Ìtàn Ìgbésí Ayé
Níní Ìtẹ́lọ́rùn tí Ọlọ́run Ń Fúnni ti Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró
GẸ́GẸ́ BÍ BENJAMIN IKECHUKWU OSUEKE ṢE SỌ Ọ́
Kété lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni mo lọ sílùú wa. Bí bàbá mi ṣe rí mi báyìí, ńṣe ló lọ́ aṣọ mọ́ mi lọ́rùn tó bẹ̀rẹ̀ sí pariwo “Olè” lé mi lórí! Ó fa àdá rẹ̀ yọ, ó sì fi pẹ̀tẹ́pẹ̀tẹ́ àdá nà mí. Ariwo tó pa yẹn ló wá mú káwọn ará abúlé kóra jọ sílé wa. Kí ni mo jí o? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.
ỌDÚN 1930 ni wọ́n bí mi ní abúlé Umuariam tó wà ní gúúsù ìlà òórùn Nàìjíríà, èmi sì ni àkọ́bí nínú àwa ọmọ méje. Èyí tó dàgbà jù nínú àwọn àbúrò mi obìnrin kú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà làwọn òbí mi máa ń lọ. Àgbẹ̀ ni bàbá mi, màmá mi sì máa ń ta àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Màmá á fẹsẹ̀ rin lọ sí àwọn ọjà abúlé tó wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà sí abúlé wa, ibẹ̀ ló ti máa ń ra garawa epo kan, táá sì padà wálé lálẹ́ ní ọjọ́ yẹn kan náà. Á tún gbéra ní òwúrọ̀ hàì ọjọ́ kejì, á fẹsẹ̀ rin lọ sí ìlú kan tí rélùwéè máa ń gbà kọjá, èyí tó wà ní nǹkan bí ogójì kìlómítà sí abúlé wa, ibẹ̀ ló ti máa ń ta epo ọ̀hún. Tó bá jèrè lórí ọjà náà, èrè yìí kì í sábà ju kọ́bọ̀ mẹ́wàá àtijọ́, á fi owó náà ra oúnjẹ tí ìdílé wa máa jẹ á sì tún padà sílé lọ́jọ́ yẹn kan náà. Ohun tó ṣe fún nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nìyẹn, títí tó fi wá kú lọ́dún 1950.
Ilé ìwé kan tí Ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà ń bójú tó lábúlé wa ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ mi, àmọ́ kí n tó lè parí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ mo ní láti lọ sí ilé ìwé tó ní ilé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń gbé, ìyẹn sì wà ní nǹkan bí kìlómítà márùndínlógójì sí abúlé wa. Nítorí pé àwọn òbí mi ò lówó tí mo máa fi tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí wáṣẹ́ kiri. Mo kọ́kọ́ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ fún ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹ̀ṣọ́ fún ilé iṣẹ́ rélùwéè ní Èkó, ìyẹn ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, ẹ̀yìn ìyẹn ni mo lọ ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ní Kàdúná, tó wà ní apá àríwá Nàìjíríà. Mo tún rí iṣẹ́ akọ̀wé fún agbẹjọ́rò kan tó wà ni Ìlú Benin ní àárín ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, kí n tó wà di lébìrà ní ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń la pákó. Àtibẹ̀ ni mo ti wá lọ sí orílẹ̀-èdè Cameroon ní ọdún 1953 lọ́dọ̀ àbúrò ìyá mi tó ràn mi lọ́wọ́ láti ríṣẹ́ ní oko rọ́bà. Owó tí mò ń gbà lóṣù ń lọ sí nǹkan bí pọ́n-ùn mẹ́ta àti ṣílè mẹ́rin. Iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ni mò ń ṣe níbẹ̀, síbẹ̀ ọkàn mi balẹ̀ níwọ̀n bí owó tí mò ń gbà ti tó mi jẹun.
Tálákà Paraku Kan Ń Pín Ọrọ̀ Fúnni
Silvanus Okemiri, tá a jọ ń ṣiṣẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo ìgbà ló máa ń sọ ohun tó mọ̀ nípa Bíbélì fún mi nígbà tá a bá ń gé koríko àti nígbà tá a bá ń bú ajílẹ̀ yí ìdí àwọn igi rọ́bà ká. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń fetí sóun tó ń sọ, àmọ́ mi ò ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀ nígbà yẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbà tí ìbátan mi rí i pé mo ń fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sá gbogbo ipá rẹ̀ láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Ó sọ fún mi pé: “Benji, o ò gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Okemiri mọ́. Jèhófà ló ń sìn, tálákà paraku sì ni. Bó ṣe rí yẹn gan-an ni ẹnikẹ́ni tó bá bá a kẹ́gbẹ́ ṣe máa rí o.”
