Orí Kẹfà
Títú Àdììtú Igi Ńlá Náà
1. Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì Ọba, àwọn ìbéèrè wo sì ni èyí mú kí ó jẹyọ?
JÈHÓFÀ gba Nebukadinésárì Ọba láàyè láti di olùṣàkóso ayé. Gẹ́gẹ́ bí ọba Bábílónì, ó ní ọlá tí ó pọ̀ gidigidi, oúnjẹ tí ó yamùrá, ààfin tí ó fa kíki—ó ní gbogbo dúkìá tí ọkàn rẹ̀ fẹ́. Ṣùgbọ́n, lójijì, ìtẹ́lógo dé bá a. Orí Nebukadinésárì wá dàrú, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ẹranko! Bí a ṣe lé e kúrò nídìí tábìlì ọba àti kúrò ní ààfin, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbé inú pápá, ó sì ń jẹ koríko bí akọ màlúù. Kí ní fa àgbákò yìí? Èé sì ti ṣe tí ó fi yẹ kí ó kàn wá?—Fi wé Jóòbù 12:17-19; Oníwàásù 6:1, 2.
ỌBA FI ÒGO FÚN ẸNI GÍGA JÙ LỌ
2, 3. Kí ni ìfẹ́-ọkàn ọba Bábílónì fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀, irú ojú wo sì ni ó fi wo Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ náà?
2 Gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí orí Nebukadinésárì tí ó dàrú pátápátá padà bọ̀ sípò, ó fi ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ ọba rẹ̀. Jèhófà mí sí Dáníẹ́lì láti kọ àkọsílẹ̀ tí ó péye nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ó fi bẹ̀rẹ̀: “Nebukadinésárì Ọba, sí gbogbo ènìyàn, àwùjọ orílẹ̀-èdè àti èdè tí ń gbé ní gbogbo ilẹ̀ ayé: Kí àlàáfíà yín di púpọ̀. Ó dára lójú mi láti polongo àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ ti ṣe fún mi. Ẹ wo bí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ ti tóbi lọ́lá tó, ẹ sì wo bí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ ti jẹ́ alágbára ńlá tó! Ìjọba rẹ̀ jẹ́ ìjọba tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin, agbára ìṣàkóso rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.”—Dáníẹ́lì 4:1-3.
3 Àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba Nebukadinésárì “ń gbé ní gbogbo ilẹ̀ ayé”—níwọ̀n bí ilẹ̀ ọba rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí gbogbo apá ilẹ̀ ayé tí a kọ sínú Bíbélì. Ní ti Ọlọ́run Dáníẹ́lì, ọba sọ pé: “Ìjọba rẹ̀ jẹ́ ìjọba tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ẹ wo bí gbólóhùn náà ṣe gbé Jèhófà ga jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Bábílónì! Ní àfikún sí i, ìgbà kejì nìyí tí a ń fi hàn Nebukadinésárì pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó wà títí ayérayé, tí ó dúró “fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
4. Báwo ni “àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Nebukadinésárì?
4 Kí ni “àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ” ṣe? Ìrírí ọba fúnra rẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ wọn, ó sọ ọ́ ní gbólóhùn wọ̀nyí: “Ó ṣẹlẹ̀ pé, èmi Nebukadinésárì, wà ní ìdẹ̀rùn nínú ilé mi tí mo sì ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ààfin mi. Mo lá àlá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú mi fòyà. Àwọn àwòrán èrò orí sì ń bẹ lórí ibùsùn mi àti àwọn ìran orí mi tí ó bẹ̀rẹ̀ sí kó jìnnìjìnnì bá mi.” (Dáníẹ́lì 4:4, 5) Kí ni ọba Bábílónì ṣe nípa àlá adaniláàmú yìí?
5. Irú ojú wo ni Nebukadinésárì fi wo Dáníẹ́lì, èé sì ti ṣe?
5 Nebukadinésárì ké sí àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì, ó sì rọ́ àlá náà fún wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n kùnà pátápátá! Wọn kò lè pèsè ìtumọ̀ kankan rárá. Àkọsílẹ̀ náà fi kún un pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹliteṣásárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ ọlọ́run mi, ẹni tí ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́ sì wà nínú rẹ̀; wọlé wá síwájú mi, níwájú rẹ̀ ni mo sì rọ́ àlá náà.” (Dáníẹ́lì 4:6-8) Orúkọ tí wọ́n ń pe Dáníẹ́lì ní ààfin ni Bẹliteṣásárì, ó sì ṣeé ṣe kí èké ọlọ́run àjúbàfún tí ọba pè ní “ọlọ́run mi” jẹ́ yálà Bélì tàbí Nébò tàbí Mádọ́kì. Níwọ̀n bí Nebukadinésárì ti jẹ́ olùjọ́sìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọlọ́run, ó ka Dáníẹ́lì sí ẹnì kan tí “ẹ̀mí àwọn ọlọ́run mímọ́” wà nínú rẹ̀. Àti pé, nítorí ipò Dáníẹ́lì gẹ́gẹ́ bí olórí lórí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Bábílónì, ọba pè é ní “olórí àwọn àlùfáà pidánpidán.” (Dáníẹ́lì 2:48; 4:9; fi wé Dáníẹ́lì 1:20.) Dájúdájú, Dáníẹ́lì olùṣòtítọ́ kò fìgbà kan rí kọ ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ pidánpidán.—Léfítíkù 19:26; Diutarónómì 18:10-12.
