Ori 13
Ẹlẹ́ṣin Ijọba naa Gẹṣin
1, 2. (a) Ta ni a dari afiyesi si nisinsinyi, ki ni oun sì mudani ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀? (b) Eeṣe tí a fi sọ fun Johannu pe ki ó maṣe sọkun mọ́? (c) Ta ni “Kinniun” ẹya Juda naa, eesitiṣe tí ó fi tootun lati ṣí awọn èdìdí naa?
Ẹ JẸ́ ki a yíjú sí Ìfihàn ori karun-un. Níhìn-ín a kà nipa iran kan tí a misi, tí a fi fun aposteli Johannu, tí ó nii ṣe ní taarata pẹlu ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun. Ó sọ ní pataki nipa Jehofa Oluwa Ọba-aláṣẹ, “Ẹni tí ó jokoo lori ìtẹ́.” Ó di àkájọ ìwé akọsilẹ kan mú ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, “tí a fi èdìdí meje dí.” Ṣugbọn aposteli Johannu búsẹ́kún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Eeṣe? Nitori pe, ní gbogbo agbaye, a kò rí ẹnikan tí ó tootun lati ṣí èdìdí àkájọ ìwé naa ki ó sì sọ ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ di mímọ̀. Ṣugbọn, kiyesii! Ẹnikan wà tí ó tootun! Oun kii ṣe ẹlomiran bikoṣe “Kinniun ẹya Juda,” àjògún ijọba Dafidi.—Ìfihàn 5:1-5.
2 Oun tootun nitori pe ó “ti bori.” Gẹgẹ bi eniyan pípé kan lori ilẹ̀-ayé, ó fi iduroṣinṣin àìyẹhùn hàn si Baba rẹ̀, àní titi dé oju iku olóró kan lori igi oró. Satani, “alade ayé yii,” kò lè ba ìwàtítọ́ rẹ̀ jẹ. Jesu le wi pe: “Mo ti ṣẹgun ayé.”—Johannu 14:30; 16:33.
3. Eeṣe tí a fi nilati yọ̀ ayọ-nla lori imuṣẹ Ìfihàn 5:9, 10?
3 Awọn miiran wà, pẹlu, tí wọn ti ṣẹgun ayé, “Kinniun” onigboya yii, Kristi Jesu, sì kà wọn sí “arakunrin” rẹ̀ nipa tẹmi. (Matteu 25:40) Nipasẹ ajinde ti ọrun kan, awọn wọnyi yoo darapọ mọ́ ọn ninu iṣakoso Ijọba rẹ̀ ẹlẹgbẹrun ọdun, wọn yoo sì ṣajọpin pẹlu rẹ̀ ní ṣiṣe ìpínfúnni anfaani ẹbọ irapada rẹ̀ fun awọn billion araye lori ilẹ̀-ayé. Nitori naa awọn ohùn ní ọrun ń kọ orin titun kan. Wọn ń wi fun Ẹni yii, tí a mú nigba kan rí gẹgẹ bi ọdọ-agutan alailẹṣẹ kan lọ si ìbupa pe:
“Iwọ ni o yẹ lati gba iwe naa, ati lati ṣí èdìdí rẹ̀, nitori a ti pa ọ, iwọ si ti fi ẹjẹ rẹ ṣe irapada eniyan si Ọlọrun lati inu ẹ̀yà gbogbo, ati èdè gbogbo, ati inu eniyan gbogbo, ati orilẹ-ede gbogbo wá. Iwọ si ti ṣe wọn ni ọba ati alufaa si Ọlọrun wa: wọn si ń jọba lori ilẹ̀-ayé.” (Ìfihàn 5:9, 10)
Ẹ wò iru ibukun tí ó jẹ́, pe Ọba naa ati awọn ajumọ jọba rẹ̀ tí a ti dánwó tí wọn sì ti yege ti muratan lati gbé ìgbésẹ̀ nitori iran eniyan tí a ń pọ́nlójú! Ṣugbọn nitori eyi, ogun-jíjà kan gbọdọ kọ́kọ́ ṣẹlẹ.
