ORÍ 9
“Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ojúsàájú”
Àwọn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fún àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́
Ó dá lórí Ìṣe 10:1–11:30
1-3. Ìran wo ni Pétérù rí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká lóye ohun tí ìran náà túmọ̀ sí?
NÍ ỌDÚN 36 Sànmánì Kristẹni, Pétérù wà nílùú Jópà. Ó ti ṣe díẹ̀ báyìí tí wọ́n ti gbà á lálejò nínú ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Símónì. Ìtòsí èbúté ìlú náà ni Símónì ń gbé, iṣẹ́ awọ ló sì ń ṣe. Àwọn Júù ò nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ awọ, kódà wọn ò ní fẹ́ dúró nílé irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Pétérù gbà láti dúró nílé ọkùnrin náà.a Jèhófà fẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé òun kì í ṣe ojúsàájú. Torí náà, lọ́sàn-án ọjọ́ kan, nígbà tí Pétérù lọ gbàdúrà ní òrùlé ilé Símónì, Jèhófà kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan.
2 Bí Pétérù ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́, Ọlọ́run fi ìran kan hàn án. Kò sí Júù kan tó máa rí irú ìran bẹ́ẹ̀ tí ò ní yà á lẹ́nu. Ó rí aṣọ ńlá kan tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, oríṣiríṣi ẹran tí Òfin kà léèwọ̀ sì wà nínú rẹ̀. Ohùn kan sọ fún Pétérù pé kó máa pa àwọn ẹran náà kó sì máa jẹ wọ́n. Àmọ́, Pétérù dáhùn pé: “Mi ò jẹ ohunkóhun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ rí.” Ohùn náà wá sọ fún un nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé: “Yéé pe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” (Ìṣe 10:14-16) Ìran náà tojú sú Pétérù, àmọ́ fúngbà díẹ̀ ni.
3 Kí ni ìtúmọ̀ ìran tí Pétérù rí yìí? Ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tí ìran náà túmọ̀ sí, torí pé ó máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn. Ó ṣe tán, káwa Kristẹni tó lè jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn wò wọ́n. Ká lè lóye ìràn tí Pétérù rí yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan àgbàyanu tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn tí Pétérù rí ìran náà.
Ó Ń “Rawọ́ Ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run Nígbà Gbogbo” (Ìṣe 10:1-8)
4, 5. Ta ni Kọ̀nílíù, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tó ń gbàdúrà?
4 Pétérù ò mọ̀ pé lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tóun rí ìran yẹn, Ọlọ́run ti fi ìran kan han ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kọ̀nílíù, ní Kesaríà tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta (50) kìlómítà sí àríwá. Ọ̀gá ọmọ ogun Róòmù ni Kọ̀nílíù, ó sì tún jẹ́ “onífọkànsìn.”b Ó ń bójú tó ìdílé rẹ̀ bó ṣe yẹ, torí Bíbélì sọ pé ẹni tó “bẹ̀rù Ọlọ́run ni òun àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.” Kọ̀nílíù kì í ṣe aláwọ̀ṣe Júù, Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ ni. Síbẹ̀, ó máa ń ṣàánú àwọn Júù tó jẹ́ aláìní, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tara. Ká sòótọ́, ọkùnrin yìí lọ́kàn tó dáa, ó sì máa “ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo.”—Ìṣe 10:2.
5 Ní nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán, Kọ̀nílíù ń gbàdúrà, áńgẹ́lì kan sì sọ fún un nínú ìran pé: “Àwọn àdúrà àti àwọn ọrẹ àánú rẹ ti dé iwájú Ọlọ́run, ó sì ti mú kó rántí rẹ.” (Ìṣe 10:4) Áńgẹ́lì náà sọ fún Kọ̀nílíù pé kó ránṣẹ́ lọ pe àpọ́sítélì Pétérù. Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan máa ṣẹlẹ̀ sí Kọ̀nílíù láìpẹ́, òun sì ni Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tírú ẹ̀ máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ sí. Ó máa tó gbọ́ ìhìn rere táá jẹ́ kó rí ìgbàlà.
