Ṣópin Ti Dé Bá Ìbẹ̀rù Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Ni?
Ó TI lé ní ogójì ọdún tí aráyé ti ń sọ̀rọ̀ nípa ewu ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Ṣùgbọ́n ní ọdún 1989, Ògiri Berlin wó lulẹ̀ gbìì—èyí sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìwólulẹ̀ ètò ìjọba Kọ́múníìsì ti Soviet. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn ìjọba alágbára ayé ti fohùn ṣọ̀kan láti ṣíwọ́ kí èkíní máa dojú ohun ìjà kọ èkejì. Níwọ̀n bó ti jọ pé “Amágẹ́dọ́nì” ọ̀gbálẹ̀gbáràwé náà ti dáwọ́ dúró, tàbí ó kéré tán pé a ti sún un síwájú, ńṣe ni gbogbo ayé mí kanlẹ̀.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi lérò pé ó ti yá jù láti máa dunnú nípa rẹ̀. Ní ọdún 1998, wọ́n fi ìṣẹ́jú márùn-ún kún agogo ọjọ́ ìparun lílókìkí náà tí ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists sọ nípa rẹ̀ nípa yíyí ọwọ́ rẹ̀ lọ sí agogo méjìlá òru ku ìṣẹ́jú mẹ́sàn-án—èyí fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ ewu ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé náà kò tí ì tán nílẹ̀.a Lóòótọ́ lóòótọ́, nǹkan ti yí padà láyé. Àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá kò dojú ohun ìjà kọra wọn mọ́. Iye orílẹ̀-èdè tó ní agbára àtiṣe ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ti pọ̀ díẹ̀ báyìí! Láfikún sí i, àwọn ògbógi ń bẹ̀rù pé láìpẹ́, àwọn ẹgbẹ́ apániláyà mélòó kan yóò bẹ̀rẹ̀ sí í máa fi èròjà onítànṣán olóró ṣe àgbélẹ̀rọ bọ́ǹbù átọ́míìkì.
Síwájú sí i, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń yí ọwọ́ rẹ̀ padà sẹ́yìn gan-an, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti Rọ́ṣíà ṣì ní àwọn ìtòpelemọ ohun ìjà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀. Ẹgbẹ́ àwọn olùwádìí kan tí ń jẹ́ Ìgbìmọ̀ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ìlànà Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé sọ pé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ni a ti kẹ́ sílẹ̀ ní báyìí. Ìròyìn wọ́n sọ pé: “Nítorí náà, bí wọ́n bá pàṣẹ pé kí wọ́n yìn wọ́n lọ́wọ́ tí a wà yìí pẹ́nrẹ́n, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [bọ́ǹbù atamátàsé tí ń lọ jìnnà] (tí ẹgbẹ̀rún méjì ń ti ìhà kọ̀ọ̀kan orílẹ̀-èdè méjèèjì wá) lè bẹ̀rẹ̀ sí í fò lọ síbi tí a rán wọn láti lọ bà jẹ́ láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀, ẹgbẹ̀rún kan mìíràn [àwọn bọ́ǹbù atamátàsé láti inú ọkọ̀ ogun abẹ́ omi] lè bẹ̀rẹ̀ sí í fò lọ síbi tí a rán wọn lọ láìpẹ́ lẹ́yìn náà.”
Wíwà tí àwọn ìtòpelemọ ohun ìjà wọ̀nyí wà fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ogun àìròtẹ́lẹ̀ tàbí ogun tí a tilẹ̀ pète rẹ̀ tẹ́lẹ̀ bẹ́ sílẹ̀. Vladimir Belous, gbajúmọ̀ olùwéwèé ogun tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà kìlọ̀ pé: “Ìjàǹbá aṣèparun kan lè kó aráyé sínú ìdàrúdàpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé fà, tó jẹ́ òdì kejì ohun tí àwọn aṣáájú olóṣèlú ń fẹ́ kó ṣẹlẹ̀.” Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ náà ti parí, ewu ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò tí ì kúrò nílẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni ewu náà ṣe le tó? Ǹjẹ́ àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lè tán lórí ilẹ̀ ayé? Àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jíròrò ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Agogo ọjọ́ ìparun tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists jẹ́ àmì tí ń fi bí a ṣe rò pé ayé ti sún mọ́ “agogo méjìlá òru” tí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé náà yóò bẹ́ sílẹ̀ hàn. Bí ọdún ti ń gorí ọdún ni wọ́n ń yí ọwọ́ agogo náà láti fi bí ipò ìṣèlú ṣe ń yí padà láyé hàn.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwòrán ìbúgbàù tó wà lójú ìwé 2 àti 3: Fọ́tò U.S. National Archives