ẸNI TÍ Ń GUN ẸṢIN FUNFUN NAA
4. (a) Ki ni a ṣapẹẹrẹ rẹ̀ nipasẹ “ẹṣin funfun” naa, “ọrun” tí ń bẹ lọwọ ẹni tí ń gùn ẹṣin naa, ati gbígbà tí ó gbà “adé” kan? (b) Ta ni ẹlẹ́ṣin yii, nigba wo ni ó sì gbà ọla-aṣẹ ọba?
4 Bi “Ọdọ-agutan” naa ti mú àkájọ ìwé naa tí ó sì ṣí èdìdí kìn-ín-ní, ohùn kan dún bi sísán ààrá latí ọrun wá pe: “Wá, wò ó!” Ki ni a sì rí? “Kiyesii, ẹṣin funfun kan”—ní iṣapẹẹrẹ ogun ododo. Ẹni tí ó gùn ún ní “ọrun” kan lọwọ. Ó lè pa awọn ọ̀tá rẹ̀ run lati ibi jijinna-réré—tí ó ń rekọja ibi jijinna pupọ jù ti awọn bọmbu atamátàsé agbókèèrè ṣọṣẹ́ ti a ti ọwọ́ eniyan lasan ṣe. A fun un ní “adé” kan, eyi sì tọkasi ọdun 1914 ti ode-oni, nigba tí Jehofa fun un ní ọla-aṣẹ ọlọ́ba lori awọn orilẹ-ede. Nitori pe ó lagbara pupọpupọ jù awọn oluwa ati awọn ọba eniyan, “Oluwa awọn oluwa ati Ọba awọn ọba” yii nilati yọ̀ ayọ iṣẹgun lori gbogbo ọ̀tá ododo, papọ pẹlu awọn Kristian ẹni-ami-ororo “tí a pè, tí a yàn, tí wọn sì jẹ́ oloootọ” tí wọn darapọ mọ ọ ninu Ijọba rẹ̀ ọrun.—Ìfihàn 6:1, 2; 17:14.
5. (a) Iṣẹgun akọkọ wo ni ẹlẹ́ṣin yii ni? (b) Ki ni ó ti jẹ́ iyọrisi rẹ̀ fun araye, ṣugbọn eeṣe tí ó fi yẹ ki a kọbiara sí ikilọ tí ó wà ninu Marku 13:32-37?
5 Ẹni tí ń gùn “ẹṣin funfun” yii jẹ́ aṣẹgun alagbara-nla kan. Nigba naa, bi ó ti ń ṣẹgun lọ, ki ni ìbá tún baamu, jù pe ki ó lé Satani, “ejo laelae nì,” ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ jade kuro ní ọrun? Sí ilẹ̀-ayé yii ni ó lé wọn jù sí! Abajọ nigba naa tí Eṣu nisinsinyi fi ní ibinu nla. Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi tẹlẹ, ó ń fi ibinu yii hàn si araye, tí ó si ń fà “ègbé” fun “ilẹ̀-ayé ati fun òkun.” Eṣu mọ̀ pe kìkì “igba kukuru” ni oun ní, ṣugbọn arekereke rẹ̀ pọ̀ gidigidi. Oun yoo fẹ́ lati lò agbara-idari lori wa lati mú ki a ronu pe “awọn ọjọ ikẹhin” ṣì nasẹ̀ jinna si ọjọ-iwaju. Ki ẹnikẹni ninu wa maṣe di ẹni tí a kùn lóorun nipasẹ irufẹ ironu bẹẹ!—Ìfihàn 12:9-12; Marku 13:32-37.
