Ta Ni Jésù Kristi?
ÌTÀN tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ sọ pé ní nǹkan tó lé ní ẹgbàá ọdún [2,000] sẹ́yìn, wọ́n bí ọkùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù sí ìlú kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ilẹ̀ Jùdíà. Nígbà náà lọ́hùn-ún, Hẹ́rọ́dù Ńlá lọba Jerúsálẹ́mù, tí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì sì jẹ́ olú ọba Róòmù. (Mátíù 2:1; Lúùkù 2:1-7) Àwọn ará Róòmù tó jẹ́ òpìtàn láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún méjì sí àkókò yẹn kì í fẹ́ pìtàn nípa Jésù nítorí pé àwọn alákòóso Róòmù nígbà yẹn ń gbìyànjú láti tẹ ìsìn Kristẹni rì.
Síbẹ̀, ìwé náà The Historians’ History of the World sọ pé: “Ká tiẹ̀ pa tẹ̀sìn tì, ipa tí àwọn nǹkan tí [Jésù] gbélé ayé ṣe ní lórí ìtàn ẹ̀dá pabanbarì ju ohun tí ẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn nínú ìtàn tíì gbé ṣe lọ. Kódà, láwọn ilẹ̀ tí ọ̀làjú ti rinlẹ̀, ìgbà tí wọ́n bí Jésù ni wọ́n kà sí ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun tí wọ́n fi ń ṣírò ọdún báyìí.”
Ìwé ìròyìn Time sọ pé kò tíì sí ẹnì kankan tí wọ́n kọ̀wé púpọ̀ nípa rẹ̀ láyé tó bí wọ́n ṣe kọ nípa Jésù. Ọ̀pọ̀ ìwé tí wọ́n ti kọ yìí ló dá lórí ẹni tí Jésù jẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máà tíì sí ọ̀rọ̀ míì táwọn èèyàn ń fà mọ́ra wọn lọ́wọ́ bí ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn Tó Kọ́kọ́ Ṣe Kàyéfì Nípa Ẹni Tí Jésù Jẹ́
Nígbà tí Màríà gbọ́ pé òun máa bímọ àti pé Jésù ni kóun sọ ọmọ náà, ìbéèrè tó béèrè ni pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?” Gébúrẹ́lì, áńgẹ́lì Ọlọ́run dá a lóhùn pé: “Agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:30-35.
Nígbà tó yá, Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó mú káwọn àpọ́sítélì rẹ̀ máa ṣe kàyéfì. Nígbà tí ìjì lílágbára kan fẹ́ da ọkọ ojú omi wọn nù lórí Òkun Gálílì, Jésù mú kí ìjì yẹn rọlẹ̀ nípa sísọ pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” Ẹnu ya àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ débi tí wọ́n ti kígbe pé: “Ta nìyí ní ti gidi?”—Máàkù 4:35-41; Mátíù 8:23-27.
Wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ làwọn èèyàn ìgbà ayé Jésù máa ń béèrè irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an, èyí ló mú kí Jésù béèrè irú ẹni táwọn èèyàn ń fi òun pè lọ́wọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Wọ́n dá a lóhùn pé: “Àwọn kan sọ pé Jòhánù Oníbatisí, àwọn mìíràn Èlíjà, síbẹ̀ àwọn mìíràn Jeremáyà tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, gbogbo àwọn tí wọ́n dárúkọ wọ̀nyí ti kú nígbà yẹn. Lẹ́yìn náà ni Jésù wá bi wọ́n pé: “‘Ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?’ Ní ìdáhùn, Símónì Pétérù sọ pé: ‘Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.’” Kódà àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì búburú sọ fún Jésù pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”—Mátíù 16:13-16; Lúùkù 4: 41.
Ta Ni Jésù Pe Ara Rẹ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kì í sábàá fẹnu ara ẹ̀ sọ pé Ọmọ Ọlọ́run lòun, síbẹ̀ kì í jiyàn tí wọ́n bá pè é bẹ́ẹ̀. (Máàkù 14:61, 62; Jòhánù 3:18; 5:25, 26; 11:4) Àmọ́, ó sábà máa ń sọ pé òun ni “Ọmọ ènìyàn.” Bó ṣe ń pe ara rẹ̀ báyìí, ńṣe ló ń fi bíbí tí wọ́n bí i léèyàn hàn, èyí sì fi í hàn bí èèyàn kan. Ó tipa báyìí fi hàn pé òun ni “ọmọ ènìyàn” náà tó dúró níwájú “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” ìyẹn Ọlọ́run Olódùmarè, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe rí i nínú ìran.—Mátíù 20:28; Dáníẹ́lì 7:13.
