Béèyàn Ṣe Lè Láyọ̀ Nínú Ìgbéyàwó
“Ọkùnrin yóò . . . fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 2:24.
JÈHÓFÀ Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa, dá ìgbéyàwó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdè ìrẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ tó yẹ kó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin títí láé. Jẹ́nẹ́sísì 2:18, 22-24 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.’ Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi egungun ìhà tí ó mú láti inú ara ọkùnrin náà mọ obìnrin, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà. Nígbà náà ni ọkùnrin náà sọ pé: ‘Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi. Obìnrin ni a óò máa pe èyí, nítorí pé láti ara ọkùnrin ni a ti mú èyí wá.’ Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.”
Lóòótọ́, kò rọrùn láti ní ìdílé tí ayọ̀ ẹ̀ á dalẹ́, ṣùgbọ́n ó dájú pé ó ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ti ṣègbéyàwó láti bí àádọ́ta ọdún, ọgọ́ta ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọgbọ́n wo ni wọ́n dá sí i? Ṣe ni wọ́n ń sapá ní gbogbo ìgbà láti rí i pé ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere wọn ò sì ní ìmọtara-ẹni-nìkan, kàkà bẹ́ẹ̀ bí wọ́n á ṣe “jèrè ìtẹ́wọ́gbà” ẹni tí wọ́n bá ṣègbéyàwó ni wọ́n ń wá. (1 Kọ́ríńtì 7:33, 34) Iṣẹ́ kékeré kọ́ nìyẹn á gbà o. Bó o bá ṣe tán àtifún un ní àkókò àti okun tó gbà, ìwọ náà lè ní ìgbéyàwó aláyọ̀, ìyẹn ọ̀kan tó máa wà pẹ́ títí.
Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni Tó Wà Lórí Ọ̀ràn Ìgbéyàwó
Agbaṣẹ́ṣe kan tó ṣeé fọkàn tán ò ní í bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kan láìṣe pé ó kọ́kọ́ yẹ àkọsílẹ̀ tó wà lórí bó ṣe máa ṣiṣẹ́ yẹn wò. Bọ́rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn tó bá dọ̀ràn ìgbéyàwó aláyọ̀, a ò lè ṣàṣeyọrí lórí ẹ̀ tá ò bá kọ́kọ́ yẹ ìtọ́ni Ọlọ́run lórí béèyàn ṣe lè ní ìgbéyàwó aláyọ̀ wò. Ìtọ́ni náà wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní . . . fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.
Àwọn tọkọtaya lè rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ nípa ìgbéyàwó bí wọ́n bá kíyè sí àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò. Kì nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀? Bíbélì fi ọ̀rọ̀ Jésù àtàwọn tó máa bá a jọba lọ́run wé ọ̀rọ̀ ọkùnrin kan àti ìyàwó ẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 11:2) Jésù dúró ti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kódà nígbà làásìgbò. “Ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tó lójú àánú Jésù máa ń gba tàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rò, pé ó níbi tágbára wọn mọ ó sì máa ń fi àìlera wọn sọ́kàn. Kò ní kí wọ́n ṣe kọjá agbára wọn lọ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò béèrè ohun tó mọ̀ pé wọn ò ní.—Jòhánù 16:12.
Kódà nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ já a kulẹ̀, ó ṣì ń fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ hùwà. Kò nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń fi ìrẹ̀lẹ̀ àti inú rere, irú èyí tí Ọlọ́run ní, bá wọn lò, ó máa ń tún ojú ìwòye wọn ṣe. (Mátíù 11:28-30; Máàkù 14:34-38; Jòhánù 13:5-17) Torí náà, tó o bá fara balẹ̀ ṣàkíyèsí ọ̀nà tí Jésù gbà fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò àti ọ̀nà táwọn náà gbà fi ìfẹ́ bá a lò, wàá rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ lórí bó o ṣe lè mú kí ìgbéyàwó rẹ láyọ̀.—1 Pétérù 2:21.
Jẹ́ Kí Ìpìlẹ̀ Ìgbéyàwó Rẹ Lágbára
Kò sí àníàní, àwọn àdánwò tó dà bí ìjì á máa rọ́ lu ìpìlẹ̀ ìgbéyàwó rẹ. Àdánwò yìí máa dán bí ìpìlẹ̀ tẹ́ ẹ kọ́ ìgbéyàwó yín lé lórí ṣe lágbára tó wò. Àmọ́, ìpìlẹ̀ tó lágbára jù téèyàn lè kọ́ ìgbéyàwó lé kó bàa lè láyọ̀ ni jíjẹ́ kí ìfẹ́ sún un láti fọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó ẹ̀. Jésù sọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn dúró lórí ìpinnu rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ.” (Mátíù 19:6.) “Ènìyàn kankan” tí Bíbélì sọ níbí yìí kan ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀, tí wọ́n ti ṣèlérí láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn.
