Ǹjẹ́ Wọ́n Á Gba Òmìnira Ẹ̀rí-Ọkàn Láyè Fàlàlà ní Mẹ́síkò?
LATỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ MẸ́SÍKÒ
ÒFIN mú un dá àwọn èèyàn lójú pé òmìnira ìsìn wà ní Mẹ́síkò. Síbẹ̀, òfin náà ṣì ká òmìnira ìsìn lọ́wọ́ kò láwọn ọ̀nà kan. Fún àpẹẹrẹ, èròǹgbà kíkọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn kò tíì fi bẹ́ẹ̀ di mímọ̀ lórílẹ̀-èdè yìí. Ìdí nìyẹn tí Ẹ̀ka Ìṣèwádìí Òfin, ní National Autonomous University ti Mẹ́síkò (UNAM), fi pinnu láti ṣe àpérò àgbáyé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Kíkọ̀ Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Nítorí Ẹ̀rí Ọkàn ní Mẹ́síkò àti Lágbàáyé.” Ìjọba ló ń darí Ẹ̀ka Ìṣèwádìí Òfin yìí ní yunifásítì UNAM, ṣùgbọ́n ète rẹ̀ jẹ́ láti wádìí àwọn òfin tó ti wà nílẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n. Wọ́n ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò fi aṣojú kan ránṣẹ́ láti jíròrò kókó ọ̀rọ̀ náà, “Bí Kíkọ̀ Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Nítorí Ẹ̀rí Ọkàn Ṣe Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Sọ̀rọ̀
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lórí kókó náà, “Èròǹgbà Kíkọ̀ Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Nítorí Ẹ̀rí Ọkàn Nínú Òfin Àgbáyé,” Ọ̀mọ̀wé Javier Martínez Torrón, ọ̀jọ̀gbọ́n ní Yunifásítì Ẹ̀kọ́ Òfin ní Granada, ní Sípéènì, sọ pé òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀tọ́ láti má ṣe pa àwọn òfin tàbí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe kan mọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹni ti di mímọ̀ jákèjádò ayé. Ó mẹ́nu kan ọ̀ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sípéènì, ó tún mẹ́nu kan ọ̀ràn ìdílé Kokkinakis ní ilẹ̀ Gíríìsì.a
Ọ̀mọ̀wé José Luis Soberanes Fernández, tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n ní Ẹ̀ka Ìṣèwádìí Òfin ní yunifásítì UNAM, sọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Ohun Tó Ti Ṣẹlẹ̀ ní Mẹ́síkò Lórí Ọ̀ràn Náà.” Ó ní: “Ó yẹ ká tọ́ka pé Òfin Mẹ́síkò Nípa Ẹgbẹ́ Onísìn àti Ṣíṣe Ìsìn ní Gbangba ka kíkọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn léèwọ̀,” ohun tó ń tọ́ka sí ni Apá Kìíní, tó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ tìtorí ẹ̀sìn sọ pé òun ò ní pa àwọn òfin orílẹ̀-èdè yìí mọ́. Kò sẹ́ni tó lè sọ pé ẹ̀sìn ni ò ní jẹ́ kóun ṣe iṣẹ́ àti ojúṣe tí òfin là sílẹ̀.” Ní paríparí rẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Soberanes sọ pé: “A mọ̀ pé ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú láti ṣe òfin kan jáde lórí ọ̀ràn kíkọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn ní Mẹ́síkò.”
Ó tọ́ka sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́dọọdún, tó fi jẹ́ pé ẹgbàágbèje ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí ní Mẹ́síkò ló ń ko ìṣòro nílé ẹ̀kọ́ nítorí pé wọ́n ń kọ̀ láti kí àsíá látàrí ohun tí wọ́n ti kọ́ nínú Bíbélì. Wọn ò tiẹ̀ gba àwọn ọmọ kan tí àwọn òbí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí sílé ìwé. Ṣùgbọ́n, nípa pípẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, wọ́n ti ń fún púpọ̀ lára wọn lẹ́tọ̀ọ́ wọn láti kàwé. Àwọn òṣìṣẹ́ kan ní ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ ti gbégbèésẹ̀ láti fòpin sí àṣà lílé àwọn ọmọ kúrò nílé ìwé, ṣùgbọ́n àwọn olùkọ́ kan kò ka irú ìsapá bẹ́ẹ̀ sí. Àwọn aláṣẹ ò tako ojú ìwòye àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣùgbọ́n kò tíì sí ìlànà pàtó tí àwọn ilé ìwé lè tẹ̀ lé ní Mẹ́síkò.
