Wíwo Ayé
Ìwà Ipá Ń Burú Sí I
Àwọn onígbọ̀wọ́ ní United States ti gbé eré àfirọ́pò tuntun kan tí ń jẹ́ “ìjà àjàkú akátá,” tàbí “ìjà àjàpa” jáde, fún àwọn tí wọ́n rò pé àwọn ìfigagbága eré ìdárayá bí ẹ̀ṣẹ́ kíkàn tàbí àwọn ìfigagbága ọ̀nà ìgbèjà-ara-ẹni kò níwà ipá púpọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ, bí wọ́n ṣe ń jìjà náà kò ṣòro: “Àwọn ọkùnrin méjì yóò máa lu ara wọn nílùkilù títí tí ọ̀kan yóò fi juwọ́ sílẹ̀ tàbí kí ó dá kú.” Wọn kì í wọ ìbọ̀wọ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ́ náà dẹ̀; a kì í ka àkókò fún wọn tàbí kí a fún wọn ní àyè ìsinmi ráńpẹ́; ìwọ̀nba òfin díẹ̀ ló ní yàtọ̀ sí kíka ìbunijẹ tàbí yíyọni lójú léèwọ̀. Àwọn méjèèjì tí ń jà ń lo ọgbọ́n ọ̀nà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn, júdò, kàréètì, ẹkẹ, tàbí ìkànṣẹ́ ìgboro—tí ó sábà máa ń yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ gan-an. Wọ́n máa ń ṣe ìfagagbága náà níwájú àwùjọ àwọn aláyẹ̀ẹ́sí wọn tí ń ké toto bí ẹhànnà, tí wọ́n san tó 200 dọ́là fún tíkẹ́ẹ̀tì ìwòran; ìjà náà tún gbajúmọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n alátagbà àti gẹ́gẹ́ bíi kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí a háyà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ ti fòfin de àwọn eré wọ̀nyí.
Àfikún Iṣẹ́ fún Àwọn Obìnrin
Ṣé àwọn ọkùnrin àti obìnrin máa ń ṣe iṣẹ́ lọ́gbọọgba nínú ilé? Kì í ṣe bí ìwádìí kan tí Ọ́fíìsì Àkójọ Ìsọfúnni Àpapọ̀ ti Germany ṣe ti sọ. Àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé Norbert Schwarz àti Dieter Schäfer ní kí 7,200 agbo ilé ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́, kí wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ iye àkókò tí wọ́n ń lò láti fi ṣiṣẹ́ ní àyíká ilé. Ìwádìí náà ní nínú, àwọn iṣẹ́ bíi fífọ abọ́, rírajà, bíbójú tó àwọn ẹbí tí ń ṣàìsàn, àti ṣíṣiṣẹ́ lórí ọkọ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung sọ pé: “Láìka pé àwọn obìnrin ní iṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí wọn kò ní sí, wọ́n ń lo nǹkan bí ìlọ́po méjì àkókò ti àwọn ọkùnrin ní ṣiṣe iṣẹ́ tí a kì í sanwó rẹ̀ fún wọn.”