Dípò tí Jésù ì bá fi máa pariwo kiri pé Ọmọ Ọlọ́run lòun, ńṣe ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ fúnra wọn. Kódà gan-an, àwọn míì yàtọ̀ sáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ̀ fúnra wọn pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù. Lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù Oníbatisí àti Màtá tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù. (Jòhánù 1:29-34; 11:27) Àwọn wọ̀nyí gbà gbọ́ pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti wà lọ́run rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tó lágbára àti pé lọ́nà ìyanu ni Ọlọ́run fi mú un kúrò lọ́run tó sì fi ìwàláàyè rẹ̀ sínú ọlẹ̀ Màríà wúńdíá.—Aísáyà 7:14; Mátíù 1:20-23.
Ohun Tí Jésù Fi Jọ Ọkùnrin Àkọ́kọ́ Náà, Ádámù
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù fi jọ Ádámù tó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹni pípé làwọn méjèèjì, wọn ò sí ní èèyàn kankan ní baba. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, 15) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Ádámù ìkẹyìn,” ẹni pípé tó lè di “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí.” Ìwàláàyè Jésù ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ti “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́,” ẹni tí Ọlọ́run dá ní pípé.—1 Kọ́ríńtì 15:45; 1 Tímótì 2:5, 6.
Bíbélì pe Ádámù àkọ́kọ́ ní “ọmọkùnrin Ọlọ́run.” (Lúùkù 3:38) Àmọ́, Ádámù pàdánù àǹfààní jíjẹ́ tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nípa mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Jésù ní tiẹ̀ máa ń fìgbà gbogbo ṣe nǹkan tí Baba rẹ̀ tó wà lọ́run bá fẹ́ kó máa ṣe, ìyẹn ló fi jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run tínú Baba ẹ̀ máa ń dùn sí nígbà gbogbo. (Mátíù 3:17; 17:5) Bíbélì sọ pé gbogbo àwọn tó bá fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, tí wọ́n bá gbà á ní Olùgbàlà wọn ló lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà.—Jòhánù 3:16, 36; Ìṣe 5:31; Róòmù 5:12, 17-19.
Síbẹ̀, àwọn míì máa ń sọ pé Jésù kì í kàn ṣe Ọmọ Ọlọ́run, wọ́n ní òun gan-an fúnra ẹ̀ ni Ọlọ́run. Wọ́n ní òun àti Baba rẹ̀ ni Ọlọ́run Olódùmarè. Ṣé òótọ́ ni wọ́n sọ? Ṣé a lè sọ pé Jésù jẹ́ apá kan lára Ọlọ́run? Ṣé nǹkan tí Jésù tàbí èyíkéyìí lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ nìyẹn? Ta ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà gan-an? Ta ni Jésù pè bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká máa bọ́rọ̀ bọ̀.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kò Sẹ́ni Tí Òkìkí Rẹ̀ Kàn Tó Bẹ́ẹ̀ Rí
Mẹ́rin lára àwọn tó wà láyé lákòókò kan náà pẹ̀lú Jésù, tí wọ́n kọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ ni Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ sì ni méjì lára wọn jẹ́ sí i. Orúkọ wọn ni wọ́n fi sọ ìwé tí wọ́n kọ, ìwé Ìhìn Rere sì làwọn èèyàn sábà máa ń pe àwọn ìwé ọ̀hún. Wọ́n ti túmọ̀ lára àwọn ìwé yìí sí èdè tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún méjì. Àwọn ìwé kéékèèké yìí wà lára àwọn ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì. Àwọn ìwé Ìhìn Rere yìí ni ìwé tá a kọ tí ẹ̀dà rẹ̀ tíì pọ̀ jù lọ, ì báà jẹ́ bí odindi ìwé kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú Bíbélì. Abájọ tó fi jẹ́ pé kò sẹ́ni tí òkìkí rẹ̀ kàn tó ti Jésù nínú àwọn tó tíì gbé láyé rí!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn àpọ́sítélì béèrè pé: “Ta nìyí ní ti gidi?”