Ìtàn Ìgbésí Ayé
Sísìn Tọkàntọkàn Lójú Onírúurú Àdánwò
GẸ́GẸ́ BÍ RODOLFO LOZANO ṢE SỌ Ọ́
Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò la bí mi sí, ní ìlú Gómez Palacio, ní Ìpínlẹ̀ Durango, ní September 17, 1917. Ìgbà yẹn ni eruku ìyípadà tegbòtigaga ń sọ lálá ní Mẹ́síkò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyípadà tegbòtigaga náà dópin lọ́dún 1920, ràbọ̀ràbọ̀ rẹ̀ ò tán ńlẹ̀. Gbogbo àgbègbè tí à ń gbé ló ṣì kún fún rúkèrúdò ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó sì mú kí ayé ni wá lára gan-an.
ÌGBÀ kan wà tí màmá mi gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ àti ti ìjọba fẹ́ figa gbága, ńṣe ló kó èmi, àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti àbúrò mi obìnrin pa mọ́ sínú ilé fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Oúnjẹ tó wà nílé ò tó nǹkan, mo sì rántí pé abẹ́ bẹ́ẹ̀dì lèmi àti àbúrò mi obìnrin sá pa mọ́ sí. Lẹ́yìn ìyẹn, màmá mi wá pinnu pé òun máa kó àwa ọmọ lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, kí bàbá mi ṣètò àtiwá bá wa lọ́hùn-ún.
A dé Ìpínlẹ̀ California ní 1926, nígbà tó kù díẹ̀ kí Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé tó bá Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fínra bẹ̀rẹ̀. Ṣe la ń ṣí kiri, a ń ṣí lọ sí ibikíbi táa bá ti lè ríṣẹ́. A lọ sí San Joaquin Valley, Santa Clara, Salinas, àti King City. A kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ lóko àti bí wọ́n ṣe ń kórè onírúurú èso àti ohun ọ̀gbìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ àṣelàágùn ni mo fi ìgbà èwe mi ṣe, síbẹ̀ ó jẹ́ àkókò tí mo gbádùn gan-an nínú ìgbésí ayé mi.
Òtítọ́ Bíbélì Dé Ọ̀dọ̀ Mi
Ní March 1928, Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, bí wọ́n ṣe ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, bẹ̀ wá wò. Bàbá àgbàlagbà kan báyìí, tí ń sọ èdè Spanish ni onítọ̀hún, orúkọ rẹ̀ ni Esteban Rivera. Ìwé kékeré náà, “Where Are the Dead?” (Níbo Làwọn Òkú Wà), tí bàbá yìí fún mi wù mí gan-an ni, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì wọ̀ mí lọ́kàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré lọ́jọ́ orí, mo tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àkókò ti ń lọ, màmá mi àti Aurora, àbúrò mi obìnrin pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí fi ìtara yin Jèhófà lógo.
Nǹkan bí ọdún 1925 sí 1927 la kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan fún ìjọ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní San Jose. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ tí ń sọ èdè Spanish ti ń ṣiṣẹ́ ní àwọn oko tó wà lágbègbè yẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún wọn, a sì ṣètò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. A ń ṣe èyí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń sọ èdè Spanish, tí wọ́n wá láti San Francisco, tí ó jẹ́ ọgọ́rin kìlómítà sí wa. Bí àkókò ti ń lọ, ó tó nǹkan bí ọgọ́ta tó ń wá sí àwọn ìpàdé tí à ń ṣe lédè Spanish nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba ní San Jose.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, February 28, 1940, ni mo fẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi nígbà àpéjọ kan ní San Jose. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, mo di aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó wá di April 1943 ni wọ́n ní kí n ṣí lọ sí Stockton, ìlú ńlá kan tó jẹ́ nǹkan bí àádóje [130] kìlómítà sí wa, láti lọ dá ìjọ èdè Spanish sílẹ̀ níbẹ̀. Nígbà yẹn, èmi ni alábòójútó olùṣalága ìjọ Gẹ̀ẹ́sì tí ń bẹ ní San Jose, èmi sì ni mo tún ń bójú tó àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń sọ èdè Spanish níbẹ̀. Bí mo ṣe gbé ẹrù iṣẹ́ wọ̀nyí lé àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nìyẹn, tí mo gbéra, ó di Stockton.
Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Dé
Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1940, léraléra ni wọ́n ń gbé mi déwájú àjọ tí ń gbani síṣẹ́ ológun. Àmọ́ gbogbo ìgbà tí mo bá lọ ni wọ́n máa ń fi mí lọ́rùn sílẹ̀ nígbà tí mo bá sọ fún wọn pé ẹ̀rí ọkàn mi lòdì sí wíwọṣẹ́ ológun. Kété tí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà wọnú Ogun Àgbáyé Kejì ní December 1941 ni àjọ yìí tún bẹ̀rẹ̀ sí fínná mọ́ mi. Níkẹyìn, ní 1944, wọ́n sọ mí sí àtìmọ́lé. Kí wọ́n tó ṣẹjọ́ mi, wọ́n sọ mí sí àjàalẹ̀ níbi táwọn ọ̀daràn wà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ipa tí ìwà ọ̀daràn táwọn hù máa ní lórí wọn lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bẹ ní San Jose gba ìdúró mi, kí wọ́n lè tú mi sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ tó bẹ̀rẹ̀. Lọ́yà kan nílùú Los Angeles tó ń ṣojú fún àwọn ajẹ́jọ́ tó lùfin gba ẹjọ́ mi rò láìgba kọ́bọ̀. Ìpinnu adájọ́ ni pé òun yóò dá mi sílẹ̀ bí mo bá gbà pé mi ò ní ṣe aṣáájú ọ̀nà mọ́, tí mo lọ wáṣẹ́ ṣe, tí mo sì gbà láti máa wá yọjú sáwọn aláṣẹ ìjọba àpapọ̀ lóṣooṣù. Mo yarí pé mi ò gba ẹjọ́ tó dá, ló bá ní kí wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ọdún méjì nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n McNeil Island ní Ìpínlẹ̀ Washington. Èmi kàn ń ka Bíbélì lọ ràì níbẹ̀ ni. Mo tún kọ́ bí a ti ń tẹ̀wé. Ọdún méjì ọ̀hún kò tíì pé tí wọ́n fi tú mi sílẹ̀ nítorí ìwà ọmọlúwàbí mi. Ojú ẹsẹ̀ ni mo ṣètò àtimáa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi nìṣó.
Ìgbòkègbodò Mi Gbòòrò Sí I
Ní ìgbà òtútù ọdún 1947, wọ́n ní kí èmi àti aṣáájú ọ̀nà kan jọ máa lọ ṣiṣẹ́ láàárín àwọn tí ń sọ èdè Spanish ní Colorado City, ní Ìpínlẹ̀ Texas. Àmọ́ ibẹ̀ tutù débi pé a ní láti lọ sílùú San Antonio níbi tí ooru ti mú díẹ̀. Àmọ́ òjò tún wá ń rọ̀ níbi táa wí yìí, débi pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé kò lọ déédéé. Kò pẹ́ tí owó ọwọ́ wa fi tán. Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ la ò fi rí oúnjẹ gidi jẹ, tó jẹ́ pé ìpápánu lásán la ń jẹ. Ẹnì kejì mi padà sílé, ṣùgbọ́n èmi ò padà. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wá gbọ́ nípa ohun tójú mi ń rí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ràn mí lọ́wọ́.
Ní ìgbà ìrúwé tó tẹ̀ lé e, mo padà síbi tí wọ́n yàn mí sí ní Colorado City. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, a dá ìjọ kékeré elédè Spanish sílẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo wá ṣí lọ sílùú Sweetwater, ní Texas, níbi tí mo ti ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ elédè Spanish mìíràn sílẹ̀. Nígbà tí mo wà ní Sweetwater, mo rí lẹ́tà kan gbà pé kí n máa bọ̀ ní kíláàsì kẹẹ̀ẹ́dógún ti Watchtower Bible School of Gilead, níbi táa ti ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láti di míṣọ́nnárì. Kíláàsì yìí bẹ̀rẹ̀ ní February 22, 1950. Lẹ́yìn táa ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún yẹn níbi àpéjọpọ̀ àgbáyé tó wáyé ní Pápá Ìṣeré Yankee, ní New York City, oṣù mẹ́ta ni mo fi wà ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn. Ibẹ̀ ni mo ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Mẹ́síkò.