ẸṢIN ALÁWỌ̀ PUPA KAN
6. (a) Gẹgẹ bi Ìfihàn 6:3, 4 ti wi, ki ni ó bẹ́ jade sojú ìran nisinsinyi? (b) Bawo ni Ogun Agbaye I ṣe yatọ si gbogbo ogun tí ó ti wà ṣaaju rẹ̀?
6 “Ọdọ-agutan” naa ṣí èdìdí keji. “Ẹṣin pupa” kan sì bẹ́ jade! “A sì fi agbara fun ẹni tí ó jokoo lori rẹ̀, lati gbà alaafia kuro lori ilẹ̀-ayé, ati pe ki wọn ki ó maa pa araawọn; a sì fi idà nla kan lé e lọwọ.” (Ìfihàn 6:4) Áà, ogun agbaye kìn-ín-ní ninu itan eniyan bújáde sí gbangba wálíà. A gba alaafia kuro, kò wulẹ jẹ́ kuro lọdọ iwọnba awọn orilẹ-ede diẹ, ṣugbọn kuro lori “ilẹ̀-ayé,” bi awọn ẹgbẹ ọmọ-ogun tìrìgàngàn ti ori ilẹ ati ti oju omi ṣe ń fìjàpẹẹ́ta pẹlu araawọn lẹnikinni-keji, tí wọn ń lò awọn ohun ija adáyàjáni fun ipanirun bẹẹrẹbẹ. Nigba tí ó jẹ́ pe awọn ogun tí ó ti jà kọja jẹ́ lati ọwọ awọn jagunjagun ògbóǹtarìgì, tí ó saba maa ń jẹ́ kiki laaarin awọn orilẹ-ede kereje, Ogun Agbaye I jẹ́ ogun àjàkú-akátá. Fun igba akọkọ ninu itan, gbogbo awọn àlùmọ́ọ́nì ọpọlọpọ orilẹ-ede patapata porogodo, titikan awọn eniyan tí a fagbara sọdi ológun, ni a sọ sinu ogun naa.
7-9. Niti ‘ipakupa,’ awọn isọfunni-oniṣiro ati awọn gbolohun-ọrọ wo ni wọn fihan pe 1914 sami si ibẹrẹ ipakupa tí ó burujulọ ninu gbogbo itan eniyan?
7 Asọtẹlẹ naa mẹnukan ‘ipakupa,’ ‘ipakupa’ ni ó sì jẹ́! Ninu ogun tí a jà ní Somme, imujade titun kan tí ó jẹ́ gbẹ̀mígbẹ̀mí, àgbá ìbọn arọta-bí-òjò, ṣá ẹgbàágbèje awọn ọmọ-ogun Britain ati ti France balẹ̀, tí ó ṣokunfa, nipasẹ ifojudiwọn kan, ipin 80 ninu ọgọrun-un iye awọn tí wọn kú. Ní oṣu mẹsan-an ní Verdun, awọn ọkunrin tí ó kú pọ̀ jù awọn ọmọ-ogun Napoleon tí wọn yan lọ si Russia. Àmì kan tí a fi ẹjẹ kọ sara itẹ́ kan ni iboji kan ní Verdun kà pe “KILOMITA MARUN-UN SI ILE IPAKUPA.” Lapapọ, nǹkan bii 9,000,000 awọn ọmọ-ogun ni a pa laaarin ọdun mẹrin Ogun Nla naa.
