Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Àti Òfin Mósè
“Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.”—GÁLÁTÍÀ 3:24.
1, 2. Kí ni díẹ̀ lára àǹfààní táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fara balẹ̀ ṣègbọràn sí Òfin Mósè ní?
ỌDÚN 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkójọ òfin. Ó sọ fáwọn èèyàn náà pé bí wọ́n bá ṣègbọràn sí ohùn òun, òun á bù kún wọn, wọ́n á sì gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀, tí ń fini lọ́kàn balẹ̀.—Ẹ́kísódù 19:5, 6.
2 Àkópọ̀ Òfin yẹn, tá à ń pè ní Òfin Mósè, tàbí ká kúkú sọ pé “Òfin,” jẹ́ “mímọ́, ó sì jẹ́ òdodo, ó sì dára.” (Róòmù 7:12) Ó gbé àwọn ànímọ́ àtàtà bí inú rere, àìlábòsí, àti jíjẹ́ aládùúgbò rere lárugẹ. (Ẹ́kísódù 23:4, 5; Léfítíkù 19:14; Diutarónómì 15:13-15; 22:10, 22) Òfin náà tún mú kí àwọn Júù nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Léfítíkù 19:18) Síwájú sí i, wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn Kèfèrí tí kò sí lábẹ́ Òfin náà kẹ́gbẹ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fi wọ́n ṣaya. (Diutarónómì 7:3, 4) Gẹ́gẹ́ bí “ògiri” tó pín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí níyà, Òfin Mósè ò jẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run di ẹni tí èrò àti ìṣe àwọn kèfèrí sọ di eléèérí.—Éfésù 2:14, 15; Jòhánù 18:28.
3. Níwọ̀n bí ò ti sẹ́ni tó lè pa Òfin náà mọ́ tán pátápátá, ipa wo ló ní?
3 Àmọ́, àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra jù lọ pàápàá ò lè pa Òfin Ọlọ́run mọ́ tán pátápátá. Ṣé Jèhófà béèrè ohun tó ju agbára wọn lọ ni? Rárá o. Ọ̀kan lára ìdí tá a fi fún Ísírẹ́lì ni Òfin yẹn ni láti “mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere.” (Gálátíà 3:19) Òfin náà jẹ́ káwọn Júù olóòótọ́ mọ báwọn ṣe nílò Olùtúnniràpadà lójú méjèèjì. Nígbà tí Ẹni yẹn dé, inú àwọn Júù olóòótọ́ dùn. Ìdáǹdè wọn kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti sún mọ́lé!—Jòhánù 1:29.
4. Lọ́nà wo ni Òfin gbà jẹ́ ‘akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi’?
4 Òfin Mósè náà yẹ kó jẹ́ ètò tá a ṣe láti wà fúngbà díẹ̀. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.’ (Gálátíà 3:24) Ńṣe ni akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan láyé ọjọ́un máa ń mú àwọn ọmọ lọ sílé ìwé, táá tún lọ mú wọn padà wálé. Òun gan-an kọ́ ni olùkọ́; ó kàn ń mú àwọn ọmọ lọ sọ́dọ̀ olùkọ́ wọn ni. Bákan náà la ṣètò Òfin Mósè láti mú àwọn Júù olùbẹ̀rù Ọlọ́run lọ sọ́dọ̀ Kristi. Jésù ṣèlérí pé òun á wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn òun “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) Nítorí náà, gbàrà tí ìjọ Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ ni “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́” náà—ìyẹn Òfin, kò ti wúlò fún ohunkóhun mọ́. (Róòmù 10:4; Gálátíà 3:25) Àmọ́, àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù ò tètè lóye òtítọ́ pàtàkì yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò jáwọ́ nínú títẹ̀lé àwọn kan lára ohun tí Òfin náà béèrè kódà lẹ́yìn àjíǹde Jésù pàápàá. Àmọ́ ṣá, àwọn tó kù yí èrò wọn padà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa lónìí. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe rí bẹ́ẹ̀.
Àwọn Òye Tuntun Tó Jẹ́ Amóríyá Nínú Ẹ̀kọ́ Kristẹni
5. Àṣẹ wo la pa fún Pétérù nínú ìran kan tó rí, kí sì nìdí tí ẹnu fi yà á?
