ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 3
Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí
‘Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń mú kí gbogbo ohun tó ń ṣe yọrí sí rere.’—JẸ́N. 39:2, 3.
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. (a) Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé a máa ń níṣòro? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
KÌ Í ya àwa èèyàn Jèhófà lẹ́nu tí ìṣòro bá dé bá wa. A mọ ohun tí Bíbélì sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 14:22) A tún mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìṣòro tá a ní ló máa yanjú títí a máa fi wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlèrí níbi tí ‘kò ti ní sí ikú mọ́, tí kò sì ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.’—Ìfi. 21:4.
2 Nígbà míì Jèhófà máa ń fàyè gba pé kí àdánwò dé bá wa. Àmọ́, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. Kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó ń gbé ní Róòmù. Ó kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn ìṣòro kan tí òun àtàwọn ará ní. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “À ń ja àjàṣẹ́gun nípasẹ̀ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa.” (Róòmù 8:35-37) Èyí fi hàn pé bí ìṣòro tó dé bá ẹ ò bá lọ, o ṣì máa rọ́wọ́ Jèhófà láyé ẹ. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ àti bó ṣe máa ran ìwọ náà lọ́wọ́.
TÍ NǸKAN BÁ YÍ PA DÀ LÓJIJÌ
3. Àyípadà wo ló dé bá Jósẹ́fù lójijì?
3 Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ Jósẹ́fù gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 37:3, 4) Torí náà, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀. Nígbà tí àǹfààní ẹ̀ yọ, wọ́n ta Jósẹ́fù fáwọn oníṣòwò ilẹ̀ Mídíánì. Àwọn oníṣòwò yẹn mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì tó jìnnà gan-an sí ìlú ẹ̀, àmọ́ àwọn náà tún tà á fún Pọ́tífárì tó jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ Fáráò. Ẹ wo bí ìgbésí ayé Jósẹ́fù ṣe yí pa dà lójijì, ọmọ tó jẹ́ ààyò bàbá ẹ̀ wá di ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì!—Jẹ́n. 39:1.
4. Ìṣòro wo ló lè dé bá àwa náà bíi ti Jósẹ́fù?
4 Bíbélì sọ pé “àjálù àti èèṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni.” (Oníw. 9:11, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Nígbà míì, ìṣòro tó dé bá wa lè jẹ́ èyí tó “máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn,” ìyẹn ìṣòro tó ń bá gbogbo èèyàn fínra. (1 Kọ́r. 10:13) Ohun míì ni pé ìyà lè jẹ wá torí pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n ta kò wá tàbí kí wọ́n ṣe inúnibíni sí wa torí ohun tá a gbà gbọ́. (2 Tím. 3:12) Àmọ́ ìṣòro yòówù kó dé bá ẹ, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Báwo ló ṣe ran Jósẹ́fù lọ́wọ́?
5. Ta ni Pọ́tífárì sọ pé ó mú kí Jósẹ́fù ṣàṣeyọrí? (Jẹ́nẹ́sísì 39:2-6)
5 Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:2-6. Pọ́tífárì rí i pé ọ̀dọ́ ni Jósẹ́fù, orí ẹ̀ pé, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára. Pọ́tífárì tún mọ̀ pé ‘Jèhófà ló ń mú kí gbogbo ohun tí Jósẹ́fù ń ṣe yọrí sí rere.’b Pọ́tífárì sọ Jósẹ́fù di ìránṣẹ́ òun fúnra ẹ̀, kódà ó fi ṣe alábòójútó gbogbo ilé rẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ńṣe ni gbogbo nǹkan ń lọ dáadáa fún Pọ́tífárì.
6. Nínú ipò tí Jósẹ́fù bá ara ẹ̀, kí ló ń fẹ́?
6 Fojú inú wo ipò tí Jósẹ́fù wà. Kí lo rò pé Jósẹ́fù fẹ́ gan-an? Ṣé o rò pé ojúure Pọ́tífárì ló ń wá? Ó jọ pé ohun tí Jósẹ́fù fẹ́ gangan ni pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ kó lè pa dà sọ́dọ̀ bàbá ẹ̀. Ìdí ni pé láìka gbogbo ipò tí Jósẹ́fù wà nílé Pọ́tífárì sí, ẹrú ṣì ni lọ́dọ̀ ọ̀gá ẹ̀ tó jẹ́ abọ̀rìṣà. Jèhófà ò ṣe ohun tó máa mú kí Pọ́tífárì dá Jósẹ́fù sílẹ̀. Kódà ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù ṣì máa burú jùyẹn lọ.
