Mímúra Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn Sílẹ̀
LỌ́SỌ̀Ọ̀SẸ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò àsọyé fún gbogbo ènìyàn, èyí tó máa ń dá lórí kókó kan látinú Ìwé Mímọ́. Bí o bá jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ǹjẹ́ o ti fi ẹ̀rí hàn pé o jẹ́ ẹni tó lè bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó múná dóko, ẹni tó mọ̀ bí a ṣe ń kọ́ni? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè dẹni tá a yàn láti sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti ṣèrànwọ́ fún ẹgbàágbèje arákùnrin láti dẹni tó tóótun láti rí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yìí gbà. Bí a bá yàn ọ́ láti wá sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀?
Fara Balẹ̀ Ka Ìwé Àsọyé Yẹn
Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí rárá, kọ́kọ́ ka ìwé àsọyé náà kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àṣàrò nípa rẹ̀ títí tí òye rẹ̀ á fi yé ọ. Fi ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé yẹn, ìyẹn àkòrí rẹ̀, sọ́kàn. Kí lo fẹ́ fi kọ́ àwùjọ? Kí lo fẹ́ kí wọ́n ṣe?
Mọ àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ pàtàkì ibẹ̀ dunjú. Gbé àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì wọ̀nyẹn yẹ̀ wò fínnífínní. Báwo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe wé mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn? Abẹ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì kọ̀ọ̀kan la to àwọn kókó ọ̀rọ̀ kéékèèké mélòó kan sí. Àwọn èrò tó ṣètìlẹyìn fún àwọn kókó ọ̀rọ̀ kéékèèké yìí la tò sísàlẹ̀ wọn. Ronú nípa bí ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan nínú ìwé àsọyé náà ṣe ń bọ́rọ̀ lọ látorí ọ̀rọ̀ tó ṣáájú ẹ̀, àti bí ó ṣe nasẹ̀ èyí tó tẹ̀ lé e, tó sì gbé ète àsọyé yẹn yọ kedere. Bí ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn bá sì ti wá yé ọ, tí o lóye ohun tí àsọyé yẹn ń fẹ́ kéèyàn mọ̀, tí o sì mọ bí àwọn kókó pàtàkì ibẹ̀ ṣe gbé nǹkan náà yọ, kó o bẹ̀rẹ̀ sí gbé àsọyé yẹn kalẹ̀ ló kù.
Lákọ̀ọ́kọ́, o lè ri pé á dára tó o bá wo àsọyé yẹn bí ọ̀rọ̀ ṣókí-ṣókí mẹ́rin tàbí márùn-ún, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ní kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan. Múra wọn sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.
Ìwé àsọyé tá a pèsè wà fún mímúra àsọyé sílẹ̀. Ìdí tá a sì fi tẹ̀ ẹ́ kì í kàn án ṣe pé kó o kàn máa ka ohun tó wà nínú rẹ̀ jáde. Ńṣe ló kàn dà bí egungun ara hangangan lásán. Ó yẹ kó o wá fi ẹran bò ó lọ́nà àpèjúwe, kó o sì sọ ọ́ di ààyè ọ̀rọ̀.
Lílo Ìwé Mímọ́
Orí Ìwé Mímọ́ ni Jésù Kristi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń gbé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni kà. (Lúùkù 4:16-21; 24:27; Ìṣe 17:2, 3) Ohun tó yẹ kí ìwọ náà ṣe nìyẹn. Ìwé Mímọ́ ni kó o gbé ọ̀rọ̀ rẹ kà. Dípò tí yóò fi jẹ́ pé kìkì ọ̀rọ̀ tá a sọ nínú ìwé àsọyé tá a pèsè ni wàá kàn máa ṣàlàyé tí wàá máa sọ ìlò rẹ̀, ronú jinlẹ̀ lórí bí Ìwé Mímọ́ ṣe ti ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lẹ́yìn, kí o sì wá lo Ìwé Mímọ́ yẹn láti fi kọ́ni.
Bí o ṣe ń múra ọ̀rọ̀ rẹ, yẹ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé àsọyé náà wò pátá. Kíyè sí ibi tí a ti lò ó nínú ọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ ìtàn pàtàkì tí ń bẹ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ kan làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yóò fi hàn. Kì í ṣe gbogbo wọn ló pọn dandan pé kó o kà tàbí pé kó o ṣàlàyé nígbà tó o bá ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Yan èyí tó bá àwọn olùgbọ́ rẹ mu jù lọ. Bí o bá pọkàn pọ̀ sórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ìwé àsọyé tọ́ka sí, ó ṣeé ṣe kó máà sídìí fún ọ láti tún lọ máa mú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn wọnú rẹ̀ ní àfikún.