Iṣẹ́ ní Mẹ́síkò
Mo dé Mexico City ní October 20, 1950. Nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni wọ́n yàn mí ṣe alábòójútó ẹ̀ka, mo sì ṣe iṣẹ́ náà fún ọdún mẹ́rin àtààbọ̀. Ìrírí tí mo ti jèrè nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, ní Gilead, àti ní Brooklyn wúlò gan-an. Nígbà tí mo dé Mẹ́síkò, wàràwéré ni mo rí ìjẹ́pàtàkì mímú kí ipò tẹ̀mí àwọn ará ní Mẹ́síkò túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ó ṣe pàtàkì gan-an láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rọ̀ mọ́ ìlànà ìwà rere tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kọ́ni.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè Látìn-Amẹ́ríkà, títí kan Mẹ́síkò, àṣà wọn ni pé kí tọkọtaya máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Àwọn ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù, àgàgà Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, ti jẹ́ kí àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu yìí tàn kálẹ̀. (Hébérù 13:4) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn kan ti di mẹ́ńbà ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Wàyí o, a yọ̀ǹda oṣù mẹ́fà fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti fi ṣàtúnṣe. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò ní kà wọ́n sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ nìyẹn.
Ṣíṣàtúnṣe kò nira fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ohun tí wọ́n kàn máa ṣe kò ju pé kí wọ́n mú ìgbéyàwó wọn bá òfin mu. Àmọ́ ìṣòro ti àwọn ẹlòmíì díjú gan-an ni. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ti ṣègbéyàwó lẹ́ẹ̀mejì, tàbí lẹ́ẹ̀mẹ́ta pàápàá, láìjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, tí ìgbéyàwó àwọn èèyàn Jèhófà wá bá ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, ńṣe làwọn ìjọ wá ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún tẹ̀mí.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
Láyé ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ará Mẹ́síkò ni kò kàwé. Kódà kí n tó dé ní 1950, ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ní àwọn ìjọ. Wàyí o, a tún ètò ẹ̀kọ́ náà ṣe, a sì ṣètò láti gba ìwé àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba. Láti 1946, táa bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú àkọsílẹ̀, ó ti lé ní ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún [143,000] èèyàn ní Mẹ́síkò táa ti kọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà nínú ètò ẹ̀kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń darí!
Àwọn òfin ilẹ̀ Mẹ́síkò mú nǹkan le gan-an fún ẹ̀sìn. Àmọ́ o, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ìyípadà pàtàkì ti wáyé. Ní 1992, wọ́n ṣe òfin tuntun kan lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn. Fún ìdí yìí ní 1993, wọ́n forúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò ẹ̀sìn ní Mẹ́síkò.
Ìyípadà wọ̀nyí ti jẹ́ orísun ìdùnnú ńláǹlà fún mi, ìyípadà tí mi ò rò pé ó lè wáyé láé. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń pààrà àwọn iléeṣẹ́ ìjọba, tí wọn ò tiẹ̀ kọbi ara sí mi. Àmọ́, ó dáa láti rí i bí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ṣe ń kojú ọ̀ràn wọ̀nyí, tó fi jẹ́ pé lọ́wọ́ táa wà yìí, kò fi bẹ́ẹ̀ sí ìdènà kankan fún iṣẹ́ ìwàásù náà.
Sísìn Pẹ̀lú Aya Tó Jẹ́ Míṣọ́nnárì
Nígbà tí mo dé Mẹ́síkò, mo bá ọ̀pọ̀ àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní àwọn kíláàsì ìṣáájú ti Gilead lórílẹ̀-èdè yìí. Ọ̀kan lára wọn ni Esther Vartanian, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ará Armenia, ẹni tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nílùú Vallejo, California, ní 1942. A ṣègbéyàwó ní July 30, 1955, a sì ń bá iṣẹ́ wa lọ ní Mẹ́síkò lẹ́yìn náà. Esther ń báṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ ní Mexico City, a sì jùmọ̀ ń gbé ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, níbi tí mo ti ń sìn nìṣó.
