Orí 126
“Dajudaju Ọmọkunrin Ọlọrun Ni Eyi”
JESU ko tii pẹ lori opo-igi nigba ti, ni ọjọ́kanrí, abàmì okunkun oni wakati mẹta kan ṣú. Imuṣokunkun oṣupa kọ ni ó fà á niwọn bi eyi ti maa nwaye kiki ni akoko oṣupa titun, oṣupa si ti yọ jade tan lakooko Irekọja. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìmúṣókùnkùn oṣupa kii pẹ ju iwọnba iṣẹju diẹ lọ. Nitori naa okunkun naa ní ipilẹṣẹ atọrunwa! O ṣeeṣe ki o pa awọn wọnni ti nfi Jesu ṣẹlẹya lẹnumọ fun ìgbà diẹ, ani ki o tilẹ dá ipẹgan wọn duro.
Bí àrà meriyiiri akojinnijinni bani naa ba ṣẹlẹ ṣaaju ki oluṣe buburu naa tó ba ẹlẹgbẹ rẹ wi ti o si bẹ Jesu lati ranti oun, o le jẹ ìdí fun ironupiwada rẹ. O ṣeeṣe ki o jẹ pe laaarin okunkun naa ni awọn obinrin mẹrin, ti wọn jẹ, iya Jesu ati Salome arabinrin rẹ, Maria Magidaleni, ati Maria iya apọsiteli Jakọbu Kekere, ti wa ọna de ìtòsí opo-igi idaloro naa. Johanu, apọsiteli aayo olufẹ Jesu, wà pẹlu wọn nibẹ.
Bawo ni ọkan iya Jesu ti ‘gbọgbẹ́’ tó bi oun ti nwo ọmọkunrin rẹ ti oun tọ́ ti oun si bọ́ dagba ti a gbe kọ́ ninu irora! Sibẹ, Jesu ko ronu nipa irora tirẹ funraarẹ, ṣugbọn nipa ipo alaafia iya rẹ. Pẹlu isapa nlanla, o mi ori si Johanu o si wi fun iya rẹ pe: “Ìyá, wòó! Ọmọkunrin rẹ!” Lẹhin naa, ni mimi ori siha Maria, o wi fun Johanu pe: “Wòó! Iya rẹ!”
Jesu tipa bayi fi itọju iya rẹ, ẹni ti o jẹ opó lọna ti o han gbangba nisinsinyi le apọsiteli rẹ ti oun nifẹẹ lọna akanṣe lọwọ. Oun ṣe eyi nitori pe awọn ọmọkunrin Maria miiran ko tii fi igbagbọ han ninu rẹ sibẹ. Oun tipa bayii fi apẹẹrẹ rere lelẹ ti ṣiṣe ipese kii ṣe kiki fun aini iya rẹ̀ nipa ti ara nikan ṣugbọn fun aini tẹmi rẹ̀ pẹlu.
Ni nǹkan bi agogo mẹta ọsan, Jesu wipe: “Oungbẹ ngbẹ mi.” Jesu nimọlara pe Baba rẹ ti, bii pe o ri bẹẹ nitootọ, fa ọwọ́ aabo sẹhin kuro lọdọ rẹ̀ ki a ba le dán iwatitọ rẹ̀ wò de gongo. Nitori naa o ke jade pẹlu ohùn rara pe: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eeṣe ti iwọ fi kọ mi silẹ?” Ni gbigbọ eyi awọn kan ti wọn duro nitosi kigbe soke pe: “Wòó! oun npe Elija.” Lọ́gán ọkan ninu wọn sare ó sì mu kàn-ìnkàn-ìn ti a ti rì bọnu ọti kikan ní ipẹkun pòròpórò hisopu kan, o fun un ni ohun mimu. Ṣugbọn awọn miiran wipe: “Ẹ jẹ ki o ku! Ẹ jẹ ki a ri boya Elija yoo wa lati sọ ọ kalẹ.”
