ÌTÀN 22
Wọ́n Ju Jósẹ́fù Sẹ́wọ̀n
ỌMỌ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] péré ni Jósẹ́fù nígbà tí wọ́n mú un lọ sí Íjíbítì. Wọ́n tà á fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Pọ́tífárì níbẹ̀. Pọ́tífárì máa ń ṣiṣẹ́ fún Fáráò ọba Íjíbítì.
Jósẹ́fù máa ń múra sí iṣẹ́ tó ń ṣe fún Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí Jósẹ́fù dàgbà, Pọ́tífárì ní kó máa bójú tó gbogbo ilé òun. Kí ló wá gbé Jósẹ́fù dé ẹ̀wọ̀n tó wà yìí? Ìyàwó Pọ́tífárì ló fà á.
Jósẹ́fù dàgbà, ó di arẹwà ọkùnrin, ìyàwó Pọ́tífárì sì fẹ́ kó bá òun dà pọ̀. Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù mọ̀ pé ìyẹn ò dára, nítorí náà, kò gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Inú bí ìyàwó Pọ́tífárì gidigidi. Nítorí náà, nígbà tí ọkọ rẹ̀ dé, ó purọ́ mọ́ Jósẹ́fù pé: ‘Ṣó o rí i, Jósẹ́fù ọmọ burúkú yẹn mà fẹ́ bá mi dà pọ̀!’ Pọ́tífárì gba ọ̀rọ̀ ìyàwó rẹ̀ gbọ́, ó sì bínú gidigidi sí Jósẹ́fù. Nítorí náà, ó ní kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n.
Láìpẹ́, ọkùnrin tó ń bójú tó ẹ̀wọ̀n náà rí i pé ẹni dáadáa ni Jósẹ́fù. Nítorí náà, ó fi í ṣe olórí gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù. Nígbà tó ṣe, inú bí Fáráò sí agbọ́tí rẹ̀ àti ẹni tó ń gbọ́ oúnjẹ fún un, ó sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Lóru ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì lá àlá àrà ọ̀tọ̀ kan, ṣùgbọ́n wọn ò mọ ìtumọ̀ àlá tí wọ́n lá. Ní ọjọ́ kejì, Jósẹ́fù wí pé: ‘Ẹ rọ́ àlá yín fún mi.’ Nígbà tí wọ́n sì rọ́ àlá náà fún Jósẹ́fù, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sọ ìtumọ̀ àlá náà fún wọn.
Jósẹ́fù sọ fún agbọ́tí pé: ‘Ní ọjọ́ mẹ́ta sí i, wọn yóò tú ọ sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n, ìwọ yóò sì tún di agbọ́tí Fáráò padà.’ Jósẹ́fù wá fi kún un pé: ‘Nígbà tó o bá jáde, sọ nípa mi fún Fáráò, kó o sì ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jáde kúrò ní ibí yìí.’ Ṣùgbọ́n Jósẹ́fù sọ fún ẹni tó ń gbọ́ oúnjẹ fún ọba pé: ‘Ní ọjọ́ mẹ́ta sí i Fáráò yóò pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ ọ lórí.’
Ní ọjọ́ kẹta, gbogbo nǹkan rí bí Jósẹ́fù ṣe sọ gẹ́lẹ́. Fáráò pàṣẹ pé kí wọ́n bẹ́ ẹni tó ń gbọ́ oúnjẹ fún un lórí. Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ kí agbọ́tí jáde kúrò lẹ́wọ̀n kó sì padà sí ẹnu iṣẹ́ rẹ̀ láti máa sin ọba. Ṣùgbọ́n agbọ́tí náà ò tún rántí Jósẹ́fù mọ́! Kò bá Fáráò sọ nǹkan kan nípa ẹ̀, Jósẹ́fù sì ní láti wà ní ẹ̀wọ̀n níbẹ̀.