Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Ṣó Yẹ Kí N Máa Ṣeré Orí Kọ̀ǹpútà?
ERÉ Orí Kọ̀ǹpútà kì í wulẹ̀ ṣe eré tí wọ́n fọgbọ́n ìjìnlẹ̀ gbé kalẹ̀ lásán. Eré tó gba kéèyàn lọ́pọlọ ni, kì í sì í súni bọ̀rọ̀. Kò wá mọ síbẹ̀ yẹn ṣá o. Eré orí kọ̀ǹpútà máa ń jẹ́ kéèyàn já fáfá, ìwádìí sì fi hàn pé ó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ béèyàn ṣe lè wo nǹkan láwòfín. Àwọn kan tiẹ̀ wà lára àwọn eré náà tó máa ń jẹ́ kéèyàn túbọ̀ mọ ìṣirò, kó sì mọ̀wé kà dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, èyí tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lára àwọn eré náà làwọn ọmọléèwé máa ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bó o bá sì ti ṣe èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lára eré náà, a jẹ́ pé ìwọ náà á lẹ́nu ọ̀rọ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ́ ẹ.
Ọwọ́ àwọn òbí ẹ ló kù sí bóyá wọ́n á jẹ́ kó o máa ṣeré orí kọ̀ǹpútà tàbí wọn ò ní jẹ́ kó o máa lọ́wọ́ sí i. (Kólósè 3:20) Bí wọ́n bá yọ̀ǹda fún ẹ, ó yẹ kó o lè rí èyí tó gbádùn mọ́ ẹ, tí kò sì la ìṣekúṣe lọ lára eré náà. Àmọ́, kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣọ́ra gidigidi?
Ewu Wà Ńbẹ̀!
Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó ń jẹ́ Brian sọ pé: “Eré orí kọ̀ǹpútà máa ń dùn gan-an, ó sì máa ń wà pa.” Síbẹ̀, ìwọ náà á ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé kì í ṣe gbogbo eré téèyàn fi ń dára yá ló dáa. Brian náà gbà pé, “Àwọn nǹkan kan wà téèyàn máa ń ṣe nínú eré náà tó jẹ́ pé èèyàn ò jẹ́ dán wò lójú ayé kéèyàn sì mú un jẹ láìkó sí ìṣòro.” Irú ìwà wo gan-an làwọn eré yìí fi ń kọ́ni?
Àwọn eré kan wà tó jẹ́ pé ìṣekúṣe, ìsọkúsọ àti ìwà ipá tí Bíbélì sọ pé kò dáa ni wọ́n máa ń gbé lárugẹ ṣáá. (Sáàmù 11:5; Gálátíà 5:19-21; Kólósè 3:8) Àwọn eré kan tiẹ̀ wà tí wọ́n ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Adrian. Ó ṣàpèjúwe eré orí kọ̀ǹpútà kan tó gbajúmọ̀ pé “àwọn ọmọọ̀ta tó ń bára wọn fa kùrákù kún ibẹ̀, wọ́n ń mu oògùn olóró, wọ́n ń bára wọn lò pọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rírùn, wọ́n ń hùwà ipá, wọ́n ń gún àwọn èèyàn yánnayànna, ẹ̀jẹ̀ sì ń ṣàn.” Bí wọ́n bá sì ti ń gbé eré tuntun jáde, ńṣe ló máa dà bíi pé ti tẹ́lẹ̀ ò tiẹ̀ burú rárá. James, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún tiẹ̀ sọ pé èèyàn lè máa báwọn ẹlòmíì ṣe èyí tó wọ́pọ̀ jù lọ lára eré yìí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìyẹn gan-an là bá sì máa sọ pé ó sọ eré ọ̀hún di àrà mérìíyìírí. James sọ pé: “Látorí kọ̀ǹpútà tó wà nínú ilé ẹ, o lè máa báwọn tó ń gbé lápá ibòmíì lórí ilẹ̀ ayé díje.”
Káwọn tó ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà máa lo kọ̀ǹpútà láti darí àwọn òṣèré àtọwọ́dá ti wá gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ́ta báyìí. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé, àwọn òṣèré tó jẹ́ èèyàn gidi á yan àwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n á máa fi kọ̀ǹpútà darí, ó lè dà bí èèyàn, ẹranko, tàbí kó jẹ́ ṣènìyàn-ṣẹranko. Ó ní ibì kan táwọn òṣèré àtọwọ́dá tí wọ́n yàn yìí àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún òṣèré àtọwọ́dá tó jẹ́ tàwọn míì máa ń wà lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ilé ìtajà, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ibùgbé, ilé ijó àti ilé aṣẹ́wó tún máa ń wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Ká ṣáà sọ pé ibẹ̀ dà bí ayé kan lọ́tọ̀. Àwọn tó ń fi kọ̀ǹpútà darí àwọn òṣèré àtọwọ́dá náà lè yára máa kọ̀wé ránṣẹ́ síra wọn bí wọ́n bá ṣe ń fàwọn òṣèré náà pitú lọ́wọ́.