8 Njẹ 1914 ni ọdun naa tí ẹni tí ó gùn ‘ẹṣin aláwọ̀ pupa’ naa gbà alaafia kuro lori ilẹ̀-ayé bi? Ọpọlọpọ awọn opitan ni wọn gbe èrò naa lẹhin. Fun apẹẹrẹ, ní eyi tí ó fẹrẹẹ tó 50 ọdun lẹhin naa, olootu iwe-irohin nipa itan American Heritage kọwe pe: “Ní igba ẹrun 1914 awọn orilẹ-ede wa ní alaafia pẹlu araawọn ti ọjọ-iwaju sì dabi eyi tí yoo tòrò minimini. Nigba naa ni awọn ìbọn dún, awọn nǹkan kò sì ni rí bakan naa mọ́ lae. . . . Ọdun naa 1914 jẹ́ ọ̀kan ninu awọn ọdun abàmì julọ ninu itan eniyan . . . Ní ọdun yẹn ni ọ̀kan ninu awọn iyipada titobijulọ ti kii ṣẹlẹ jù igba kan tabi meji ninu ẹgbẹrun ọdun kan dé. Boya yoo tó igba gígùn kan ki a tó lè loye lẹkunrẹrẹ ohun tí 1914 ti mú wa wọ̀ inu rẹ̀, ṣugbọn ó keretan a lè bẹrẹ sii rí ohun ti o fi ipa já wa gbà kuro lọwọ rẹ̀.” Nitootọ, ẹni tí ó gun ‘ẹṣin aláwọ̀ pupa’ naa gbà alaafia kuro ní ayé, 1914 sì ni ọdun naa.
9 Ẹlẹ́ṣin naa ń bá ìgẹṣin aṣekupani rẹ̀ nìṣó titi wọnú ogun agbaye keji, ninu eyi tí 16,000,000 awọn ọmọ-ogun kú ninu ogun. Bi a ti ń tẹsiwaju ninu awọn ọdun 1980, ọjọgbọn ara Hungary kan ṣe iṣiro pe ọgbọ̀n ọdun lẹhin Ogun Agbaye II, 25,000,000 awọn ọmọ-ogun miiran ni wọn kú ninu ogun. Ó sọ pe laaarin 33 ọdun tí ó tẹle apá ipari Ogun Agbaye II, 26 ọjọ péré ni ó wà ninu eyi tí kò sí ogun nibi kankan ninu ayé.
10. Bawo ni ẹlẹ́ṣin yii ṣe lò “idà nla”?
10 Asọtẹlẹ naa sọ fun wa pe a fi “idà nla” kan fun ẹlẹ́ṣin yii. Dajudaju, awọn ohun-ija panipani ti kó ipa titobi ninu ipakupa ti awọn ogun ọ̀rúndún ogún yii. Ninu Ogun Agbaye I, afẹfẹ onimajele, awọn ohun-ija tí ń dá-ṣiṣẹ́ funraawọn, awọn ọkọ̀ arọ̀jò-ọta, awọn ọkọ̀ ofuurufu ati ọkọ̀ ogun abẹ́ omi farahan kedere ni gbangba láìkù sibikan fun igba akọkọ. Ninu Ogun Agbaye II, ogun-jíjà ní ofuurufu niti gidi gbá awọn ilu-nla lọ ráúráú, pupọ julọ ninu awọn tí a ṣekupa jẹ́ awọn obinrin, awọn ọmọde ati arugbo aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Ní òru ọjọ kan ilu-nla Coventry, England, ni a parun, ati lẹhin naa ikọlu kan lati ofuurufu nipasẹ awọn Orilẹ-ede Aladehun Ifọwọsowọpọ, mú ẹmi 135,000 eniyan lọ ní Dresden, Germany. Tẹle eyi ni ipakupa tìrìgàngàn nipasẹ awọn bọmbu atọmiki eyi tí ó gbẹ̀mí ó keretan 92,000 eniyan ní Hiroshima ati 40,000 ní Nagasaki, Japan, lẹẹkan sii pupọ julọ ninu wọn jẹ́ ara-ilu. Ohun tí “idà nla” naa lè ṣe aṣepari lonii bi ogun atọmiki olóró bá ṣèèṣì bẹsilẹ yoo rekọja ohun tí a lè ronúwòye!
‘WÒ Ó! ẸṢIN DUDU KAN’
11, 12. (a) Bawo ni ẹni tí ń gùn “ẹṣin dudu” naa ṣe fi araarẹ̀ hàn gẹgẹ bi ọ̀rẹ́ ẹlẹ́ṣin keji? (b) Ki ni ó fihan pe ìgẹṣin rẹ̀ ń tẹsiwaju titi di ọjọ wa?