IGI ARABARÌBÌ KAN
6, 7. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàpèjúwe ohun tí Nebukadinésárì rí nínú àlá rẹ̀?
6 Kí ní ń bẹ nínú ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ àlá ọba Bábílónì? Nebukadinésárì sọ pé: “Wàyí o, ìran orí mi lórí ibùsùn mi ni ó ṣẹlẹ̀ pé mo rí, sì wò ó! igi kan wà ní àárín ilẹ̀ ayé, tí gíga rẹ̀ jẹ́ arabarìbì. Igi náà dàgbà, ó sì di alágbára, níkẹyìn gíga rẹ̀ dé ọ̀run, a sì lè rí i ní ìkángun gbogbo ilẹ̀ ayé. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé rí gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́, èso rẹ̀ sì pọ̀ yanturu, oúnjẹ sì wà fún gbogbo gbòò lórí rẹ̀. Lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko inú pápá ti ń wá ibòji, àti lórí ẹ̀tun rẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ń gbé, láti ara rẹ̀ sì ni olúkúlùkù ẹran ara ti ń bọ́ ara rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 4:10-12) A ròyìn rẹ̀ pé Nebukadinésárì fẹ́ràn àwọn igi kédárì ńláńlá tí ó wà ní Lẹ́bánónì, ó lọ wò wọ́n, ó sì mú kí wọ́n kó díẹ̀ lára wọn wá sí Bábílónì láti fi ṣe gẹdú. Ṣùgbọ́n kò tí ì rí ohun tí ó jọ irú igi inú àlá rẹ̀ yìí rí. Ó wà ní ibi tí ó hàn ketekete kan “ní àárín ilẹ̀ ayé,” tí gbogbo ayé fi lè rí i, ó sì so èso púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi pèsè oúnjẹ fún gbogbo ẹran ara.
7 Àlá yẹn tún ní ohun tí ó ju èyí lọ nínú, nítorí pé Nebukadinésárì fi kún un pé: “Mo sì rí ní ìran orí mi lórí ibùsùn mi, sì wò ó! olùṣọ́ kan, àní ẹni mímọ́ kan, ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run gan-an. Ó ń ké kíkankíkan, ohun tí ó sì ń sọ nìyí: ‘Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì ké ẹ̀tun rẹ̀ kúrò. Ẹ gbọn àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé dànù, kí ẹ sì tú èso rẹ̀ ká. Kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, àti àwọn ẹyẹ kúrò lórí àwọn ẹ̀tun rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀, àní tòun ti ọ̀já irin àti bàbà, láàárín koríko pápá; sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run rin ín, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko láàárín ewéko ilẹ̀ ayé.’—Dáníẹ́lì 4:13-15.
8. Ta ni “olùṣọ́” náà?
8 Àwọn ará Bábílónì ní ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rere àti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú. Ṣùgbọ́n ta ni “olùṣọ́,” tàbí alóre, tí ó ti ọ̀run wá yìí? Níwọ̀n bí a ti pè é ní “ẹni mímọ́ kan,” áńgẹ́lì olódodo kan tí ó ń ṣojú fún Ọlọ́run ni. (Fi wé Sáàmù 103:20, 21.) Sáà fojú inú wo irú àwọn ìbéèrè tí yóò máa jà gùdù nínú Nebukadinésárì! Èé ṣe tí a fi fẹ́ gé igi yìí lulẹ̀? Ire wo ni ó wà lára gbòǹgbò ìdí rẹ̀ tí ọ̀já irin àti bàbà kò jẹ́ kí ó hù? Ní ti gidi, kí ni ète tí kùkùté kan lásán fẹ́ ṣiṣẹ́ fún?
9. Ní kúkúrú, kí ni olùṣọ́ náà sọ, àwọn ìbéèrè wo ni ó sì jẹyọ?
9 Ọ̀ràn náà ti ní láti dojú rú pátápátá fún Nebukadinésárì bí ó ṣe tún gbọ́ ọ̀rọ̀ tí olùṣọ́ náà sọ síwájú sí i pé: “Kí a yí ọkàn-àyà rẹ̀ padà kúrò ní ti aráyé, kí a sì fi ọkàn-àyà ẹranko fún un, kí ìgbà méje sì kọjá lórí rẹ̀. Nípa àṣẹ àgbékalẹ̀ àwọn olùṣọ́ ni ohun náà, nípa àsọjáde àwọn ẹni mímọ́ sì ni ìbéèrè náà, fún ète pé kí àwọn ènìyàn tí ó wà láàyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́, ni ó ń fi í fún, ó sì ń gbé àní ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé ka orí rẹ̀.” (Dáníẹ́lì 4:16, 17) Gbòǹgbò ìdí igi kò ní ọkàn-àyà ènìyàn tí ń lù kìkì nínú. Nígbà náà, báwo wá ni a ṣe lè gbé ọkàn-àyà ẹranko fún gbòǹgbò ìdí igi kan? Kí ni “ìgbà méje” náà? Báwo sí ni gbogbo ìwọ̀nyí ṣe kan ọ̀ràn ìṣàkóso nínú “ìjọba aráyé”? Ó dájú pé Nebukadinésárì fẹ́ mọ̀.