Kì í ṣe bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o lò bá ṣe pọ̀ tó ni àsọyé rẹ yóò ṣe gbéṣẹ́ tó, bí kò ṣe kíkọ́ tó o bá kọ́ni lọ́nà tó múná dóko. Nígbà tó o bá fẹ́ nasẹ̀ Ìwé Mímọ́, sọ ìdí tí o fi fẹ́ lò ó. Lo àsìkò láti sọ bó ṣe jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Tó o bá ti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tán, má pa Bíbélì rẹ dé nígbà tó o bá ń ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Ó ṣeé ṣe kí àwùjọ má pa tiwọn dé bákan náà. Ọ̀nà wo lo máa gbà mú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wu àwọn olùgbọ́ rẹ láti kà, kí wọ́n sì túbọ̀ jàǹfààní kíkún nínú rẹ̀? (Neh. 8:8, 12) Nípa ṣíṣe àlàyé, nípa lílo àpèjúwe, àti nípa sísọ bí a ṣe lè fi sílò ni.
Ṣíṣe Àlàyé. Nígbà tó o bá fẹ́ ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì kan, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Kí ló túmọ̀ sí? Kí nìdí tí mo fi fẹ́ lò ó nínú ọ̀rọ̀ mi? Ìbéèrè wo ni àwọn tó wà nínú àwùjọ lè máa bi ara wọn nípa ẹsẹ yìí?’ Ó lè béèrè pé kó o ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yẹn ká fínnífínní, àti ìtàn ohun tó fà á, bí a ṣe gbé ọ̀rọ̀ yẹn kalẹ̀, bí ìlò ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe lágbára tó, àti iṣẹ́ tí òǹkọ̀wé onímìísí tó kọ ọ́ fẹ́ fi jẹ́. Èyí gba ìwádìí. Wàá rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni oníyebíye nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè. (Mát. 24:45-47) Má ṣe gbìyànjú láti ṣàlàyé gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ẹsẹ yẹn pátá, àmọ́ ṣàlàyé ìdí tó o fi ní kí àwùjọ kà á nígbà tó o bọ́rọ̀ dórí kókó tí ò ń ṣàlàyé.
Lílo Àpèjúwe. Ohun tí àwọn àpèjúwe wà fún ni láti mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ ní òye tó túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, tàbí kí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rántí kókó kan tàbí ìlànà kan tí o sọ̀rọ̀ lé lórí. Àpèjúwe máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye ohun tó o bá wọn sọ, kí wọ́n sì so ó mọ́ ohun tí wọ́n ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn nígbà tó ń ṣe Ìwàásù olókìkí tó ṣe lórí Òkè. Àwọn gbólóhùn bí “àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run,” “àwọn òdòdó lílì pápá,” “ẹnubodè tóóró,” ‘ilé orí àpáta ràbàtà’ àti ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbé kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ, ó mú kó ṣe kedere, ó sì mú kó má ṣeé gbàgbé.—Mát., orí 5 sí 7.
Sísọ Bí A Ṣe Máa Fi Ọ̀rọ̀ Sílò. Òótọ́ ni pé ṣíṣe àlàyé àti lílo àpèjúwe láti fi ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yóò fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀, síbẹ̀, lílo ìmọ̀ yẹn ni yóò mú àṣeyọrí wá. Lóòótọ́, ojúṣe àwọn olùgbọ́ rẹ ló jẹ́ láti fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tí wọ́n gbọ́ sílò, ṣùgbọ́n o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Bó bá sì ti dá ọ lójú pé àwùjọ lóye ẹsẹ tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí wàyí, tí wọ́n sì rí bó ṣe kan kókó tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí, lo àkókò tí ó tó láti ṣàlàyé bí ó ṣe kan ìgbàgbọ́ àti ìwà híhù ẹni. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní tí ń bẹ nínú yíyàgò pátápátá fún àwọn èrò tàbí ìwà tó lòdì, tí kò bá òtítọ́ tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu.
Bí o ṣe ń ronú nípa ọ̀nà tó o máa gbà ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, máa rántí pé onírúurú ibi làwọn èèyàn inú àwùjọ rẹ ti wá, àti pé ipò tó dojú kọ kálukú yàtọ̀ síra gan-an. Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn, àwọn ọ̀dọ́, àwọn àgbàlagbà, àtàwọn tí wọ́n ní onírúurú ìṣòro lè wà nínú àwùjọ náà. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣeé mú lò kí ó sì jẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé. Yàgò fún sísọ ìmọ̀ràn tó bá máa dà bíi pé kìkì àwọn mélòó kan ní pàtó lò ń fi ọ̀rọ̀ yẹn bá wí.
