Ìlérí Tí Mo Múra Tán Láti Mú Ṣẹ
GẸ́GẸ́ BÍ MARIAN TSIBOULSKI ṢE SỌ Ọ́
NÍ February 1945, mo jẹ́ jagunjagun ọmọ 20 ọdún nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Soviet, tó ti lé àwọn ará Germany padà sí orílẹ̀-èdè wọn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà. Ojoojúmọ́ ni mo ti rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ogun ń fà, bí àwọn jagunjagun ẹlẹgbẹ́ mi ṣe ń kú ní àyíká mi. A ti sún mọ́ ìlú Breslau, Germany, tí ń jẹ́ Wrocław, Poland, nísinsìnyí. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan níbẹ̀, tí pípani nípakúpa àti ìfìyàjẹni náà sú mi, mo ṣèlérí fún Ọlọ́run pé, bí ó bá fi lè jẹ́ kí n padà délé láyọ̀, n ó ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Ní oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, a ṣẹ́gun Germany. Lẹ́yìn tí a dá mi sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ológun, ní December 1945, mo yan wọ Rogizno, abúlé kan nítòsí Lvov (tí ń jẹ́ Lviv nísinsìnyí), ní Ukraine, tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ baba mi. Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo bá ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, ó sì jẹ́rìí fún mi kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti mọ nǹkan díẹ̀ nípa Bíbélì tẹ́lẹ̀, tí mo sì tilẹ̀ ti ka díẹ̀ lára àwọn ìwé Àwọn Ẹlẹ́rìí, ó ru ọkàn mi sókè nísinsìnyí. Ó yé mi pé ìbápàdé yìí kan ìlérí tí mo ṣe.
Mímú Ìlérí Mi Ṣẹ
Láìpẹ́, mo gba iṣẹ́ olùkọ́ nílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan. Àmọ́, kò pé ọdún méjì lẹ́yìn náà tí ilé iṣẹ́ ètò ẹ̀kọ́ àgbègbè náà fi pàṣẹ pé kí a máa kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ àìgbọlọ́rungbọ́, wọ́n sì lé mi kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Ní nǹkan bí àkókò kan náà, ní May 1947, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde lọ wàásù ní gbangba. Àwọn Ẹlẹ́rìí rọ̀ mí láti kó lọ sí gúúsù, sí ìlú Borislav, níbi tí mo ti yára ríṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ mànàmáná.
Ní Borislav, mo bá àwọn ènìyàn tí wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí ní àwọn ọdún 1930 pàdé. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde tí ń ṣàlàyé Bíbélì, tí mo kà gan-an, títí kan àwọn ìdìpọ̀ ìwé Studies in the Scriptures, àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé tí Joseph F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà kan, kọ. Mo tún ka àwọn ẹ̀dà àtijọ́ Ilé Ìṣọ́ àti The Golden Age (tí ń jẹ́ Jí! nísinsìnyí). Àmọ́ ohun tó wọ̀ mí lọ́kàn jù ni àkójọ àwọn lẹ́tà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Germany, tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún lábẹ́ ìṣàkóso Hitler, kọ. Wọ́n ti túmọ̀ àwọn lẹ́tà wọ̀nyí sí èdè Polish, wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ ẹ̀dà wọn, wọ́n sì ṣe wọ́n ní ìwọ̀n ìwé kékeré. Lẹ́yìn náà, rírántí bí àwọn arákùnrin ará Germany wọ̀nyẹn ṣe dúró ṣinṣin ń fún mi lókun láti fara da ìdánwò.
Níkẹyìn, ní 1949, mo ṣe batisí nínú ọ̀kan lára àwọn adágún tó wà ní Borislav, mo sì tipa bẹ́ẹ̀ ń mú ìlérí tí mo ṣe lójú ogun láti sin Ọlọ́run ṣẹ. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó jẹ́ ìlérí tí a gbé karí ìmọ̀ pípéye.