Lójú àwọn kan, ìnira ni láti dúró lórí ẹ̀jẹ̀ téèyàn jẹ́ láti wà pa pọ̀, wàhálà àti àkókò púpọ̀ ló ń gbà. Lóde òní, ohun táwọn èèyàn fẹ́ jù ni ohun tó rọrùn fún wọn dípò kí wọ́n fi nǹkan du ara wọn torí pé wọ́n fẹ́ dúró lórí ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn.
Kí ló lè mú káwọn èèyàn dúró lórí ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.” (Éfésù 5:28, 29) Nígbà náà, lápá kan ‘síso tí wọ́n so yín pọ̀’ fi hàn pé wàá máa ronú nípa bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún ẹnì kejì rẹ gẹ́gẹ́ bó o ṣe ń ronú lórí tìẹ náà. Dípò táwọn tó ti ṣègbéyàwó á fi máa sọ pé “tèmi” tàbí “èmi,” ohun tó yẹ kí wọ́n máa sọ ni “tiwa” tàbí “àwa.”
Bó o bá ṣe ń jàjàbọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ń bì lu ìgbéyàwó ẹ bí ìgbà tí ìjì ń fẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá túbọ̀ máa gbọ́n sí i. Irú ọgbọ́n tó o ní yẹn á mú ẹ láyọ̀. Òwe 3:13 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó ti wá ọgbọ́n rí.”
Fi Àwọn Ohun Èlò Tí Kò Lè Jóná Gbé Ìgbéyàwó Rẹ Ró
Téèyàn bá fẹ́ kí ilé kan tọ́jọ́ kó sì ṣeé gbé, ó gbọ́dọ̀ kọ́ ọ dáadáa. Torí náà, rí i dájú pé ò ń gbé ìgbéyàwó rẹ ró kó bàa lè tọ́jọ́. Lo àwọn ohun èlò tí kò ní tètè bà jẹ́, ìyẹn àwọn ohun tó lè dúró tí àdánwò tó dà bí iná bá dán ìdúróṣinṣin ẹ̀ wò. Àwọn ànímọ́ pàtàkì tó yẹ kó o kà sí iyebíye bíi wúrà ni ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìwà ọ̀làwọ́, ìfòyemọ̀, ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀yàyà, fífi ìfẹ́ mọrírì àwọn òfin Ọlọ́run, tó fi mọ́ ojúlówó ìgbàgbọ́.
Ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú ìgbéyàwó kò sinmi lórí àwọn ohun ìní tara tàbí béèyàn ṣe rọ́wọ́ mú tó nínú ayé. Inú ọkàn èèyàn làwọn ànímọ́ yìí máa ń wà, òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló sì máa ń fún wọn lágbára. A tún lè lo ìmọ̀ràn náà pé, “kí olúkúlùkù máa ṣọ́ bí ó ti ń kọ́lé,” nínú ìgbéyàwó.—1 Kọ́ríńtì 3:10.
Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Ìṣoro Bá Yọjú
Téèyàn bá fẹ́ kí ilé kan wà pẹ́ títí, ọwọ́ àtúnṣe ò gbọdọ̀ kúrò lára rẹ̀. Nígbà tí ọkọ àti ìyàwó bá ń ṣètìlẹ́yìn fún ara wọn kọ́wọ́ lè tẹ àfojúsùn wọn tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn, ìgbéyàwó wọn á fìdí múlẹ̀. Ìmọtara-ẹni-nìkan ò ní ráàyè láàárín wọn, wọn ò sì ní í máa bínú sódì.
Ìbínú kíkorò àti ìjákulẹ̀ lè paná ìfẹ́ nínú ìgbéyàwó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ọkùnrin nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) Ìmọ̀ràn yìí kan àwọn aya bákan náà. Bí tọkọtaya bá ń gbìyànjú láti máa gba tara wọn rò, tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì lóye ara wọn, ìgbéyàwó wọn á máa láyọ̀, ọkàn wọn á sì balẹ̀. Bí inú yín ò bá le, tẹ́ ò sì máa bá ara yín fà á, á ṣeé ṣe fún yín láti ṣe é tí kò fi ní sí ìforígbárí nígbà tí ìṣòro bá dé. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Éfésù 4:32.
