Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Ewu Wo Ló Wà Nínú Sìgá Mímu Tó Yẹ Kí N Mọ̀?
Wo àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o sì fi àmì yìí ✔ sínú àpótí tó wà níwájú ohun kọ̀ọ̀kàn tá a ṣàpèjúwe síbẹ̀.
□ Mo fẹ́ mọ bó ṣe máa ń rí
□ Mo fẹ́ fi pa ìrònú rẹ́
□ Mo fẹ́ káwọn èèyàn gba tèmi
□ Mi ò fẹ́ bí mo ṣe sanra jù yìí
TÓ O bá sàmì sí èyíkéyìí lára àwọn àpótí náà, á jẹ́ pé ohun kan wà tó jọra nínú ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn ojúgbà rẹ tó ń mu sìgá tàbí tí wọ́n ti ronú láti mú un.a Bí àpẹẹrẹ, ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ rèé:
Mo fẹ́ mọ bó ṣe máa ń rí. “Mi ò mọ bó ṣe rí, torí náà mo gba sìgá lọ́wọ́ ọmọbìnrin kan níléèwé, mo yọ́ kẹ́lẹ́ jáde mo sì lọ mu ún.”—Tracy.
Mo fẹ́ fi pa ìrònú rẹ́, káwọn èèyàn sì gba tèmi. “Àwọn ọmọ iléèwé máa ń sọ pé, ‘Mo fẹ́ mu sìgá,’ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mú un tán, wọ́n á sọ pé, ‘ọkàn mi ti wá balẹ̀ báyìí!’ Sìgá máa ń wù mí mu nígbà tí nǹkan bá tojú sú mi.”—Nikki.
Mi ò fẹ́ sanra jù. “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan máa ń mu sìgá kí wọ́n má bàa sanra, ó rọrùn ju kéèyàn máa ṣọ́ oúnjẹ jẹ lọ!”—Samantha.
Àmọ́, kó o tó tanná sí sìgá tó o máa kọ́kọ́ mu, tàbí èyí tó kàn tí wàá mu, dúró ná, kó o sì ronú. Má ṣe dà bí ẹja tó ń jẹ ìjẹ̀ tó wà lára ìwọ̀. Òótọ́ ni pé ẹja yẹn lè jàǹfààní díẹ̀, àmọ́ àfàìmọ̀ kí ẹ̀mí rẹ̀ má lọ sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, kó o sì lo “ìrònú [rẹ] ṣíṣe kedere.” (2 Pétérù 3:1) Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Kí Lo Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?
Kọ òótọ́ tàbí irọ́ sí gbólóhùn kọ̀ọ̀kan.
a. ․․․ Téèyàn bá mu sìgá, ó máa ń dín ìdààmú ọkàn kù.
b. ․․․ Tí mo bá mu sìgá, gbogbo èéfín sìgá yẹn ni màá tú jáde.
d. ․․․ Bí mo bá ń mu sìgá, kò lè ṣàkóbá fún ìlera mi báyìí, ó dìgbà tí mo bá dàgbà sí i.
e. ․․․ Sìgá mímu máa jẹ́ kí àwọn ọkùnrin tàbí àwọn obìnrin gba tèmi.
ẹ. ․․․ Bí mo bá mu sìgá, kò pa ẹlòmíì lára, àfèmi nìkan.
f. ․․․ Bóyá mò ń mu sìgá àbí mi ò mu sìgá, ìyẹn kò kan Ọlọ́run.
Ìdáhùn
a. Sìgá mímu máa ń dín ìdààmú ọkàn kù.—Irọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé sìgá mímu máa ń gbani lọ́wọ́ àwọn ìnira téèyàn máa ń kojú tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá, àmọ́ ìtura ọ̀hún kì í pẹ́ lọ títí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí pé ńṣe ni èròjà olóró nicotine tó wà nínú sìgá máa ń dá kún ìdààmú ọkàn.
b. Gbogbo èéfín sìgá yẹn ni màá tú jáde.—Irọ́. Ìwádìí fi hàn pé ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá èéfín sìgá tó o bá mu ló máa ń dúró sínú ara rẹ.
d. Sìgá mímu kò lè ṣàkóbá fún ìlera mi báyìí, ó dìgbà tí mo bá dàgbà sí i.—Irọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bó o ṣe ń mu sìgá kọ̀ọ̀kan ni ewu tó rọ̀ mọ́ ọn ń pọ̀ sí i, síbẹ̀ o ò lè tètè rí àbájáde rẹ̀. Sìgá àkọ́kọ́ tí àwọn kan mu ló ti di bárakú sí wọn lára. Agbára ọ̀nà ọ̀fun rẹ á dín kù, ó sì ṣeé ṣe kó o bẹ̀rẹ̀ sí í wúkọ́ lemọ́lemọ́. Ara rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í hun jọ láìjẹ́ pé o ti darúgbó. Sìgá mímu lè dín agbára ìbálòpọ̀ kù, ó lè mú kí àyà rẹ máa là gààrà, ó sì lè fa ìsoríkọ́.
e. Bí mo bá ń mu sìgá, ó máa jẹ́ kí àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin gba tèmi.—Irọ́. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Lloyd Johnston ṣàwárí pé “ọ̀pọ̀ jù lọ ọkùnrin àti obìnrin ni kì í fi bẹ́ẹ̀ gba ti” àwọn ọ̀dọ́langba tó ń mu sìgá.
