Ojú Ìwòye Bibeli
Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristian Kín Ìfìyà-Ikú-Jẹni Lẹ́yìn Bí?
“KÒ TỌ̀NÀ ní ti ìwà híhù àti ìlànà ìwà rere.” “Ó bójú mu, ó sì tọ́.” Ojú ìwòye tí ó ta kora yìí jẹ́ ti àwọn àlùfáà méjì, tí àwọn méjéèjì jẹ́ Kristian aláfẹnujẹ́ lásán. Wọ́n ń jiyàn lórí ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn ṣíṣe pàtàkì lónìí—Ìfìyà-ikú-jẹni. Nígbà tí àpilẹ̀kọ inú ìwé agbéròyìnjáde kan ń fa ọ̀rọ̀ wọn yọ, ó sọ pé: “Nígbà tí àwọn olórí ìsìn bá ń jiyàn lórí ìfìyà-ikú-jẹni, àwọn ìhà méjèèjì ń fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Bibeli láti kín ohun tí wọ́n ń sọ lẹ́yìn.”
Àwọn kan sọ pé ìfìyà-ikú-jẹni ń dàábò bo àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀, ó ń mú kí ìdájọ́ òdodo wà, ó sì ń dènà ìwà ọ̀daràn gbígbórín. Àwọn kan yarí pé, kò bójú mu—ó jẹ́ ọ̀nà àtigbógun ti ìwà ipá nípa lílo ìwà ipá tí ó pọ̀ sí i, ó sì jìnnà pátápátá sí ọ̀nà tí ọmọlúàbí fi ń tún ìwà àwọn ọ̀daràn ṣe, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti di mẹ́ḿbà ti ó ní láárí láwùjọ.
Ní agbo àwọn òṣèlú ní United States, àríyànjiyàn yìí gbóná janjan lọ́nà tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀, àwọn olórí ìsìn pẹ̀lú kò sì gbẹ́yìn níbẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Bibeli ha ní ohunkóhun láti sọ lórí ọ̀ràn ìfìyà-ikú-jẹni bí?’ Lóòótọ́ ló ní in.
Gbígbé “Idà” lé Àwọn Aláṣẹ Ènìyàn Lọ́wọ́
Láìpẹ́ lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Noah, Jehofa Ọlọrun fìdí ìṣeyebíye ìwàláàyè ènìyàn múlẹ̀, ó sì sọ nígbà náà pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn silẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a óò sì ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.” (Genesisi 9:6) Ó dájú pé èyí kì í ṣe ìwé àṣẹ fún gbígbẹ̀san bí ó bá ti wuni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí pé, a óò fàyè gba ọlá àṣẹ ènìyàn tí a fòfin gbé kalẹ̀ kan láti ìgbà náà wá, láti máa gba ẹ̀mí àwọn tí wọ́n bá gba ẹ̀mí àwọn mìíràn.
Ní Israeli ìgbàanì, Òfin tí Ọlọrun fi rán Mose fi ìfìyà-ikú-jẹni lélẹ̀ fún àwọn ìwà ìrúfin gbígbórín pàtó kan. (Lefitiku 18:29) Bí ó ti wù kí ó rí, Òfin náà tún pèsè ọ̀nà fún ìdájọ́ aláìṣègbè, níní ẹlẹ́rìí ojúkojú, ó sì dènà ìwà ìbàjẹ́. (Lefitiku 19:15; Deuteronomi 16:18-20; 19:15) Àwọn adájọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkùnrin tí ó ní ẹ̀mí ìfọkànsìn, wọn yóò sì jíhìn níwájú Ọlọrun fúnra rẹ̀! (Deuteronomi 1:16, 17; 2 Kronika 19:6-10) Nípa báyìí, ààbò wà kí wọ́n má baà ṣi ìfìyà-ikú-jẹni lò.