Ìsìn Nínú “Ayé Onígbòkègbodò Kọ̀m̀pútà”
Àwọn tí ń lo kọ̀m̀pútà láti ṣàyẹ̀wò “ayé onígbòkègbodò kọ̀m̀pútà,” àwọn ìsokọ́ra ìpìlẹ̀ ìsọfúnni oníṣirò kọ̀m̀pútà, ní ohun púpọ̀ sí i láti yàn ní ti ìsìn lóde òní. Ìsokọ́ra Jákèjádò Ayé náà ní Ojú Ewé Maria, níbi tí ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ ìtọpinpin ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́wàá tí a sábà máa ń béèrè nípa Maria Wúndíá, bí ìdí tí a fi sábà máa ń fi í hàn bí ẹni tí ó wọ aṣọ aláwọ̀ búlúù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ẹ̀ya Amish, tí kò fara mọ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bí iná mànàmáná, ni ohun tí a pè ní Béèrè Lọ́wọ́ Ẹ̀ya Amish dúró fún. A tún tẹ àwọn ìbéèrè jáde fún wọn, wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ ìdáhùn wọn, kọ̀m̀pútà sì gbé àwọn ìdáhùn wọn jáde—nípasẹ̀ ohun kan láàárín méjì. Ìwé ìròyìn The Christian Century sọ pé “àyíká” kan ti wà báyìí lórí ẹ̀rọ Internet tí a ń pè ní Àtíbàbà Ìjẹ́wọ́, níbi tí ohun tí ìṣètò kọ̀m̀pútà kan tí a yàwòrán àlùfáà sí ti ń béèrè pé, “Kí ni o sì fẹ́ jẹ́wọ́ rẹ̀?” Ilà tí ó tẹ̀ lé e jẹ́ ti ìdáhùn èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ. “Mo dẹ́ṣẹ̀ àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí: (Ìpànìyàn) (Panṣágà) (Ìmẹ́lẹ́) (Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́) (Ìfẹ́ Ọrọ̀ Láfẹ̀ẹ́jù) (Ẹ̀tàn) (Àjẹjù) (Ìgbéraga) (Ìbínú) (Ojúkòkòrò) (Fífí Ohun Àìtọ́ Ṣáájú).”
Òdòdó Títóbi Gan-an, Tí Ń Rùn Gan-an
Ìṣẹ̀dá ṣíṣàjèjì gbáà ni òdòdó tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé. Wọ́n ń pè é ní rafflesia, ó tóbi tó táyà ọkọ̀ akérò, ó sì ń gba tó àkókò tí ènìyàn fi ń dàgbà nínú oyún láti tanná òdòdó. Títóbi sì kọ́ ni ìdí kan ṣoṣo tí òdòdó yìí kò fi dára fún àkójọ òdòdó. Ó ń ṣíyàn-án. Ńṣe ni rafflesia máa ń rùn bí ẹran jíjẹrà, kí ó baà lè fa àwọn kòkòrò tí ó nílò láti gbakọ. Nígbà kan, àwọn ará abúlé ní ilẹ̀ Malaysia, tí wọ́n ń gbé inú igbó olójò tí rafflesia ti máa ń hù ti sọ ọ́ ní agbada èṣù, wọ́n sì máa ń gé e lulẹ̀ gbàrà tí wọ́n bá ti gán-ánní rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde South China Morning Post ti sọ, ọgbà ìtura ìpínlẹ̀ Kinabalu ní ilẹ̀ Malaysia ti gbégbèésẹ̀ láti dáàbò bo òdòdó ṣíṣọ̀wọ́n náà, kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ baà lè ṣèwádìí síwájú sí i nípa rẹ̀. Àwọn ará abúlé máa ń gba àlékún owó ní báyìí fún mímú àwọn arìnrìn àjò mọ igbó náà láti ya fọ́tò àwọn rafflesia. Láìsí àníàní, ọ̀pọ̀ ènìyàn ta kété sí òdòdó náà.
Lourdes ní Itali Kẹ̀?
Wọ́n sọ pé ère Madonna kan ní ìlú ńlá Civitavecchia ní ilẹ̀ Itali ń sun ẹ̀jẹ̀, nítorí rírọ́ tí ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn òǹwòran ati àwọn arìnrìn àjò mímọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìtọpinpin ń rọ́ wá. Nítorí ìdí yìí, olórí agbègbè náà, Pietro Tidei, tí ó pe ara rẹ̀ ní aláìgbàgbọ́, lọ sí Faransé pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì kan. Wọ́n ṣèbẹ̀wò sí Lourdes, ìlú olókìkí tí a mọ̀ dáradára fún àwọn ibi mímọ́ Kátólíìkì rẹ̀, tí ó yẹ̀ kí “àwọn ìyanu” ti máa ṣẹlẹ̀. Ìbẹ̀wò náà kì í ṣe ti ìrìn àjò mímọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ète rẹ̀ jẹ́ láti ṣèwádìí “ìyanu ọrọ̀ ajé” ti Lourdes, tí ó ṣe kedere pé ó jẹ́ kí a rí àwọn èrò nípa bí a ṣe lè ṣètò Civitavecchia kí a sì lò ó, gẹ́gẹ́ bíi Mecca tí ń mówó wọlé, fún àwọn arìnrìn àjò àti àwọn arìnrìn àjò mímọ́.