Nígbà tó di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1954, tí mi ò lè fara da bí nǹkan ṣe lè koko nílé iṣẹ́ náà mọ́, mo padà wá sílé. Ìjọ Áńgílíkà kò fàyè gba ìwà pálapàla rárá nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ìyẹn sì jẹ́ kí n kórìíra ìwà pálapàla gan-an. Àmọ́, láìpẹ́, ìwà àgàbàgebè táwọn tá a jọ ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ń hù tún bẹ̀rẹ̀ sí kó mi nírìíra. Wọ́n ń fi gbogbo ẹnu sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn ò bá ohun tí wọ́n ń sọ yìí mu rárá. (Mátíù 15:8) Gbogbo ìgbà ni èmi àti bàbá mi máa ń ṣe àríyànjiyàn, ìyẹn ò sì jẹ́ kí àárín wa fi bẹ́ẹ̀ gún. Ni mo bá fi ilé sílẹ̀ ní òru ọjọ́ kan.
Mo lọ sí Omoba, ìyẹn ìlú kékeré kan tó ní ọ̀nà ojú rélùwéè. Ibẹ̀ ni mo tún ti wá bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Priscilla Isiocha, tí mo ti mọ̀ láti abúlé mi, fún mi ní ìwé kékeré “Ihinrere Ijọba Yi” àti ìwé Lẹhin Armagẹddọn—Aiye Titun ti Ọlọrun.a Kíá ni mo kà wọ́n tán, mo sì wá rí i dájú pé mo ti rí òtítọ́. A kì í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣọ́ọ̀ṣì mi; àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn la máa ń sọ̀rọ̀ lé lórí níbẹ̀. Àmọ́, nínú ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí, léraléra ni wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ̀ látinú Bíbélì.
Kò pé oṣù kan lẹ́yìn ìyẹn ti mo bi Arákùnrin àti Arábìnrin Isiocha nípa ìgbà tí wọ́n máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì wọn. Ọjọ́ tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàá, mi ò lóye ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ rárá. Ọ̀rọ̀ nípa ìkọlù ‘Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù’ tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ọjọ́ náà dá lé lórí. (Ìsíkíẹ́lì 38:1, 2) Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ló ṣàjèjì sí mi, àmọ́ bí wọ́n ṣe kí mi káàbọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà níbẹ̀ wú mi lórí gan-an tí mo fi pinnu pé máa tún padà lọ ní Sunday tó tẹ̀ lé e. Nígbà ìpàdé kejì yìí, mo gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìwàásù. Mo wá béèrè ọjọ́ tí wọ́n máa ń jáde lọ wàásù lọ́wọ́ Priscilla. Mo bá wọn jáde òde ẹ̀rí ní Sunday kẹta, mo sì gbé Bíbélì kékeré kan dání. Mi ò ní àpò òde ẹ̀rí, mi ò sì ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kankan. Síbẹ̀, mo di akéde Ìjọba Ọlọ́run mo sì ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí oṣù yẹn parí!
Kò sẹ́ni tó kọ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ìgbàkigbà tí mo bá ti lọ sílé àwọn Isiocha ni mo máa ń rí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ìṣírí gbà látinú Ìwé Mímọ́ tí máa sì gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan dáni. Ìpàdé àgbègbè tá a ṣe ní Aba ní December 11, 1954 ni mo ti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ìbátan mi tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ tí mo sì ń kọ́ṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ kò fún mi lóúnjẹ mọ́, kó sì kọ́ mi níṣẹ́ mọ́, kò tiẹ̀ san kọ́bọ̀ fún mi lórí gbogbo iṣẹ́ tí mo ṣe fún un. Síbẹ̀, mi ò bínú sí i, ńṣe ni mo kàn ń dúpẹ́ pé mo ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Èyí ló ń fún mi ní ìtùnú àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò ibẹ̀ ràn mí lọ́wọ́. Ìdílé Isiocha fún mi lóúnjẹ, àwọn mìíràn sì yá mi lówó pé kí n fi bẹ̀rẹ̀ sí ta àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Mo ra àlòkù kẹ̀kẹ́ kan ní àárín ọdún 1955, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní March 1956. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí mo san gbogbo gbèsè tó wa lọ́rùn mi padà. Èrè tí mò ń rí lórí ọjà tí mò ń ta kéré gan-an, àmọ́ mo lè gbọ́ bùkátà ara mi báyìí. Ohun tí Jèhófà ń pèsè tó fún mi.
