Mo Ti Fìgbà Kan Rí Dà bí Ọmọ Onínàákúnàá
Gẹ́gẹ́ Bí Meros William Sunday Ṣe Sọ Ọ́
Láti kékeré làwọn òbí mi ti kọ́ mi láti fẹ́ràn Ọlọ́run, àmọ́ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, mo ya tara mi, mo sì kó kúrò nílé. Ọdún mẹ́tàlá ni mo fi filé sílẹ̀ bíi tọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù. (Lúùkù 15:11-24) Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbé oògùn olóró, díẹ̀ ló sì kù kí n ba ayé ara mi jẹ́. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé ohun tó fà á tí mo fi pe orí ara mi wálé bíi tọmọ onínàákúnàá tó padà sílé.
KRISTẸNI làwọn òbí tó bí mi lọ́mọ. Ọdún 1956 ni wọ́n bí mi, èmi sì lọmọ kejì nínú ọmọ mẹ́sàn-án tí wọ́n bí. Ìlú Iléṣà, tó wà ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, là ń gbé nígbà náà. Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ bàbá mi dàgbà, àmọ́, lọ́dún 1945, bàbá kan tó jẹ́ àbúrò bàbá mi àgbà fún bàbá mi ní ìwé Duru Ọlọrun.a Lẹ́yìn tí bàbá mi ka ìwé náà tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni màmá mi pẹ̀lú ṣèrìbọmi.
Mo ṣì máa ń rántí bí ìgbàgbọ́ ti mo ní nínú Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó nígbà tí mo wà lọ́mọdé àti bí mo ṣe máa ń fìtara báwọn òbí mi lọ sóde ẹ̀rí. Bàbá mi ló bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin Alice Obarah, tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ládùúgbò wa nígbà yẹn, tún máa ń bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn òbí mi fẹ́ kí n di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ìyẹn ẹni tó ń fàkókò púpọ̀ wàásù. Àmọ́, màmá mi sọ pé á dára kí n jáde ilé ẹ̀kọ́ girama ná kí n tó bẹ̀rẹ̀.
Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ girama, lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, tí àìgbọ́n fi sún mi láti bẹ̀rẹ̀ sí í dọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ìwé mi tí wọn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì. Àṣìṣe ńlá gbáà ni mo ṣe! Ká tó wí, ká tó fọ̀, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá, mo sì ń ṣèṣekúṣe. Mo mọ̀ pé irú ìgbésí ayé tí mò ń gbé yẹn ò bá àwọn nǹkan tí mò ń kọ́ nípàdé ìjọ mu, bí mi ò ṣe lọ sípàdé mọ́ nìyẹn, tí mo sì figi gún òde ẹ̀rí. Ọkàn àwọn òbí mi bà jẹ́, àmọ́ mi ò ṣe bí ẹni tó rí wọn ńtèmi.
Mo Kó Kúrò Nílé
Lẹ́yìn tí mo lo ọdún méjì ní ilé ẹ̀kọ́ girama, mo kó kúrò nínú ilé témi àtàwọn òbí mi ń gbé mo sì kó tọ àwọn ọ̀rẹ́ mi tó wà ládùúgbò lọ. Nígbà míì, màá yọ́ wálé, màá kó oúnjẹ èyíkéyìí tọ́wọ́ mi bá bà, màá sì sá lọ. Ìgbà tára bàbá mi ò gbà á mọ́, ó ṣíwọ́ sísan owó ilé ìwé mi, nírètí pé màá yí padà.
Àmọ́, déédéé ìgbà yẹn náà ni mo rí àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gbà. Àwọn tó ṣonígbọ̀wọ́ ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ náà máa ń fowó ilé ìwé ránṣẹ́ sí mi láti orílẹ̀-èdè Scotland, wọ́n sì tún máa ń fún mi lẹ́bùn àtowó nígbà míì. Lákòókò yìí kan náà, bùrọ̀dá mi àti àbúrò mi ọkùnrin kan ò ṣe ajẹ́rìí mọ́. Bí ìbànújẹ́ ṣe tún gorí ìbànújẹ́ fáwọn òbí mi nìyẹn o. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni màmá mi ń bẹ̀ mí pẹ̀lú omijé lójú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dùn mí gan-an, ìyẹn ò ní kí n yí padà.