6, 7. (a) Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dáhùn àdúrà àwọn tó lọ́kàn rere tí wọ́n sì fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa rẹ̀. (b) Ohun méjì wo la rí kọ́ látinú irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀?
6 Lónìí ńkọ́, ṣé Ọlọ́run máa ń dáhùn àdúrà àwọn tó bá lọ́kàn rere tí wọ́n sì fẹ́ mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìrírí kan rèé: Ní Alibéníà, obìnrin kan gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan tó ní àpilẹ̀kọ tó dá lórí ọmọ títọ́.c Ó sọ fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wàásù fún un pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ńṣe ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà tán pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ bí màá ṣe tọ́ àwọn ọmọbìnrin mi? Ọlọ́run ló rán ẹ wá! Ohun tí mo nílò gan-an lo wá fún mi!” Bí obìnrin náà àtàwọn ọmọbìnrin ẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn, nígbà tó yá ọkọ ẹ̀ náà dara pọ̀ mọ́ wọn.
7 Léraléra là ń rí irú ìrírí bí èyí karí ayé. Torí náà, a ò lè sọ pé ńṣe ló ń ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Ohun méjì la lè rí kọ́ látinú àwọn ìrírí náà. Àkọ́kọ́, ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn wá a. (1 Ọba 8:41-43; Sm. 65:2) Èkejì ni pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà.—Ìfi. 14:6, 7.
“Pétérù . . . Ń Ṣe Kàyéfì” (Ìṣe 10:9-23a)
8, 9. Kí ni ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ kí Pétérù mọ̀, kí ni Pétérù sì ṣe?
8 Orí òrùlé ni Pétérù ṣì wà, tó “ń ṣe kàyéfì” nípa ohun tí ìran tó rí túmọ̀ sí nígbà táwọn ọkùnrin tí Kọ̀nílíù rán sí i dé. (Ìṣe 10:17) Ìgbà mẹ́tà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù ti sọ pé òun ò lè jẹ oúnjẹ tí Òfin pè ní aláìmọ́, ṣé ó máa wá gbà láti tẹ̀ lé àwọn ọkùnrin yìí wọnú ilé Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí? Ẹ̀mí mímọ́ ti jẹ́ kí Pétérù mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀mí mímọ́ sọ fún Pétérù pé: “Wò ó! Àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń béèrè rẹ. Torí náà, dìde, sọ̀ kalẹ̀, kí o sì bá wọn lọ, má ṣiyèméjì rárá, nítorí èmi ni mo rán wọn wá.” (Ìṣe 10:19, 20) Ó dájú pé ìran tí Pétérù rí ti jẹ́ kó múra tán láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe.
9 Ní báyìí tí Pétérù ti rí i pé Ọlọ́run ló ní kí Kọ̀nílíù rán àwọn ọkùnrin náà sóun, Pétérù ní kí wọ́n wọlé, “ó sì gbà wọ́n lálejò.” (Ìṣe 10:23a) Bí Pétérù ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í yí èrò ẹ̀ pa dà nìyẹn, tó sì ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́!
10. Báwo ni Jèhófà ṣe ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
10 Títí di àsìkò wa yìí, díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ mọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe. (Òwe 4:18) Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ darí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mát. 24:45) Nígbà míì, a lè ní òye tuntun nípa ohun kan nínú Bíbélì tàbí kí àyípadà bá ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan nínú ètò Ọlọ́run. Ó máa dáa ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń fara mọ́ irú àtúnṣe tàbí àyípadà bẹ́ẹ̀? Ṣé ibi tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá darí ètò rẹ̀ sí ni mo máa ń fẹ́ láti gbà?’
Pétérù “Pàṣẹ Pé Kí A Batisí Wọn” (Ìṣe 10:23b-48)
11, 12. Kí ni Pétérù ṣe nígbà tó dé Kesaríà, kí ló sì ti wá yé e báyìí?