“Ogun Mímọ́” Brazil
Pásítọ̀ ìjọ Penticostal kan ní Brazil gbégbèésẹ̀ ṣíṣe ohun tí àwọn agbéròyìnjáde ilẹ̀ náà pè ní ogun mímọ́. Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n kan tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́, pásítọ̀ náà, Sergio von Helde, bẹnu àtẹ́ lu ìjọsìn ère tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń ṣe. Láti fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀, ó gbé ère amọ̀ Obinrin Aparecida Wa kalẹ̀, ẹ̀yà dúdú Maria Mímọ́ tí ó wà gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì alátìlẹ́yìn mímọ́ fún àwọn Kátólíìkì Brazil tí iye wọn jẹ́ 110,000,000. Von Helde pe ère náà ní “ère tí kò bójú mu, tí ń tẹ́ni lógo” bí ó ti ń gbá a, tí ó sì ń ta á nípàá léraléra. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kátólíìkì ti fẹ̀hónú hàn, wọ́n ń gbé àwọn ère alátìlẹ́yìn mímọ́ náà kiri ojú pópó. Àwọn akọluni tí ń ké toto, tí wọ́n ń sọ òkúta ti paro jọ yíká àwọn tẹ́ḿpìlì ẹ̀ya Penticostal ti Von Helde, tí ń jẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé ti Ìjọba Ọlọrun. Von Helde, tí olórí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ ti gba ipò lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà náà, dẹ́bi fún àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde fún gbígbé fíìmù ìkọlù rẹ̀ sáfẹ́fẹ́ léraléra. Pásítọ̀ náà sọ pé: “TV Globo [ìsokọ́ra tẹlifíṣọ̀n orílẹ̀-èdè náà tí ó tóbi jù lọ] sọ mí di ẹhànnà.”
Ìpànìyàn Nínú Ẹgbẹ́ Ojú-Lalákàn-Fi-Ń-Ṣọ́rí
Ní Gúúsù Áfíríkà, àwọn akọluni kan tí inú ń bí lọ kó àwọn ènìyàn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ajámọ́tògbà, láti inú ilé wọn, wọ́n ṣá wọn pa, wọ́n sì fi ọ̀dà kùn wọ́n. Ìwé agbéròyìnjáde Saturday Star sọ pé pípọ̀ tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ń pọ̀ sí i jẹ́ “àmi ẹgbẹ́ àwùjọ tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọlọ́pàá rẹ̀, tí ìwà ipá sì gbà lọ́kàn, tí kò sì lè ṣàkóso rẹ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò fara mọ́ irú ìwà bẹ́ẹ̀, àwọn onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn wo ìwà ti fífi ọ̀dà kun òkú àwọn òjìyà náà gẹ́gẹ́ bí ohun pàtàkì kan. Ó wà bí ìkìlọ̀ fún àwọn ọ̀daràn lọ́jọ́ iwájú. Onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn kan sọ pé: “Gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé apá kò ká ìṣẹ̀lẹ̀ náà mọ́ rárá àti pé àwọn aráàlú kò lẹ́mìí láti máa pa èrò pé àwọ́n wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ àwọn ọ̀daràn mọ́ra mọ́.”