11 Bi “Ọdọ-agutan” naa ti ń ṣí èdìdí kẹta, “ẹṣin dudu kan” jade wá. “Ẹni tí ó jokoo lori rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́-méjì ní ọwọ́ rẹ̀.” (Ìfihàn 6:5) Áà, níhìn-ín ni a rí ẹlẹ́ṣin alabaakẹgbẹ pẹlu ẹlẹ́ṣin ogun àjàkú-akátá! Eyi ni ẹlẹ́ṣin naa tí ó mú ìyàn wá. Nigba ogun agbaye mejeeji, ìyàn kọlu ọpọlọpọ orilẹ-ede. Pípín ounjẹ níwọ̀n-níwọ̀n, gẹgẹ bi “ìwọ̀n aláwẹ́-méjì” naa ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀, di aṣa fun awọn ara ilu ni awọn orilẹ-ede tí ń jagun. Nigba ipari Ogun Agbaye I ni ìyàn titobijulọ ninu itan bẹ́sílẹ̀. The Nation ti June 7, 1919, rohin pe 32,000,000 eniyan ní India “ni ebi ti fẹẹrẹ pa kú.” World’s Work ti March 1921 sọ pe ní ariwa China nikan 15,000 eniyan ni wọn ń kú lojoojumọ nitori ebi. Itẹjade iwe irohin Times ti New York, tí a ń pè ní Current History Magazine ti October 1921 ṣàyọlò irohin ilẹ Britain kan pe ní Russia “awọn eniyan ti kò dín ni 35,000,000 ni ìyàn ati ajakalẹ-arun ti gbámú.” Iru ìyàn bẹẹ gbòdekan lẹhin Ogun Agbaye II, nigba tí iwe-irohin Look ti June 11, 1946, rohin pe: “Idamẹrin ayé ni ebi ń pa lonii.”
12 Kódà laisi ogun gbogbogboo paapaa, ìkùnà irugbin ninu ayé ọlọ́làjú wa saba maa ń ṣokunfa awọn akori gàdàgbà ninu irohin gẹgẹ bi iru eyi ní 1974: “India wà labẹ òjìji ẹlẹ́ṣin kẹta.” Ní 1976: “Ayé kan Tí Ebi ti Hàn-Léèmọ̀ Dojukọ Rogbodiyan Ounjẹ Titobiju.” Ati ní 1979: “450 million eniyan ni ebi n pa ku.” Bi iye awọn olugbe ayé ti ń di ìlọ́po, ipo-ọran ounjẹ ninu awọn orilẹ-ede tí kò tíì dagbasoke tobẹẹ ati eyi tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ tubọ ń lekoko sii. The Atlas World Press Review, ninu New Scientist ti May 1975, sọ pe: “Ayé dojukọ iwin olórí-méjì kan. Ìyàn wulẹ jẹ́ apakan ninu irisi rẹ̀ ni: ekeji ni àìjẹun-re-kánú ti ń baa lọ laidawọduro. Eto-ajọ fun Ounjẹ ati ti Ọ̀gbìn [FAO] ṣiro pe 61 ninu 97 awọn orilẹ-ede tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dagbasoke pese tabi kó ounjẹ tí ó kere gidigidi wọle ní 1970 si ohun ti wọn nilo lati fi bọ́ awọn eniyan wọn. Ninu iṣiro kan tí a fojudiwọn, FAO ronu pe nǹkan bii 460 million awọn eniyan ni wọn ń jiya lọwọ àìjẹun-re-kánú; itumọ tí ó tubọ gbooro kan lè fi iṣiro naa si 1 billion.” Nisinsinyi, ní awọn ọdun 1980 siwaju, ipo-ọran naa ti tubọ buru sii.