Irú itú wo gan-an ni wọ́n máa ń fàwọn òṣèré àtọwọ́dá yìí pa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Akọ̀ròyìn kan sọ pé: “Àwọn kan tiẹ̀ máa ń ṣe àwọn nǹkan kan nínú eré náà tó jẹ́ pé wọn ò jẹ́ ṣe láé, tàbí kí wọn dábàá àtiṣe lójú ayé.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ìbálòpọ̀ àti iṣẹ́ aṣẹ́wó pọ̀ gan-an nínú eré náà.” Bí wọ́n bá ti tẹ àwọn bọ́tìnnì bíi mélòó kan, àwọn òṣèré àtọwọ́dá náà á bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn lò pọ̀, àwọn èèyàn tó ń fi kọ̀ǹpútà darí wọn á sì máa fi lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì bára wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Ìwé ìròyìn New Scientist tún sọ pé, “ìwà ọ̀daràn, àwọn oníjàgídíjàgan, àwọn tó ń báwọn aṣẹ́wó wá oníbàárà, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, àwọn gbájúẹ̀, àtàwọn apààyàn” máa ń pọ̀ gan-an níbẹ̀. Ìwé ìròyìn míì sọ pé “àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọminú nípa káwọn èèyàn máa hùwà tí kò bófin mu lórúkọ eré. Bíi kí wọ́n máa gbé àwọn èèyàn tí ń fipá báni lò pọ̀ nílé aṣẹ́wó sáfẹ́fẹ́, tàbí kí wọ́n máa fi ìṣekúṣe ṣayọ̀ nípa lílo àwọn òṣèré àtọwọ́dá tó jẹ́ ọmọdé.”
Rò Ó Kó O Tó Ṣe É
Àwọn tó ń fàwọn òṣèré àtọwọ́dá hùwà ipá tàbí tí wọ́n ń fi wọ́n ṣèṣekúṣe lórí kọ̀ǹpútà lè sọ pé: “Kò sóhun tó fi ń ṣèèyàn. Kì í kúkú ṣòótọ́. Eré lásán ṣáà ni.” Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni firú èrò èké bẹ́ẹ̀ tàn ẹ́ jẹ o!
Bíbélì sọ pé: ‘Ìṣe ọmọdé pàápàá ni a fi í mọ̀ ọ́n, bí ìwà rẹ̀ ṣe rere àti títọ́.’ (Òwe 20:11, Bibeli Mimọ) Bó o bá sọ ọ́ dàṣà láti máa fi kọ̀ǹpútà hùwà ipá, tó o sì tún fi ń ṣèṣekúṣe, ǹjẹ́ a lè sọ pé o ní ọkàn rere àti ọkàn títọ́? Ìwádìí fi hàn léraléra pé wíwò táwọn kan ń wo eré ìnàjú tí wọ́n ti ń hùwà ipá, túbọ̀ ń mú kí wọ́n di oníjàgídíjàgan. Ìwé ìròyìn New Scientist tiẹ̀ sọ láìpẹ́ yìí pé: “Nítorí pé àjọṣe ni eré orí kọ̀ǹpútà, ó máa ń nípa tó pọ̀ lórí àwọn tó ń ṣe eré náà ju wíwo tẹlifíṣọ̀n lọ.”
Ńṣe ni yíyàn láti máa fi kọ̀ǹpútà hùwà ipá tàbí láti máa fi ṣèṣekúṣe dà bí ìgbà téèyàn bá ń fi ohun olóró ṣeré. Èèyàn lè má tètè rí i pó ń ṣèpalára o, àmọ́ ó máa pàpà lẹ́yìn. Lọ́nà wo? Béèyàn bá ń fimú kó òórùn ohun olóró lemọ́lemọ́ ó lè ba àgọ́ ara jẹ́ kó sì jẹ́ káwọn kòkòrò àrùn tó wà nínú ìfun rọ́ lọ sínú ẹ̀jẹ̀ tó ń yíká ara, bí àìsàn á ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ béèyàn bá ń wo ìṣekúṣe àti ìwà ipá, wọ́n lè ba “agbára òye” rẹ jẹ́, kí wọ́n wá jẹ́ kó o máa ro èròkerò kó o sì máa ṣèṣekúṣe.—Éfésù 4:19; Gálátíà 6:7, 8.