Ọdún 1947 ni Esther dé ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ táa yàn fún un nílùú Monterrey, ní Ìpínlẹ̀ Nuevo León, ní Mẹ́síkò. Ìjọ kan ṣoṣo tó ní ogójì Ẹlẹ́rìí nínú ló wà ní Monterrey nígbà yẹn, àmọ́ ìjọ ti pé mẹ́rin níbẹ̀ nígbà tí wọ́n máa fi gbé e wá sí Mexico City ní 1950. Méjì lára àtọmọdọ́mọ àwọn ìdílé tí Esther bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nígbà tó ń sìn ní Monterrey ló wà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tí ń bẹ nítòsí Mexico City báyìí.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní 1950, ṣàṣà ni ìpínlẹ̀ táwọn míṣọ́nnárì kì í wàásù dé ní gbogbo Mexico City. Ẹsẹ̀ ni wọ́n fi ń rin gbogbo ìpínlẹ̀ wọn tàbí kí wọ́n wọ ògbólógbòó bọ́ọ̀sì táwọn èèyàn kún fọ́fọ́. Ìjọ méje ló wà lágbègbè náà nígbà tí mo dé síbẹ̀ ní apá ìparí ọdún 1950. Ó ti di ẹgbẹ̀jọ [1,600] báyìí, àwọn tí ń kéde Ìjọba náà nílùú Mexico City sì lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ààbọ̀ [90,000], ó sì lé ní ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] tó wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi níbẹ̀ lọ́dún tó kọjá! Láti ọdún wọ̀nyí wá, èmi àti Esther ti ní àǹfààní láti sìn nínú ọ̀pọ̀ lára ìjọ wọ̀nyí.
Bí èmi àti Esther bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, a máa ń gbìyànjú láti rí i pé olórí ìdílé nífẹ̀ẹ́ sí i, kí gbogbo ìdílé náà lè jọ máa nípìn-ín nínú rẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé a ti rí ọ̀pọ̀ ìdílé ńlá tí wọ́n ti di olùjọsìn Jèhófà. Mo gbà pé ọ̀kan lára ìdí tí ìjọsìn tòótọ́ fi gbèrú gidigidi ní Mẹ́síkò ni pé odindi ìdílé ló sábà máa ń para pọ̀ tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́.
Jèhófà Ti Bù Kún Iṣẹ́ Náà
Látọdún 1950 ni ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ náà ní Mẹ́síkò ti gbàfiyèsí, ní ti ìbísí àti ní ti àtúntò. Orísun ìdùnnú gidi ló jẹ́ láti kópa díẹ̀ nínú ìbísí náà, àti láti ní àǹfààní láti bá àwọn èèyàn tó ní ẹ̀mí aájò àlejò tí wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀ ṣiṣẹ́.
Karl Klein, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Alákòóso àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àti Margaret aya rẹ̀, bẹ̀ wá wò nígbà ìsinmi wọn lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn. Arákùnrin Klein fẹ́ mọ bí iṣẹ́ náà ṣe ń lọ sí ní ìpínlẹ̀ wa ní Mẹ́síkò. Nítorí náà, òun àti Margaret wá sí Ìjọ San Juan Tezontla, nítòsí Mexico City, ìyẹn sì ni ìjọ tí à ń dara pọ̀ mọ́ nígbà yẹn. Gbọ̀ngàn wa kéré, kò ju nǹkan bíi mítà mẹ́rin àtààbọ̀ ní fífẹ̀, àti mítà márùn-ún àtààbọ̀ ní gígùn. Nígbà táa dé, nǹkan bí àádọ́rin làwọn táa bá níbẹ̀, èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ríbi dúró sí mọ́. Àwọn àgbàlagbà jókòó sórí àga, àwọn ọ̀dọ́ jókòó sórí bẹ́ǹṣì, àwọn ọmọdé sì jókòó sórí àwọn bíríkì tàbí sí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Inú Arákùnrin Klein dùn gan-an nítorí pé gbogbo ọmọdé ló ní Bíbélì lọ́wọ́, wọ́n sì ń ṣí i bí olùbánisọ̀rọ̀ ṣe ń pè é. Lẹ́yìn àsọyé fún gbogbo ènìyàn, Arákùnrin Klein sọ̀rọ̀ lórí Mátíù 13:19-23, ó sì sọ pé “erùpẹ̀ àtàtà” tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀ gan-an ní Mẹ́síkò. Ní báyìí, méje lára àwọn ọmọ tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ti ń ṣiṣẹ́ níbi àwọn ilé ńlá tí à ń kọ́ nítòsí Mexico City ní àfikún sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa. Òmíràn ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn kan sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà!