5 Ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù rí ìran kan tó kàmàmà. Lákòókò yẹn, ohùn kan láti ọ̀run pàṣẹ fún un pé kó pa àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko tí wọ́n kà sí aláìmọ́ lábẹ́ Òfin, kó sì jẹ wọ́n. Ẹnu ya Pétérù! Kò tíì “jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìmọ́ rí.” Àmọ́ ohùn náà sọ fún un pé: “Ìwọ dẹ́kun pípe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” (Ìṣe 10:9-15) Dípò kí Pétérù fi orí kunkun rọ̀ mọ́ Òfin, ńṣe ló yí èrò tó ní tẹ́lẹ̀ pa dà. Èyí ló wá jẹ́ kó ní òye pípabanbarì nípa àwọn ète Ọlọ́run.
6, 7. Kí ló mú kí Pétérù gbà pé òun lè wàásù fáwọn Kèfèrí báyìí, kí sì làwọn nǹkan mìíràn tó tún ṣeé ṣe kó ronú nípa rẹ̀?
6 Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé. Àwọn ọkùnrin mẹ́ta wá sílé tí Pétérù dé sí láti wá bẹ̀ ẹ́ pé kó tẹ̀ lé àwọn lọ sílé Kọ̀nílíù, ìyẹn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ kan tó jẹ́ olùfọkànsìn. Pétérù mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wọlé, ó si ṣe wọ́n lálejò níbẹ̀. Nítorí pé Pétérù ti wá lóye ohun tí ìran yìí túmọ̀ sí, ó tẹ̀ lé wọn lọ sílé Kọ̀nílíù lọ́jọ́ kejì. Ibẹ̀ ni Pétérù ti jẹ́rìí kíkúnná nípa Jésù Kristi. Àkókò yẹn ni Pétérù sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Kì í ṣe Kọ̀nílíù nìkan ló lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù o, àwọn ìbátan rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ náà lo ìgbàgbọ́ pẹ̀lú, “ẹ̀mí mímọ́ [sì] bà lé gbogbo àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.” Nígbà tí Pétérù wá rí i pé Jèhófà lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn náà, ó “pàṣẹ pé kí a batisí wọn ní orúkọ Jésù Kristi.”—Ìṣe 10:17-48.
7 Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Pétérù láti parí èrò sí pé àwọn Kèfèrí tí wọn ò tẹ̀ lé Òfin Mósè lè di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi báyìí? Ìfòyemọ̀ tẹ̀mí ni. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba àwọn Kèfèrí aláìkọlà, tó tú ẹ̀mí rẹ̀ dà sórí wọn, Pétérù náà wá fòye mọ̀ pé wọ́n lè ṣe batisí. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ṣe kedere pé Pétérù ti mọ̀ pé Ọlọ́run ò retí pé káwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí pa Òfin Mósè mọ́ kí wọ́n tó lè ṣe batisí. Ká ní o wà láyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ṣe ìwọ náà ì bá ṣe bíi ti Pétérù kó o múra tán láti yí èrò tó o ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ padà?
Àwọn Kan Ò Padà Lẹ́yìn “Akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Náà”
8. Èrò tó yàtọ̀ sí ti Pétérù wo làwọn Kristẹni kan tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ní nípa ìdádọ̀dọ́, kí sì nìdí?
8 Lẹ́yìn tí Pétérù kúrò nílé Kọ̀nílíù, Jerúsálẹ́mù ló forí lé. Àwọn ará ìjọ tó wà níbẹ̀ ti gbọ́ ìròyìn pé àwọn Kèfèrí aláìkọlà ti “gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” èyí ò sì dùn mọ́ àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ Júù nínú. (Ìṣe 11:1-3) Bí wọ́n ṣe ń dúpẹ́ pé àwọn Kèfèrí náà lè di ọmọlẹ́yìn Jésù ni “àwọn alátìlẹyìn ìdádọ̀dọ́” yarí pé àwọn èèyàn tó jẹ́ àwọn ará orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Júù wọ̀nyí gbọ́dọ̀ pa Òfin mọ́ kí wọ́n tó lè rí ìgbàlà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀ràn nípa ìkọlà ò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan bàbàrà láwọn àgbègbè táwọn Kèfèrí pọ̀ sí, ìyẹn níbi táwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ti kéré níye. Èrò méjì tó yàtọ̀ síra yìí wà bẹ́ẹ̀ fún nǹkan bí ọdún mẹ́tàlá gbáko. (1 Kọ́ríńtì 1:10) Àdánwò gidi nìyẹn á mà jẹ́ fáwọn Kristẹni ìjímìjí wọ̀nyẹn ò, àgàgà àwọn Kèfèrí tí wọ́n ń gbé lágbègbè táwọn Júù pọ̀ sí!
9. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n yanjú ọ̀ràn nípa ìdádọ̀dọ́?
9 Ọ̀ràn náà wá dójú ẹ̀ pátápátá lọ́dún 49 Sànmánì Tiwa, nígbà táwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù wá sí Síríà Áńtíókù, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti ń wàásù nígbà yẹn. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni pé àwọn Kèfèrí tó yí padà ní láti dá adọ̀dọ́ gẹ́gẹ́ bí Òfin ti wí. Ìyapa àti awuyewuye tó wáyé láàárín àwọn àti Pọ́ọ̀lù òun Bánábà kì í ṣe kékeré! Bí ọ̀ràn náà ò bá sì yanjú, ó di dandan káwọn Kristẹni kan kọsẹ̀, yálà àwọn Júù tàbí àwọn Kèfèrí. Látàrí èyí, wọ́n ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn díẹ̀ mìíràn lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n sì sọ pé kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣàkóso yanjú ọ̀ràn náà pátápátá.—Ìṣe 15:1, 2, 24.
Èrò Tó Yàtọ̀ Síra—Lẹ́yìn Náà, Ìṣọ̀kan!
10. Kí ni díẹ̀ lára àwọn kókó tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso gbé yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣe ìpinnu tí wọ́n ṣe nípa àwọn Kèfèrí?
10 Níbi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe, ó hàn gbangba pé àwọn kan wí pé ìdádọ̀dọ́ pọn dandan, táwọn mìíràn sì sọ pé kò pọn dandan. Àmọ́ wọn ò jẹ́ kí bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára olúkúlùkù borí lọ́jọ́ yẹn. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀ awuyewuye, àpọ́sítélì Pétérù àti Pọ́ọ̀lù wá sọ gbogbo iṣẹ́ àmì tí Jèhófà ti ṣe láàárín àwọn aláìdádọ̀dọ́. Wọ́n ṣàlàyé pé Ọlọ́run ti tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́. Lẹ́nu kan, wọ́n béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ ìjọ Kristẹni lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ àwọn tí Ọlọ́run ti tẹ́wọ́ gbà?’ Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ran gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ láti fòye mọ̀ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà nínú ọ̀ràn náà.— Ìṣe 15:4-17.
11. Kókó wo ni kò sí lára ohun tí wọ́n wò nígbà tí wọ́n ṣe ìpinnu tí wọ́n ṣe lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́, kí ló sì fi hàn pé ìbùkún Jèhófà wà lórí ìpinnu náà?
11 Gbogbo èèyàn wá ń retí ohun tí ẹgbẹ́ alákòóso máa sọ. Ǹjẹ́ Júù tí wọ́n jẹ́ ò ní mú wọn ṣe ìpinnu tó fì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nípa ìdádọ̀dọ́ báyìí? Rárá o. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ wọ̀nyẹn ti pinnu láti tẹ̀ lé Ìwé Mímọ́ àti ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ gbogbo ẹ̀rí táwọn èèyàn jẹ́ sí ọ̀ràn náà, ẹgbẹ́ alákòóso jùmọ̀ fohùn ṣọ̀kan pé kò pọn dandan káwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí máa dá adọ̀dọ́, kò sì pọn dandan kí wọ́n wà lábẹ́ Òfin Mósè. Nígbà tí ìpinnu náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ará, inú wọn dùn gan-an, àwọn ìjọ sì bẹ̀rẹ̀ sí “pọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” Àwọn Kristẹni tí wọ́n fara mọ́ ìtọ́sọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run tó ṣe kedere yìí rí ìdáhùn tó ṣe gúnmọ́, tá a gbe karí Ìwé Mímọ́ gbà. (Ìṣe 15:19-23, 28, 29; 16:1-5) Àmọ́ ó ṣì ku ìbéèrè pàtàkì kan tí wọ́n ní láti dáhùn.