Àwọn Ìpinnu Tí Alásọyé Yóò Ṣe
Àwọn ìpinnu kan wà nípa àsọyé rẹ tá a ti ṣe fún ọ. A ti fi àwọn kókó pàtàkì inú rẹ̀ hàn kedere, a sì ti fi iye àkókò tó yẹ kó o lò láti fi sọ̀rọ̀ lórí ìsọ̀rí pàtàkì kọ̀ọ̀kan hàn kedere. Ọwọ́ rẹ ni àwọn ìpinnu yòókù kù sí. O lè yàn láti lo àkókò púpọ̀ lórí àwọn kókó kéékèèké kan, kí o má sì lò tó bẹ́ẹ̀ lórí àwọn mìíràn. Má ṣe rò pé dandan ni kó o kárí gbogbo kókó kéékèèké ibẹ̀ dọ́gba-dọ́gba. Ìyẹn lè mú kó o wá máa sáré sọ̀rọ̀, kí o sì pin àwùjọ lẹ́mìí. Báwo ni wàá ṣe mọ èyí tó yẹ kó o túbọ̀ ṣàlàyé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àti èyí tó o kàn máa mẹ́nu kàn ní ṣókí, tàbí èyí tó o kàn máa yán fẹ́rẹ́? Ńṣe ni kí o bí ara rẹ léèrè pé: ‘Àwọn kókó wo ni yóò ràn mí lọ́wọ́ láti lè gbé lájorí èrò àsọyé yìí yọ? Àwọn wo ló ní ohun tó máa ṣe àwọn olùgbọ́ mi láǹfààní jù lọ? Ṣé bí mo bá fo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n kàn tọ́ka sí àti kókó tó jẹ mọ́ ọn, ṣé kò ní dín agbára ẹ̀rí tó ti ọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn kù?’
Sa gbogbo ipá rẹ láti rí i pé o yẹra fún mímú ìméfò tàbí èrò tara ẹni wọnú àsọyé. Kódà Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run yẹra fún sísọ̀rọ̀ ‘látinú àpilẹ̀ṣe ti ara rẹ̀.’ (Jòh. 14:10) Mọ̀ dájú pé ìdí tí àwọn èèyàn fi ń wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ sọ látinú Bíbélì. Bí o bá dẹni tí a kà sí ògbóṣáṣá asọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé ńṣe ló ti mọ́ ọ lára pé kí o máa pe àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, dípò sí ara rẹ. Ìyẹn la fi mọrírì àwọn àsọyé rẹ.—Fílí. 1:10, 11.
Nígbà tó o ti wá sọ ìwé àsọyé tó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ nìkan di ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí Ìwé Mímọ́ tán, ohun tó kàn ni kó o wá fi àsọyé náà dánra wò. Ó ṣàǹfààní láti sọ̀rọ̀ síta nígbà téèyàn bá ń fi dánra wò. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí o rí i dájú pé o mọ gbogbo kókó inú rẹ̀ dáadáa lọ́kàn rẹ. O gbọ́dọ̀ lè fi tọkàntọkàn sọ̀rọ̀ rẹ, kó o sọ ọ́ lọ́nà tó tani jí, kí o sì fi ìtara sọ̀rọ̀ òtítọ́ jáde. Kí o tó sọ ọ̀rọ̀ rẹ, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Kí ni mo fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi sún àwọn èèyàn láti ṣe?’ Tún béère pe: ‘Ǹjẹ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì ibẹ̀ ṣe kedere? Ǹjẹ́ mo gbé ọ̀rọ̀ mi karí Ìwé Mímọ́ ní tòótọ́? Ṣé kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì kọ̀ọ̀kan so pọ̀ mọ́ èyí tó tẹ̀ lé e bó ṣe yẹ kó rí? Ǹjẹ́ àsọyé yìí mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọyì Jèhófà àti àwọn ìpèsè rẹ̀ bí? Ǹjẹ́ ìparí ọ̀rọ̀ mi wé mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ mi ní tààràtà, kí ó fi ohun tó yẹ kí àwùjọ ṣe hàn, kí ó sì sún wọn láti ṣe é?’ Bó o bá lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè wọ̀nyí, a jẹ́ pé o wà nípò tó o fi lè “lo ìmọ̀ lọ́nà rere,” tí ìjọ yóò fi lè jàǹfààní, tí yóò sì yin Jèhófà lógo!—Òwe 15:2.