Àwọn Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ Igún Ń Ṣèyọnu
Igún California—ẹyẹ ńlá kan tí ń jẹ òkú ẹran tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú run ní ọ̀rúndún yìí—ń gbé àwọn ìpèníjà àkànṣe dìde fún àwọn olùdáàbòbo ẹranko tí ń gbìyànjú láti tú àwọn igún tí a tọ́ lábẹ́ àkámọ́ dà sínú igbó. Olùdáàbòbo ẹranko kan tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, àwọn ẹyẹ tí a tú sílẹ̀ bí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ náà, wà “ní àkókò èwe, títọwọ́ bọ nǹkan lójú, ìṣòfíntótó.” Àìní ìbẹ̀rù fún àwọn ènìyàn tàbí wáyà iná ti mú kí àwọn igún bíi mélòó kan pàdánù ẹ̀mí tàbí òmìnira wọn. Nítorí náà ni àwọn olùdáàbòbo ẹranko ṣe hùmọ̀ àwọn ọ̀nà ọgbọ́n tuntun ní títọ́jú àwọn òròmọ igún. Wọ́n lo ọ̀nà fífi mànàmáná mú wọn gbọ̀n rìrì ní fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ láti kọ́ ẹyẹ náà bí wọn yóò ṣe yẹra fún wáyà iná. Láti kọ́ wọn ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá fún ènìyàn, wọn kò jẹ́ kí igún náà rí wọn àyàfi ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí àwọn ènìyàn bíi mélòó kan bá rọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹyẹ náà lójijì, tí wọ́n mú un, tí wọ́n sì fi ẹ̀yìn rẹ̀ lélẹ̀. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn igún kórìíra èyí,” wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ láti sá fún ènìyàn. Títí di báyìí, ọgbọ́n ìwéwèé náà ti kẹ́sẹ járí díẹ̀.
Àbá Nípa Àràmàǹdà Ọ̀nà Abẹ́lẹ̀
Tipẹ́tipẹ́ ni àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ Hesekiah, tí a gbẹ́ ní ọ̀rúndún kẹjọ Ṣáájú Sànmánì Tiwa láti rí i dájú pé Jerusalemu ní omi nígbà tí ẹgbẹ́ ogun Assiria ká a mọ́, fi ní irú ipa ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ, dídíjú bẹ́ẹ̀. Ọ̀nà gbọnrangandan, tí ó túbọ̀ dára yóò gba ilẹ̀ gbígbẹ́ tí ó jẹ́ mítà 320, dípò ti 533 mítà tí ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà gbà. A rí àkọlé kan, tí a kọ̀ ní Heberu ìgbàanì, lórí ògiri ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà ní 1880. Ó ṣàlàyé bí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ méjì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ìhà dídojúkọra ọ̀nà abẹ́lẹ̀ àpáta tí a gbẹ́ náà, tí wọ́n sì pàdé láàárín. Èyí gbé àfikún ìbéèrè dìde nípa bí wọ́n ṣe ṣe é, ní ríronú nípa ipa ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà tí ó rí kọ́lọkọ̀lọ. Àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ àti ohun inú rẹ̀ lérò pé àwọ́n ti ní ìdáhùn nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí Dan Gill ti àjọ Ìṣèwádìí Ìmọ̀ Nípa Ilẹ̀ àti Ohun Inú Rẹ̀ ti Israeli ti sọ, àwọn òṣìṣẹ́ náà tọ àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ àdánidá tí omi là, nígbà tí ó ń gba àárín àwọn àpáta kọjá níbi tí ó ti sán nítorí ìmìtìtì lílágbára tàbí níbi tí ipele yíyàtọ̀ síra ti pàdé, wọ́n sì fẹ ojú wọ́n. Láàárín àkókò díẹ̀, wọ́n lè fẹjú gan-an ní àwọn ibì kan, tí èyí sì lè ṣàlàyé ìdí tí gíga ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà ṣe máa ń yàtọ̀ síra láti 1.7 mítà sí ohun tí ó pọ̀ tó mítà 5, àti bí ó ṣe ṣeé ṣe fún àwọn òṣìṣẹ́ náà láti ní atẹ́gùn tí ó pọ̀ tó ní lílo àtùpà elépo. Àwọn òṣìṣẹ́ náà jáfáfá pẹ̀lú, nítorí pé ṣíṣe àṣeyọrí níbi ọ̀nà abẹ́lẹ̀ náà sinmi lórí níní àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí ó dagun níwọ̀nba—kìkì sẹ̀ǹtímítà 31.75 lórí gbogbo ipa ọ̀nà náà.