Nigba ti Jesu gba ọti kikan naa, o kigbe jade pe: “O pari!” Bẹẹni, oun ti pari ohun gbogbo ti Baba rẹ ti ran an wa si ilẹ-aye lati ṣe. Nikẹhin, oun wipe: “Baba, ni ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le.” Jesu tipa bayi fi ipá iwalaaye rẹ̀ le Ọlọrun lọwọ pẹlu igbọkanle pe Ọlọrun yoo mú un pada bọsipo fun oun lẹẹkan sii. Lẹhin naa o tẹri ara rẹ ba o si ku.
Lakooko ti Jesu mi èémí rẹ ikẹhin, isẹlẹ buburu kan waye, ti o ṣi awọn apata ràbàtàràbàtà silẹ. Isẹlẹ naa lagbara tobẹẹ gẹẹ ti awọn iboji iranti lẹhin ode Jerusalẹmu fi fọ, ara awọn oku ni a si gbe sọ sita kuro ninu wọn. Awọn ti nkọja lọ, ti wọn ri awọn ara oku naa ti o wà ni gbangba, wọ inu ilu lọ wọn si rohin rẹ̀.
Siwaju sii pẹlu, ni akoko ti Jesu ku, ìkélé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ ti o pin ibi Mimọ kuro lara ibi Mimọ Julọ ninu tẹmpili Ọlọrun ni o faya si meji, lati oke delẹ. Yoo fẹrẹẹ jẹ pe, ìkélé ti a ṣe lọṣọọ daradara yi jẹ nǹkan bi ẹsẹ bata 60 lóòró o si wuwo gan-an! Kii ṣe kìkì pe àgbàyanu Iṣẹ-iyanu naa fi ibinu Ọlọrun han lodisi awọn ti o pa Ọmọkunrin Rẹ nikan ni, ṣugbọn o fihan pe wiwọle sinu ibi Mimọ Julọ naa, ọrun funraarẹ, ni a mu ki o ṣeeṣe nisinsinyi nipasẹ iku Jesu.
O dara, nigba ti awọn eniyan nimọlara isẹlẹ naa ti wọn si ri ohun ti nṣẹlẹ, ẹru ba wọn gidigidi. Ijoye oṣiṣẹ ti o wa nidii ifiya iku jẹni naa fi ogo fun Ọlọrun. “Dajudaju Ọmọkunrin Ọlọrun ni eyi,” ni oun polongo. O ṣeeṣe ki oun ti wa nibẹ nigba ti a jiroro jijẹ ọmọkunrin atọrunwa nibi igbẹjọ Jesu niwaju Pilatu. Nisinsinyi oun ni idaniloju pe Jesu ni Ọmọkunrin Ọlọrun, bẹẹni, pe oun nitootọ ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tíì gbe aye ri.
Awọn miiran pẹlu ni awọn iṣẹlẹ agbayanu wọnyi já láyà, wọn si bẹrẹsii pada si ile wọn ni lílu àyà wọn, gẹgẹ bi ifaraṣapejuwe ìbànújẹ́ ati ìtìjú mímúná. Ọpọlọpọ awọn obinrin ti wọn jẹ ọmọ-ẹhin Jesu ni a sun lọna jijinlẹ nipa awọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wọnyi bi wọn ti nkiyesi iran apewo yii lati okeere. Apọsiteli Johanu wà nibẹ pẹlu. Matiu 27:45-56, NW; Maaku 15:33-41; Luuku 23:44-49; 2:34, 35; Johanu 19:25-30.
▪ Eeṣe ti ìmúṣókùnkùn òṣùpá ko fi lè jẹ́ idi fun òkùnkùn oni wákàtí mẹta naa?
▪ Ní kete ṣaájú ikú rẹ̀, apẹẹrẹ rere wo ni Jesu pèsè fun awọn wọnni ti wọ́n ní awọn obi ọlọ́jọ́lórí?
▪ Ki ni awọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ mẹrin ti Jesu sọ kẹhin ṣaaju iku rẹ̀?
▪ Ki ni ìsẹ̀lẹ̀ naa ṣàṣeparí rẹ̀, ki si ni ìjẹ́pàtàkì ìkélé tẹmpili ti o fàya si meji?
▪ Bawo ni awọn iṣẹlẹ naa ṣe nípalórí ìjòyè òṣìṣẹ́ ti o wa nidii ìfìyà ikú jẹni naa?