Irú Eré Wo Ló Yẹ Kí N Máa Ṣe?
Báwọn òbí rẹ bá gbà fún ẹ pé kó o máa ṣeré orí kọ̀ǹpútà, báwo lo ṣe lè mọ èyí tó yẹ kó o yàn àti bó ṣe yẹ kó o máa pẹ́ tó nídìí ẹ̀? Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:
◼ Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí eré tí mo bá yàn? Eré tó o bá yàn ló máa sọ irú ojú tí Ọlọ́run á fi máa wò ẹ́. Sáàmù 11:5 sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Ní tàwọn tó ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Bá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ tẹ́tí sí ìmọ̀ràn inú Sáàmù 97:10 tó sọ pé: “Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú.”
◼ Kí ni eré tí mo bá yàn máa gbìn sí mi lọ́kàn? Bi ara ẹ pé, ‘Bí mo bá ń ṣeré yìí, ṣó máa jẹ́ kó rọrùn fún mi láti “sá fún àgbèrè” ni àbí ó máa mú kó ṣòro? (1 Kọ́ríńtì 6:18) Eré tó bá ń jẹ́ kó o rí àwòrán tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí tó ń jẹ́ kó o gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ò ní jẹ́ kó o lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́ níwà, tí kò sì lábààwọ́n. (Fílípì 4:8) Amy, ọmọ ọdún méjìlélógún, sọ pé: “Ńṣe lọ̀pọ̀ lára àwọn eré wọ̀nyí máa ń sọni di ògbólógbòó nínú àwọn nǹkan bí ìwà ipá, ọ̀rọ̀ rírùn àti ìṣekúṣe, ó sì lè jẹ́ kéèyàn tètè kó sínú ìdẹwò báwọn ọ̀ràn míì bá dojú kọni. Torí náà, o gbọ́dọ̀ fìṣọ́ra yan irú eré tó o bá fẹ́ máa ṣe.”
◼ Báwo ló ṣe yẹ kí n máa pẹ́ tó nídìí eré náà? Deborah, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún, sọ pé: “Mi ò rò pé gbogbo eré orí kọ̀ǹpútà ló burú. Àmọ́, wọ́n máa ń gba àkókò, kì í sì í sábà rọrùn láti jáwọ́ nínú wọn.” Eré orí kọ̀ǹpútà tó dà bíi pé kò tiẹ̀ léwu rárá pàápàá máa ń gba àkókò tó pọ̀ gan-an. Nítorí náà, máa kọ àkókò tó o fi ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà sílẹ̀, lẹ́yìn náà, kó o wá fi wéra pẹ̀lú àkókò tó ò ń lò nídìí àwọn ìgbòkègbodò míì tó ṣe pàtàkì jù ú lọ. Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní máa fi ohun tó yẹ sílẹ̀ kó o wá máa mú nǹkan míì ṣe.—Éfésù 5:15, 16.
Bíbélì ò sọ pé kó o fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ kàwé tàbí kó o fi ṣiṣẹ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rán gbogbo wa létí pé “ìgbà rírẹ́rìn-ín . . . àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. (Oníwàásù 3:4) Ó dára ká kíyè sí i pé gbólóhùn náà, “títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ eré ṣíṣe lásán, àmọ́ irú eré tó gba kéèyàn lo ara ẹ̀ ni. Nítorí náà, o ò ṣe lo díẹ̀ lára àkókò tọ́wọ́ ẹ bá dilẹ̀ láti ṣe eré tó gba pé kó o lo ara ẹ dípò tí wàá fi jókòó gẹlẹtẹ síwájú kọ̀ǹpútà?
Fọgbọ́n Yan Irú Eré Tó O Bá Fẹ́
Kò sí iyè méjì pé ṣíṣeré orí kọ̀ǹpútà máa ń dùn mọ́ọ̀yàn, àgàgà téèyàn bá mọwọ́ ẹ̀ gan-an. Nítorí èyí gan-an ló fi yẹ kó o fọgbọ́n yan irú eré tó o bá fẹ́ máa ṣe dáadáa. Bi ara ẹ pé, ‘Iṣẹ́ wo ni mo máa ń ṣe dáadáa jù lọ nínú ẹ̀ nílé ìwé?’ Ìwọ náà mọ̀ pé iṣẹ́ tó o fẹ́ràn jù lọ ni, àbí? Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, béèyàn bá ṣe fẹ́ràn iṣẹ́ kan tó, ló ṣe máa nípa lórí èèyàn tó. Wá bi ara ẹ báyìí pé: ‘Eré orí kọ̀ǹpútà wo ni mo kúndùn àtimáa ṣe jù lọ? Ẹ̀kọ́ wo gan-an leré náà sì fi ń kọ́ mi?’
Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o kọ àkọsílẹ̀ ṣókí nípa eré kọ̀ọ̀kan tó o bá fẹ́ láti ṣe pẹ̀lú àlàyé tó sọ ohun tí eré náà dá lé àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe é. Lẹ́yìn náà, fi àwọn ìlànà Bíbélì tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí wé àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀, kó o wá fìyẹn pinnu bóyá ó yẹ kó o máa ṣe irú eré bẹ́ẹ̀.
Dípò kó o máa ṣe eré kan torí pé àwọn ẹgbẹ́ ẹ ń ṣerú ẹ̀, fìgboyà dá ìpinnu tìẹ ṣe. Èyí tó ṣe pàtàkì ju gbogbo ẹ̀ lọ ni pé kó o fi ìmọ̀ràn Bíbélì náà sílò pé: “Máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—Éfésù 5:10.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí ni wàá sọ bí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ní kẹ́ ẹ jọ ṣeré orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n fi ń hùwà ipá tàbí tí wọ́n fi ń ṣèṣekúṣe?
◼ Báwo lo ṣe lè rí i dájú pé ṣíṣeré orí kọ̀ǹpútà kò gba àkókò tó yẹ kó o máa lò fáwọn ìgbòkègbodò míì tó ṣe pàtàkì mọ́ ẹ lọ́wọ́?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
Yíyàn láti máa fi kọ̀ǹpútà hùwà ipá tàbí láti máa fi ṣèṣekúṣe dà bí ìgbà téèyàn bá ń fi pàǹtírí ohun olóró ṣeré. Èèyàn lè má tètè rí i pó ń ṣèpalára, àmọ́ ó máa pàpà lẹ́yìn
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Báwo lo ṣe ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà lemọ́lemọ́ tó?
□ Ń kì í sábàá ṣe é
□ Ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀
□ Ojoojúmọ́
Bó o bá ń ṣeré orí kọ̀ǹpútà, báwo lo ṣe máa ń pẹ́ tó nídìí ẹ̀?
□ Ìṣẹ́jú díẹ̀
□ Wákàtí kan tàbí kó dín díẹ̀
□ Ó máa ń lé ní wákàtí méjì
Irú eré wo ló máa ń wù ẹ́ jù lọ láti ṣe?
□ Fífi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ sáré
□ Eré ìdárayá
□ Kí n máa yìnbọn
□ Àwọn míì
Bí eré orí kọ̀ǹpútà kan bá wà tí o kò ní fẹ́ láti ṣe torí pé kò dára, kọ orúkọ ẹ̀ síbí.
․․․․․
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ
Ìwọ náà ti lè rí i lẹ́yìn tó o ti ka àpilẹ̀kọ wa tó dá lórí eré orí kọ̀ǹpútà pé ọ̀pọ̀ ìyípadà ló ti bá eré náà látìgbà tó o ti wà lọ́dọ̀ọ́. Gẹ́gẹ́ bí òbí, báwo lo ṣe lè ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ewu tó wà nínú eré orí kọ̀ǹpútà kó sì máa sá fún wọn?
Bá a bá ní ká máa bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó ṣí ṣọ́ọ̀bù ilé eré kọ̀ǹpútà tàbí ká kàn máa tàbùkù eré náà pé àìríkan-ṣèkan ni, bí ẹni ń yín àgbàdo sẹ́yìn igbá lásán ni o. Má ṣe gbàgbé pé kì í ṣe gbogbo eré orí kọ̀ǹpútà ló burú. Ó kàn jẹ́ pé wọ́n máa ń wọni lára, wọ́n sì máa ń gbani lákòókò. Nítorí náà, wá àyè láti fi mọ bí àkókò tọ́mọ ẹ ń lò nídìí eré náà ṣe pọ̀ tó. Kó o sì tún mọ irú eré orí kọ̀ǹpútà tó dà bíi pé ó máa ń fẹ́ láti ṣe. O tiẹ̀ lè bi í láwọn ìbéèrè bíi:
◼ Eré wo làwọn ọmọ kíláàsì rẹ fẹ́ràn jù lọ láti máa ṣe?
◼ Kí ni wọ́n máa ń ṣe nínú eré náà?
◼ Kí lo rò pó fà á tí wọ́n fi fẹ́ràn eré náà?