ỌBA GBA ÌRÒYÌN TÍ KÒ MÚ AYỌ̀ WÁ
10. (a) Lójú ìwòye Ìwé Mímọ́, kí ni igi lè ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni igi ńlá náà ṣàpẹẹrẹ?
10 Bí Dáníẹ́lì ṣe gbọ́ àlá náà, kàyéfì kọ́kọ́ bá a fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà ẹ̀rù bà á. Bí Nebukadinésárì ṣe rọ̀ ọ́ pé kí ó ṣàlàyé rẹ̀, wòlíì náà sọ pé: “Olúwa mi, kí àlá náà ṣẹ sí àwọn tí ó kórìíra rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ fún àwọn elénìní rẹ. Igi tí o rí, tí ó di ńlá tí ó sì di alágbára . . . , ìwọ ni, ọba, nítorí pé o ti di ẹni ńlá, o sì ti di alágbára, ìtóbilọ́lá rẹ ti di ńlá, ó sì ti dé ọ̀run, agbára ìṣàkóso rẹ sì ti dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.” (Dáníẹ́lì 4:18-22) Nínú Ìwé Mímọ́, igi lè ṣàpẹẹrẹ ẹnì kan, ọba kan, tàbí ìjọba kan. (Sáàmù 1:3; Jeremáyà 17:7, 8; Ìsíkíẹ́lì orí 31) Bí ti arabarìbì igi inú àlá rẹ̀, Nebukadinésárì “ti di ẹni ńlá, ó sì ti di alágbára” gẹ́gẹ́ bí orí agbára ayé kan. Ṣùgbọ́n “agbára ìṣàkóso . . . dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé,” tí ó kan ìjọba aráyé látòkè délẹ̀, ni igi ńlá náà ṣàpẹẹrẹ. Nígbà náà, ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà ni ó dúró fún, pàápàá, ní ti bí ó ṣe kan ilẹ̀ ayé.—Dáníẹ́lì 4:17.
11. Báwo ni àlá ọba ṣe fi hàn pé àyípadà tí ń rẹni nípò wálẹ̀ yóò bá ọba?
11 Àyípadà tí ń rẹni nípò wálẹ̀ kan máa tó dé bá Nebukadinésárì. Ní títọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Dáníẹ́lì sọ síwájú sí i pé: “Nítorí pé ọba rí olùṣọ́ kan, àní ẹni mímọ́ kan, tí ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run, tí ó sì wí pé: ‘Ẹ gé igi náà lulẹ̀, kí ẹ sì run ún. Àmọ́ ṣá o, ẹ fi gbòǹgbò ìdí rẹ̀ sílẹ̀ nínú ilẹ̀, ṣùgbọ́n tòun ti ọ̀já irin àti ti bàbà, láàárín koríko pápá, sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run rin ín, sì jẹ́ kí ìpín rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí rẹ̀,’ ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí, ọba, àṣẹ àgbékalẹ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ sì ni èyí tí yóò ṣẹlẹ̀ sí olúwa mi ọba.” (Dáníẹ́lì 4:23, 24) Dájúdájú, ó ń béèrè ìgboyà láti lè sọ ìhìn iṣẹ́ yìí fún ọba alágbára náà!
12. Kí ló fẹ́ dé bá Nebukadinésárì?
12 Kí ló fẹ́ dé bá Nebukadinésárì? Fojú inú wo ìṣesí rẹ̀ bí Dáníẹ́lì ṣe fi kún un pé: “Ìwọ ni wọn yóò sì lé lọ kúrò láàárín àwọn ènìyàn, ibùgbé rẹ yóò sì wá wà pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá, ewéko ni wọn yóò sì fún ọ jẹ gan-an bí akọ màlúù; ìrì ọ̀run yóò sì máa rin ọ́, ìgbà méje yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́ ni ó ń fi í fún.” (Dáníẹ́lì 4:25) Ní kedere, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin Nebukadinésárì pàápàá yóò ‘lé e lọ kúrò láàárín àwọn ènìyàn.’ Ṣùgbọ́n ṣe àwọn aláàánú olùṣọ́ agbo ẹran tàbí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò máa bójútó o ni? Rárá o, nítorí Ọlọ́run ti pàṣẹ pé kí Nebukadinésárì gbé láàárín “àwọn ẹranko inú pápá” kí ó máa jẹ ewéko.
