Ìwé Kejì Pétérù
2 Àmọ́ o, àwọn wòlíì èké tún wà láàárín àwọn èèyàn náà, bí àwọn olùkọ́ èké ṣe máa wà láàárín ẹ̀yin náà.+ Àwọn yìí máa dọ́gbọ́n mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tó ń fa ìparun wọlé, wọ́n tiẹ̀ máa sẹ́ ẹni tó rà wọ́n pàápàá,+ wọ́n á sì mú ìparun wá sórí ara wọn ní kíákíá. 2 Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ máa hu ìwà àìnítìjú*+ bíi tiwọn, àwọn èèyàn sì máa sọ̀rọ̀ àbùkù sí ọ̀nà òtítọ́ nítorí wọn.+ 3 Bákan náà, torí wọ́n jẹ́ olójúkòkòrò, wọ́n máa fi àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn kó yín nífà. Àmọ́ ìdájọ́ wọn tí a ti ṣe tipẹ́tipẹ́+ ò falẹ̀, ìparun wọn ò sì ní yẹ̀.*+
4 Ó dájú pé Ọlọ́run kò fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ àwọn áńgẹ́lì tó ṣẹ̀,+ àmọ́ ó jù wọ́n sínú Tátárọ́sì,*+ ó fi wọ́n sí ìdè* òkùnkùn biribiri de ìdájọ́.+ 5 Kò sì fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ ayé ìgbàanì,+ àmọ́ ó dá ẹ̀mí Nóà, oníwàásù òdodo sí+ pẹ̀lú àwọn méje míì + nígbà tó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+ 6 Ó mú kí ìlú Sódómù àti Gòmórà jóná di eérú, ó tipa bẹ́ẹ̀ dá wọn lẹ́bi,+ ìyẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+ 7 Ó gba Lọ́ọ̀tì olódodo là,+ ẹni tó banú jẹ́ gidigidi nítorí ìwà àìnítìjú* àwọn arúfin èèyàn— 8 torí ojoojúmọ́ ni ọkùnrin olódodo yẹn ń mú kí ọkàn* rẹ̀ gbọgbẹ́ nítorí ohun tó rí àti ohun tó gbọ́ tí àwọn arúfin yẹn ń ṣe nígbà tó ń gbé láàárín wọn. 9 Torí náà, Jèhófà* mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò,+ síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ìparun* ní ọjọ́ ìdájọ́,+ 10 ní pàtàkì àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa sọ ẹran ara àwọn míì di aláìmọ́,+ tí wọn ò sì ka àwọn aláṣẹ sí.*+
Wọ́n gbójúgbóyà, wọ́n jẹ́ aṣetinú-ẹni, wọn ò sì bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo láìdáa, 11 bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn áńgẹ́lì, tí wọ́n tiẹ̀ ní okun àti agbára jù wọ́n lọ, kì í sọ̀rọ̀ àbùkù nípa wọn tí wọ́n bá ń fẹ̀sùn kàn wọ́n, torí wọ́n bọ̀wọ̀ fún* Jèhófà.*+ 12 Àmọ́ àwọn èèyàn yìí ń sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa àwọn ohun tí wọn ò mọ̀,+ wọ́n dà bí àwọn ẹranko tí kì í ronú, tí wọ́n kàn máa ń ṣe ohun tí a dá mọ́ wọn, wọ́n wà* ká lè mú wọn, ká sì pa wọ́n. Ọ̀nà ìparun tí wọ́n ń tọ̀ máa mú ìparun wá sórí wọn, 13 àwọn ìwà burúkú tí wọ́n ń hù sì máa kóyà jẹ wọ́n.
Kódà ní ojúmọmọ, wọ́n ka ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ sí ìgbádùn.+ Èérí àti àbààwọ́n ni wọ́n, wọ́n ń gbádùn* àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń tanni jẹ, bí wọ́n ṣe ń bá yín jẹ àsè.+ 14 Àgbèrè ló kún ojú wọn,+ wọn ò lè jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì ń tan àwọn* tí kò dúró ṣinṣin jẹ. Wọ́n ti fi ojúkòkòrò kọ́ ọkàn wọn. Ọmọ ègún ni wọ́n. 15 Wọ́n pa ọ̀nà tó tọ́ tì, a sì ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ṣe bíi ti Báláámù,+ ọmọ Béórì, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ èrè ìwà àìtọ́,+ 16 àmọ́ a bá a wí torí ó ṣe ohun tí kò tọ́.+ Ẹran akẹ́rù tí kò lè sọ̀rọ̀ tó sọ̀rọ̀ bí èèyàn, kò jẹ́ kí wòlíì náà ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.+
17 Wọ́n jẹ́ ìsun tí kò lómi àti ìkùukùu tí ìjì líle ń fẹ́ kiri, a sì ti fi òkùnkùn biribiri pa mọ́ dè wọ́n.+ 18 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tí kò nítumọ̀. Wọ́n ń fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara+ àti ìwà àìnítìjú* tan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń fi ẹ̀ṣẹ̀ ṣomi mu.+ 19 Wọ́n ń ṣèlérí òmìnira fún wọn, àmọ́ ẹrú ìwà ìbàjẹ́ làwọn fúnra wọn;+ torí ẹnikẹ́ni tí ẹlòmíì bá borí jẹ́ ẹrú ẹni tó borí rẹ̀.*+ 20 Ó dájú pé, lẹ́yìn tí ìmọ̀ tó péye nípa Jésù Kristi Olúwa àti Olùgbàlà bá ti mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbin ayé,+ tí wọ́n bá tún pa dà sí àwọn nǹkan yìí tó sì borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn ti burú ju ìbẹ̀rẹ̀ wọn.+ 21 Torí ì bá sàn kí wọ́n má mọ ọ̀nà òdodo lọ́nà tó péye ju pé lẹ́yìn tí wọ́n ti mọ̀ ọ́n kí wọ́n yí pa dà kúrò nínú àṣẹ mímọ́ tí wọ́n ti gbà.+ 22 Ohun tí òwe tòótọ́ náà sọ ti ṣẹlẹ̀ sí wọn: “Ajá ti pa dà sídìí èébì rẹ̀, abo ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀ ti ń yíra mọ́lẹ̀ nínú ẹrẹ̀.”+