Mò Ń Tìlú Kan Lọ sí Òmíràn
Lẹ́yìn tí mo jáde ilé ìwé girama lọ́dún 1977, mo gba Èkó lọ, mo sì ríṣẹ́ níbẹ̀. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, mo fèrú kó owó jọ mo sì ra ọkọ̀ takisí kan. Bó ṣe wá di pé owó tó ń wọlé sọ́wọ́ mi ń pọ̀ sí i báyìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mo sì ń pẹ́ lóde àríyá alaalẹ́ àti nílé aṣẹ́wó. Ìgbà tó ṣe, ó sú mi láti máa gbé nílùú Èkó, mo sì gba ìlú London lọ lọ́dún 1981. Láti ibẹ̀ ni mo ti kọjá sí orílẹ̀-èdè Belgium níbi tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Faransé tí mo sì ń wáṣẹ́ kan fọwọ́ pa nílé àrójẹ. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àkókò mi ni mo fi ń kó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àtàwọn ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́ ránṣẹ́ sí Nàìjíríà.
Bàbá mi kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Belgium ó sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá mi kàn kí wọ́n sì gbìyànjú láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, nígbàkigbà táwọn Ẹlẹ́rìí bá wá síbi tí mò ń gbé, n kì í gbọ́rọ̀ wọn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tí fàájì ti ń ṣàn níbi tí jíjẹ àti mímu máa ń wà, tá a sì tún máa ń ṣe oríṣiríṣi eré ìdárayá lẹ́yìn ìsìn.
Mo Bẹ̀rẹ̀ sí Í Gbé Oògùn Olóró
Lọ́dún 1982, mo gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ olówó gọbọi, tó rí mìnìjọ̀jọ̀ wọlé sórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, mo sì lọ sọ́dọ̀ àwọn aṣọ́bodè láti lọ gbà á wọlé. Iléeṣẹ́ Aṣọ́bodè lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà rí i pé ayédèrú làwọn ìwé tí mo fi gbé ọkọ̀ náà wọlé, wọ́n sì fi mí sátìmọ́lé fún ogójì ọjọ́. Bàbá mi gba béèlì mi. Níwọ̀n bí mo sì ti nílò owó láti parí ẹjọ́ náà, mo kó àwọn ọjà kan, tó fi mọ́ igbó tó pọ̀ díẹ̀, padà lọ sí orílẹ̀-èdè Belgium. Lẹ́yìn tí mo bọ́ nínú ẹjọ́ ìwé tí mo yí láti gbé ọkọ̀ wọlé, mo kúkú ki gbogbo ara bọ òwò gbígbé oògùn olóró.
Nígbà kan tí mo gbé oògùn olóró lọ sókè òkun, wọ́n mú mi lórílẹ̀-èdè Netherlands. Àwọn aṣọ́bodè fi mí lé ọkọ̀ òfuurufú tó ń bọ̀ ní Nàìjíríà, kó lè gbé mi padà sílé. Nínú ọkọ̀ òfuurufú ọ̀hún ni mo ti bá àwọn míì tó ń gbé oògùn olóró pàdé, a dòwò pọ̀ a sì jọ ń gbé oògùn olóró. Lóṣù January, ọdún 1984, mo tún kọjá lọ sí orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Áfíríkà. Nítorí pé mo gbọ́ èdè Faransé tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà, kò pẹ́ tí mo fi dọ̀rẹ́ àwọn ọlọ́pàá, sójà àtàwọn òṣìṣẹ́ tó ń wọ̀lú tàbí tó ń jáde nílùú láìgbàṣẹ. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹrù igbó wọ orílẹ̀-èdè náà.
Wọ́n Mú Mi Wọ́n sì Sọ Mí Sẹ́wọ̀n
Mo tún kó sí ìṣòro. Mo ti bá ọ̀gá sọ́jà kan dì í pé kó jọ̀ọ́ kó bá mi rí sí i pé ẹrù mi gba ibùdókọ̀ òfuurufú wọ orílẹ̀-èdè náà láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni tú u wò. Àmọ́, ó pẹ́ kó tó dé, bọ́wọ́ ṣe bà mí nìyẹn. Àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n ń pè ní gendarme lù mí ní àlùbami débi tí mo fi dákú. Wọ́n gbé mi lọ sílé ìwòsàn wọ́n sì fi mí sílẹ̀ níbẹ̀, nírètí pé màá kú. Àmọ́, mo yè é, lẹ́yìn náà ni wọ́n fẹ̀sùn kàn mí, wọ́n dá mi lẹ́bi lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n.