11 Ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tí Pétérù rí ìran yìí, ó lọ sí Kesaríà pẹ̀lú àwọn mẹ́sàn-án míì, ìyẹn àwọn mẹ́ta tí Kọ̀nílíù rán sí i àtàwọn “arákùnrin mẹ́fà [tí wọ́n jẹ́ Júù],” tí wọ́n sì wá láti Jópà. (Ìṣe 11:12) Kọ̀nílíù ti ń retí Pétérù, torí náà ó kó “àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.” Ó jọ pé Kèfèrí bíi tiẹ̀ ni gbogbo àwọn tó kó jọ náà. (Ìṣe 10:24) Nígbà tí Pétérù débẹ̀, ó ṣe ohun tí kò lérò pé òun lè ṣe. Ó wọ ilé Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́! Ó wá sọ pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ dáadáa pé kò bófin mu rárá fún Júù láti dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ ẹ̀yà míì tàbí kó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ Ọlọ́run fi hàn mí pé kí n má ṣe pe èèyàn kankan ní ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́.” (Ìṣe 10:28) Ní báyìí, Pétérù ti fòye mọ̀ pé ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ kọ́ òun látinú ìran tóun rí kò mọ sórí irú àwọn oúnjẹ tó yẹ kéèyàn máa jẹ́. Ó rí i pé kò yẹ kóun máa “pe èèyàn kankan [títí kan àwọn Kèfèrí] ní ẹlẹ́gbin.”
12 Ara àwọn tó ń dúró de Pétérù ti wà lọ́nà láti gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ. Kọ̀nílíù sọ pé: “Gbogbo wa wà níwájú Ọlọ́run láti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà ti pàṣẹ pé kí o sọ.” (Ìṣe 10:33) Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ ná tí ẹnì kan tó o fẹ́ wàásù fún bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí fún ẹ? Ohun pàtàkì tí Pétérù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìyí, ó sọ pé: “Ní báyìí, ó ti wá yé mi dáadáa pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ìṣe 10:34, 35) Ó ti wá yé Pétérù báyìí pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn èèyàn ò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè, àtàwọn nǹkan míì bí ìrísí tàbí ipò wọn láwùjọ. Pétérù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó wàásù fáwọn èèyàn náà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀.
13, 14. (a) Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa bí Kọ̀nílíù àtàwọn Kèfèrí míì ṣe di Kristẹni lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni? (b) Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ torí ìrísí wọn tàbí ipò wọn láwùjọ?
13 Lẹ́yìn náà, ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀. “Nígbà tí Pétérù ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́,” Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí “àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.” (Ìṣe 10:44, 45) Èyí ni ìgbà kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí àwọn èèyàn kí wọ́n tó ṣèrìbọmi. Pétérù rí èyí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Torí náà, Pétérù “pàṣẹ pé kí a batisí [àwùjọ àwọn Kèfèrí náà].” (Ìṣe 10:48) Báwọn Kèfèrí yìí ṣe yí pa dà lọ́dún 36 Sànmánì Kristẹni ló fòpin sí àkókò tí Ọlọ́run fi ń ṣojúure sáwọn Júù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Dán. 9:24-27) Pétérù ló múpò iwájú láti jẹ́rìí fún wọn lọ́jọ́ yẹn, torí náà ọjọ́ yẹn ló lo kọ́kọ́rọ́ kẹta tó kẹ́yìn lára àwọn “kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run.” (Mat. 16:19) Kọ́kọ́rọ́ yìí fún àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ láǹfààní láti di Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn.
14 Bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí, a mọ̀ pé “kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (Róòmù 2:11) Ìfẹ́ rẹ̀ ni pé ká “gba onírúurú èèyàn là.” (1 Tím. 2:4) Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ nítorí ìrísí wọn tàbí ipò wọn láwùjọ. Àṣẹ tí Jésù pa fún wa ni pé ká jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó túmọ̀ sí pé ká wàásù fún gbogbo èèyàn, láìka ìran, orílẹ̀-èdè, ìrísí, tàbí ẹ̀sìn wọn sí.