Wọ́n tún sọ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn tí wọ́n kọ̀ láti ṣe àwọn ohun kan nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn, bíi fífipá mú wọn láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ọjọ́ tí wọ́n kà sí ọjọ́ mímọ́, sísọ pé kí wọ́n máa múra wá síbi iṣẹ́ lọ́nà tó tako ẹ̀sìn wọn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n tún sọ́rọ̀ nípa àwọn tó ń kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun àti láti gba irú àwọn ìtọ́jú ìṣègùn kan.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Késárì
Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ nílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mẹ́síkò ṣàlàyé ṣókí nípa àwọn lájorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ó ṣàlàyé nípa bí wọ́n ṣe ń pa àwọn ìlànà Bíbélì mọ́, irú èyí tó wà nínú Lúùkù 20:25, tó ní kí àwọn Kristẹni máa “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.” Ó tún tọ́ka sí ìwé Róòmù 13:1, tó sọ pé kí àwọn Kristẹni bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ tó ń ṣèjọba. Ó tẹnu mọ́ ọn pé orí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé, wọ́n ń pa òfin mọ́, wọ́n sì ń san owó orí wọn, pé èèyàn àlàáfíà ni wọ́n, wọ́n máa ń tún ilé wọn ṣe dáadáa, wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn lọ sílé ìwé.
Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu, tó fà á tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í kí àsíá, èyí wà lára Òfin Mẹ́wàá, nínú Ẹ́kísódù 20:3-5, tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n.”
Ọlọ́run nìkan làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sìn, wọn kì í torí ohunkóhun sin ère. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ fojú di àwòrán ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè tàbí kí wọ́n sọ̀rọ̀ àbùkù nípa rẹ̀.
Láti lè ṣàlàyé dáadáa nípa èrò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa ọ̀ràn yìí, wọ́n fi fídíò tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ Purple Triangles hàn wọ́n. Fídíò náà fi ipò ìdúróṣinṣin tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú nígbà ìjọba Násì ní Jámánì hàn (1933 sí 1945). Ó sọ ìtàn ìdílé Kusserow, ìdílé tó di ìgbàgbọ́ wọn mú ṣinṣin nígbà ìṣàkóso Násì.b
Wọ́n wá ṣàlàyé ìdí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ̀ láti gbẹ̀jẹ̀ sára. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Ìṣe 15:28, 29) Wọ́n ṣàlàyé nípa ètò àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tó wà jákèjádò ayé. Láfikún sí i, wọ́n ṣàlàyé àṣeyọrí tí àwọn dókítà tó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ti ṣe nínú àwọn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ń ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìlo ẹ̀jẹ̀.
Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún èèyàn ló ń wá síbi àpérò náà lójoojúmọ́, amòfin sì ni ọ̀pọ̀ lára wọn. Àwọn aṣojú láti Ilé Iṣẹ́ Alábòójútó Ọ̀ràn Ẹ̀sìn ní Mẹ́síkò pẹ̀lú wà níbi àpérò náà. Gbogbo ẹni tó wà níbẹ̀ ló gbọ́ ohun tí àwọn ògbógi rò nípa bíbọ̀wọ̀ fún ẹni tó bá kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀rí ọkàn. Èròǹgbà yìí ṣì jẹ́ tuntun sí àwọn aṣòfin ní Mẹ́síkò, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti di ohun ìtẹ́wọ́gbà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń ṣe ìjọba tiwa-n-tiwa, ìyẹn àwọn orílẹ̀-èdè bíi Faransé, Potogí, Sípéènì, àti Amẹ́ríkà àti ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tó ń lo ètò ìjọba Kọ́múníìsì tẹ́lẹ̀ rí, bíi Czechia àti Slovakia.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn àpilẹ̀kọ yìí, “Ilé-ẹjọ́ Gíga Ti Europe Gbèjà Ẹ̀tọ́ Láti Wàásù Ní Greece,” àti “Dídáàbò Bo Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin,” Ilé Ìṣọ́, September 1, 1993, àti December 1, 1998.
b Wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 1986, “Ifẹ Idile Mi fun Ọlọrun Laika Ẹ̀wọ̀n ati Iku Sí.” Tún wo ìtẹ̀jáde ti January 15, 1994, ojú ìwé 5.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò mọyì àǹfààní òmìnira ìwàásù tí wọ́n ní