Nígbà tí mo fi máa tẹ̀wọ̀n dé, ọ̀rẹ́ mi tí mo ní kó máa wo ilé dè mí ti gbé gbogbo ohun ìní mi tà ó sì ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Nítorí àtijẹ àtimu, ojú ẹsẹ̀ ni mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ta igbó. Àmọ́, ní ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n tún mú mi, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta. Nígbà tí wọ́n dá mí sílẹ̀, mo ṣàìsàn débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Bákan bàkàn ṣá, mo ṣáà tún bára mi nílùú Èkó.
Mo Tún Padà Sídìí Gbígbé Oògùn Olóró
Nígbà tí mo dé ìlú Èkó, èmi àti díẹ̀ lára àwọn tá a jọ ń gbé oògùn olóró tún pàdé, a sì forí lé ìlú Íńdíà, níbi tá a ti ra oògùn olóró tí wọ́n ń pè ní heroin tó tó nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí táá tó mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́rin náírà báyìí. Láti Bombay (tó ń jẹ́ Mumbai báyìí) a kọjá lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland, ibẹ̀ la gbà yọ sí orílẹ̀-èdè Portugal ká tó wá lọ gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì. Èrè gọbọi lẹnì kọ̀ọ̀kan wa rí nínú oògùn olóró tá a gbé náà, ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la sì bá padà wọ ìlú Èkó. Lọ́wọ́ ìparí ọdún 1984, mo tún ta oògùn olóró míì. Mo ti fọkàn dá a pé lẹ́yìn tí mo bá ti rí iye tó tó mílíọ̀nù kan owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà nídìí oògùn olóró, táá tó mílíọ̀nù méjìdínláàádóje náírà báyìí, màá lọ fìdí kalẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà màá sì máa gbé ìgbésí ayé mi lọ níbẹ̀.
Lọ́dún 1986, mo kó gbogbo owó tí mo ní jọ mo sì ra ògidì heroin nílùú Èkó. Mó gbé e, ó di orílẹ̀-èdè mìíràn, àmọ́ ọwọ́ oníwọra èèyàn kan báyìí ni ọjà náà bọ́ sí, kò sì sanwó fún mi. Kí wọ́n má bàa pa mí, mo padà sílùú Èkó, mi ò sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ẹ̀dá Ọlọ́run kankan. Mo di ẹdun arinlẹ̀, gbogbo nǹkan sì tojú sú mi. Fún ìgbà àkọ́kọ́, mo forúnkún tẹ̀pá ìrònú pé kí ni ilé ayé yìí já mọ́ gan-an. Mo wá bi ara mi pé, ‘Kí ló fà á tí gbogbo ọ̀rọ̀ mi fi dojú rú bí ìrìn alákàn báyìí o?’
Bí Mo Ṣe Padà Sínú Ètò Ọlọ́run
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni mo gbàdúrà sí Jèhófà lálẹ́ ọjọ́ kan báyìí pé kó ràn mí lọ́wọ́. Kí ni mó máa rí, lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì, ṣe ni ọkùnrin àgbàlagbà kan àti ìyàwó rẹ̀ kan ilẹ̀kùn mi. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Mo fara balẹ̀ gbọ́rọ̀ wọn, mo sì gba ìwé ìròyìn kan. Mo ṣàlàyé pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi. Àti pé Alice Obarah máa ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀.”
Bàbá àgbàlagbà náà tó ń jẹ́ P. K. Ogbanefe, dá mi lóhùn pé: “Ẹni mímọ̀ wa làwọn Obarah. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ti Nàìjíríà tó wà nílùú Èkó ni wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ báyìí.” Wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n lọ rí wọn. Lílọ tí mo lọ rí wọn mú kí n rí ọ̀pọ̀ ìṣírí gbà. Lẹ́yìn ìyẹn, Arákùnrin Ogbanefe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọwọ́ ìṣekúṣe mi bọlẹ̀. Èyí ò rọrùn nítorí pé ó ṣòro fún mi láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró tí mo ti ń lò látọjọ́ tó ti pẹ́. Síbẹ̀, mo dúró lórí ìpinnu mi pé màá fọ ìgbésí ayé mi mọ́.