13. Awọn ipò ode-oni ati awọn ibẹru wo ni a rí ojiji-iṣaaju wọn ninu Ìfihàn 6:6?
13 Bi ẹlẹ́ṣin kẹta ti ń tẹsiwaju ninu ìgẹṣin rẹ̀, ohùn kan lati ọrun wá kigbe pe: “Oṣuwọn àlìkámà kan fun owó idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barli mẹta fun owó idẹ kan; sì kiyesii, ki ó má sì ṣe pa òróró ati ọtí-waini lara.” (Ìfihàn 6:6) Pẹlu owó idẹ kan tí ó duro fun owó-ọ̀yà ojúmọ́ kan, dajudaju inu yoo bí oṣiṣẹ kan nitori owó-ọjà tí ó gasoke fiofio yii. Ǹjẹ́ ifosoke owó-ọjà kò ha ń gbà ọ̀nà èbùrú yọ si owó-oṣù awọn mẹ̀kúnnù lonii bi? Ipese awọn ohun kòṣeémánìí miiran wọnni, “ororo” ati “ọti-waini,” pẹlu kò ní tó-ǹkan mọ́. Ṣugbọn ki ni nipa ti awọn oniwọra tí ń jèrè àjẹpajúdé ti yoo fẹ lati daabobo igbesi-aye wọn onígbẹdẹmukẹ? Wọn yoo ha kẹ́sẹjárí bi? Awa yoo ríi, bi “ẹṣin dudu” naa ti ń bẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún jakejado ayé.
‘ẸṢIN RỌNDỌNRỌNDỌN KAN, PẸLU IKU’
14. Bawo ni ẹlẹ́ṣin kẹrin ati alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣe ṣedeedee pẹlu awọn iṣẹlẹ lati 1914?
14 A ṣí èdìdí kẹrin, “ẹṣin rọndọnrọndọn” kan sì darapọ mọ́ awọn ẹṣin tí ń sá eré àsápajúdé naa. Ẹni tí ó gùn ún ni Iku. Ipò-okú sì tẹle e pẹkipẹki—yala lori ẹṣin miiran tabi bẹẹkọ, akọsilẹ naa kò sọ. Ṣugbọn wọn ní iṣẹ adáyàfoni kan lati jẹ́: “A sì fi agbara fun wọn lori idamẹrin ayé, lati fi idà, ati ebi, ati [ìyọnu àjàkálẹ̀ aṣekupani, NW], ati ẹranko ilẹ̀-ayé pa.” (Ìfihàn 6:7, 8) Lati ọdun mánigbàgbé naa 1914, wíwàníhìn-ín Iku ati Ipò-òkú dajudaju ti tànkálẹ̀ lọ si igun mẹrẹẹrin ayé.
15, 16. (a) Imuṣẹ yiyanilẹnu wo ni asọtẹlẹ yii ní ní 1918 si 1919? (b) Ki ni fihan pe ẹṣin yii ti bẹrẹsii sare tete laidawọduro lati 1914?
15 “Ìyọnu àjàkálẹ̀ aṣekupani”! Wọn pè é ní àrùn àjàkálẹ̀ ti 1918 si 1919, tabi àrùn-gágá. Laaarin awọn ọsẹ diẹ, awọn ojiya ipalara rẹ̀ ti lọpo iye awọn tí ó kú ní pápá Ogun Agbaye I—àròpọ̀ bibanilẹru ti kò dín ni 21,000,000 eniyan. Ní United States iye tí a kede pe àrùn-gágá pa jẹ́ 548,452, tí ó jù ilọpo 10 iye awọn ọmọ-ogun America tí a pa ninu ogun naa. Fun eyi tí ó pọ̀ julọ, awọn ẹran-ijẹ rẹ̀ jẹ́ awọn ọ̀dọ́ ati awọn gìrìpá. Ní India, eyi ti o jú 12,000,000 lọ ni o kú. Kò dá àgbáálá-ilẹ̀ tabi erekuṣu kankan sí—ayafi kiki erekuṣu St. Helena nikan. Gbogbo awọn abúlé laaarin awọn ilẹ Eskimo ati ní Aarin Gbùngbùn Africa ni a sọdahoro. Ní Tahiti, awọn ibi-ìdáná-sun-òkú ni a lò lati fi ṣe ìpalẹ̀mọ́ 4,500 awọn eniyan tí ó kú laaarin 15 ọjọ péré, ti 7,500 ninu 38,000 olugbe Western Samoa si parun ninu ìyọnu àjàkálẹ̀ naa.