ẹ. Bí mo bá mu sìgá, kò pa ẹlòmíì lára, àfèmi nìkan.—Irọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún torí pé wọ́n ń fa èéfín sìgá táwọn míì ń mu sínú; bó o bá ń mu sìgá, ó máa ṣèpalára fáwọn ẹbí rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn ohun ọ̀sìn rẹ pàápàá.
f. Bóyá mò ń mu sìgá àbí mi ò mu sìgá, ìyẹn kò kan Ọlọ́run.—Irọ́. Àwọn tó bá fẹ́ múnú Ọlọrun dùn gbọ́dọ̀ wẹ ara wọn mọ́ kúrò “nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ohun kan tó dájú ni pé sìgá mímu máa ń sọ ara èèyàn di ẹlẹ́gbin. Bó o bá yàn láti jẹ́ ẹlẹ́gbin, tí o sì ń ṣèpalára fún ara rẹ àtàwọn ẹlòmíì nípa mímu sìgá, o kò lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Mátíù 22:39; Gálátíà 5:19-21.
Bó O Ṣe Lè Dènà Sìgá Mímu
Kí lo máa wá ṣe báyìí bí ẹnìkan bá fún ẹ ní sìgá? Ó sábà máa ń dáa gan-an béèyàn bá kàn sọ pé “Rárá, èmi kì í mu sìgá.” Bí onítọ̀hún ò bá fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀ tàbí tó ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́, má ṣe gbàgbé pé ohun tó o pinnu nìyẹn. O lè sọ pé:
● “Nígbà tí mo rí i pé sìgá mímu lè ṣèpalára gan-an fún ara mi, mo pinnu pé mi ò ní mu sìgá.”
● “Mo ṣì ní àwọn nǹkan pàtàkì tí mo fẹ́ gbé ṣe lọ́jọ́ iwájú, bí mi ò bá sì lè mí dáadáa mọ́, mi ò ní lè ṣe àwọn nǹkan ọ̀hún.”
Bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, o lè rí i pé bó ṣe ń wu ìwọ fúnra rẹ láti mu sìgá ni olórí ìṣòro tó o ní. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, o lè borí ìṣòro yìí tó o bá ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi:
● Ṣé ó máa ṣe mí láǹfààní kankan tí mo bá mu sìgá? Bí àpẹẹrẹ, tí mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá torí kí àwọn èèyàn lè gba tèmi, ṣé gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe lèmi náà á lè máa bá wọn lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Ṣé mo tiẹ̀ fẹ́ kí àwọn tí inú wọn máa dùn pé ayé mi bà jẹ́ gba tèmi?
● Èló ni sìgá mímu máa ná mi, ìlera mi ńkọ́, ṣé àwọn ẹlòmíì á sì máa bọ̀wọ̀ fún mi?
● Ṣé máa fi àjọṣe àárín èmi àti Ọlọ́run tàfàlà nítorí sìgá mímu?
Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ó ti di bárakú ńkọ́. Kí lo lè ṣe kó o lè jáwọ́ nínú rẹ̀?
Bó O Ṣe Lè Jáwọ́
1. Jẹ́ kí ohun tó o fẹ́ ṣe dá ẹ lójú. Kọ àwọn ìdí tó o fi fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, kó o sì máa ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà déédéé. Fífẹ́ tó o fẹ́ láti jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run lè túbọ̀ fún ẹ lókun.—Róòmù 12:1; Éfésù 4:17-19.
2. Wá ìrànlọ́wọ́. Tó o bá ti ń mu sìgá ní kọ̀rọ̀, àkókò nìyí fún ẹ láti jẹ́ mímọ́. Sọ fún àwọn tí o kò fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ò ń mu sìgá tẹ́lẹ̀ pé o fẹ́ jáwọ́, kó o sì ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá fẹ́ sin Ọlọ́run, gbàdúrà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́.—1 Jòhánù 5:14.
3. Dá ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́. Dá ọ̀sẹ̀ méjì tàbí kó má tó bẹ́ẹ̀ fún ara rẹ, kó o sì sàmì sí ọjọ́ tó o pinnu láti jáwọ́ sórí kàlẹ́ńdà rẹ. Sọ ọjọ́ tó o fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu fún àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́.