Mo Bẹ̀rẹ̀ sí Rí Ìdánwò
Láìpẹ́, wọ́n lé mi kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Nítorí náà, ní February 1950, mo kó lọ sí ìlú Stry tó wà nítòsí, níbi tí mo ti rí iṣẹ́ mànàmáná ṣe lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn Kristẹni arákùnrin gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀, èmi ni wọ́n tilẹ̀ ní kí n sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi tí a ń ṣe lọ́dọọdún, tí a ṣe lọ́sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà.
Ní àkókò yìí, fífín Àwọn Ẹlẹ́rìí níràn àti wíwu wọ́n léwu ń le sí i. Àwọn òṣìṣẹ́ KGB, Ìgbìmọ̀ Ààbò Orílẹ̀-Èdè, ń ṣọ́ wa tọwọ́tẹsẹ̀. Nítorí náà, a lo ìṣọ́ra bí a ti ń múra de ṣíṣeéṣe tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n mú wa, kí wọ́n sì gbọ́ tẹnu wa. Kíkọ àwọn orin Ìjọba ní àwọn ìpàdé ràn wá lọ́wọ́ láti lókun nípa tẹ̀mí.
Ní July 3, 1950, wọ́n ní kí n fọwọ́ sí Ìwé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Stockholm, ìwé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lòdì sí ohun ìjà alágbára átọ̀mù tí a gbọ́ pé àwọn tó fọwọ́ sí i lé ní 273,000,000, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn wá láti àwọn orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì. Nígbà tí mo kọ̀ láti fọwọ́ sí i, tí mo sì ṣàlàyé pé n kì í dá sí ọ̀ràn ìṣèlú, wọ́n tún lé mi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n mú mi, wọ́n gbọ́ ẹjọ́ mi, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún 25 nínú àgọ́ ìfìyàjẹni oníṣẹ́ àṣekára.
Láti Àgọ́ Kan Dé Òmíràn
Ní December 1950, wọ́n kó ọ̀pọ̀ nínú wa sínú ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n fi ń kó màlúù, wọ́n sì kó wa lọ sí nǹkan bí 3,000 kìlómítà ní àgbègbè kan nítòsí ìhà àríwá àwọn Òkè Ural, tó ya ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti Éṣíà kúrò lára ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti Yúróòpù láàbọ̀. Ńṣe ni wọ́n ń mú mi lọ láti àgọ́ kan sí òmíràn léraléra. Bákan náà ni gbogbo rẹ̀ rí—iṣẹ́ àṣekára àti oúnjẹ tí kò tó nǹkan. Oṣù méjì tàbí mẹ́ta ti tó láti sọ abarapá ọkùnrin kan dà bí òkú tí ń rìn. Ọ̀pọ̀ ló kú. A kò jẹ́ ronú pé a kò ní kú, pàápàá, ní ti àwọn tí wọ́n bu ọjọ́ gbọọrọ fún lẹ́wọ̀n nínú wa.
Ọdún tí n kò rí ìwé tí ń ṣàlàyé Bíbélì kankan, tí n kò sì rí Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ló ni mí lára jù. Ìdáwà náà jẹ́ ìdálóró gidigidi. Ṣùgbọ́n mo rí okun tẹ̀mí gbà nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n díẹ̀ ń fetí sí mi bí mo bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Níkẹyìn, a dáhùn àdúrà àtọkànwá mi, tí wọ́n sì gbé mi lọ sí àkọ́pọ̀ àgọ́ ńlá kan ní ìhà ìlà oòrùn gúúsù ní nǹkan bí 2,000 kìlómítà, ní ìlú Angarsk tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ dó, ní ìlà oòrùn Siberia. Wọ́n ń kọ́ ilé iṣẹ́ aṣekẹ́míkà kan lọ́wọ́ níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló sì ń ṣe èyí tó pọ̀ jú nínú iṣẹ́ náà.
