Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
6 Mo rí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà+ nígbà tó ṣí ọ̀kan nínú àwọn èdìdì méje náà,+ mo sì gbọ́ tí ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà+ fi ohùn tó dún bí ààrá sọ pé: “Máa bọ̀!” 2 Sì wò ó! mo rí ẹṣin funfun kan,+ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ ní ọfà* kan; a sì fún un ní adé,+ ó jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun, kó lè parí ìṣẹ́gun rẹ̀.+
3 Nígbà tó ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kejì+ sọ pé: “Máa bọ̀!” 4 Ẹṣin míì jáde wá, ó jẹ́ aláwọ̀ iná, a sì gba ẹni tó jókòó sórí rẹ̀ láyè láti mú àlàáfíà kúrò ní ayé kí wọ́n lè máa pa ara wọn, a sì fún un ní idà ńlá kan.+
5 Nígbà tó ṣí èdìdì kẹta,+ mo gbọ́ tí ẹ̀dá alààyè kẹta+ sọ pé: “Máa bọ̀!” Sì wò ó! mo rí ẹṣin dúdú kan, òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì sì wà lọ́wọ́ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. 6 Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ó sọ pé: “Òṣùwọ̀n kúọ̀tì* àlìkámà* kan fún owó dínárì*+ kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.”+
7 Nígbà tó ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹrin,+ ó sọ pé: “Máa bọ̀!” 8 Sì wò ó! mo rí ẹṣin ràndánràndán kan, Ikú ni orúkọ ẹni tó jókòó sórí rẹ̀. Isà Òkú* sì ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí. A sì fún wọn ní àṣẹ lórí ìdá mẹ́rin ayé pé kí wọ́n fi idà gígùn, ìyàn,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti àwọn ẹran inú igbó pani.+
9 Nígbà tó ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí ọkàn*+ àwọn kan lábẹ́ pẹpẹ,+ àwọn tí wọ́n pa torí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti torí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́.+ 10 Wọ́n ké jáde pé: “Olúwa Ọba Aláṣẹ, ẹni mímọ́ àti olóòótọ́,+ títí di ìgbà wo lo fi máa dúró kí o tó ṣe ìdájọ́, kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára àwọn tó ń gbé ayé?”+ 11 A fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ funfun kan,+ a sì sọ fún wọn pé kí wọ́n sinmi fúngbà díẹ̀ sí i, títí iye àwọn ẹrú bíi tiwọn àti àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n máa tó pa bí wọ́n ṣe pa àwọn náà fi máa pé.+
12 Mo sì rí i nígbà tó ṣí èdìdì kẹfà, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀; oòrùn di dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀* tí a fi irun* ṣe, gbogbo òṣùpá dà bí ẹ̀jẹ̀,+ 13 àwọn ìràwọ̀ ọ̀run sì já bọ́ sí ayé, bí ìgbà tí atẹ́gùn líle mú kí èso igi ọ̀pọ̀tọ́ tí kò tíì pọ́n já bọ́. 14 Ọ̀run sì lọ bí àkájọ ìwé tí wọ́n ká,+ a sì mú kí gbogbo òkè àti gbogbo erékùṣù kúrò ní àyè wọn.+ 15 Lẹ́yìn náà, àwọn ọba ayé, àwọn aláṣẹ, àwọn ọ̀gágun, àwọn ọlọ́rọ̀, àwọn alágbára, gbogbo ẹrú àti gbogbo àwọn tó wà lómìnira fi ara wọn pa mọ́ sínú àwọn ihò àti sáàárín àwọn àpáta àwọn òkè.+ 16 Wọ́n sì ń sọ fún àwọn àpáta àti àwọn òkè náà pé: “Ẹ wó lù wá,+ kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò lójú Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́+ àti kúrò lọ́wọ́ ìbínú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,+ 17 torí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn ti dé,+ ta ló sì lè dúró?”+