“Wọn Ò Ta Kò Ó Mọ́, Wọ́n sì Yin Ọlọ́run Lógo” (Ìṣe 11:1-18)
15, 16. Kí nìdí táwọn Júù kan tó jẹ́ Kristẹni fi ń ṣàríwísí Pétérù, báwo ló sì ṣe ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kèfèrí?
15 Ó dájú pé ara Pétérù ti wà lọ́nà láti ròyìn ohun tójú ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí, torí náà ó gbéra, ó sì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, ó dà bíi pé kó tó débẹ̀, wọ́n ti gbọ́ pé àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ náà ti “gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Kò sì pẹ́ tí Pétérù débẹ̀ tí “àwọn tó ń ti ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ lẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí rẹ̀.” Wọ́n ń bínú sí Pétérù torí pé ó wọnú “ilé àwọn tí kò dádọ̀dọ́, [ó] sì bá wọn jẹun.” (Ìṣe 11:1-3) Kì í ṣe báwọn Kèfèrí ṣe di ọmọlẹ́yìn Kristi ló ń múnú bí àwọn Júù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn náà. Àmọ́, ohun tí wọ́n ń tẹnu mọ́ ni pé àwọn Kèfèrí yẹn gbọ́dọ̀ máa pa Òfin mọ́, títí kan ìdádọ̀dọ́, kí Jèhófà tó lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Kò rọrùn fáwọn Júù yìí láti gbà pé kò pọn dandan káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́.
16 Báwo ni Pétérù ṣe ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀? Bó ṣe wà ní Ìṣe 11:4-16, ó ṣàlàyé ohun mẹ́rin tó jẹ́ kó mọ̀ pé ọwọ́ Ọlọ́run wà nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kèfèrí: (1) ìran tí Ọlọ́run fi hàn án (Ẹsẹ 4 sí 10); (2) àṣẹ tí ẹ̀mí mímọ́ pa fún un (Ẹsẹ 11, 12); (3) bí áńgẹ́lì ṣe lọ sọ́dọ̀ Kọ̀nílíù (Ẹsẹ 13, 14); àti (4) bí Ọlọ́run ṣe tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn Kèfèrí. (Ẹsẹ 15, 16) Pétérù wá fi ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Torí náà, tí Ọlọ́run bá fún wọn [àwọn Kèfèrí tó di onígbàgbọ́] ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ [ẹ̀mí mímọ́] kan náà tí ó fún àwa [Júù] tí a ti gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí màá fi dí Ọlọ́run lọ́wọ́?”—Ìṣe 11:17.
17, 18. (a) Ìpinnu pàtàkì wo ni ohun tí Pétérù sọ nípa àwọn Kèfèrí mú kó pọn dandan fáwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni láti ṣe? (b) Kí ló lè mú kó nira láti wà níṣọ̀kan nínú ìjọ, àwọn ìbéèrè wo ló sì dáa ká bi ara wa?
17 Ohun tí Pétérù sọ mú kó pọn dandan fáwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni yẹn láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan. Ṣó máa ṣeé ṣe fún wọn láti pa ẹ̀tanú tì, kí wọ́n sì gba àwọn Kèfèrí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi náà gẹ́gẹ́ bí arákùnrin àti arábìnrin wọn? Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Nígbà tí wọ́n [àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Júù yòókù tó jẹ́ Kristẹni] gbọ́ àwọn nǹkan yìí, wọn ò ta kò ó mọ́, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé: ‘Tóò, Ọlọ́run ti fún àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè láǹfààní láti ronú pìwà dà kí àwọn náà lè ní ìyè.’ ” (Ìṣe 11:18) Torí pé àwọn ará yẹn yí èrò wọn pa dà, ìjọ ń bá a lọ láti wà níṣọ̀kan.