TÍ NǸKAN BÁ Ń BURÚ SÍ I
7. Báwo ni ipò tí Jósẹ́fù wà ṣe burú sí i? (Jẹ́nẹ́sísì 39:14, 15)
7 Jẹ́nẹ́sísì orí 39 sọ pé ọkàn ìyàwó Pọ́tífárì ń fà sí Jósẹ́fù, léraléra ló sì ń fa ojú rẹ̀ mọ́ra. Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà rárá. Níkẹyìn, ó bínú gidigidi sí Jósẹ́fù, ó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó fẹ́ fipá bá òun lòpọ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:14, 15.) Nígbà tí Pọ́tífárì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ju Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n, ó sì pẹ́ díẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n yẹn. (Jẹ́n. 39:19, 20) Báwo ni ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ṣe rí? Ọ̀rọ̀ Hébérù tí Jósẹ́fù fi ṣàlàyé “ẹ̀wọ̀n” lè túmọ̀ sí “kòtò omi” tàbí “ihò,” tó fi hàn pé àyíká ibẹ̀ dúdú, gbogbo nǹkan sì máa tojú sú u. (Jẹ́n. 40:15; àlàyé ìsàlẹ̀) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan wà tí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ Jósẹ́fù tí wọ́n sì fi irin de ọrùn rẹ̀. (Sm. 105:17, 18) Ẹ ò rí i pé ipò tí Jósẹ́fù wà ń burú sí i ni. Ẹrú tí wọ́n fọkàn tán tẹ́lẹ̀ ti wá di ẹlẹ́wọ̀n báyìí.
8. Tí ìṣòro tá a ní bá tiẹ̀ ń burú sí i, kí ló yẹ kó dá wa lójú?
8 Ṣé o ní ìṣòro kan tó ń burú sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò dákẹ́ àdúrà lórí ẹ̀? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀. Jèhófà lè fàyè gba pé káwọn ìṣòro kan dé bá wa nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (1 Jòh. 5:19) Àmọ́ ohun kan dájú, Jèhófà mọ gbogbo ohun tójú ẹ ń rí, ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹ. (Mát. 10:29-31; 1 Pét. 5:6, 7) Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣèlérí pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” (Héb. 13:5) Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da ìṣòro ẹ, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran Jósẹ́fù lọ́wọ́.
9. Kí ló fi hàn pé Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n? (Jẹ́nẹ́sísì 39:21-23)
9 Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:21-23. Jèhófà ò fi Jósẹ́fù sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nígbà tí nǹkan le. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Nígbà tó yá, Jósẹ́fù rí ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n bó ṣe rí ojúure Pọ́tífárì. Ká tó pajú pẹ́, ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ti fi Jósẹ́fù ṣe olórí gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù. Kódà Bíbélì sọ pé “ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ò yẹ Jósẹ́fù lọ́wọ́ wò rárá.” Iṣẹ́ gidi tí Jósẹ́fù ṣe yìí kò jẹ́ kó máa ro èròkerò. Àbẹ́ ò rí bí nǹkan ṣe yí pa dà fún Jósẹ́fù! Ṣé ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó fẹ́ fipá bá ìyàwó ọ̀gá ẹ̀ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin lòpọ̀ ló yẹ kí wọ́n gbé irú iṣẹ́ yìí fún? Ohun kan ṣoṣo ló lè jẹ́ kó ṣeé ṣe. Jẹ́nẹ́sísì 39:23 sọ fún wa pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, Jèhófà sì ń mú kí gbogbo ohun tó bá ṣe yọrí sí rere.”
10. Ṣàlàyé ìdí tí Jósẹ́fù fi lè máa rò pé kì í ṣe gbogbo ohun tóun ń ṣe ló yọrí sí rere.
10 Tún fojú inú wo ipò tí Jósẹ́fù bá ara ẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án tí wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n, ṣé o rò pé ó máa gbà pé gbogbo ohun tóun ń ṣe ló yọrí sí rere? Kí ni Jósẹ́fù ń fẹ́ gan-an báyìí? Ṣé bó ṣe máa rí ojúure ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn ni? Ó jọ pé ohun tí Jósẹ́fù fẹ́ gangan ni pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ lómìnira. Kódà ó sọ fún ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n fẹ́ dá sílẹ̀ pé kó sọ̀rọ̀ òun fún Fáráò kó lè tú òun sílẹ̀ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n burúkú yẹn. (Jẹ́n. 40:14) Àmọ́ ọkùnrin yẹn ò sọ̀rọ̀ Jósẹ́fù fún Fáráò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó jáde lẹ́wọ̀n. Torí náà, ọdún méjì gbáko ni Jósẹ́fù tún lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yẹn kó tó jáde. (Jẹ́n. 40:23; 41:1, 14) Síbẹ̀, Jèhófà mú kí gbogbo ohun tí Jósẹ́fù ń ṣe yọrí sí rere. Lọ́nà wo?