16 Àmọ́ ṣáá o, àrùn-gágá kii ṣe kìkìdá arun tí ń paniku tí ẹni tí ń gùn “ẹṣin rọndọnrọndọn” naa ti mú wá. New York Times rohin pe ní 1915, ninu ogun-jíjà fun Gallipoli, ìgbẹ́-ọ̀rìn pa awọn ọmọ-ogun jù ọta ìbọn lọ. Lati 1914 si 1923 àrùn onígbá-méjì pa 3,250,000 ní India. Ní 1915, “iku million meji-ààbọ̀ si mẹta” ní Russia ni a sọ pe ibà typhus ṣe okunfa rẹ̀. Bi ẹlẹ́ṣin naa sì ti ń sare tete wọnú awọn akoko lọ́ọ́lọ́ọ́, àrùn ọkàn-àyà ati jẹjẹrẹ ti di awọn arun panipani tí ó gbà iwaju, àrùn rẹ́kórẹ́kó jẹ́ “Panipani Onípò-Kéjì Ninu Àrùn Tí Ń Ranni” nigba tí arun mẹ́dọ̀wú jẹ́ “Ìbúrẹ́kẹrẹ̀kẹ Àrùn Jakejado Ayé.”
ITURA SUNMỌLE!
17, 18. (a) Ki ni oloṣelu kan wí, tí ó fi isopọ tí ó wà laaarin ẹlẹ́ṣin ekeji, ẹkẹta ati ẹkẹrin hàn? (b) Ṣugbọn ta ni awọn aláṣẹ ayé ṣàìnáání? (c) Eeṣe tí a fi lè dunnú nipa ohun tí Ọba ológo naa yoo ṣe?
17 Nisinsinyi ní eyi tí ó jù 60 ọdun lọ, ‘ẹṣin aláwọ̀ pupa,’ “ẹṣin dudu” ati “ẹṣin ràndánràndán” ti ń sare ní ifẹgbẹkẹgbẹ, pẹlu Ipò-òkú tí ń tẹle wọn pẹkipẹki. Nitootọ, Ipò-òkú ti kórè ọpọ jàáǹrẹrẹ awọn ojiya ipalara, tí ń lọ si ọgọrọọrun lọna araadọta ọkẹ. Ó jẹ́ ohun tí ó dùnmọ́ni ninu pe ààrẹ United States tẹlẹri, Herbert Hoover, so awọn ẹlẹ́ṣin mẹta wọnyi papọ, nigba tí ó wí ní 1941 pe: “Abajade awọn ogun nla saba maa ń jẹ́ ìyàn ati ajakalẹ-arun . . . Ogun Agbaye ti ọdun mẹẹdọgbọn sẹhin mú ebi wá bá 300,000,000 eniyan. . . . Lẹhin ọdun kan ati aabọ ti ogun isinsinyi [Ogun Agbaye II] iye tí ó fẹrẹẹ tó 100,000,000 awọn eniyan pupọ sii ni ounjẹ kò tó fun jù ti ọdun mẹta lẹhin ogun tí ó kọja.” Ẹ wò iru ìjábá tí ogun agbaye kẹta kan yoo tumọsi fun araye!