Àwọn Kristẹni Tó Jẹ́ Júù Wá Ńkọ́?
12. Ìbéèrè wo ló kù tí wọn ò tíì yanjú?
12 Ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti sọ ní kedere pé kò pọn dandan káwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí dá adọ̀dọ́. Àmọ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù wá ńkọ́? Ìpinnu tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ṣe ò tíì yanjú apá yẹn nínú ọ̀ràn náà.
13. Kí nìdí tó fi jẹ́ àṣìṣe láti rin kinkin mọ́ ọn pé pípa Òfin Mósè mọ́ pọn dandan fún ìgbàlà?
13 Àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù tí wọ́n “jẹ́ onítara fún Òfin” kò ṣíwọ́ nínú dídá adọ̀dọ́ fáwọn ọmọ wọn, wọn ò sì jáwọ́ pípa àwọn kan lára Òfin náà mọ́. (Ìṣe 21:20) Àwọn kan tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, kódà wọ́n rin kinkin mọ́ ọn pé ó pọn dandan káwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù pa Òfin náà mọ́ kí wọ́n tó lè rí ìgbàlà. Nínú èyí, àṣìṣe ńlá ni wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ẹnikẹ́ni nínú àwọn Kristẹni ṣe lè fi ẹran rúbọ nítorí àtirí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà? Ẹbọ Kristi ti sọ irú àwọn ìrúbọ bẹ́ẹ̀ di èyí tí kò bóde mu mọ́. Sísọ tí Òfin náà sọ pé káwọn Júù má ṣe ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn Kèfèrí ńkọ́? Kò lè rọrùn rárá kí Kristẹni kan tó ń fi ìtara wàásù máa pa àwọn ìkálọ́wọ́kò wọ̀nyẹn mọ́, kó sì tún ṣègbọràn sí àṣẹ tó sọ pé kí wọ́n kọ́ àwọn Kèfèrí ní ohun gbogbo tí Jésù fi kọ́ni. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 1:8; 10:28)a Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n yanjú ọ̀ràn yìí nínú èyíkéyìí lára ìpàdé tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ṣe. Síbẹ̀, ìjọ ò kàn wà bẹ́ẹ̀ láìní olùrànlọ́wọ́.
14. Ìtọ́sọ́nà wo ni lẹ́tà onímìísí tí Pọ́ọ̀lù kọ fúnni nípa Òfin?
14 Wọ́n rí ìtọ́sọ́nà gbà, kì í ṣe nípasẹ̀ lẹ́tà tó wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ olùṣàkóso nìkan o, àmọ́ látinú àwọn lẹ́tà onímìísí mìíràn táwọn àpọ́sítélì kọ. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìsọfúnni lílágbára kan ránṣẹ́ sáwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó ń gbé Róòmù. Nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn, ó ṣàlàyé pé ojúlówó Júù ni “ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní inú, ìdádọ̀dọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí.” (Róòmù 2:28, 29) Inú lẹ́tà kan náà ni Pọ́ọ̀lù ti lo àpèjúwe kan tó fi ẹ̀rí hàn pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin náà mọ́. Ó ṣàlàyé pé obìnrin kan ò lè fẹ́ ọkùnrin méjì lẹ́ẹ̀kan náà. Àmọ́ bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó lómìnira àtifẹ́ ọkọ mìíràn. Pọ́ọ̀lù wá mú àpèjúwe yìí bá ohun tó ń sọ mu, ó fi hàn pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ò lè wà lábẹ́ Òfin Mósè, kí wọ́n sì tún jẹ́ ti Kristi lákòókò kan náà. Wọ́n ní láti di “òkú sí Òfin” kí wọ́n lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi.—Róòmù 7:1-5.