11. Agbára àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà fún Jósẹ́fù, báwo sì nìyẹn ṣe mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ?
11 Nígbà tí Jósẹ́fù wà lẹ́wọ̀n, Jèhófà mú kí Fáráò ọba Íjíbítì lá àlá méjì tó bà á lẹ́rù. Fáráò wá gbogbo ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ àwọn àlá náà. Nígbà tó gbọ́ pé Jósẹ́fù lè túmọ̀ àlá, ó ní kí wọ́n lọ mú un wá. Jèhófà ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti túmọ̀ àwọn àlá náà. Inú Fáráò sì dùn gan-an nígbà tí Jósẹ́fù gbà á nímọ̀ràn ohun tó máa ṣe. Fáráò rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ló bá fi ṣe alábòójútó oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́n. 41:38, 41-44) Nígbà tó yá, ìyàn ńlá kan mú nílẹ̀ Íjíbítì àti láwọn ilẹ̀ míì, kódà ó dé ilẹ̀ Kénáánì níbi táwọn èèyàn Jósẹ́fù ń gbé. Ní báyìí, Jósẹ́fù ti wà nípò tó ti lè gba ìdílé ẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn ni ò sì ní jẹ́ kí ìdílé tí Mèsáyà ti máa wá pa run.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí ohun tí Jósẹ́fù ń ṣe yọrí sí rere?
12 Ronú nípa àwọn nǹkan àrà ọ̀tọ̀ tó ṣẹlẹ̀ láyé Jósẹ́fù. Ta ló mú kí Pọ́tífárì kíyè sí Jósẹ́fù tó jẹ́ ẹrú lásán? Ta ló mú kí ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n ṣojúure sí Jósẹ́fù? Ta ló mú kí Fáráò lá àwọn àlá tó bà á lẹ́rù, tó sì tún mú kí Jósẹ́fù túmọ̀ àlá náà? Ta ló mú kí Fáráò yan Jósẹ́fù ṣe alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì? (Jẹ́n. 45:5) Ó dájú pé Jèhófà ló wà lẹ́yìn Jósẹ́fù tí gbogbo ohun tó ń ṣe fi yọrí sí rere. Jèhófà yí gbogbo aburú táwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe sí i pa dà, ìyẹn sì wá mú kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE MÁA JẸ́ KÓ O ṢÀṢEYỌRÍ
13. Ṣé Jèhófà máa ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tó bá dé bá wa? Ṣàlàyé.
13 Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù? Ṣé Jèhófà máa ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ìṣòro tó bá dé bá wa? Ṣé gbogbo aburú tó bá ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé wa ni Jèhófà máa ń yí pa dà sí rere? Rárá o. Bíbélì ò sọ bẹ́ẹ̀. (Oníw. 8:9; 9:11) Àmọ́ ohun tó dá wa lójú ni pé tá a bá níṣòro, Jèhófà mọ̀, ó sì máa ń gbọ́ wa tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 34:15; 55:22; Àìsá. 59:1) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà máa ń fún wa lókun ká lè fara da àwọn ìṣòro tá a ní. Báwo ló ṣe ń ṣe é?
14. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro?
14 Jèhófà máa ń tù wá nínú, ó sì máa ń fún wa níṣìírí lákòókò tá a nílò ẹ̀ gan-an. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún Arákùnrin Eziz lórílẹ̀-èdè Turkmenistan. Wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún méjì torí ohun tó gbà gbọ́. Ó sọ pé: “Láàárọ̀ ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ mi, arákùnrin kan fi ohun tó wà nínú Àìsáyà 30:15 hàn mí tó sọ pé: ‘Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.’ Ẹsẹ Bíbélì yìí máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Bí mo ṣe ń ronú lórí ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ kí n lè fara dà á ní gbogbo àkókò tí mo wà lẹ́wọ̀n.” Ṣé ìwọ náà rántí ìgbà kan tó o níṣòro, tí Jèhófà tù ẹ́ nínú tó sì fún ẹ lókun lákòókò tó o nílò ẹ̀ gan-an?
