Ẹ̀kọ́ 7
Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti máa gbàdúrà déédéé? (1)
Ta ni ó yẹ kí á gbàdúrà sí, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí á gbàdúrà? (2, 3)
Kí ni a lè gbàdúrà fún? (4)
Ìgbà wo ni ó yẹ kí o gbàdúrà? (5, 6)
Ọlọrun ha ń tẹ́tí sí gbogbo àdúrà bí? (7)
1. Àdúrà jẹ́ fífi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bá Ọlọrun sọ̀rọ̀. Ó yẹ kí o máa gbàdúrà sí Ọlọrun déédéé. Nípa báyìí, o lè sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan. Jehofa ga lọ́lá, ó sì jẹ́ alágbára, síbẹ̀, ó ń tẹ́tí sí àdúrà wa! Ìwọ́ ha máa ń gbàdúrà sí Ọlọrun déédéé bí?—Orin Dafidi 65:2; 1 Tessalonika 5:17.
2. Àdúrà jẹ́ apá kan ìjọsìn wa. Nípa báyìí, a ní láti gbàdúrà sí Jehofa Ọlọrun nìkan ṣoṣo. Nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀ ayé, ó máa ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe sí ẹlòmíràn. A gbọ́dọ̀ ṣe bákan náà. (Matteu 4:10; 6:9) Ṣùgbọ́n, a ní láti gba gbogbo àdúrà wa ní orúkọ Jesu. Èyí n fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ipò Jesu, a sì ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀.—Johannu 14:6; 1 Johannu 2:1, 2.
3. Nígbà tí a bá ń gbàdúrà, a ní láti bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ láti inú ọkàn wá. A kò ní láti gba àdúrà àkọ́sórí tàbí kà wọ́n jáde láti inú ìwé àdúrà. (Matteu 6:7, 8) A lè gbàdúrà ní ipò èyíkéyìí tí ó ní ọ̀wọ̀, ní ìgbàkigbà, àti ní ibikíbi. Ọlọrun lè gbọ́ àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tí a gbà sínú pàápàá. (1 Samueli 1:12, 13) Ó dára láti wá ibì kan tí ó dákẹ́ rọ́rọ́, níbi tí àwọn ènìyàn kò sí, láti gba àdúrà ìdákọ́ńkọ́.—Marku 1:35.
4. Kí ni o lè gbàdúrà fún? Ohunkóhun tí ó lè nípa lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ̀. (Filippi 4:6, 7) Àdúrà àwòṣe fi hàn pé a ní láti gbàdúrà nípa orúkọ àti ète Jehofa. A tún lè béèrè fún ìpèsè àwọn àìní wa nípa ti ara, fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti fún ìrànwọ́ láti dènà àdánwò. (Matteu 6:9-13) Àwọn àdúrà wa kò yẹ kí ó jẹ́ ti onímọtara-ẹni-nìkan. A ní láti gbàdúrà fún kìkì àwọn ohun tí ó bá ìfẹ́ Ọlọrun mu.—1 Johannu 5:14.
5. O lè gbàdúrà nígbàkigbà tí ọkàn rẹ bá sún ọ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tàbí láti yìn ín. (1 Kronika 29:10-13) Ó yẹ kí o gbàdúrà nígbà tí o bá ní ìṣòro, tí a sì ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò. (Orin Dafidi 55:22; 120:1) Ó bá a mu wẹ́kú láti gbàdúrà ṣáájú kí o tó jẹun. (Matteu 14:19) Jehofa ké sí wa láti gbàdúrà “ní gbogbo ìgbà.”—Efesu 6:18.
6. Ní pàtàkì, a ní láti gbàdúrà bí a bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, a ní láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú àti ìdáríjì Jehofa. Bí a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún un, tí a sì ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti má ṣe tún wọn dá, Ọlọrun “múra àti dárí jì.”—Orin Dafidi 86:5; Owe 28:13.
7. Àdúrà àwọn olódodo nìkan ni Jehofa ń tẹ́tí sí. Kí Ọlọrun lè gbọ́ àdúrà rẹ, o gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin rẹ̀. (Owe 15:29; 28:9) O gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tí o bá ń gbàdúrà. (Luku 18:9-14) O ní láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí o bá gbàdúrà fún. Nípa báyìí, ìwọ yóò fẹ̀rí hàn pé o ní ìgbàgbọ́, o sì ní ohun tí o sọ lọ́kàn. Kìkì nígbà náà ní Jehofa yóò tó dáhùn àdúrà rẹ.—Heberu 11:6.