18 Awọn aṣaaju ayé mọ̀ dajudaju nipa ewu tí awọn ẹni tí ń gùn ‘ẹṣin aláwọ̀ pupa,’ “ẹṣin dudu,” ati “ẹṣin rọndọnrọndọn” ń mú wá. Bi ó ti wù ki ó rí, wọn ṣaibikita nipa Ẹni tí ń gùn “ẹṣin funfun” naa. Ọjọ onidunnu naa ń sunmọle fun Ọba ológo yii lati gbé ìgbésẹ̀ ní yíyí itolẹsẹẹsẹ eto awọn nǹkan pada! Dipo ogun, oun yoo mú alaafia wá. Ní ipò ìyàn, oun yoo pese ọpọ yanturu. Dipo àrùn, oun yoo mú araye padabọ si ilera pípé, kódà Ipò-òkú paapaa yoo jọ̀wọ́ awọn òkú tí ń bẹ ninu rẹ̀ lọwọ. Àyọkà-ọ̀rọ̀ kan tí ó bá a dọgba ninu Orin Dafidi ṣapejuwe ẹni tí ń gùn “ẹṣin funfun” yii pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:
“Sán idà rẹ mọ́ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-ńlá rẹ. Ati ninu ọlá-ńlá rẹ maa gẹṣin lọ ni alaafia, nitori otitọ ati iwa-tutu ati ododo; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yoo kọ́ ọ ni ohun ẹ̀rù.” (Orin Dafidi 45:3, 4)
Ayọ-iṣẹgun Ẹlẹṣin Ijọba naa kù sí dẹ̀dẹ̀!
19. (a) Lójú imuṣẹ Ìfihàn 6:2-8, a ha nilati daamu bi? (b) Apẹẹrẹ wo ni a tọkasi lati fun wa ní iṣiri lati jẹ́ alagbara ninu igbagbọ?
19 Nitori naa, ẹ maṣe jẹ́ ki a daamu jù bi ó ti yẹ lọ nitori awọn ipo-ọran tí ń buru sii ninu ayé lonii. Kàkà bẹẹ, ǹjẹ́ ki oju-iwoye wa rí bi ti ọ̀kan ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ẹni tí, nitori awọn igbagbọ rẹ̀, lò 20 ọdun lara awọn ọdun 1956 si 1978 ninu ẹ̀wọ̀n ní orilẹ-ede elétò-afẹ́nifẹ́re kan. Ní akoko kan a dájọ́ iku fun un, titi di òní-olónìí oun ṣì ní awọn ami ìdálóró ní awọn apá rẹ̀. Bawo ni oun ṣe jẹ́ alagbara ninu igbagbọ? Ó jẹ́ nipa ṣiṣe aṣaro lori awọn àyọkà ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó ranti lati inu ikẹkọọ alaapọn rẹ̀ iṣaaju ninu Bibeli. Ó sọ pe ọ̀kan ninu awọn wọnyi ni Ìfihàn 6:2. Ó dá a lójú ṣákáṣáká pe Ẹni tí ń gùn “ẹṣin funfun” naa, Jesu Kristi Ọba, ni a ti fi jọba ní ọrun ní 1914, ó sì pinnu lati farada titi yoo fi ‘pari iṣẹgun rẹ̀.’ Ǹjẹ́ ki gbogbo awọn ẹlomiran tí wọn ń gbadura fun ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun di iduroṣinṣin wọn mu titi Ọba naa yoo fi jagunmólú ní kíkún!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 123]
ẸṢIN DÚDÚ NAA Ń BẸ́ GÌJÀGÌJÀ NÌṢÓ
“Banki Agbaye ṣiro rẹ̀ pe 780 million awọn eniyan yika ayé ni wọn ń gbé ninu òṣì paraku, ipò kan tí ó ‘rẹlẹ si iwọn eyikeyii ti a le fi oju wo bi eyi ti o bojumu fun eniyan ninu awujọ eniyan.’”—Detroit “Free Press,” September 1, 1980