Wọ́n pín mi sí Àgọ́ 13, nítòsí ibi ìkọ́lé náà. Lọ́gán ni mo pàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn níbẹ̀, wọ́n fún mi ní ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Informant, bí a ṣe ń pe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nígbà náà, tí ó jáde kẹ́yìn. Ẹ wo irú àsè tẹ̀mí tí ó jẹ́! Ṣùgbọ́n, ibo ni gbogbo rẹ̀ ti wá?
Ní April 1951, ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Ukraine ti sá lọ sí Siberia, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì lọ sí àgbègbè tí kò jìnnà sí Angarsk. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí ń gba Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìwé mìíràn, wọ́n ń ṣe ẹ̀dà wọn láṣìírí, wọ́n sì ń dọ́gbọ́n mú wọn wọ inú àwọn àgọ́. Ó ṣeé ṣe fún wa láti rí Bíbélì kan gbà pẹ̀lú. A pín in sí apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a pín láàárín ara wa. Nípa bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá tilẹ̀ tú ẹrù wà, apá kan Bíbélì náà ni wọ́n máa rí mú lọ. A tilẹ̀ ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run nínú àwọn àgọ́ náà!
Nígbà tí 1952 ń parí lọ, wọ́n gbé mi lọ sí Àgọ́ 8. Ní oṣù March tó tẹ̀ lé e, a ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí nínú iyàrá kékeré kan tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń kó ẹrù wọn pa mọ́ sí. Ènìyàn 12 péré ló wà níbẹ̀—Àwọn Ẹlẹ́rìí 3 àti àwọn olùfìfẹ́hàn 9. Lọ́nà kan ṣáá, àwọn aláṣẹ wá mọ̀ nípa ìpàdé wa, wọ́n sì sọ mí sí Àgọ́ ìfìyàjẹni 12 nítorí pé wọ́n ní mo jẹ́ “amọ̀ọ́mọ̀-dárúgúdù.” Mo bá Àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún mìíràn tí wọ́n ń fìyà jẹ nítorí pé wọ́n ń wàásù ní àgọ́ yìí. Nígbà tí a wà níbẹ̀, wọ́n fipá mú kí a fi jígà àti ṣọ́bìrì lásán gbẹ́ ìpìlẹ̀ ilé tó fẹ̀ kan.
Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní Àgọ́ 12 jẹ́ ọ̀daràn paraku. Ní kedere, àwọn aláṣẹ rò pé fífi wá sí àhámọ́ kan náà pẹ̀lú wọn yóò sè wá rọ̀ ni. Ṣùgbọ́n a ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, a sì ń kọ àwọn orin Ìjọba nínú bárékè náà. Ní ìgbà kan, lẹ́yìn tí a kọrin tán, olórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n àgọ́ náà sún mọ́ Ẹlẹ́rìí kan, ó sì wí pé: “Ẹ jẹ́ kí ẹnì kan dán an wò, kó fọwọ́ kàn yín, n ó pa á ni!” Kódà, àwọn díẹ̀ lára àwọn ọ̀daràn náà kọ́ àwọn orin Ìjọba wa, wọ́n sì ń bá wa kọ wọ́n!
Ní agbedeméjì 1953, wọ́n kó Àwọn Ẹlẹ́rìí púpọ̀ láti àwọn àgọ́ mìíràn lọ sí Àgọ́ 1. Níbẹ̀rẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí 48 ló wà ní Àgọ́ 1, ṣùgbọ́n láìtó ọdún mẹ́ta, a ti pé 64. Ní gidi, èèyàn 16 ló mú ìdúró wọn fún òtítọ́ Bíbélì tí a sì batisí wọn! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ àgọ́ ń ṣọ́ wa nígbà gbogbo láti rí ẹ̀rí pé a ń ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìsìn, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa ṣe àwọn ìpàdé wa, kí a sì máa ṣe batisí ní ilé ìwẹ̀ àgọ́ náà nítorí pé ẹni tí ó wà nídìí àbójútó rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí.
