Jíjẹ́ Adúróṣinṣin—Lolórí Àníyàn Mi
GẸ́GẸ́ BÍ ALEXEI DAVIDJUK TI SỌ Ọ́
Ọdún 1947 lọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ yìí ṣẹlẹ̀; ibi tó sì ti ṣẹlẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mélòó kan sí abúlé wa ní Laskiv, Ukraine, ní tòsí àlà ilẹ̀ Poland. Ọ̀rẹ́ mi kan tó dàgbà jù mí lọ, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Stepan jẹ́ ońṣẹ́ kan tó máa ń dọ́gbọ́n kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ Ukraine láti Poland. Lóru ọjọ́ kan, ẹ̀ṣọ́ kan tó ń ṣọ́ àlà ilẹ̀ náà rí i, ó sáré tẹ̀ lé Stepan, ó sì yìnbọn fún un. Ọdún méjìlá lẹ́yìn náà, ikú Stepan ní ipa tí ń gbàfiyèsí lórí ìgbésí ayé mi, bí màá ṣe ṣàlàyé níwájú.
NÍGBÀ tí wọ́n fi bí mi ní Laskiv lọ́dún 1932, àwọn ìdílé mẹ́wàá lábúlé wa ló jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí wọ́n ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn. Àwọn òbí mi wà lára wọn, wọ́n sì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti jíjẹ́ adúróṣinṣin ti Jèhófà títí tí wọ́n fi kú láàárín ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1970. Ní gbogbo ìgbésí ayé mi, jíjẹ́ adúróṣinṣin ti Ọlọ́run lolórí àníyàn tèmi náà.—Sáàmù 18:25.
Lọ́dún 1939, ìyẹn lọ́dún tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, wọ́n sọ àgbègbè tí a ń gbé ní ìhà ìlà oòrùn Poland di apá kan Soviet Union. Abẹ́ àkóso ilẹ̀ Soviet la wà títí di June 1941, nígbà tí àwọn ará Jámánì ṣẹ́gun tí wọ́n sì gba àgbègbè wa.
Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, nǹkan le fún mi ní ilé ẹ̀kọ́. Wọ́n kọ́ àwa ọmọdé ní àwọn orin tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè hàn, kí a sì kópa nínú iṣẹ́ ológun. Kódà, bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ ju bọ́ǹbù abúgbàù wà lára ohun tí wọ́n ń kọ́ wa. Ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti kọ àwọn orin tó ń fi ìfẹ́ orílẹ̀-èdè hàn, mo sì kọ̀ láti kópa nínú èyíkéyìí lára ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun. Kíkẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà ọmọdé láti di ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ mi tí a gbé karí Bíbélì mú ràn mí lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ wa tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì, èyí sì mú kí wọ́n yan àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sí àgbègbè wa láti ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ àwọn èèyàn. Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà náà, Ilja Fedorovitsch, tún bá èmi pẹ̀lú ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì kọ́ mi bí a ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Nígbà tí Jámánì fi ń ṣàkóso ọ̀dọ̀ wa, wọ́n lé Ilja kúrò, wọ́n sì fi í sí ọ̀kan lára àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Násì, ibẹ̀ ló sì kú sí.
Ìlàkàkà Bàbá Láti Jẹ́ Aláìdásí Tọ̀tún Tòsì
Lọ́dún 1941, ìjọba ilẹ̀ Soviet gbìyànjú láti mú kí Bàbá fọwọ́ sí ìwé kan tí yóò fi ṣèlérí pé òun yóò fi owó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ológun. Ó sọ fún wọn pé òun kò lè gbè sí ẹ̀yìn èyíkéyìí lára àwọn ìhà méjèèjì tí ń jagun àti pé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, òun kò ní dá sì tọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni òun kò ní dá sí tòsì. Ni wọ́n bá sọ pé ọ̀tá ìlú ni Bàbá, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́rin. Ṣùgbọ́n ọjọ́ mẹ́rin péré ló fi ṣẹ̀wọ̀n náà. Kí ló dé? Ìdí ni pé ní ọjọ́ Sunday àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n fi í sẹ́wọ̀n, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì gba àgbègbè tí a ń gbé.
Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n gbọ́ pé àwọn ará Jámánì ti sún mọ́ tòsí, wọ́n ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì sá lọ. Ní ìta, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n ni àwọn sójà ilẹ̀ Soviet yìnbọn pa. Bàbá kò jáde kúrò lójú ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tó ṣe díẹ̀ ló sá lọ sí ilé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan. Látibẹ̀, ó ránṣẹ́ sí Màmá pé kí ó kó àwọn ìwé òun wá, ìwé tó fẹ̀rí hàn pé ṣe lòun kọ̀ láti ṣètìlẹyìn fún ilẹ̀ Soviet nínú ogun, ìyẹn ló sì gbé òun dé ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tí Bàbá fi wọ́n han àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Jámánì, wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ sí.
Àwọn ará Jámánì fẹ́ láti mọ orúkọ gbogbo àwọn tó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Soviet. Wọ́n fagbára mú Bàbá pé kó tọ́ka sí wọn, ṣùgbọ́n ó kọ̀. Ó ṣàlàyé ipò àìdásí tọ̀tún tòsì rẹ̀ fún wọn. Ká ní ó dárúkọ ẹnì kankan ni, wọn ì bá yìnbọn pa ẹni yẹn. Nítorí náà, àìdásí tọ̀tún tòsì Bàbá tún gba ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn là, àwọn wọ̀nyẹn sì mọrírì ohun tó ṣe.
Ṣíṣiṣẹ́ Lábẹ́lẹ̀
Àwọn Soviet padà sí Ukraine ní August 1944, nígbà tó sì di May 1945, Ogun Àgbáyé Kejì parí láàárín àwọn ará Yúróòpù. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ohun tí wọ́n pè ní Ìbòjú Irin ya àwa tí a wà ní Soviet Union sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn aráyé yòókù. Kódà kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní òdìkejì àlà ilẹ̀ wa ní Poland ṣòro. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó gbóyà yóò rọra yọ́ kọjá àlà náà sí òdìkejì, wọ́n á sì kó ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ṣíṣeyebíye mélòó kan wá. Níwọ̀n bí àlà kò ti ju kìlómítà mẹ́jọ sí ilé wa ní Laskiv, mo gbọ́ nípa ewu tí àwọn ońṣẹ́ wọ̀nyẹn forí là.
Bí àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n ń pè ní Silvester ré kọjá lẹ́ẹ̀mejì, ó sì padà nígbà méjèèjì láìsí ìṣòro. Ṣùgbọ́n nígbà tó lọ lẹ́ẹ̀kẹta, àwùjọ ẹ̀ṣọ́ tó ń káàkiri àlà náà àti àwọn ajá ọdẹ wọn rí i. Àwọn sójà náà kígbe pé kó dúró, ṣùgbọ́n Silvester sá nítorí ẹ̀mí rẹ̀. Ohun kan ṣoṣo tó lè mú kó bọ́ lọ́wọ́ àwọn ajá náà ni nípa wíwọ́dò lọ́ sínú adágún kan tó wà ní tòsí. Inú omi tó mù ún dé ọrùn ló wà ní gbogbo òru yẹn, tó sá pa mọ́ sínú esùsú. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ń káàkiri yẹn jáwọ́ nínú wíwá a, Silvester ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ lọ sílé, ó ti rẹ̀ ẹ́.
Bí mo ṣe ṣàlàyé tẹ́lẹ̀, wọ́n pa ìbátan Silvester kan tó ń jẹ́ Stepan nígbà tó ń gbìyànjú láti ré kọjá. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí a máa kàn sí àwọn ènìyàn Jèhófà. Nípasẹ̀ ìsapá àwọn ońṣẹ́ tó gbóyà, ó ṣeé ṣe fún wa láti máa rí oúnjẹ tẹ̀mí àti ìtọ́sọ́nà tí ń ranni lọ́wọ́ gbà.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ìyẹn lọ́dún 1948, wọ́n ṣèrìbọmi fún mi lóru nínú adágún kan tó wà ní tòsí ilé wa. Àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi pàdé ní ilé wa, ṣùgbọ́n mi ò mọ̀ wọ́n nítorí pé inú òkùnkùn ni, ìkọ̀kọ̀ la ti ṣe gbogbo nǹkan tí a ṣe láìsí ariwo rárá. Àwa tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi kò sọ̀rọ̀ sí ara wa. Mi ò mọ ẹni tó sọ àsọyé ìrìbọmi, mi ò mọ ẹni tó bi mí ní àwọn ìbéèrè ìrìbọmi bí a ti dúró sí tòsí adágún náà, bẹ́ẹ̀ ni mi ò mọ ẹni tó rì mí bọmi. Láwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí èmi àti ọ̀rẹ́ mi kan ń fi àkọsílẹ̀ wa wéra wọn, a rí i pé àwa méjèèjì wà lára àwọn tó ṣèrìbọmi lóru ọjọ́ yẹn!