Àmọ́ tínú bá ń bí ọ torí pé agara dá ọ, tàbí tí wọ́n ṣe nǹkan tó dùn ọ́ tàbí tó ò rí ọ̀wọ̀ tó yẹ ọ́ gbà ńkọ́? Fi pẹ̀lẹ́tù sọ ohun tó ń dùn ẹ́ fẹ́nì kejì ẹ. Àmọ́, o lè jẹ́ kí ìfẹ́ bo àwọn ọ̀ràn kéèkèèké mọ́lẹ̀.—1 Pétérù 4:8.
Ọkọ kan tó ti ní ọ̀pọ̀ iṣòro nínú ìgbéyàwó rẹ̀ láti ọdún karùndínlógójì tó ti fẹ́yàwó sọ pé kò sí bínú ṣe lè máa bí ọ sí ìyàwó ẹ tó, “má ṣe yàn án lódì láé.” Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wá fi kún un ni pé: “Má ṣe síwọ́ nínífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”
Ìgbéyàwó Rẹ Lè Láyọ̀!
Lóòótọ́, kò rọrùn láti gbádùn ìgbéyàwó aláyọ̀ o. Àmọ́, nígbà tẹ́yin méjèèjì bá ti pinnu pé ẹ máa fi ti Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbéyàwó yín, ẹ́ óò láyọ̀, ọkàn yín á sì balẹ̀. Fún ìdí èyí, lójú méjèèjì ni kó o máa ṣọ́ bí ìdílé rẹ ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó; dúró gbọn-in ti ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó rẹ. Sì rántí pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jésù, nínú ọkọ tàbí ìyàwó, kò sí ẹni tó tó gbọpẹ́ pé ìgbéyàwó láyọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tọ́pẹ́ yẹ torí ìyẹn ni Jèhófà Ọlọ́run, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó. “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:6.
ÌWÉ TÓ O LÈ KÀ FÚN ÀLÀYÉ SÍ I
Ìwe Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀, ní àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tó lè ran èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìgbéyàwó aláyọ̀ tọ́jọ́ rẹ̀ á kalẹ́. Jákèjádò ayé, ẹgbàágbèje tọkọtaya tó ti kà á ló rí i pé ìmọ̀ràn rẹ̀ wúlò ó sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí àárín wọn gún régé sí i.—Wo ojú ewé 32 nínú ìwé ìròyìn yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Kí Ló Lè Ràn Yín Lọ́wọ́ Láti Láyọ̀ Nínú Ìgbéyàwó Yín?
◼ Ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀, ẹ máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ kó sì kọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe máa yanjú ìṣòro yín.—Òwe 3:5, 6; Fílípì 4:6, 7; 2 Tímótì 3:16, 17.
◼ Àárín ara yín nìkan ṣoṣo ni kẹ́ ẹ fi ìbálòpọ̀ mọ sí.—Òwe 5:15-21; Hébérù 13:4.
◼ Ẹ máa bá ara yín sọ ohun tó bá wà lọ́kàn yín, tẹ́ ẹ bá ní ìṣòro tàbí àìgbọ́ra ẹni yé, ẹ máa fi òtítọ́ àti ìfẹ́ sọ ọ́.—Òwe 15:22; 20:5; 25:11.
◼ Ẹ máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá ara yín sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ máa gba tara yín rò lẹ́nì kìíní kejì; ẹ má máa jẹ́ kí inú yín máa ru jáde, ẹ má máa ro ẹjọ́ wẹ́wẹ́ kẹ́ ẹ sì má máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí ara yín.—Òwe 15:1; 20:3; 21:9; 31:26, 28; Efésù 4:31, 32.
◼ Máa fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò kódà lẹ́yìn tó o ti rí i pé ìyàwó tàbí ọkọ rẹ kì í ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó máa ṣe.—Róòmù 14:12; 1 Pétérù 3:1, 2.
◼ Ṣiṣẹ́ kára láti lè ní àwọn ìwà tínú Ọlọ́run dùn sí, èyí tí Bíbélì mẹ́nu bà.—Gálátíà 5:22, 23; Kólósè 3:12-14; 1 Pétérù 3:3-6.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run lórí ìdílé, èyí tó wà nínú Bíbélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹ fi ìfẹ́ aláìmọtara ẹni nìkan àti ìdúróṣinṣin ṣe ìpìlẹ̀ ìgbéyàwó yín
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ẹ ní ànímọ́ tó bá Ìwé Mímọ́ mu, èyí tó lè rí ara gba àwọn ìṣòro tó dà bí iná
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ó yẹ ká sapá bí ìgbéyàwó wa bá máa dáa táá sì tọ́jọ́