4. Wá àwọn sìgá tó kù sí ẹ lọ́wọ́, kó o sì kó o dà nù. Kó tó di ọjọ́ tó o máa jáwọ́ nínú sìgá mímu, wo inú yàrá rẹ, inú ọkọ̀ rẹ àti inú àpò àwọn aṣọ rẹ bóyá wàá rí sìgá. Kó àwọn sìgá, àwọn ohun tó o fi ń tanná ràn án àti àwo eérú sìgá dà nù.
5. Fara da àìfararọ tó lè wáyé nígbà tó o bá fẹ́ jáwọ́. Máa mu omi èso tàbí omi tó pọ̀ gan-an, kó o sì máa sùn dáadáa. Máa fi sọ́kàn pé àìfararọ tó o máa rí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ àǹfààní rẹ̀ máa wà títí gbére!
6. Yẹra fún nǹkan tó lè mú kí sìgá wù ẹ́ mu. Máa yẹra fún àwọn ibi àti ipò tó o ti lè rí ìdẹwò láti mu sìgá. Ó tún lè gba pé kó o má ṣe máa bá àwọn tó ń mu sìgá rìn.—Òwe 13:20.
7. Má tan ara rẹ jẹ. Má ṣe máa tan ara rẹ̀ nípa sísọ pé, “Mi ò ní fà ju ọwọ́ kan péré lọ.” Tó o bá ń tan ara rẹ jẹ lọ́nà yẹn, ó lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá pa dà.—Jeremáyà 17:9.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Wọ́n Tàn Ẹ́ O!
Lọ́dọọdún, àwọn ilé iṣẹ́ tó ń ṣe sìgá máa ń ná ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún owó dọ́là sórí ìpolówó sìgá. Ṣé wọn ò mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ làwọ́n máa tàn jẹ láti dẹni tó ń mu sìgá ni, tí wọ́n á sì dàgbà di ẹni tí sìgá mímu di bárakú fún?
Má ṣe jẹ́ kí àwọn aṣojú àwọn tó ń ta sìgá gba owó rẹ. Kí ló dé tí wàá fi jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́ jẹ? Àwọn tó ń polówó sìgá àtàwọn ojúgbà rẹ tí wọ́n fẹ́ kó o mu sìgá kò fẹ́ ọ fẹ́re. Dípò tí wàá fi gbọ́ tiwọn, ìmọ̀ràn Bíbélì ni kó o fetí sí, kó o sì kọ́ bí wàá ṣe “ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Aísáyà 48:17.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń mu sìgá la jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ìṣòro àtàwọn ewu tó wà níbẹ̀ kan àwọn tó máa ń jẹ tábà pẹ̀lú.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ
“Bí ẹnì kan bá bi mí pé kí ló dé tí mi ò mu sìgá, ohun tí màá sọ ni pé, ‘Mi ò fẹ́ kí èéfín sọ ẹ̀dọ̀fóró mi di dúdú, kí n sì dá ẹ̀mí ara mi légbodò.’”
“Bí ẹnì kan bá sọ pé kí n gba sìgá, màá sọ pé ‘Mi ò fẹ́.’ Tí wọ́n bá fẹ́ fipá mú mi, màá sọ pé, ‘Ṣé ìwọ lo fẹ́ pinnu ohun tí màá ṣe fún mi ni? Mo mọ̀ pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ á já wọn láyà, torí pé ayé ọ̀làjú la wà yìí!’”
[Àwọn àwòrán]
Benjamin
Heather
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
● ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Tábà, irú èyí tí wọ́n máa ń jẹ lẹnu máa ń ní èròjà olóró nicotine tó pọ̀ ju sìgá lọ, ó sì ní ìdá méjì ààbọ̀ nínú mẹ́wàá èròjà olóró tó máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ, ó tún ń mú kí àwọn tó ń lò ó wà nínú ewu dídi ẹni tó ní àrùn jẹjẹrẹ ọ̀nà ọ̀fun àti ti ẹnu.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?
O lè borí ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe tó o bá ti múra sílẹ̀ dáadáa. O lè sọ fún àwọn òbí rẹ pé kí wọ́n ṣe ìdánrawò pẹ̀lú rẹ, kó o lè mọ ohun tó o máa sọ nígbà tí wọ́n bá ní kó o wá mu sìgá. Ní kí àwọn òbí rẹ ṣe bí ọkàn lára àwọn ojúgbà rẹ tó fẹ́ tì ẹ́ sínú sìgá mímu. Ohun tó o lè ṣe: Lo apá tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” lójú ìwé 132 àti 133 nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá 2. Wàá rí àwọn àbá mélòó kan níbẹ̀ lórí bó o ṣe máa dáhùn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bí ẹja ṣe máa ń jẹ ìjẹ̀, ẹni tó ń mu sìgá máa ń rí èrè àmọ́ ohun tí wọ́n ń fi dí i kì í ṣe kékeré