Lọ́dún 1949, àwọn Ẹlẹ́rìí ní Ukraine rí ìsọfúnni gbà láti Brooklyn tó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n bẹ ìlú Moscow pé kó fàṣẹ sí iṣẹ́ ìwàásù ní Soviet Union. Nígbà tí wọ́n rí ìtọ́sọ́nà yẹn, wọ́n kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Gíga Jù Lọ ní U.S.S.R, wọ́n sì fi rán mínísítà ọ̀rọ̀ abẹ́lé. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí Mykola Pyatokha àti Ilya Babijchuk lọ sí Moscow láti gba èsì ìjọba nípa ìwé ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n kọ. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí Moscow nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn.
Aláṣẹ tó gba àwọn aṣojú yìí lálejò fetí sílẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣàlàyé ìdí tí a fi ń ṣe iṣẹ́ wa, èyí tó bá Bíbélì mu. Wọ́n ṣàlàyé pé a ń ṣe iṣẹ́ wa ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù pé “a ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Ṣùgbọ́n, aláṣẹ náà sọ pé Orílẹ̀-Èdè náà kò ní fàṣẹ sí iṣẹ́ wa láé.
Àwọn Ẹlẹ́rìí náà padà sílé, wọ́n sì lọ sí ìlú Kiev tó jẹ́ olú ìlú àwọn ará Ukraine láti gba àṣẹ láti máa ṣe iṣẹ́ wa ní Ukraine níhìn-ín lábẹ́ òfin. Lọ́tẹ̀ yìí pẹ̀lú, àwọn aláṣẹ kò fún wọn lóhun tí wọ́n béèrè. Wọ́n sọ pé wọn kò ní dààmú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kìkì bí wọn yóò bá ṣètìlẹ́yìn fún Orílẹ̀-Èdè náà. Wọ́n sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ní láti sìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ológun, kí wọ́n sì bá wọn dìbò. Ni wọ́n bá tún ṣàlàyé ipò àìdásí tọ̀tún tòsì wa fún wọn, pé ní àfarawé Jésù Kristi tó jẹ́ Ọ̀gá wa, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé.—Jòhánù 17:14-16.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n fàṣẹ ọba mú Arákùnrin Pyatokha àti Babijchuk, wọ́n fẹ̀sùn kàn wọ́n, wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Kó tó di ìgbà yẹn, lọ́dún 1950, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí títí kan bàbá mi ni àwọn aláṣẹ mú lọ. Wọ́n sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wọ́n sì fi í ránṣẹ́ sí Khabarovsk ní ìhà ìlà oòrùn ìkángun ilẹ̀ Soviet Union tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jìnnà tó ẹgbẹ̀rún méje kìlómítà!
Wọ́n Rán Wa Sígbèkùn ní Siberia
Lẹ́yìn náà, ní April 1951, Orílẹ̀-Èdè Soviet gbéjà ko àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́nà àfètòṣe, ní àwọn ìpínlẹ̀ ìhà ìwọ̀ oòrùn rẹ̀ tí a wá mọ̀ sí Latvia, Estonia, Lithuania, Moldova, Belarus, àti Ukraine báyìí. Lóṣù yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje lára wa, títí kan èmi àti Màmá ni wọ́n rán sígbèkùn ní Siberia. Ṣe làwọn sójà ṣàdédé wá sílé wa lóru, wọ́n sì kó wa lọ sí ibùdó ọkọ̀ ojú irin. Wọ́n tì wá mọ́ inú ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n fi ń kó màlúù, àwa bí àádọ́ta ni wọ́n kó sínú iyàrá kọ̀ọ̀kan, nígbà tó sì di ẹ̀yìn ọ̀sẹ̀ méjì, wọ́n já wa sí ibì kan tí wọ́n ń pè ní Zalari, tó wà ní tòsí Adágún Baikal lágbègbè Irkutsk.