Òmìnira, àti Ìdílé
Ní 1956, wọ́n dá ọ̀pọ̀ jù lọ Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àwọn àgọ́ sílẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere náà tú ká lọ sí gbogbo apá ilẹ̀ Soviet tó gbòòrò náà. Wọ́n ti dín ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún 25 tí wọ́n ṣe fún mi kù sí ọdún 10, wọ́n sì dín in kù sí ọdún 6 àti oṣù 6 nígbẹ̀yìn. Nítorí náà, ní February 1957, wọ́n dá èmi náà sílẹ̀.
Mo kọ́kọ́ lọ sí Biryusinsk, ìlú kan ní Siberia, tó wà ní nǹkan bí 600 kìlómítà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Angarsk. Ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Ukraine ni wọ́n ti lé lọ sí àdúgbò yẹn, mo sì gbádùn bíbá wọn ṣàjọpín àwọn ìrírí, tí mo sì ń gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa tí a jọ mọ̀. Láti ibẹ̀, mo padà sí Borislav, ní Ukraine, níbi tí Ẹlẹ́rìí ará Ukraine kan tí ń jẹ́ Eugenia Bachinskaja ń gbé. Wọ́n ti dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní ọdún kan kí wọ́n tó dá mi sílẹ̀.
Ògbógi Ẹlẹ́rìí ni Eugenia, wọ́n sì ti dájọ́ ikú fún un ní 1950 nítorí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn ọjọ́ 18 tí ó ti ń retí ikú, wọ́n sọ ìdájọ́ ikú rẹ̀ di ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún 25 ní àgọ́ àkànṣe kan. Nígbà tí ọdún 1957 ń parí lọ, tí mo padà sí Ukraine, a ṣègbéyàwó. Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, a wéwèé láti máa gbé Borislav, níbi ti mo ti ṣèrìbọmi ní ọdún mẹ́sàn-án ṣáájú. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n fún mi ní wákàtí 48 láti kó kúrò ní Ukraine!
Mo kó lọ sí Caucasus, níhà gúúsù Rọ́ṣíà, Eugenia wá bá mi níbẹ̀ nígbà tó yá. Lẹ́yìn tí a lo nǹkan bí oṣù mẹ́fà nínú ahéré kékeré kan níbẹ̀, a kó lọ sí Biryusinsk láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa tí wọ́n ti sá kúrò nílùú. Àwọn tó wà ní Biryusinsk jẹ nǹkan bí 500, a ní ìjọ márùn-ún, wọ́n sì yàn mí bí alábòójútó olùṣalága ọ̀kan nínú àwọn ìjọ náà. Ní 1959, a bí ọmọbìnrin wa, Oksana, a sì bí Marianna tẹ̀ lé e ní 1960. Láti ìgbà ọmọ ọwọ́ ni wọ́n ti ń lọ sípàdé déédéé, wọ́n sì wá dàgbà sínú ọ̀nà ìṣeǹkan tẹ̀mí ti ìjọ ní Siberia.
Àwọn aláṣẹ Siberia rára gba àwọn ìgbòkègbodò ìjọ wa lọ́nà tó sàn díẹ̀, ó kéré tán, bí a bá fi wé àwọn ìkàléèwọ̀ líle koko tí wọ́n gbé lé orí iṣẹ́ wa ní Ukraine. Síbẹ̀, kò rọrùn fún ìjọ láti pàdé pọ̀ lódindi. Àwọn ètò ìsìnkú ń fún wa láǹfààní láti pàdé pọ̀ lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Ní àwọn àkókò báwọ̀nyí, àwọn arákùnrin mélòó kan máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìtọ́ni tí a gbé karí Bíbélì. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aláṣẹ wá mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, wọ́n wá nǹkan ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan, wọ́n dá ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ ètò ìsìnkú kan dúró, wọ́n sì fipá gbé pósí náà lọ sí itẹ́, wọ́n sì sin ín.