13. Kí ni àlá igi náà fi hàn pé yóò ṣẹlẹ̀ sí ipò Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ayé?
13 Bí a ṣe gé igi yẹn lulẹ̀ gan-an ni a óò ṣe gba ipò ìṣàkóso ayé kúrò lọ́wọ́ Nebukadinésárì—ṣùgbọ́n fún àkókò kan ni. Dáníẹ́lì ṣàlàyé pé: “Nítorí tí wọ́n sọ pé kí wọ́n fi gbòǹgbò ìdí igi náà sílẹ̀, ó dájú pé ìjọba rẹ yóò jẹ́ tìrẹ lẹ́yìn tí o bá ti mọ̀ pé ọ̀run ní ń ṣàkóso.” (Dáníẹ́lì 4:26) Ní inú àlá Nebukadinésárì, a fi gbòǹgbò ìdí, tàbí kùkùté igi tí a gé lulẹ̀ náà sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi ọ̀já dè é kí ó má bàa hù. Lọ́nà kan náà, a óò fi “gbòǹgbò ìdí” ọba Bábílónì sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi ọ̀já wé e kí ó má bàa rúwé fún “ìgbà méje.” Ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ayé yóò dà bí gbòǹgbò ìdí igi tí a fi ọ̀já wé. A óò dáàbò bò ó títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí rẹ̀. Jèhófà yóò rí i dájú pé láàárín àkókò yẹn, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbapò Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo tí ń ṣàkóso Bábílónì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Efili-méródákì ọmọ rẹ̀ bá a ṣe àkóso gẹ́gẹ́ bí adelé.
14. Kí ni Dáníẹ́lì rọ Nebukadinésárì láti ṣe?
14 Lójú ìwòye ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa Nebukadinésárì, Dáníẹ́lì fi ìgboyà rọ̀ ọ́ pé: “Nítorí náà, ọba, kí ìmọ̀ràn mi dára lójú rẹ, kí o sì mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò nípa òdodo, kí o sì mú àìṣẹ̀tọ́ rẹ kúrò nípa fífi àánú hàn sí àwọn òtòṣì. Bóyá a óò mú aásìkí rẹ gùn sí i.” (Dáníẹ́lì 4:27) Bí Nebukadinésárì yóò bá yí padà kúrò nínú ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ìninilára àti ìgbéraga, bóyá èyí yóò mú kí ọ̀ràn rẹ̀ yí padà. Ó ṣe tán, ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì ṣáájú, Jèhófà ti pinnu láti pa àwọn ènìyàn Nínéfè olú ìlú Ásíríà run, ṣùgbọ́n kò wá ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí tí ọba ibẹ̀ àti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ronú pìwàdà. (Jónà 3:4, 10; Lúùkù 11:32) Nebukadinésárì agbéraga wá ńkọ́? Yóò ha yí àwọn ọ̀nà rẹ̀ padà bí?
ÌMÚṢẸ ÀKỌ́KỌ́ TI ÀLÁ NÁÀ
15. (a) Ìṣarasíhùwà wo ni Nebukadinésárì ń bá a lọ láti fi hàn? (b) Kí ni àwọn àkọsílẹ̀ fífín fi hàn nípa àwọn ìgbòkègbodò Nebukadinésárì?
15 Nebukadinésárì ń bá ìgbéraga rẹ̀ nìṣó. Bí ó ṣe ń rìn kiri lórí òrùlé ààfin rẹ̀ ní oṣù méjìlá lẹ́yìn tí ó lá àlá igi náà, ó yangàn pé: “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí, tí èmi fúnra mi fi okun agbára ńlá mi kọ́ fún ilé ọba àti fún iyì ọlá ọba tí ó jẹ́ tèmi?” (Dáníẹ́lì 4:28-30) Nímírọ́dù ni ó tẹ Bábílónì (Bábélì) dó, ṣùgbọ́n Nebukadinésárì ni ó sọ ọ́ di ìlú ọlọ́lá ńlá. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8-10) Nínú ọ̀kan nínú àkọsílẹ̀ tí ó fín, ó fọ́nnu pé: “Nebukadirésárì, Ọba Bábílónì, ẹni tí ó mú Esagílà àti Ésídà padà bọ̀ sípò, ọmọ Nabopolassar ni mí. . . . Mo mú odi Esagílà àti ti Bábílónì lágbára sí i, mo sì fìdí orúkọ ìjọba mi múlẹ̀ láéláé.” (Ìwé Archaeology and the Bible, láti ọwọ́ George A. Barton, 1949, ojú ìwé 478 àti 479) Àkọsílẹ̀ fífín mìíràn tọ́ka sí nǹkan bí ogún tẹ́ńpìlì tí ó tún ṣe tàbí tí ó tún kọ́. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Lábẹ́ àkóso Nebukadinésárì, Bábílónì di ọ̀kan nínú àwọn ìlú tí ó ní ọlá ńlá jù lọ ní ayé ìgbàanì. Nínú àkọsílẹ̀ tirẹ̀, ó ṣọ̀wọ́n kí ó tó mẹ́nu kan ìgbòkègbodò rẹ̀ ní ti ogun, ṣùgbọ́n ó kọ nípa àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tí ó ṣe, àti bí ó ṣe fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn àwọn ọlọ́run Bábílónì. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Nebukadinésárì ni ó kọ́ àwọn Ọgbà Àsorọ̀ ti Bábílónì, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ohun Ìyanu Méje ti Ayé Ìgbàanì.”