“Jíjí” Àwọn Ọmọ Ìyá Mi “Kó”
Kété tí mo di ẹni ara mi, ohun tó kọ́kọ́ ká mi lára jù lọ ni bí mo ṣe máa ran àwọn ọmọ ìyá mi lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Bàbá ò fẹ́ kí n di Ẹlẹ́rìí nítorí ẹ̀tanú tó ní àti nítorí bó ṣe máa ń fura sí èèyàn. Báwo ni kí n ṣe wá ran àwọn àbúrò mi lọ́wọ́ láti mọ nípa òtítọ́ Bíbélì? Mo sọ pé máa gbọ́ bùkátà Ernest, àbúrò mi ọkùnrin, ìyẹn ni Bàbá fi gbà pé kó máa gbé lọ́dọ̀ mi. Kíá ni Ernest tẹ́wọ́ gba òtítọ́, ó sì ṣe ìrìbọmi ni 1956. Ìyípadà rẹ̀ yìí ló wá jẹ́ kí bàbá mi túbọ̀ gbé àtakò dìde. Síbẹ̀síbẹ̀, àbúrò mi obìnrin tó ti lọ́kọ tún wà sínú òtítọ́ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. Nígbà tí mo sọ pé kí àbúrò mi obìnrin kejì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Felicia wá lo họlidé lọ́dọ̀ mi, tìlọ́ratìlọ́ra ni Bàbá fi gbà. Láìpẹ́, Felicia náà ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ọdún 1959 ni mo lọ sílé láti mú Bernice, àbúrò mi obìnrin kẹta, pé kó wá lọ máa gbé lọ́dọ̀ Ernest. Ìgbà yẹn ni Bàbá gbéjà kò mí, tó ni mo ń jí àwọn ọmọ òun kó. Kò mọ̀ pé àwọn fúnra wọn ló pinnu láti sin Jèhófà. Bàbá búra pé òun ò ní gbà kí Bernice tẹ̀ lé mi láé. Àmọ́ ọwọ́ Jèhófà kò kúrú, ọdún tó tẹ̀ lé e gan-an ni Bernice wá lo họlidé tí wọ́n fún wọn nílé ìwé lọ́dọ̀ Ernest. Òun náà fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà òtítọ́ ó sì ṣèrìbọmi bíi táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin yòókù.
‘Kíkọ́ Àṣírí Náà’
Ní oṣù September 1957, mo bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, tí mò ń fi nǹkan bí àádọ́jọ wákàtí ṣe ìwàásù lóṣooṣù. Èmi àti ẹnì kejì mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sunday Irogbelachi ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ gbígbòòrò tó wà ní Akpu-na-abuo, Etche. Àwọn mẹ́tàlá lára àwọn tó wà ní àwùjọ wa ló ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká tá a kọ́kọ́ lọ ṣe nígbà tá a wà níbẹ̀. Inú wa dùn gan-an láti rí i pé ogún ìjọ ti wà lágbègbè yẹn báyìí!
Ọdún 1958 ni mo wá mọ Christiana Azuike, tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé nínú Ìjọ East ni Aba. Ìtara tó ní wú mi lórí gan-an, a sì ṣègbéyàwó ní December ọdún yẹn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1959, wọ́n yàn mi pe kí n wá sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, ìyẹn ni pé kí n máa bẹ ìjọ àwọn arákùnrin wa nípa tẹ̀mí wò kí n sì máa fún wọn níṣìírí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà tó wà ní ìlà oòrùn àti àárín ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ni èmi àti ìyàwó mi bẹ̀ wò láti àkókò yẹn títí di ọdún 1972.