Bí a ti dúró nínú ìrì dídì, tí ẹ̀fúùfù títutù nini ń fẹ́, tí àwọn sójà tó dìhámọ́ra sì yí wa ká, mo ṣe kàyéfì nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wa. Báwo ni màá ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin ti Jèhófà níhìn-ín? A bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin Ìjọba Ọlọ́run kí a lè gbàgbé nípa òtútù. Nígbà tó yá, àwọn ọ̀gá tó ní ilé iṣẹ́ ládùúgbò náà dé. Àwọn kan ń wá àwọn ọkùnrin tó lè máa bá wọn ṣe iṣẹ́ tó lágbára, àwọn mìíràn sì ń wá àwọn obìnrin tó lè máa bá wọn tọ́jú nǹkan, irú bíi títọ́jú ẹranko. Wọ́n mú èmi àti Màmá lọ sí ibi iṣẹ́ ìkọ́lé kan níbi tí wọ́n ti ń kọ Ilé Iṣẹ́ Iná Mànàmáná ti Tagninskaya.
Nígbà tí a débẹ̀, a rí àwọn ilé onígi, ilé tí àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn máa ń gbé. Wọ́n yàn mí pé kí n máa wa katakata, kí n sì máa ṣe iṣẹ́ iná mànàmáná, wọ́n sì ní kí Màmá máa ṣiṣẹ́ nínú oko kan. Ẹni tí wọ́n lé nílùú ni wọ́n kà wá sí, wọn ò kà wá sí ẹlẹ́wọ̀n. Nítorí náà, a lómìnira láti máa rìn káàkiri ní tòsí ilé iṣẹ́ iná mànàmáná náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò jẹ́ ká lọ sí ibùdó tó sún mọ́ wa, tó jìnnà tó nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà. Àwọn aláṣẹ fagbára mú wa pé ká fọwọ́ sí ìwé kan tó sọ pé títí ayé la máa fi wà níbẹ̀. Ìyẹn dà bí ẹni pé àkókò tó gùn gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni lójú mi, èmi tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ní mo bá kọ̀, mo ní mi ò fọwọ́ síwèé. Síbẹ̀, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún la fi wà níbẹ̀.
Ní ibi tí a wà ní Siberia, kì í ṣe kìlómítà mẹ́jọ péré ni àlà ilẹ̀ Poland fi jìnnà sí wa mọ́, ṣùgbọ́n ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́fà kìlómítà lọ tó fi jìnnà sí wa! Àwa Ẹlẹ́rìí ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti ṣètò ara wa, a sì dá àwọn ìjọ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, a yan àwọn ọkùnrin láti máa mú ipò iwájú. Lákọ̀ọ́kọ́, a kò ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àyàfi àwọn ìwé díẹ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí kan dọ́gbọ́n mú dání nígbà tí wọ́n ń bọ̀ láti Ukraine. Àwọn la fọwọ́ dà kọ, tí a sì pín wọn káàkiri láàárín ara wa.
Kò pẹ́ tí a fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìpàdé. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé púpọ̀ wa ló ń gbé nínú àwọn ilé onígi wọ̀nyẹn, a sábà máa ń péjọ ní ìrọ̀lẹ́. Nǹkan bí àádọ́ta èèyàn ló wà ní ìjọ wa, èmi ni wọ́n sì yàn pé kí n máa darí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwa ọkùnrin díẹ̀ ló wà ní ìjọ wa, nítorí náà, àwọn obìnrin pẹ̀lú máa ń ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́, ìlànà yìí ni ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í lò ní àwọn ìjọ mìíràn gbogbo lọ́dún 1958. Gbogbo wa ló máa ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wa, a máa ń wo ilé ẹ̀kọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti yin Jèhófà, kí a sì fún àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ níṣìírí.
A Bù Kún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ń bá wa gbé ní ibùdó yẹn, agbára káká ni ọjọ́ kan yóò kọjá tí a kò ní sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ka ṣíṣe bẹ́ẹ̀ léèwọ̀ pátápátá. Lẹ́yìn tí Joseph Stalin, tó jẹ́ olórí ìjọba ilẹ̀ Soviet kú lọ́dún 1953, ipò nǹkan sunwọ̀n sí i. Wọ́n jẹ́ kí a máa sọ àwọn ohun tí a gbà gbọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì fún àwọn ènìyàn, a sì láǹfààní láti sọ ọ́ ní gbangba ju ti tẹ́lẹ̀. Nípa kíkọ lẹ́tà sí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà ní Ukraine, a mọ ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn wà ní àgbègbè wa, a sì wá wọn kàn. Èyí jẹ́ kí a lè ṣètò àwọn ìjọ wa sí àwọn àyíká.