Síbẹ̀ náà, kò rọrùn. Ọ̀pọ̀ àdánwò ló dojú kọ mí, àwọn tó pera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ mi ò sì yé yọ mi lẹ́nu! Wọ́n tiẹ̀ máa ń wá sílé mi nígbà míì tí wọ́n á sì máa fi àwọn nǹkan tó la owó lọ lọ̀ mí. Àwọn àkókò kan tiẹ̀ wà tí mo tún padà sídìí sìgá mímu àti ìṣekúṣe. Mo ṣí ọkàn mi payá fún Ọlọ́run nínú àdúrà. Ìgbà tó ṣe ni mó wá mọ̀ pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ ayé ló ṣì mí lọ́nà, kò sí bí wọ́n ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ nísinsìnyí. Mo mọ̀ pé kí n tó lè tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àfi kí n fi Èkó sílẹ̀. Àtipadà sí Iléṣà ló sì ń tì mí lójú yìí. Nígbà tó yá ṣáá, mo kọ lẹ́tà sí bàbá mi àti bùrọ̀dá mi pé ṣé kí n máa bọ̀ nílé.
Bàbá mi fi dá mi lójú pé ilé nilé mi, kí n máa bọ̀, bùrọ̀dá mi náà sì sọ pé ohun á bá mi wá owó díẹ̀. Bí mo ṣe padà sílé lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá ti mo ti fàwọn òbí mi sílẹ̀ nìyẹn o. Wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀. Inú màmá mi dùn, wọ́n ò mọ̀gbà tí wọ́n sọ pé: “Jèhófà, o mà ṣeun o!” Nígbà tí bàbá mi dé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n ní, “Jèhófà á ràn ẹ́ lọ́wọ́.” Lẹ́yìn náà, wọ́n pe gbogbo ilé jọ, wọ́n sì gbàdúrà sí Jèhófà, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ léyìí tí mo ti padà dé láti wá ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ yìí.
Mo Padà sí Ẹsẹ Àárọ̀
Mo padà bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìtẹ̀síwájú mi sì ṣe kánmọ́ kánmọ́ débi pé mo ṣèrìbọmi ní April 24, ọdún 1988. Lójú ẹsẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sóde ẹ̀rí déédéé. Ní November 1, 1989, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn ajíhìnrere tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù. Lọ́dún 1995, wọ́n pè mí sí kíláàsì kẹwàá Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní Nàìjíríà. Nígbà tó sì di oṣù July, ọdún 1998, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, tí yóò máa bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò. Lọ́dún kan lẹ́yìn náà, Jèhófà fi Ruth kẹ́ mi, ó di ìyàwó mi, a sì jọ ń lọ káàkiri láti bẹ àwọn ìjọ wò.
Àwọn tó kù nínú ìdílé wa náà ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn Jèhófà. Ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tóun náà ti fìgbà kan fi ètò sílẹ̀ tún ti padà sínú ètò, ó sì ti ṣèrìbọmi. Inú mi dùn pé pípadà tá a padà ṣojú ẹ̀mí bàbá wa. Tayọ̀tayọ̀ ló fi sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ kó tó di pó kú lọ́dún 1993, lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rin. Màmá mi ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà nìṣó nílùú Iléṣà.
Mo rìnrìn-àjò dé orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlógún nílẹ̀ Yúróòpù, Éṣíà àti Áfíríkà níbi tí mo ti ń wá ọrọ̀ kiri. Èyí tó mú kí n “fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara [mi] káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Bí n bá wẹ̀yìn wo báyìí, ńṣe ló máa ń dùn mí pé mo fi èyí tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú àkókò ìgbà ọ̀dọ́ mi ṣòfò lé oògùn olóró àti ìṣekúṣe lórí. Ó dùn mí pé mo ṣe ohun tó dun Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn òbí mi. Síbẹ̀, mo ṣọpẹ́ pé mi ò tíì rí ikú he títí tí orí mi fi wálé. Mo ti wá pinnu báyìí láti dúró sínú ètò Jèhófà láìyẹsẹ̀ kí n sì máa sìn ín títí ayérayé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́, ṣùgbọ́n a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ìgbà ọ̀dọ́ tí mo ya tara mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Lọ́jọ́ tí mo ṣèrìbọmi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Èmi àti Ruth, ìyàwó mi