Àwọn ìjọ jìnnà síra wọn, kẹ̀kẹ́ sì ni ohun ìrìnnà tá a ní nígbà yẹn. Nígbà tá a bá bẹ àwọn ìjọ tó wà láwọn ìlú ńlá wò, ńṣe ni àwọn arákùnrin wa máa ń bá wa háyà takisí tó máa gbé wa lọ sí ìjọ tó kàn. Àwọn ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé àwọn yàrá tí wọn ò rẹ́ ilẹ̀ rẹ̀ tí ò sì ní àjà la máa ń dé sí. Àwọn ibùsùn tí wọ́n fi ọpa igi ògùrọ̀ ṣe la máa ń sùn sí. Díẹ̀ lára àwọn ibùsùn náà ní mátírẹ́ẹ̀sì oníkoríko tí wọ́n fi ẹní bò; àwọn mìíràn ò tiẹ̀ ní mátírẹ́ẹ̀sì lórí rárá. Bí oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa ṣe rí àti bó ṣe pọ̀ tó kì í ṣe ìṣòro fún wa rárá. Níwọ̀n bí a ti kẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ kí àwọn ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá gbé fún wa la máa ń gbádùn, inú àwọn tó gbà wá sílé sì máa ń dùn sí èyí gan-an ni. Àwọn ìlú ńlá bíi mélòó kan kò ní iná mànàmáná láyé ọjọ́un, ìdí nìyẹn tá a fi máa ń gbé àtùpà elépo òyìnbó lọ síbi tá a bá ń lọ. Àmọ́ láìfi gbogbo ipò líle koko yẹn pè, a gbádùn àwọn ìjọ wọ̀nyẹn gan-an ni.
Àárín àwọn ọdún wọ̀nyẹn la wá mọyì ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnni pé: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:8) Nítorí ìpọ́njú, Pọ́ọ̀lù kọ́ àṣírí tó ràn án lọ́wọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn. Kí ni àṣírí náà? Ó ṣàlàyé pé: “Ní tòótọ́, mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín, ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.” Àwa náà kọ́ àṣírí yìí. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye [Ọlọ́run] tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:12, 13) Ìyẹn sì rí bẹ́ẹ̀ gan-an nínú ọ̀ràn ti wa! Ọlọ́run fi ìtẹ́lọ́rùn jíǹkí wa, a kó ipa tó pọ̀ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni tó ń gbéni ró, a sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
Ìdílé Wa Lódindi Bẹ Àwọn Ìjọ Wò
Ní òpin ọdún 1959, a bí Joel, ọmọkùnrin wa àkọ́kọ́, Samuel, ọmọkùnrin wa kejì sì tẹ̀ lé e ní 1962. Èmi àti Christiana ń bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò wa nìṣó, àwa àtàwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì sì jọ ń bẹ àwọn ìjọ wò. Ní ọdún 1967, ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ ní Nàìjíríà. Wọ́n ti gbogbo ilé ìwé pa nítorí ohun ọṣẹ́ táwọn èèyàn ń rọ̀jò rẹ̀ láti òfuurufú láìdáwọ́dúró. Olùkọ́ ni ìyàwó mi kó tó di pé ó wá dara pọ̀ mọ́ mi nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, nítorí náà ó kọ́ àwọn ọmọ nílé lákòókò tí ogun ń lọ lọ́wọ́. Nígbà tí Samuel fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́fà, ó ti mọ̀wé kà, ó sì ti mọ̀ ọ́n kọ. Nígbà tó wọ ilé ìwé lẹ́yìn ogun, kíláàsì méjì tán-n-tán ló fi ṣáájú àwọn ojúgbà rẹ̀.
Nígbà yẹn tá a wà nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò, a ò fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ìṣòro tó wà nínú ọmọ títọ́. Àmọ́, yíyàn tí wọ́n yàn wá sí iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ọdún 1972 ṣàǹfààní fún wa gan-an ni. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà lójú kan tá a fi ráyè bójú tó ipò tẹ̀mí ìdílé wa lọ́nà tó dára. Àtikékeré la ti kọ́ àwọn ọmọ wa ní ìjẹ́pàtàkì níní ìtẹ́lọ́rùn tí Ọlọ́run ń fúnni. Samuel wá ṣe ìrìbọmi ní ọdún 1973, Joel náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ní ọdún yẹn kan náà. Àwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì ló fẹ́ àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni rere, àwọn náà sì ti ń tọ́ ìdílé tiwọn nínú òtítọ́ báyìí.