Mo Padà sí Ukraine
Ní 1965, a padà sí Ukraine, a sì ń gbé Kremenchug. Ẹlẹ́rìí 12 péré ló wà ní ìlú yìí, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 800 kìlómítà níhà ìlà oòrùn Borislav. A lo nǹkan bí ọdún márùn-ún níbẹ̀; èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò yẹn ni mo sì fi ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Ní 1969, nígbà tí ọmọbìnrin wa kan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, wọ́n ní kí a kó lọ sí ìhà gúúsù láti ran àwọn ará lọ́wọ́ ní ìlú kékeré Molochansk.
Ní Molochansk, àwọn òṣìṣẹ́ KGB pè mí fún ìjíròrò kan tó gba wákàtí mélòó kan. Ní gidi, ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n pè mí bẹ́ẹ̀! Nígbà ìjíròrò kọ̀ọ̀kan, wọ́n ń lérí láti fún mi ní ipò tó sàn jù bí mo bá sá ti lè jáwọ́ nínú àjọṣe mi pẹ̀lú “àwọn oní-Jèhófà.” Níkẹyìn, ó pin àwọn òṣìṣẹ́ KGB náà lẹ́mìí, wọ́n sì sọ èmi àti Ẹlẹ́rìí mìíràn kan sẹ́wọ̀n ọdún kan.
Lẹ́yìn tí mo ṣẹ̀wọ̀n mi tán, èmi àti ìdílé mi kó lọ sí abúlé kékeré kan nítòsí Kremenchug ní 1973. A ń yọ́ ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni nínú ilé wa, títí kan ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi, ní 1974. Wọ́n wá tú ilé wa ní ọjọ́ kejì, wọ́n sì mú mi.
Ìgbẹ́jọ́, Àgọ́ Ìṣiṣẹ́kára, àti Ìlélọsígbèkùn
Bòńkẹ́lẹ́ ni wọ́n fi ìgbẹ́jọ́ mi ṣe, àwọn tí wọ́n pè nìkan ló lè wà níbẹ̀. Àwọn lọ́gàálọ́gàá iṣẹ́ ìjọba àti àwọn aṣáájú ìlú, àwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ ló wà níbẹ̀. Mo pinnu pé n kò ní gba lọ́yà, wọ́n sì fún mi ní ìṣẹ́jú 45 láti rojọ́ ìgbèjà ara mi. Ní ọjọ́ tó ṣáájú ìgbẹ́jọ́ náà, Eugenia àti àwọn ọmọ wa kúnlẹ̀ àdúrà, wọn kò gbàdúrà pé kí ìdájọ́ náà má le jù tàbí pé kí wọ́n dárí jì mí, ṣùgbọ́n wọ́n gbàdúrà pé kí a lè jẹ́rìí lọ́nà gbígbéṣẹ́ nípa Ìjọba náà àti orúkọ mímọ́ ti Jèhófà.
Ìgbẹ́jọ́ náà bẹ̀rẹ̀ bí adájọ́ ṣe ń ka ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àyọkà láti inú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwùjọ náà kò ṣe bí adájọ́ ọ̀hún ti retí kí wọ́n ṣe. Bí àwọn ènìyàn náà ti gbọ́ pé ayé búburú yìí yóò kọjá lọ ní Amágẹ́dọ́nì, Ìjọba Ọlọ́run yóò sì ṣàkóso ayé, ọkàn wọn dà rú—wọn kò mọ ohun tí wọ́n ní láti gbà gbọ́. Láìpẹ́, adájọ́ náà rí àṣìṣe rẹ̀, nígbà tí mo sì ń wí àwíjàre mi ìkẹyìn, ó gbìyànjú láti tún ọ̀ràn ara rẹ̀ ṣe nípa jíjá lu ọ̀rọ̀ mi léraléra. Síbẹ̀, nípa kíkà tí adájọ́ náà ti ka ọ̀rọ̀ jáde láti inú àwọn ìtẹ̀jáde wa ní tààràtà, ó ti ṣèrànwọ́ láti jẹ́rìí lọ́nà gbígbéṣẹ́, ọkàn mi sì kún fún ọpẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún oníṣẹ́ àṣekára fún mi, lẹ́yìn èyí tí wọ́n ní n ó lọ sígbèkùn ọdún márùn-ún.