Lónìí, kò sí ìjọba kan lórí ilẹ̀ ayé tí ó lè ṣojú fún ìdájọ́ òdodo àtọ̀runwá ní tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Israeli ìgbàanì ti ṣe. Àmọ́ àwọn ìjọba máa ń ṣe gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́,” tàbí aṣojú Ọlọrun, ní ti pé wọ́n máa ń pa ìwàlétòletò àti ìwàdéédéé mọ́, wọ́n sì máa ń pèsè àwọn nǹkan tí gbogbo ará ìlú nílò. Aposteli Paulu rán àwọn Kristian létí láti jẹ́ onígbọràn sí “awọn aláṣẹ onípò gíga,” ó sì tún fi kún un pé: “Bí iwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, wà ninu ìbẹ̀rù: nitori kì í ṣe láìsí ète ni ó [alákòóso] gbé idà; nitori òjíṣẹ́ Ọlọrun ni, olùgbẹ̀san lati fi ìrunú hàn jáde sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwàhù.”—Romu 13:1-4.
“Idà” tí Paulu mẹ́nu kàn túmọ̀ sí ẹ̀tọ́ ìjọba láti fìyà jẹ àwọn ọ̀daràn—àní pẹ̀lú ikú pàápàá. Àwọn Kristian máa ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ yẹn, ṣùgbọ́n ó ha yẹ kí wọ́n gbìyànjú láti níí sọ sí bí ó ti yẹ kí wọ́n lò ó bí?
Wọ́n Ṣi “Idà” Náà Lò
Ó dájú pé àwọn ìjọba ènìyàn ti lo “idà” náà nítorí ìdájọ́ òdodo lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ sọ òtítọ́ pé wọ́n tún ti jẹ̀bi ṣíṣì í lò pẹ̀lú. (Oniwasu 8:9) Ìjọba Romu ìgbàanì jẹ̀bi lílo “idà” ìdájọ́ láti fi pa àwọn ìránṣẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ti Ọlọrun. Lára àwọn tí wọ́n kàgbákò ọ̀ràn yìí ni Johannu Olùbatisí, Jakọbu, àti Jesu Kristi alára.—Matteu 14:8-11; Marku 15:15; Ìṣe 12:1, 2.
Ní òde òní, ohun tí ó jọra ti ṣẹlẹ̀. Wọ́n ti pa àwọn ìránṣẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ti Jehofa ní onírúurú àwọn orílẹ̀-èdè—nípa fífi ẹ̀yìn wọn ti àgbá, nípa bíbẹ́ wọn lórí, nípa yíyẹgi fún wọn, nípa fífi gáàsì fín wọn pa—gbogbo rẹ̀ ni ìjọba tí ń gbìyànjú láti dá ìsìn Kristian dúró ti ṣe “lábẹ́ òfin.” Gbogbo àwọn aláṣẹ tí wọ́n bá ṣi ọlá àṣẹ wọn lò ni yóò jíhìn lọ́dọ̀ Ọlọrun. Ẹ wo bí wọ́n ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó!—Ìṣípayá 6:9, 10.
Ìrònú nípa jíjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ lásán gan-an níwájú Jehofa Ọlọrun máa ń pá àwọn Kristian tòótọ́ láyà. Nítorí báyìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ìjọba láti lo “idà,” wọ́n mọ̀ dáradára bí wọ́n ti ṣì í lò tó. Wọ́n ti lò ó gẹ́gẹ́ bí irin isẹ́ inúnibíni, wọ́n sì ti lò ó nígbà míràn pẹ̀lú ẹ̀tanú kíkorò lòdì sí àwọn kan, àti pẹ̀lú ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ aláìbójúmu fún àwọn mìíràn.a Nítorí náà, báwo ni àwọn Kristian ṣe máa ń dáhùn padà nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìfìyà-ikú-jẹni? Wọ́n ha máa ń dá sí i bí, kí wọ́n sì máa wá ọ̀nà bí nǹkan yóò ti yí padà?
Àìdásí-Tọ̀tún-Tòsì Àwọn Kristian
Àwọn Kristian tòótọ́ kò dà bí àwọn àlùfáà tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú láti fi ìlànà pàtàkì kan sọ́kàn pé: Jesu Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ‘wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ apákan ayé.’—Johannu 15:19; 17:16.