Wàhálà Ogun Abẹ́lé
Ìjọ kan ní Onitsha ni èmi àti ìdílé mi ń bẹ̀ wò lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká nígbà tí ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀. Ogun yẹn jẹ́ ká túbọ̀ rí ìmúlẹ̀mófo tó wà nínú kéèyàn máa kó àwọn nǹkan ti ara jọ tàbí kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé wọn. Mo rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń sá nítorí ẹ̀mí wọn, tí wọ́n si ń fi àwọn ohun ṣíṣeyebíye tí wọ́n ní sílẹ̀ lójú pópó.
Bí ogun náà ṣe ń le sí i ni wọ́n ń fa gbogbo àwọn abarapá ọkùnrin sínú iṣẹ́ ogun. Ọ̀pọ̀ arákùnrin tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun ni wọ́n dá lóró. A ò lè rìn káàkiri bá a ṣe fẹ́. Àìtó oúnjẹ jẹ àwọn èèyàn níyà gan-an. Iye tí wọ́n ń ta pákí tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ kékeré lọ sókè látorí sísì dé orí pọ́n-ùn márùn-ún, agolo iyọ̀ náà kúrò látorí pọ́n-ùn mẹ́ta sí pọ́n-un mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Mílíìkì, bọ́tà, àti ṣúgà ò tiẹ̀ sí mọ́ rárá. Ọgbọ́n tá a dá ni pé a ń lọ ìbẹ́pẹ tí kò tíì pọ́n mọ́ láfún díẹ̀. A tún jẹ àwọn kòkòrò tata, èèpo pákí, èwé òdòdó hibiscus, koríko eèsún—ká ṣáà sọ pé gbogbo ewé tá a bá rí là ń jẹ. Ẹran ò ṣe é rà, mo ní láti máa pa aláǹgbá fáwọn ọmọ jẹ. Síbẹ̀síbẹ̀, bó ti wù kí nǹkan le tó, Jèhófà máa ń pèsè fún wa ṣáá ni.
Èyí tó burú jù lọ ni ewu àìrí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ tí ogun náà fà. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ló fi àgbègbè tí ogun ti le sílẹ̀, wọ́n sá lọ sínú aginjù tàbí sáwọn abúlé mìíràn, èyí sì mú kí wọ́n pàdánù ọ̀pọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì. Òfin táwọn ọmọ ogun ìjọba fi de kíkó ẹrù wọlé kò jẹ́ kí àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wà ní àgbègbè tó jẹ́ ti Biafra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìjọ gbìyànjú láti máa ṣèpàdé, síbẹ̀ ọ̀ràn náà nípa lórí ipò tẹ̀mí àwọn ará gan-an nítorí pé àwọn ìtọ́ni tó ń wá láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ kò lè dé ọ̀dọ̀ wọn.
Gbígbógunti Ìyàn Tẹ̀mí
Àwa alábòójútó arìnrìn-àjò sa gbogbo ipá wa láti máa bẹ àwọn ìjọ kọ̀ọ̀kan wò. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn ará ti fi ìlú sílẹ̀, mo ní láti máa wá wọn káàkiri gbogbo ibi tá a bá ti lè rí wọn. Ìgbà kan wà tí mo fi ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi sílẹ̀ sí ibi kan tó láàbò tí mo si rin ìrìn àjò fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà gbáko, tí mò ń bẹ onírúurú abúlé wò tí mò tiẹ̀ tún ń wá àwọn ará lọ sínú aginjù pàápàá.
Nígbà tí mò ń bẹ ìjọ kan wo lọ́wọ́ ní Ogbunka, mo gbọ́ pé àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan wà ní ibi kan ní Isuochi tó wà ní àgbègbè Okigwe. Mo wá ní kí ẹnì kan bá mi sọ fún àwọn arákùnrin tó wà ní àgbègbè yẹn pé kí wọ́n kóra jọ sí oko ọ̀gbìn ńlá kan tí wọ́n gbin kajú sí ní abúlé Umuaku. Èmi àti arákùnrin àgbàlagbà kan gun kẹ̀kẹ́ wa fún nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ sí oko ọ̀gbìn ńlá náà, níbi táwọn Ẹlẹ́rìí bí igba kóra jọ sí, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ràn mí lọ́wọ́ láti rí àwùjọ Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún, tí wọ́n wá ibi ìsádi lọ sínú igbó Lomara.