16. Báwo ni a óò ṣe tẹ́ Nebukadinésárì lógo láìpẹ́?
16 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Nebukadinésárì agbéraga ti fọ́nnu, a fẹ́rẹ̀ẹ́ tẹ́ ẹ lógo ná. Àkọsílẹ̀ onímìísí náà sọ pé: “Nígbà tí ọ̀rọ̀ náà ṣì wà lẹ́nu ọba, ohùn kan wá láti ọ̀run pé: ‘Nebukadinésárì Ọba, ìwọ ni a sọ fún pé, “Ìjọba náà gan-an ti lọ kúrò lọ́wọ́ rẹ, àní ìwọ ni wọn yóò lé kúrò láàárín àwọn ènìyàn, ibùgbé rẹ yóò sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá. Ewéko ni wọn yóò fún ọ jẹ gan-an bí akọ màlúù, ìgbà méje pàápàá yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́ ni ó ń fi í fún.”’”—Dáníẹ́lì 4:31, 32.
17. Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì agbéraga, inú ipò wo sì ni ó ti bá ara rẹ̀ láìpẹ́?
17 Kíákíá, iyè Nebukadinésárì bá rá mọ́ ọn nínú. Bí wọ́n ṣe lé e lọ kúrò láàárín aráyé, ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ewéko “gan-an bí akọ màlúù.” Lọ́hùn-ún, láàárín àwọn ẹranko inú pápá, ó dájú pé kì í ṣe pé yóò jókòó gbẹndẹ́kẹ sáàárín àwọn koríko ibi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí párádísè kan, kí ó sì máa gba afẹ́fẹ́ atunilára sára lójoojúmọ́. Ní Iraq òde òní, níbi tí àwókù Bábílónì wà, ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù ojú ọjọ́ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, máa ń ti orí ìwọ̀n tí ó ròkè tó àádọ́ta lórí òṣùwọ̀n ti Celsius, já lọ sí ìsàlẹ̀ òdo, tí í ṣe ìwọ̀n tí nǹkan fi ń dì, ní ìgbà òtútù. Láìrí ìtọ́jú, àti lábẹ́ ojú ọjọ́ tí kò fara rọ, ńṣe ni irun Nebukadinésárì tí ó gùn, tí ó sì ran pọ̀ mọ́ra, rí bí ìyẹ́ idì, èékánná ọwọ́ àti ti ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí a kò gé sì dá bí èékánná ẹsẹ̀ ẹyẹ. (Dáníẹ́lì 4:33) Ìtẹ́lógo ńlá gbáà ni èyí jẹ́ fún agbéraga olùṣàkóso ayé!
18. Nínú ìgbà méje náà, kí ní ṣẹlẹ̀ ní ti ọ̀ràn ìtẹ́ Bábílónì?
18 Nínú àlá Nebukadinésárì, a gé igi ńlá náà lulẹ̀, a sì fi ọ̀já de gbòǹgbò ìdí rẹ̀ kí ó má bàa hù fún ìgbà méje. Bákan náà, ‘a rẹ’ Nebukadinésárì “sílẹ̀ láti orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀” nígbà tí Jèhófà mú kí orí rẹ̀ dàrú. (Dáníẹ́lì 5:20) Nítorí náà, èyí yí ọkàn-àyà ọba padà kúrò ní ti ènìyàn sí ti akọ màlúù. Síbẹ̀, Ọlọ́run pa ìtẹ́ Nebukadinésárì mọ́ dè é títí ìgbà méje náà fi parí. Bí ó ti ṣeé ṣe kí Efili-méródákì wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adelé fún olórí ìjọba, Dáníẹ́lì jẹ́ “olùṣàkóso lórí gbogbo àgbègbè abẹ́ àṣẹ Bábílónì àti olórí pátápátá lórí gbogbo ọlọ́gbọ́n Bábílónì.” Àwọn Hébérù alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń bá a lọ láti nípìn-ín nínú bíbójútó ọ̀ràn àgbègbè náà. (Dáníẹ́lì 1:11-19; 2:48, 49; 3:30) Àwọn ìgbèkùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń retí ìgbà tí Nebukadinésárì yóò padà sórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba tí orí rẹ̀ ti pé padà, tí ó sì ti mọ̀ pé “Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé, ẹni tí ó bá sì fẹ́ ni ó ń fi í fún.”
ÌMÚBỌ̀SÍPÒ NEBUKADINÉSÁRÌ
19. Lẹ́yìn tí Jèhófà mú kí orí Nebukadinésárì pé padà, kí ni ọba Bábílónì náà wá tẹ́wọ́ gbà?
19 Jèhófà mú kí orí Nebukadinésárì pé padà ní òpin ìgbà méje náà. Ní títúúbá fún Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ, ọba sọ pé: “Ní òpin àwọn ọjọ́ náà, èmi Nebukadinésárì gbé ojú mi sókè ọ̀run, òye mi sì bẹ̀rẹ̀ sí padà sínú mi; mo sì fi ìbùkún fún Ẹni Gíga Jù Lọ fúnra rẹ̀, mo sì fi ìyìn àti ògo fún Ẹni tí ó wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí pé agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso fún àkókò tí ó lọ kánrin, ìjọba rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran. Gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé kò sì jámọ́ nǹkan kan, ó sì ń ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run àti àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé. Kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè dá a lọ́wọ́ dúró tàbí tí ó lè sọ fún un pé, ‘Kí ni o ti ń ṣe?’” (Dáníẹ́lì 4:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni, Nebukadinésárì wá mọ̀ lóòótọ́ pé Ẹni Gíga Jù Lọ ni Ọba Aláṣẹ Olùṣàkóso nínú ìjọba aráyé.