Lọ́dún 1954, mo gbé Olga, tí òun náà wà lára àwa tí a wà ní ìgbèkùn láti Ukraine, níyàwó. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó ṣe ìtìlẹyìn fún mi gidigidi nínú iṣẹ́ ìsìn mi sí Jèhófà. Ẹ̀gbọ́n Olga ni Stepan, tí wọ́n pa ní àlà Ukraine àti Poland lọ́dún 1947 yẹn. Nígbà tó yá, a bí ọmọbìnrin tí ń jẹ́ Valentina.
Èmi àti Olga rí ọ̀pọ̀ ìbùkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa ní Siberia. Bí àpẹẹrẹ, a pàdé George, tó jẹ́ aṣíwájú ìjọ Onítẹ̀bọmi kan. A máa ń dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ déédéé, a sì máa ń bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ èyíkéyìí tó bá wà. Kò pẹ́ tí George fi rí i pé òtítọ́ ni ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń wàásù rẹ̀ látinú Bíbélì. A tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ Onítẹ̀bọmi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú. Inú wa mà dùn gan-an nígbà tí George àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ṣe ìrìbọmi, tí wọ́n sì di arákùnrin wa nípa tẹ̀mí!
Lọ́dún 1956, wọ́n sọ mí di alábòójútó arìnrìn-àjò, tó ń béèrè pé kí n máa bẹ ìjọ kọ̀ọ̀kan wò lágbègbè wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Màá ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, lẹ́yìn náà màá gun alùpùpù mi ní alẹ́ lọ sí ìjọ tí mo fẹ́ bá ṣèpàdé. Lówùúrọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, màá padà lọ síbi iṣẹ́ mi. Mykhailo Serdinsky, tí wọ́n yàn pé kí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìrìn àjò, kú nínú ìjàǹbá mọ́tò lọ́dún 1958. Ó kú ní ọjọ́ Wednesday, ṣùgbọ́n a dá ìsìnkú rẹ̀ dúró di ọjọ́ Sunday kí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí lè láǹfààní láti wá.
Nígbà tí èrò púpọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí itẹ́, àwọn mẹ́ńbà Àjọ Aláàbò Orílẹ̀-Èdè tẹ̀ lé wa. Sísọ àsọyé tó sọ ìrètí wa tí a gbé karí Bíbélì nípa àjíǹde túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n fàṣẹ mú wa. Ṣùgbọ́n ó di dandan pé kí ń sọ nípa Mykhailo àti ìrètí àgbàyanu tó ní lọ́jọ́ ọ̀la. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo lo Bíbélì, Àjọ Aláàbò Ìlú kò fàṣẹ mú mi. Ó hàn gbangba pé wọ́n ronú pé kò sóhun tí wọ́n fẹ́ rí gbà nínú mímú mi, wọ́n sì tún mọ̀ mí dáadáa níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti jẹ́ “àlejò” wọn ní orílé-iṣẹ́ wọn, tí wọ́n ti máa ń bi mí ní ìbéèrè.
Afinisùn Kan Tú Àṣírí Wa
Lọ́dún 1959, Àjọ Aláàbò Orílẹ̀-Èdè fàṣẹ mú àwọn Ẹlẹ́rìí méjìlá tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Wọ́n tún ké sí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n sì bi wọ́n láwọn ìbéèrè, mo sì wà lára wọn. Nígbà tó kàn mí láti bi ní ìbéèrè, ó yà mí lẹ́nu láti gbọ́ tí àwọn aláṣẹ náà ń sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó jẹ́ àṣírí nípa iṣẹ́ wa. Báwo ni wọ́n ṣe mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ó dájú pé afinisùn kan wà, ẹnì kan tó mọ̀ wá dáadáa, tó sì ti pẹ́ díẹ̀ tó ti ń bá Orílẹ̀-Èdè yìí ṣiṣẹ́.