Mo lo ọdún márùn-ún tó tẹ̀ lé e láàárín àwọn ọ̀daràn paraku níhà àríwá, ní àgọ́ ìfìyàjẹni oníṣẹ́ àṣekára ti Yodva, ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Komi Autonomous Soviet Socialist. Láàárín àkókò yẹn, mo ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti wàásù Ìjọba fún nǹkan bí 1,200 ẹlẹ́wọ̀n àti àwọn alábòójútó àgọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ ní 1979, wọ́n sọ mí sígbèkùn ní Vorkuta, lápá òkè Àgbègbè Olótùútù Ìhà Àríwá Ayé. Láìpẹ́, mo rí iṣẹ́ àti ibùgbé ní Vorkuta, ìdílé mi sì kó wá sọ́dọ̀ mi.
Vorkuta gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a tẹ̀ dó sórí egungun òkú àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó ṣiṣẹ́ kú síbẹ̀, tí ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní àwọn ẹ̀wádún ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ wà lára wọn. Lónìí, kò sí nǹkan àrà ọ̀tọ̀ kankan nípa ìlú náà, a kò sì lè rí àwọn àgọ́ ìfìyàjẹni oníṣẹ́ àṣekára níbẹ̀ mọ́. Àmọ́, àìníye ajẹ́rìíkú tó fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ fún ìyìn Jèhófà ló wà nínú àwọn yìnyín dídì tó wà nínú ìlú náà àti ní àwọn àgbègbè rẹ̀.
Ìdùnnú Òmìnira Ìsìn
Ní 1989, a ti Vorkuta wá sí Poland láti ṣe àpéjọpọ̀ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì. Ojú kò tì wá bí omijé ayọ̀ ṣe ń bọ́ lójú wa bí a ti ń rí ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin ní Warsaw àti Katowice tí wọ́n ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ láìbẹ̀rù pé wọ́n lè wá kó wọn. Ohun kan tí a retí ti ṣẹ. Bí a ti padà sí Vorkuta, a túbọ̀ múra tán láti ṣiṣẹ́ fún ire Ìjọba náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, ojú ọjọ́ lókè Àgbègbè Olótùútù Ìhà Àríwá Ayé ti tutù jù, ó sì ń mú kí Eugenia ṣàìsàn. Nítorí náà, lọ́dún yẹn, a padà sí Kremenchug níkẹyìn, níbi tí a ti ń dunnú bí a ti ń sin Jèhófà nínú òmìnira púpọ̀ sí i tí a ń gbádùn nísinsìnyí. Àwọn ọkọ ọmọ wa méjèèjì jẹ́ alàgbà nínú ìjọ tó wà ní Ukraine níbí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ wa náà ń tọ́ ọmọ mẹ́rin lọ́wọ́, wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo ṣì ń rántí ojú ogun ní 1945 àti ìlérí tí mo ṣe ní èyí tó ti lé ní ìdajì ọ̀rúndún kan sẹ́yìn. Kí n lè mú un ṣẹ, Jèhófà ti fún mi ní ìmọ̀ pípéye, ìmọ̀ kan náà tí ó ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn ṣe irú ìlérí kan náà—láti sin Jèhófà títí láé.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
RỌ́ṢÍÀ
Vorkuta
Lviv
Borislav
UKRAINE
Kremenchug
Molochansk
Caucasus
Biryusinsk
Angarsk
Àwa àti àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì, àwọn ọkọ wọn, àti àwọn ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.