20, 21. (a) Báwo ni ìbáradọ́gba ṣe wà nínú títú tí a tú ọ̀já onírin náà kúrò lára gbòǹgbò ìdí igi inú àlá náà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì? (b) Kí ni Nebukadinésárì sọ láti fi túúbá, èyí ha sì sọ ọ́ di olùjọ́sìn Jèhófà bí?
20 Nígbà tí Nebukadinésárì padà sórí ìtẹ́ rẹ̀, ṣe ni ó dà bí pé a tú ọ̀já irin tí a fi de gbòǹgbò ìdí igi inú àlá náà. Ní ti ìmúbọ̀sípò rẹ̀, ó sọ pé: “Ní àkókò náà gan-an, òye mi bẹ̀rẹ̀ sí padà sínú mi, àti ní ti iyì ìjọba mi, ọlá ọba mi àti ìtànyòò mi, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí padà sára mi; àní àwọn olóyè mi onípò gíga àti àwọn ènìyàn mi jàǹkàn-jàǹkàn bẹ̀rẹ̀ sí fi ìháragàgà wá mi káàkiri, a sì fìdí mi múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i sórí ìjọba mi, a sì fi ìtóbi àrà ọ̀tọ̀ kún un fún mi.” (Dáníẹ́lì 4:36) Bí òṣìṣẹ́ ààfin kankan bá ti fìgbà kan tẹ́ńbẹ́lú ayírí ọba náà, ní báyìí, ńṣe ni wọ́n ‘ń fi ìháragàgà wá’ ojú rere rẹ̀.
21 Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ mà ṣe “àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” o! Kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé ọba Bábílónì tí a mú bọ̀ sípò náà sọ pé: “Nísinsìnyí, èmi Nebukadinésárì ń yin Ọba ọ̀run, mo ń gbé e ga, mo sì ń fi ògo fún un, nítorí òtítọ́ ni gbogbo iṣẹ́ rẹ̀, ìdájọ́ òdodo sì ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀, àti nítorí pé gbogbo àwọn tí ń rìn nínú ìgbéraga ni òun lè tẹ́ lógo.” (Dáníẹ́lì 4:2, 37) Pé Nebukadinésárì túúbá lọ́nà yìí kò mú kí ó di Kèfèrí olùjọ́sìn Jèhófà.
Ẹ̀RÍ ÌTÌLẸYÌN TÍ KÌ Í ṢE TI ÌSÌN HA WÀ BÍ?
22. Irú àrùn wo ni àwọn kan fi ìsínwín Nebukadinésárì wé, ṣùgbọ́n kí ni ó yẹ kí a mọ̀ ní ti okùnfà orí rẹ̀ tí ó dàrú?
22 Àwọn kan ti tọ́ka ìsínwín Nebukadinésárì gẹ́gẹ́ bí àrùn lycanthropy. Ìwé atúmọ̀ èdè ìṣègùn kan sọ pé: “Àrùn LYCANTHROPY . . . láti inú [lyʹkos], lupus, ìkookò; [anʹthro·pos], homo, ènìyàn. Orúkọ yìí ni a fi sọ àrùn àwọn ènìyàn tí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ti yí padà di ẹranko kan, tí wọ́n a sì máa dún tàbí kí wọ́n ké bí ẹranko yẹn, wọn a máa ṣàfarawé ìrísí àti ìṣesí rẹ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń wo ara wọn bí pé wọ́n para dà di ìkookò, ajá tàbí ológbò; nígbà mìíràn, wọ́n tún lè rò pé àwọn ti di akọ màlúù, bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì.” (Ìwé atúmọ̀ èdè ìṣègùn Dictionnaire des sciences médicales, par une société de médicins et de chirurgiens, Paris, 1818, Ìdìpọ̀ 29, ojú ìwé 246) Àwọn àmì àrùn lycanthropy jọ ti Nebukadinésárì nígbà tí ó sínwín. Àmọ́, níwọ̀n bí àrùn ọpọlọ tí ó ní ti jẹ́ nípa àṣẹ àtọ̀runwá, a kò lè so ó pọ̀ mọ́ àrùn pàtó kan tí a mọ̀.
23. Ẹ̀rí tí kì í ṣe ti ìsìn wo ni ó wà ní ti orí Nebukadinésárì tí ó dàrú?
23 Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ John E. Goldingay tọ́ka sí onírúurú àpẹẹrẹ tí ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìsínwín àti ìmúpadàbọ̀sípò Nebukadinésárì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Ó jọ pé gbólóhùn inú àfọ́kù àkọsílẹ̀ fífín kan tọ́ka pé Nebukadinésárì ní àrùn ọpọlọ kan, àti bóyá pé ó pa Bábílónì tì, pé ó sì lọ kúrò níbẹ̀.” Goldingay tọ́ka sí àkọsílẹ̀ kan tí wọ́n pè ní “Jóòbù ti Bábílónì,” ó sì sọ pé ó “jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run jẹ ẹ́ níyà, àìsàn kọlù ú, a tẹ́ ẹ lógo, ó ń wá ìtumọ̀ àlá tí ó kó jìnnìjìnnì bá a, pé a bì í wó bí igi, a gbé e síta, ó jẹ koríko, òye rẹ̀ pòórá, ó dà bí akọ màlúù, Mádọ́kì rọ òjò sí i lórí, èékánná rẹ̀ bàjẹ́, irun rẹ̀ kún, ó sì ran pọ̀ mọ́ra, àti pé a mú un bọ̀ sípò tí ó fi torí ìyẹn yín ọlọ́run lógo.”