O lè wá rí i pé ọmọ ẹ mọ púpọ̀ nípa eré orí kọ̀ǹpútà ju bó o ṣe rò lọ! Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kóun náà ti ṣe lára irú àwọn eré orí kọ̀ǹpútà tó o rò pé kò dáa yẹn. Bó bá jóòótọ́ ló ti ṣe é rí, má ṣe bínú sódì. Ńṣe ni kó o kàn rí i bí àǹfààní láti ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó bàa lè kọ́ béèyàn ṣe lè fọgbọ́n yan ohun tó dáa.—Hébérù 5:14.
Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ọmọ ẹ kó o bàa lè mọ̀dí ẹ̀ gan-an táwọn tí kò dáa lára eré orí kọ̀ǹpútà fi máa ń wù ú. Bí àpẹẹrẹ, o lè bí i pé:
◼ Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé a fi ohun kan dù ẹ́ tá ò bá jẹ́ kó o ṣe irú eré táwọn ẹgbẹ́ ẹ ń ṣe?
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mẹ́nu kàn án lójú ìwé àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ wa tó dá lórí eré orí kọ̀ǹpútà, ó lè jẹ́ nítorí àtimáa rí ọ̀rọ̀ sọ láàárín àwọn ẹgbẹ́ wọn làwọn èwe ṣe máa ń ṣe irú àwọn eré kan. Bó bá jẹ́ pé ohun tó ń sún ọmọ ẹ dédìí ẹ̀ nìyẹn, a jẹ́ pé ọwọ́ tó o máa fi mú ọ̀ràn náà ò ní le tó ọwọ́ tó o máa fi mú un bó bá jẹ́ pé ńṣe ló wulẹ̀ fẹ́ láti máa ṣe àwọn eré tí wọ́n ti ń fìwà ipá tàjẹ̀ sílẹ̀ tàbí tí wọ́n ti ń bára wọn ṣèṣekúṣe.—Kólósè 4:6.
Bó bá wá jẹ́ pé ohun tí ò dáa nínú eré orí kọ̀ǹpútà yẹn gan-an ló máa ń wu ọmọ ẹ ńkọ́? Ó lè yá àwọn ọ̀dọ́ kan lára láti sọ pé ẹ̀jẹ̀ tó ń dà yàà nínú eré orí kọ̀ǹpútà ò ṣe àwọn ní nǹkan kan. Wọ́n lè máa rò pé: ‘Ṣíṣe tí mò ń ṣe é lórí kọ̀ǹpútà ò ní kí n máa ṣe é lójú ayé.’ Bó bá jẹ́ pé bó ṣe rí lára ọmọ ẹ nìyẹn, rán an létí ohun tó wà nínú Sáàmù 11:5, tá a fa ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ yọ lójú ìwé 26. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe ṣàlàyé, kò dìgbà téèyàn bá ń hu ìwà ipá kó tó rí ìbínú Ọlọ́run, èèyàn tún lè rí ìbínú Ọlọ́run bó bá fẹ́ràn ìwà ipá. Ìlànà kan náà ló kan ìṣekúṣe tàbí ìwà búburú èyíkéyìí mìíràn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kò dáa.—Sáàmù 97:10.
Àbá táwọn ògbógi kan dá nìwọ̀nyí:
◼ Má ṣe gba eré orí kọ̀ǹpútà èyíkéyìí láyè níbi tójú gbogbo èèyàn ò ti lè tó o, bíi nínú iyàrá.
◼ Jẹ́ kí ìlànà wà láti tẹ̀ lé tó bá dọ̀ràn eré orí kọ̀ǹpútà (bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn iṣẹ́ àṣetiléwá, lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, tàbí lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ ilé pàtàkì mìíràn lẹni kẹ́ni tó lè ṣeré orí kọ̀ǹpútà).
◼ Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti wá àwọn nǹkan míì tó gba kéèyàn fara ṣiṣẹ́.
◼ Má máa fàwọn ọmọ ẹ nìkan sílẹ̀ nídìí eré orí kọ̀ǹpútà, o tiẹ̀ lè máa bá wọn ṣeré náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Àmọ́ ṣá o, kó o bàa lè máa dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ lórí ọ̀ràn eré ìnàjú, ó yẹ kẹ́nu tìẹ náà gbọ̀rọ̀. Nítorí náà, bí ara ẹ pé, ‘Irú eré orí tẹlifíṣọ̀n wo tàbí irú fíìmù wo ni mo máa ń wò?’ Bó bá jẹ́ pé àtèyí tó dáa àtèyí tí ò dáa nìwọ náà máa ń wò, jẹ́ kó yé ẹ pé àwọn ọmọ ẹ ń rí ẹ o!