18 Ó lè má rọrùn fáwọn olùjọsìn tòótọ́ láti wà níṣọ̀kan lóde òní, torí pé inú “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n” ni wọ́n ti wá. (Ìfi. 7:9) Nínú ọ̀pọ̀ ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń rí onírúurú èèyàn tí ẹ̀yà, àṣà àti ibi tí wọ́n gbé dàgbà yàtọ̀ síra. Torí náà, á dáa ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kò sí ẹ̀tanú kankan lọ́kàn mi mọ́? Ṣé mo ti pinnu pé mi ò ní jẹ́ kí àwọn ohun tó ń fa ìpínyà nínú ayé yìí, ìyẹn ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìgbéraga nítorí àṣà tàbí àwọ̀ nípa lórí àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni?’ Rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù (Kéfà) ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Ó jẹ́ kí ẹ̀tanú táwọn kan ń ṣe sáwọn Kèfèrí tó jẹ́ Kristẹni nípa lórí òun, “ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀” kúrò lọ́dọ̀ wọn débi pé Pọ́ọ̀lù ní láti bá a wí. (Gál. 2:11-14) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa kíyè sára ká má bàa gba ẹ̀tanú láyè nínú ọkàn wa.
“Ọ̀pọ̀ Èèyàn Di Onígbàgbọ́” (Ìṣe 11:19-26a)
19. Àwọn wo ni àwọn Júù tó di Kristẹni nílùú Áńtíókù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
19 Lẹ́yìn táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe, ṣé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Áńtíókù ti Síríà nígbà tó yá.d Àwọn Júù tó ń gbé nílùú náà pọ̀ gan-an, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìṣòro láàárín àwọn Júù yẹn àtàwọn Kèfèrí. Torí náà, ó rọrùn láti wàásù fáwọn Kèfèrí tó ń gbé níbẹ̀. Ibẹ̀ sì làwọn Júù kan tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fún “àwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì.” (Ìṣe 11:20) Àmọ́, àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì nìkan kọ́ ni Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n wàásù fún, ó tún fẹ́ kí wọ́n wàásù fáwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́. Jèhófà bù kún iṣẹ́ ìwàásù wọn, “ọ̀pọ̀ èèyàn [sì] di onígbàgbọ́.”—Ìṣe 11:21.
20, 21. Báwo ni Bánábà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
20 Torí káwọn ọmọ ẹ̀yìn lè wàásù fáwọn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere ní Áńtíókù, ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù rán Bánábà lọ síbẹ̀. Àwọn èèyàn fìfẹ́ hàn gan-an níbẹ̀ débi pé Bánábà nìkan ò lè dá ṣe iṣẹ́ náà. Báwo ni ì bá ṣe rí ká ní Sọ́ọ̀lù lè wá ràn án lọ́wọ́ níbẹ̀? Ó ṣe tán, Sọ́ọ̀lù máa tó di àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 9:15; Róòmù 1:5) Àmọ́, ṣé Bánábà á máa wò ó pé Sọ́ọ̀lù lè mọ̀ọ̀yàn kọ́ ju òun, kó wà tórí ìyẹn sọ pé òun ò ní pè é? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí pé onírẹ̀lẹ̀ ni Bánábà, ó gbà pé òun nílò ìrànlọ́wọ́. Kódà, òun fúnra ẹ̀ ló lọ wá Sọ́ọ̀lù kàn ní Tásù, tó sì mú un wá sí Áńtíókù kó lè wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Odindi ọdún kan làwọn méjèèjì fi jọ ń gbé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ró nínú ìjọ tó wà níbẹ̀.—Ìṣe 11:22-26.
21 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká má sì ṣe jura wa lọ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká mọ̀wọ̀n ara wa. Ohun tí agbára wa gbé àti ẹ̀bùn àbínibí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè mọ béèyàn ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, àmọ́ kó ṣòro fún wọn láti máa ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí láti máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o tẹ̀ síwájú láwọn apá ibì kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, á dáa kó o jẹ́ kẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà lè ran èèyàn tó pọ̀ sí i lọ́wọ́, wà á sì túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.—1 Kọ́r. 9:26.
Wọ́n Fi “Nǹkan Ìrànwọ́ Ránṣẹ́ sí Àwọn Ará” (Ìṣe 11:26b-30)
22, 23. Kí làwọn ará tó wà ní Áńtíókù ṣe tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ọ̀nà wo làwa èèyàn Ọlọ́run sì gbà ń ṣe ohun tó jọ ọ́ lónìí?