ÌGBÀ MÉJE TÍ Ó KÀN WÁ
24. (a) Kí ni igi ńlá inú àlá yẹn dúró fún? (b) Kí ni a ṣèdíwọ́ fún títí di ìgbà méje, báwo sì ni ìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀?
24 Bí igi ńlá náà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rẹ̀, Nebukadinésárì ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso ayé. Ṣùgbọ́n rántí pé igi náà dúró fún ìṣàkóso àti ipò ọba aláṣẹ tí ó tóbi lọ́lá ju ti ọba Bábílónì lọ fíìfíì. Ó ṣàpẹẹrẹ ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà, “Ọba ọ̀run,” pàápàá ní ti bí ó ṣe kan ọ̀ràn ilẹ̀ ayé. Ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù láti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì, ìjọba tí ó fìdí kalẹ̀ sí ìlú ńlá náà, nínú èyí tí Dáfídì àti ìlà ọmọ rẹ̀ tí ń jọba ti jókòó sórí “ìtẹ́ Jèhófà,” ṣàpẹẹrẹ ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ayé. (1 Kíróníkà 29:23) Ọlọ́run fúnra rẹ̀ mú kí a gé ipò ọba aláṣẹ yẹn lulẹ̀ kí wọ́n sì fi ọ̀já dè é ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí ó lo Nebukadinésárì láti pa Jerúsálẹ́mù run. Fún ìgbà méje, a ṣèdíwọ́ fún lílò tí ìjọba ìlà Dáfídì ń lo ipò ọba aláṣẹ àtọ̀runwá lórí ilẹ̀ ayé. Báwo ni ìgbà méje yìí ṣe gùn tó? Ìgbà wo ni wọ́n bẹ̀rẹ̀, kì ni ó sì jẹ́ àmì pé wọ́n ti dópin?
25, 26. (a) Nínú ọ̀ràn Nebukadinésárì, báwo ni “ìgbà méje” náà ṣe gùn tó, èé sì ti ṣe tí o fi dáhùn bẹ́ẹ̀? (b) Nínú ìmúṣẹ pàtàkì náà, ìgbà wo àti báwo ni “ìgbà méje” náà ṣe bẹ̀rẹ̀?
25 Nígbà tí Nebukadinésárì fi ń sínwín, “irun rẹ̀ . . . gùn bí ti ìyẹ́ idì àti èékánná rẹ̀ bí èékánná ẹyẹ.” (Dáníẹ́lì 4:33) Èyí gba ìgbà tí ó gùn ju ọjọ́ méje tàbí ọ̀sẹ̀ méje lọ. Onírúurú ìtumọ̀ sọ pé “ìgbà méje,” àwọn tí a tún lò fún un ni “àkókò tí a yàn kalẹ̀ (ní pàtó)” tàbí “sáà àwọn àkókò.” (Dáníẹ́lì 4:16, 23, 25, 32) Kíkà mìíràn láti inú Bíbélì Old Greek (Septuagint) sọ pé “ọdún méje.” Júù òpìtàn ti ọ̀rúndún kìíní náà, Josephus, ka “ìgbà méje” yẹn bí “ọdún méje.” (Ìwé Antiquities of the Jews, Ìwé 10, Orí 10, ìpínrọ̀ 6) Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí ó jẹ́ Hébérù ka àwọn “ìgbà” yìí sí àwọn “ọdún.” “Ọdún méje” ni wọ́n lò nínú Bíbélì An American Translation, Today’s English Version, àti ìtumọ̀ ti James Moffatt.
26 Ní kedere, ọdún méje ni “ìgbà méje” Nebukadinésárì ní nínú. Nínú àsọtẹ́lẹ̀, ìpíndọ́gba ọdún kọ̀ọ̀kan jẹ́ òjìdín-nírínwó [360] ọjọ́, tàbí oṣù méjìlá tí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n ọjọ́. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 7:11–8:4; Ìṣípayá 12:6, 14.) Nítorí náà, “ìgbà méje,” tàbí ọdún méje ọba yẹn, jẹ́ òjìdín-nírínwó ọjọ́ lọ́nà méje, tàbí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún [2,520] ọjọ́. Ṣùgbọ́n ìmúṣẹ pàtàkì inú àlá rẹ̀ wá ńkọ́? “Ìgbà méje” alásọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ ìgbà tí ó gùn púpọ̀ ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọjọ́ lọ. Èyí ni a fi hàn láti inú ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò . . . tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi pé.” (Lúùkù 21:24) ‘Ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí a pa Jerúsálẹ́mù run, tí ìjọba Ọlọ́run àfiṣàpẹẹrẹ sì dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní Júdà. Ìgbà wo ni ìtẹ̀mọ́lẹ̀ náà yóò dópin? Ní “àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo,” nígbà tí ipò ọba aláṣẹ àtọ̀runwá yóò di èyí tí a tún bẹ̀rẹ̀ sí lò nínú ọ̀ràn ayé lẹ́ẹ̀kan sí i nípasẹ̀ Jerúsálẹ́mù ìṣàpẹẹrẹ, Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣe 3:21.