15-16. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tori?
15 Lọ́pọ̀ ìgbà, tá a bá wà nínú ìṣòro, a kì í mọ bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ àfi tá a bá ronú lórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Tori gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Ọdún mẹ́fà ni àrùn jẹjẹrẹ fi ṣe ọmọkùnrin ẹ̀ tó ń jẹ́ Mason, lẹ́yìn náà ó kú. Ṣẹ́ ẹ rí i, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ba Tori lọ́kàn jẹ́ gan-an. Ó sọ pé, “Mi ò rò pé ohun míì wà tó lè dun abiyamọ ju ikú ọmọ ẹ̀ lọ, bó sì ṣe rí lára mi nìyẹn.” Ó tún sọ pé, “Ó dá mi lójú pé àwọn òbí mọ̀ pé ó sàn káwọn máa jìyà ju káwọn máa wo ọmọ àwọn kó máa jìyà.”
16 Bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe ba Tori nínú jẹ́ tó, ó ronú lórí bí Jèhófà ṣe ran òun lọ́wọ́ kóun lè fara dà á. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀, mo rọ́wọ́ Jèhófà lára mi nígbà tí ọmọ mi ń ṣàìsàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àìsàn Mason le gan-an táwọn dókítà sì sọ pé kí àlejò kankan má wá sọ́dọ̀ ẹ̀, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ṣì máa ń wá, wọ́n á fi wákàtí méjì wakọ̀ wá sílé ìwòsàn. Kò sígbà tá a kì í rí àwọn ará ní yàrá ìgbàlejò, wọ́n múra tán láti ràn wá lọ́wọ́. Bákan náà, àwọn ará máa ń gbé àwọn ohun tá a nílò wá fún wa. Kódà, nígbà tí nǹkan nira gan-an, a ò ṣaláìní ohunkóhun.” Jèhófà ran Tori lọ́wọ́ kó lè fara dà á, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún Mason náà.—Wo àpótí náà, “Ohun Tá A Nílò Gan-an Ni Jèhófà Fún Wa.”
MÁA RÁNTÍ OHUN TÍ JÈHÓFÀ TI ṢE FÚN Ẹ
17-18. Kí ló máa jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, ká sì mọyì ẹ̀? (Sáàmù 40:5)
17 Ka Sáàmù 40:5. Tẹ́nì kan bá ń gun òkè, ohun tó fẹ́ ni pé kóun gùn ún dé òkè pátápátá. Àmọ́ bó ṣe ń gùn ún lọ, àwọn ibì kan wà tó ti lè dúró kó sì wo àwọn ohun tó wà láyìíká ibẹ̀. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa wáyè ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Ká tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún mi lónìí? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro tí mo ní ò tíì lọ, báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á?’ Wò ó bóyá wàá rí ohun tí Jèhófà ṣe fún ẹ, bí ò tiẹ̀ ju ẹyọ kan lọ.
18 Òótọ́ ni pé o lè máa gbàdúrà pé kí ìṣòro ẹ tán, ohun tó sì yẹ kó o ṣe nìyẹn torí kò sẹ́ni tó fẹ́ jìyà. (Fílí. 4:6) Àmọ́, ó yẹ ká tún máa rántí àwọn ohun rere tí Jèhófà ń ṣe fún wa báyìí. A mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí pé òun ò ní dá wa dá ìṣòro wa, òun á fún wa lókun ká lè fara dà á. Torí náà, máa dúpẹ́ gbogbo oore tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.—Jẹ́n. 41:51, 52.
ORIN 32 Dúró Ti Jèhófà!
a Tá a bá ní ìṣòro ńlá kan tó ń bá wa fínra, ó lè máa ṣe wá bíi pé Jèhófà ti gbàgbé wa. A lè máa rò pé ó dìgbà tí ìṣòro náà bá lọ ká tó gbà pé a ṣàṣeyọrí. Àmọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan. Ẹ̀kọ́ náà ni pé bí ìṣòro tó dé bá wa ò bá lọ, Jèhófà ṣì máa ràn wá lọ́wọ́. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.
b Ẹsẹ Bíbélì mélòó kan ni Bíbélì fi ṣàkópọ̀ àwọn àyípadà tó kọ́kọ́ dé bá Jósẹ́fù nígbà tó ń ṣẹrú ní Íjíbítì, àmọ́ ó ṣeé ṣe káwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn gba ọdún tó pọ̀ díẹ̀.