Àwọn méjìlá tí wọ́n mú wà nínú sẹ́ẹ̀lì tó so mọ́ra wọn, wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan pé wọn kò ní dá àwọn aláṣẹ náà lóhùn ọ̀rọ̀ kankan mọ́. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, á di dandan pé kí afinisùn yẹn fúnra rẹ̀ yọjú nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìgbẹ́jọ́ láti jẹ́rìí mọ́ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fẹ̀sùn kàn mí, mo lọ sí kóòtù kí n lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Adájọ́ béèrè àwọn ìbéèrè, àwọn méjìlá náà kò sì fèsì. Ìgbà yẹn ni Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Konstantyn Polishchuk, tí mo ti mọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, wá jẹ́rìí mọ́ àwọn méjìlá náà. Wọ́n parí ìgbẹ́jọ́ náà nípa jíju díẹ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn sẹ́wọ̀n. Ní òpópónà, ní ìta kóòtù náà, mo lọ já bá Polishchuk.
Mo bi í léèrè pé: “Kí ló dé tí o fi ń táṣìírí wa?”
Ó fèsì pé: “Nítorí pé mi ò gbà gbọ́ mọ́ ni.”
Mo bi í pé: “Kí lohun tí o kò gbà gbọ́ mọ́?”
Ó fèsì pé: “Mi ò lè gba Bíbélì gbọ́ mọ́ rárá ni.”
Polishchuk lè ti táṣìírí èmi pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kò dárúkọ mi nígbà tó ń jẹ́rìí. Nítorí náà, mo bi í léèrè ìdí tí kò ṣe dárúkọ mi.
Ó ṣàlàyé pé: “Mi ò fẹ́ kí o lọ sẹ́wọ̀n. Ọkàn mi ṣì ń dá mi lẹ́bi nítorí Stepan tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyàwó rẹ. Èmi ni mo rán an lọ sí òdì kejì àlà yẹn ní òru ọjọ́ tí wọ́n pa á yẹn. Ó dùn mí gan-an ní.”
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yà mí lẹ́nu gidigidi. Ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ti gbòdì pátápátá! Inú rẹ̀ bà jẹ́ pé Stepan kú, síbẹ̀ ó wá ń táṣìírí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà báyìí. Mi ò tún fojú mi kan Polishchuk mọ́. Ó kú ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà. Ní tèmi, láti rí ẹnì kan tí mo ti fọkàn tán fún ọ̀pọ̀ ọdún, tó wá táṣìírí àwọn ará wa bà mí lọ́kàn jẹ́ gidigidi. Ṣùgbọ́n ìrírí yẹn kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye kan: Polishchuk di aláìṣòótọ́ nítorí pé kò ka Bíbélì mọ́, kò sì gba ohun tó wà nínú rẹ̀ gbọ́ mọ́.
Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ yìí sọ́kàn pé: Bí a óò bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé. Bíbélì wí pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” Ní àfikún sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n kíyè sára. Nítorí kí ni? “Kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.”—Òwe 4:23; Hébérù 3:12.
A Padà sí Ukraine
Nígbà tí ìgbèkùn wa ní Siberia parí ní ọdún 1966, èmi àti Olga padà sí Ukraine, sí ìlú kan tí ń jẹ́ Sokal, tó fi nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà jìnnà sí L’viv. Iṣẹ́ táa ní láti ṣe pọ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n péré ló wà ní Sokal àti ní ìlú Cervonograd àti Sosnivka tí wọ́n wà ní tòsí. Lónìí, ìjọ mọ́kànlá ló wà ní àgbègbè yìí!
Olga jẹ́ olùṣòtítọ́ títí tó fi kú lọ́dún 1993. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo fẹ́ Lidiya, òun sì ti jẹ́ okun ńláǹlà fún mi láti ìgbà yẹn wá. Láfikún sí i, Valentina tó jẹ́ ọmọbìnrin mi àti ìdílé rẹ̀ jẹ́ onítara ìránṣẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ti jẹ́ orísun ìṣírí fún mi pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n o, ohun tó ṣì ń mú inú mi dùn jù lọ ni pé mo ti dúró ṣinṣin ti Jèhófà, Ọlọ́run tó jẹ́ adúróṣinṣin nínú àwọn ohun tó ń ṣe.—2 Sámúẹ́lì 22:26.
Alexei Davidjuk jẹ́ adúróṣinṣin ti Jèhófà títí tó fi kú ní February 18, 2000, nígbà tí a ń ṣètò láti tẹ àpilẹ̀kọ yìí jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìjọ wa tó máa ń ṣèpàdé ní ibùdó náà ní ọdún 1952, ní ìhà ìlà oòrùn Siberia
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run wa ní ọdún 1953
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ààtò Ìsìnkú Mykhailo Serdinsky lọ́dún 1958
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àti Lidiya, aya mi