Arákùnrin Lawrence Ugwuegbu jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ àwọn arákùnrin onígboyà tó ń gbé ní ìlú Owerri tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sọ fún mi pé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí wà ní àgbègbè Ohaji. Wọn ò lè rìn káàkiri bí wọ́n ṣe fẹ́ nítorí pé àwọn sójà gba gbogbo àgbègbè náà kan. Bí àwa méjèèjì ṣe gun kẹ̀kẹ́ lọ síbẹ̀ lóru nìyẹn, a sì bá nǹkan bí ọgọ́fà Ẹlẹ́rìí ní àgbàlá arákùnrin kan. A tún fi àǹfààní yẹn bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn wò níbi tí wọ́n sá pa mọ́ sí.
Arákùnrin Isaac Nwagwu fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu kó sáà lè bá mi rí àwọn arákùnrin mìíràn tí wọ́n ti fi ilé wọn sílẹ̀. Ó fi ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ wà mi kọjá Odò Otamiri kí n lè dé ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní àádọ́jọ tí wọ́n kóra jọ sí Egbu-Etche. Arákùnrin kan níbẹ̀ fi ìdùnnú sọ pé: “Òní lọjọ́ tó dára jù lọ nínú ìgbésí ayé mi! Mi ò mọ̀ pé màá tún fojú rí alábòójútó àyíká mọ́. Bi ogun gbígbóná janjan yìí bá tiẹ̀ wá pa mí báyìí, ó tẹ́ mi lọ́rùn.”
Mo bọ́ sọ́wọ́ àwọn sójà tó fẹ́ fà mí sínú iṣẹ́ ológun, àmọ́ gbogbo ìgbà ni mò ń rí i pé Jèhófà ń dáàbò bò mí. Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, bí mò ṣe ń padà sí ilé tí wọ́n fi mí sí lẹ́yìn tí mo bá àwọn ará bí igbá ó lé àádọ́ta ṣèpàdé tán ni ẹgbẹ́ ológun kan dá mi dúró níbi tí wọ́n ti ń yẹ àwọn èèyàn wò. Wọ́n béèrè pé: “Kí ló dé tó o tíì wọṣẹ́ ológun?” Mo sọ fún wọn pé míṣọ́nnárì ni mi tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Mo rí i pé wọn fẹ́ fàṣẹ ọba mú mi. Lẹ́yìn tí mo sáré gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́, mo sọ fún ọ̀gá wọn pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n máa lọ.” Ẹnu yà mí nígbà tó fèsì pé, “Ṣé o sọ pé ká jẹ́ kó o máa lọ ni?” Mo dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí n máa lọ.” Ó ní, “A ti fi ọ́ sílẹ̀, máa lọ.” Kò sí ẹni tó tún sọ ohunkóhun mọ́ nínú àwọn sójà tó kù.—Sáàmù 65:1, 2.
Ìtẹ́lọ́rùn Mú Àwọn Ìbùkún Mìíràn Wá
Mo ṣì ń bá iṣẹ́ àyíká tí mò ń ṣe nìṣó lẹ́yìn tí ogun parí lọ́dún 1970. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi láti ṣèrànwọ́ nínú títún àwọn ìjọ ṣètò. Ẹ̀yìn ìyẹn ni èmi àti Christiana wá sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe títí di ọdún 1976, nígbà tí wọ́n tún padà yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Ìgbà tí ọdún yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ìdajì ni wọ́n yàn mí sí iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè. Ọdún méje lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n pe èmi àti ìyàwó mi pé ká wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Nàìjíríà, níbi tá a ń gbé báyìí. Ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ tá a wà yìí, nǹkan ayọ̀ ńlá ló máa ń jẹ́ fún wa láti padà rí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a ti bá pàdé lákòókò ogun abẹ́lé àti láwọn àkókò mìíràn tí wọ́n ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Christiana ti jẹ́ alátìlẹyìn gidi àti alábàákẹ́gbẹ́ tó dúró tì mí gbágbáágbá. Ẹ̀mí nǹkan yòó dára tó ní àti bí kì í ṣe ráhùn láìfi àìsàn tó ti ń fara dà láti ọdún 1978 pè, ló ràn mí lọ́wọ́ tí mo ṣì fi ń báṣẹ́ lọ di òní olónìí. A ti rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi.”—Sáàmù 41:3.