Kristian kan ha lè máa ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn, kí ó sì tún máa dara pọ̀ nínú àríyànjiyàn nípa ìfìyà-ikú-jẹni bí? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀. Kí ló tún kù, ọ̀ràn àwọn ará ìlú àti ti ìṣèlú ni èyí jẹ́. Ní United States, àwọn tí ń du ipò ìṣèlú sábà máa ń lò ìdúró wọn lórí ọ̀ràn ìfìyà-ikú-jẹni—ì báà jẹ́ ní ìgbèjà rẹ̀, tàbí lòdì sí í—gẹ́gẹ́ bí afárá kan láti fi pòkìkí àwọn ìlànà wọn. Wọ́n máa ń ṣàríyànjiyàn lórí ọ̀ràn náà lọ́nà tí ó múná janjan, wọ́n sì máa ń lò ìmọ̀lára gbígbóná janjan tí ó máa ń tinú ọ̀ràn yìí jáde gẹ́gẹ́ bí ìtìsẹ̀ láti yí àwọn olùdìbò lérò padà láti dìbò fún wọn.
Bóyá ìbéèrè tí ó yẹ kí Kristian kan ronú lé lórí ni pé: Tí ó bá jẹ́ pé Jesu ni, yóò ha dá sí àríyànjiyàn lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn ìjọba ayé yìí lo “idà” náà bí? Rántí pé, nígbà tí àwọn ará ìlú Jesu gbìyànjú láti ki ọrùn rẹ̀ bọ inú ìṣèlú, ó “tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè-ńlá ní oun nìkanṣoṣo.” (Johannu 6:15) Nígbà náà, ó jọ bí ẹni pé, bí ó bá jẹ́ pé òun ni, kì bá fi ọ̀ràn yìí sí ibi tí Ọlọrun fi í sí—ní ọwọ́ àwọn ìjọba.
Bákan náà lónìí, ènìyàn yóò retí pé kí àwọn Kristian ṣọ́ra láti má ṣe dá sí àríyànjiyàn lórí ọ̀ràn yìí. Wọn yóò mọ ẹ̀tọ́ àwọn ìjọba láti ṣe bí ó bá ti wù wọ́n. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí Kristian òjíṣẹ́ tí kì í ṣe apá kan ayé, wọn kò ní sọ gbangba-gbàǹgbà síta nípa ìtìlẹ́yìn wọn fún ìfìyà-ikú-jẹni, bẹ́ẹ̀ ní wọn kò ní ṣagbátẹrù ìmúkúrò rẹ̀.
Dípò bẹ́ẹ̀, wọn yóò fi ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Oniwasu 8:4 sọ́kàn pé: “Níbi tí ọ̀rọ̀ ọba gbé wà, agbára ń bẹ níbẹ̀; ta ni ó sì lè wí fún un pé, kí ni ìwọ ń ṣe nì.” Bẹ́ẹ̀ ni, a ti fún ‘àwọn ọba’ ayé, tàbí àwọn olórí òṣèlú, ní agbára láti ṣe ìfẹ́ inú wọn. Kò sí Kristian kankan tí ó ní ọlá àṣẹ láti dá wọn lẹ́bi. Àmọ́ Jehofa lè ṣe bẹ́ẹ̀. Yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Bibeli ń mú kí a máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ tí Ọlọrun yóò mú ìdájọ́ òdodo pátápátá wá sórí gbogbo ìwà ọ̀daràn àti gbogbo àṣìlò “idà” náà tí ń ṣẹlẹ̀ ní ayé ògbólógbòó yìí.—Jeremiah 25:31-33; Ìṣípayá 19:11-21.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àpẹẹrẹ, àwọn ènìyàn ti ṣe àríwísí ẹ̀ka ọgbà ẹ̀wọ̀n ti United States fún pípa tí wọ́n ń pa kìkì ohun tí ó dín sí ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀daràn wọn tí ikú yẹ lọ́dọọdún. Àwọn tí ń kú fúnra wọn nítorí àìsàn ju àwọn tí wọ́n ń pa lọ. Wọ́n tún ti fi ẹ̀sùn ẹ̀tanú kàn wọ́n—níwọ̀n bí ìṣirò tí fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kí a dájọ́ ikú fún apààyàn kan bí ẹni tí ó pa bá jẹ́ aláwọ̀ funfun, jù bí ẹni tí ó pa bá jẹ́ aláwọ̀ dúdú lọ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]
The Bettmann Archive