan-an. Mo sorí kọ́ díẹ̀.”
Ó wulẹ̀ jẹ́ ìwà ẹ̀dá láti banú jẹ́ nítorí irú àdánù bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, jíjíròrò ìmọ̀lára rẹ pẹ̀lú ẹnì kan tí ìwọ́ gbẹ́kẹ̀ lé lè ṣèrànwọ́. (Owe 12:25) Rebekah sọ pé: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn òbí mi, ó ṣeé ṣe fún mi láti borí rẹ̀.” O tún lè sọ ìmọ̀lára rẹ fún Jehofa Ọlọrun nínú àdúrà. (Orin Dafidi 62:8) Caroline ṣàkópọ̀ ọ̀ràn náà dáradára nípa sísọ pé: “Gbígbàdúrà sí Jehofa àti wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn ràn mí lọ́wọ́ gidigidi. Mo tún sún mọ́ àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ, ní pàtàkì, àwọn àgbà obìnrin. Mo wá mọ̀ ní paríparí rẹ̀ pé, àwọn ènìyàn yóò jíhìn fún àwọn ìgbésẹ̀ wọn, àti pé, mo ní láti máa bá ìgbésí ayé mi nìṣó.” Nípa ṣíṣe gbogbo ìyẹn, ìwọ dájúdájú yóò ran ara rẹ lọ́wọ́. O sì lè ran ọ̀rẹ́ rẹ oníwà wíwọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Díẹ̀ ti yí padà nínú àwọn orúkọ yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Fún ọ̀rẹ́ rẹ níṣìírí láti wá ìrànlọ́wọ́