27. Èé ṣe tí o fi lè sọ pé “ìgbà méje” náà tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, kò dópin ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọjọ́ gidi lẹ́yìn náà?
27 Bí a bá ní kí a ka ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọjọ́ ní ti gidi, láti ìgbà ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ìyẹn yóò wulẹ̀ mú wa dé ọdún 600 ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì jẹ́ ọdún ti kò ní ìjẹ́pàtàkì kankan nínú Ìwé Mímọ́. Kódà ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àwọn Júù tí a fún ní òmìnira padà dé Júdà, a kò fi ipò ọba aláṣẹ Jèhófà hàn lórí ilẹ̀ ayé. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé a kò fi Serubábélì, tí ó jẹ́ ajogún tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìtẹ́ Dáfídì nígbà náà, jẹ ọba bí kò ṣe kìkì gómìnà ní Júdà tí ó jẹ́ ẹkùn ìpínlẹ̀ Páṣíà.
28. (a) Ìlànà wo ni a ní láti lò fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọjọ́ inú “ìgbà méje” alásọtẹ́lẹ̀ náà? (b) Báwo ni “ìgbà méje” alásọtẹ́lẹ̀ náà ṣe gùn tó, ọjọ́ wo ni ó sì sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ àti ìparí rẹ̀?
28 Níwọ̀n bí “ìgbà méje” náà ti jẹ́ ti alásọtẹ́lẹ̀, ìlànà Ìwé Mímọ́ tí a ní láti lò fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọjọ́ náà ni: “Ọjọ́ kan fún ọdún kan.” Èyí ni a là lẹ́sẹẹsẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa bí Bábílónì yóò ṣe gbógun ti Jerúsálẹ́mù. (Ìsíkíẹ́lì 4:6, 7; fi wé Númérì 14:34.) Nítorí náà, “ìgbà méje” tí àwọn agbára ayé ti àwọn Kèfèrí fi ṣàkóso ayé láìsí ìdásí láti ọ̀dọ̀ Ìjọba Ọlọ́run gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọdún. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìsọdahoro Júdà àti Jerúsálẹ́mù ní oṣù òṣùpá keje (Tishri 15) lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. (2 Àwọn Ọba 25:8, 9, 25, 26) Bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà yẹn títí dé ọdún 1 ṣááju Sànmánì Tiwa jẹ́ ẹgbẹ̀ta ọdún ó lé mẹ́fà. Lẹ́yìn èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá ọdún ó lé mẹ́rìnlá [1,914] yòókù bẹ̀rẹ̀, ó sì parí sí ọdún 1914 Sànmánì Tiwa. Nípa báyìí, “ìgbà méje” náà, tàbí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá ó lé ogún ọdún, dópin ní nǹkan bí Tishri 15, tàbí October 4 sí 5, 1914.
29. Ta ni “ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé,” kí sì ni Jèhófà ṣe láti gbé e gorí ìtẹ́?
29 Ní ọdún yẹn ni “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” pé, tí Ọlọ́run sì fi ìṣàkóso fún “ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé”—Jésù Kristi—ẹni tí àwọn elénìní rẹ̀ kà sí ẹni ìtẹ́ńbẹ́lú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi kàn án mọ́gi. (Dáníẹ́lì 4:17) Láti lè gbé Mèsáyà Ọba náà sórí ìtẹ́, Jèhófà tú ọ̀já irin àti bàbà ìṣàpẹẹrẹ náà kúrò lára “gbòǹgbò ìdí igi” ipò ọba aláṣẹ ti òun fúnra rẹ̀. Ọlọ́run, Ẹni Gíga Jù Lọ náà tipa báyìí gba “èèhù” ọba náà láàyè láti hù láti ara igi náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbà fi ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ hàn síhà ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run ní ọwọ́ Ajogún Dáfídì títóbi jù lọ, Jésù Kristi. (Aísáyà 11:1, 2; Jóòbù 14:7-9; Ìsíkíẹ́lì 21:27) A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o, fún àbájáde aláyọ̀ tí ọ̀ràn yìí wá ní, àti fún bí ó ṣe tú àdììtú igi ńlá náà!
KÍ LO LÓYE?
• Kí ni igi ńlá inú àlá Nebukadinésárì ṣàpẹẹrẹ?
• Kí ló dé bá Nebukadinésárì nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ àlá rẹ̀?
• Lẹ́yìn tí àlá rẹ̀ ṣẹ sí i lára, báwo ni Nebukadinésárì ṣe túúbá?
• Nínú ìmúṣẹ pàtàkì ti àlá igi alásọtẹ́lẹ̀ náà, báwo ni “ìgbà méje” náà ṣe gùn tó, ìgbà wo ni ó bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo ni ó sì dópin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 83]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 91]