Mọ́kànlá péré làwọn tó wà ní ẹ̀ka wa nígbà tí mo dé sí Mexico City. Nísinsìnyí, àádọ́ta dín légbèje [1,350] ni iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka wa, àwọn bí àádọ́ta lé rúgba lára wọn ń ṣiṣẹ́ ilé kíkọ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tuntun. Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ yìí bá parí, bóyá lọ́dún 2002, àyè yóò wà fún ẹgbẹ̀fà [1,200] èèyàn púpọ̀ sí i láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa táa mú gbòòrò. Àwa tó jẹ́ pé lọ́dún 1950, a ò pé ẹgbẹ̀rún méje akéde Ìjọba náà jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí, ṣebí àwa ọ̀hún rèé tí a ti lé ní ìdajì mílíọ̀nù báyìí! Ayọ̀ mi kún àkúnwọ́sílẹ̀ bí mo ti ń rí bí Jèhófà ti ń bù kún ìsapá àwọn ará wa onírẹ̀lẹ̀ tó wà ní Mẹ́síkò, bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láti yìn ín lógo.
Kíkojú Ìṣòro Ńlá
Ọ̀kan lára ìṣòro ńlá tí mo dojú kọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni àìsàn. Tẹ́lẹ̀ rí, n kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàìsàn. Àmọ́ ní November 1988, àrùn ẹ̀gbà kọlù mí, ó sì sọ mí di arúgbó ọ̀sán gangan. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé nípasẹ̀ eré ìmárale àti àwọn ìtọ́jú mìíràn, àjíǹde ara ń jẹ́ díẹ̀díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ibòmíì nínú àgọ́ ara mi kò ṣiṣẹ́ mọ́ bí mo ti fẹ́. Mo ṣì ń gba ìtọ́jú nítorí akọ ẹ̀fọ́rí àtàwọn ìṣòro míì tí kò tíì lọ tán.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè ṣe gbogbo ohun tí n bá fẹ́, ayọ̀ mi ṣì ń kún nítorí mo mọ̀ pé mo ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ète Jèhófà, àti láti ya ara wọn sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀. Mo tún ń gbádùn bíbá ọ̀pọ̀ Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá wá bẹ ẹ̀ka wa wò; mo gbà pé ṣe ni a jùmọ̀ ń fún ara wa níṣìírí.
Mímọ̀ pé Jèhófà mọrírì iṣẹ́ ìsìn tí à ń ṣe fún un, àti pé iṣẹ́ wa kì í ṣe asán, ń fún mi lókun gan-an. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Láìfi àwọn àìlera àti àìsàn mi pè, mo ṣì ń rántí ọ̀rọ̀ inú Kólósè 3:23, 24, tó sọ pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn, nítorí ẹ mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ẹ ó ti gba ẹ̀san yíyẹ ti ogún náà.” Ní ìbámu pẹ̀lú ìṣílétí yìí, mo ti kọ́ bí a ti ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lójú onírúurú àdánwò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ní 1942 nígbà tí mo ń ṣe aṣáájú ọ̀nà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ ní Mẹ́síkò ní 1947
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Èmi àti Esther lónìí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Òkè lápá òsì: Èmi rèé níwájú, nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa ní Mẹ́síkò ní 1952
Lókè: Ó lé ní 109,000 èèyàn tó pésẹ̀ sí pápá ìṣeré yìí ní Mexico City fún àpéjọpọ̀ àgbègbè kan ní 1999
Ìsàlẹ̀ lápá òsì: Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tuntun tí a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ́ tán báyìí