Bí mo ṣe ń bojú wẹ̀yìn wo àwọn ọdún tí mo ti fi kópa nínú ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run yìí, kò sí bí mi ò ṣe ní dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí àwọn àgbàyanu ìbùkún rẹ̀. Pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn tí mo ní nínú àwọn ohun tó pèsè, mo lè fi tọkàntọkàn sọ pé mo ti rí ayọ̀ ńlá. Ayọ̀ rírí tí mò ń rí àwọn ọmọ ìyá mi, àwọn ọmọ mi, àtàwọn ìdílé wọn tí gbogbo wọn ń sin Jèhófà pẹ̀lú èmi àti ìyàwó mi jẹ́ ìbùkún tí kò láfiwé. Jèhófà ti fi ìgbésí ayé tó dùn tó sì nítumọ̀ jíǹkí mi. Kò sí ohun tí mo fẹ́ tí kò ṣe fún mi.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ é jáde. A ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́ báyìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Ìṣètò Tó Bọ́ Sákòókò Gbé Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Ró
Ní àárín àwọn ọdún 1960, kèéta tó wà láàárín àwọn ẹ̀yà tó wà ní àríwá àtàwọn ẹ̀yà tó wà ní ìlà oòrùn Nàìjíríà fa rògbòdìyàn, ọ̀tẹ̀, ìwà ta-ni-yóò-mú-mi, àti ìwà ipá kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Èyí fa ìṣòro ńlá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti pinnu láti wà ní àìdásí-tọ̀tún-tòsì nínú ìforígbárí náà. Wọ́n pa àwọn bí ogún lára wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ sí pàdánù gbogbo ohun ìní wọn.
Ní May 30, 1967, àwọn tó wà ní ìhà ìlà oòrùn Nàìjíríà ya ara wọn kúrò lára orílẹ̀-èdè náà, wọ́n sì dá Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Biafra sílẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti ìjọba múra ogun, wọn ò sì jẹ́ kí ohunkóhun kọjá sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní Ìlà Oòrùn yìí. Bí ogun abẹ́lé tí wọn ti ta ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní apá ibi tó jẹ́ ti àwọn Biafra ló mú kí wọ́n di ẹni tí wọ́n dájú sọ láti fìyà jẹ. Àwọn ìwé ìròyìn ń sọ ohun tí kò dára nípa wọn, wọn ń jẹ́ kí inú àwọn èèyàn túbọ̀ máa ru gùdù sí wọn. Síbẹ̀, Jèhófà rí i dájú pé àwọn ìránṣẹ́ òun rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà. Lọ́nà wo?
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1968, wọ́n yan òṣìṣẹ́ ìjọba kan sí ọ́fíìsì kan ní Yúróòpù, wọ́n sì yan ọkàn sí ibi tí àwọn Biafra ti ń gba ẹrú tó ń bọ látòkèèrè. Ẹlẹ́rìí làwọn méjèèjì. Iṣẹ́ wọn yìí mú kí wọ́n wà ní ìhà méjèèjì tí àwọn tó wà ní àgbègbè Biafra fi lè mọ ohun tó ń lọ láwọn ibòmíràn. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjèèjì yìí yọ̀ǹda ara wọn láti máa kó oúnjẹ tẹ̀mí wọ Biafra, ìyẹn sì jẹ́ iṣẹ́ tó lè fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Wọ́n tún ṣèrànwọ́ láti kó àwọn ẹrù táwọn èèyàn fi ṣèrànwọ́ wá fún àwọn arákùnrin wa tí nǹkan ò rọgbọ fún. Àwọn arákùnrin méjèèjì náà rí i pé ìṣètò pàtàkì yìí ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àkókò ogun yẹn, èyí tó wá parí ní ọdún 1970. Ọ̀kan nínú wọn wá sọ níkẹyìn pé: “Ìṣètò yìí kọjá ohun tí ẹ̀dá ènìyàn lásán lè wéwèé rẹ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ní 1956
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwa àtàwọn ọmọ wa, Joel àti Samuel, ní 1965
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Lónìí, èmi àti Christiana ń sìn ní ẹ̀ka ti Nàìjíríà