22 Áńtíókù ni ibi tí “Ọlọ́run ti kọ́kọ́ mú kí á máa pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni.” (Ìṣe 11:26b) Orúkọ tí Ọlọ́run fọwọ́ sí yẹn bá a mu gan-an láti fi ṣàpèjúwe àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Bí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè ṣe ń di Kristẹni, ṣé ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn onígbàgbọ́ tó jẹ́ Júù àtàwọn tó jẹ́ Kèfèrí túbọ̀ lágbára sí i? Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìyàn ńlá kan mú ní nǹkan bí ọdún 46 Sànmánì Kristẹni.e Nígbà àtijọ́, ìyàn máa ń fojú àwọn aláìní rí màbo, torí pé wọn ò kì í ní oúnjẹ tàbí owó ní ìpamọ́. Ó dájú pé nígbà tí ìyàn mú ní Jùdíà, aláìní lèyí tó pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù níbẹ̀, wọ́n sì nílò oúnjẹ àtàwọn ohun kòṣeémáàní míì. Nígbà táwọn ará tó wà ní Áńtíókù àtàwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí gbọ́, wọ́n fi “nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ará tó ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:29) Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ni wọ́n ní sáwọn ará yẹn!
23 Bọ́rọ̀ ṣe rí láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí náà nìyẹn. Tá a bá gbọ́ pé àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè míì tàbí ládùúgbò wa ṣaláìní ohunkóhun, tinútinú ló fi máa ń wù wá pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka máa ń tètè yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù kí wọ́n lè bójú tó àwọn ará wa tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ sí, irú bí omíyalé, ìjì líle tàbí ìmìtìtì ilẹ̀. Àwọn nǹkan yìí ń jẹ́rìí sí i pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa dénú.—Jòhánù 13:34, 35; 1 Jòhánù 3:17.
24. Báwo la ṣe lè máa fi hàn pé à ń fọwọ́ pàtàkì mú ìtumọ̀ ìran tí Pétérù rí?
24 Ọwọ́ pàtàkì làwa Kristẹni tòótọ́ fi mú ìtumọ̀ ìran tí Pétérù rí lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní, lórí òrùlé ilé ní Jópà. Ọlọ́run wa kì í ṣe ojúsàájú. Ó fẹ́ ká jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba òun, ìyẹn sì gba pé ká máa wàásù fáwọn ẹlòmíì láìka ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá, tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ sí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká múra tán láti fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ tẹ́tí sí ìhìn rere láǹfààní láti gbọ́.—Róòmù 10:11-13.
a Àwọn Júù kan máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹni tó bá ń ṣiṣẹ́ awọ, torí pé iṣẹ́ yìí á mú kó máa fọwọ́ kan awọ ẹran àti òkú ẹran, bí wọ́n sì ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà máa ń ríni lára. Àwọn Júù ò fẹ́ káwọn tó ń ṣe iṣẹ́ awọ wọnú tẹ́ńpìlì, wọ́n sọ pé ibi tí ìsọ̀ wọn máa wà gbọ́dọ̀ jìnnà sílùú ní ìwọ̀n àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, ìyẹn mítà méjìlélógún (22). Abájọ tí ilé Símónì fi wà ‘létí òkun.’—Ìṣe 10:6.
b Wo àpótí náà, “Kọ̀nílíù àti Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Róòmù.”
c Àpilẹ̀kọ náà, “Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lórí Ọ̀rọ̀ Ọmọ Títọ́,” wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2006, ojú ìwé 4 sí 7.
d Wo àpótí náà, “Áńtíókù ti Síríà.”
e Òpìtàn Júù náà, Josephus sọ̀rọ̀ nípa irú “ìyàn ńlá” yìí nígbà ìṣàkóso Olú Ọba Kíláúdíù (ọdún 41 sí ọdún 54 Sànmánì Kristẹni).