Wọn Ò Tètè Lóye Kókó Náà
15, 16. Kí nìdí táwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù fi kùnà láti lóye pé kò pọn dandan káwọn tẹ̀ lé Òfin, kí sì ni èyí fi hàn nípa ìdí tó fi yẹ ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
15 Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Òfin náà kò ṣeé já ní koro rárá. Kí ló wá fà á táwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù ò fi lóye kókó náà? Ìdí kan ni pé, wọn ò ní ìfòyemọ̀ tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò jẹ oúnjẹ líle nípa tẹ̀mí. (Hébérù 5:11-14) Wọn kì í sì í lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. (Hébérù 10:23-25) Ìdí mìíràn táwọn kan ò fi lóye kókó náà tún lè ní í ṣe pẹ̀lú bí Òfin náà fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́. Ó dá lórí àwọn ohun tó ṣeé fojú rí, ohun tó ṣeé yẹ̀ wò, tó sì ṣeé fọwọ́ kàn, bíi tẹ́ńpìlì àti ipò àlùfáà. Ó rọrùn fẹ́ni tí ò ní ìfòyemọ̀ tẹ̀mí láti fara mọ́ Òfin ju kó tẹ́wọ́ gba ohun tó dìídì jẹ́ ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni, tó dá lórí àwọn ohun tí kò ṣeé fojú rí.—2 Kọ́ríńtì 4:18.
16 Ìdí mìíràn táwọn kan tó pera wọn ní Kristẹni fi ń hára gàgà láti pa Òfin náà mọ́ ni èyí tí Pọ́ọ̀lù tò lẹ́sẹẹsẹ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Gálátíà. Ó ṣàlàyé pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí fẹ́ káwọn èèyàn máa bọ̀wọ̀ fún àwọn, nítorí pé wọ́n wà nínú ẹ̀sìn tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń ṣe. Dípò kí wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wọ́n sí Kristẹni, wọ́n ṣe tán láti juwọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà kí wọ́n lè ṣe báwọn èèyàn ti ń ṣe láwùjọ. Wọ́n fẹ́ràn àtirí ojú rere ènìyàn ju àtirí ojú rere Ọlọ́run.—Gálátíà 6:12.
17. Ìgbà wo ni ojú ìwòye tó tọ̀nà nípa pípa Òfin náà mọ́ wá di èyí tó ṣe kedere?
17 Àwọn Kristẹni tó ní ìfòyemọ̀, tí wọ́n fara balẹ̀ ka àwọn lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí, èyí tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn kọ, parí èrò síbi tó dára nípa Òfin náà. Àmọ́, ìgbà tó di ọdún 70 Sànmánì Tiwa ni ojú ìwòye tó tọ̀nà nípa Òfin Mósè ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe kedere sí gbogbo àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù, ipò àlùfáà rẹ̀, àti àwọn àkọsílẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀ run. Èyí ni ò wá jẹ́ kó ṣeé ṣe mọ́ fún ẹnikẹ́ni láti pa gbogbo ohun tó wà nínú Òfin náà mọ́.
Fífi Ẹ̀kọ́ Náà Sílò Lóde Òní
18, 19. (a) Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní, irú ẹ̀mí wo ló sì yẹ ká yẹra fún tá a bá fẹ́ jẹ́ ẹni tó lera nípa tẹ̀mí? (b) Kí ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù kọ́ wa nípa títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin tí ń mú ipò iwájú? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 24.)
18 Lẹ́yìn gbígbé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ tipẹ́ yìí yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe kó o wá máa ronú pé: ‘Ká ní mo wà láyé lákòókò yẹn ni, kí ni ǹ bá ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣí ìfẹ́ Ọlọ́run payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé yẹn? Ṣé ǹ bá rin kinkin mọ́ ojú ìwòye tí mo bá láyé ni? Àbí ǹ bá ti ní sùúrù títí dìgbà tí òye tó tọ̀nà wá ṣe kedere? Nígbà tó sì ṣe kedere tán, ǹjẹ́ ǹ bá fara mọ́ ọn tọkàntọkàn?’
19 Ká sòótọ́, a ò lè sọ ohun tí à bá ṣe ká ní a wà láyé nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Àmọ́, a lè wá bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe nígbà tá a bá mú àwọn ìlàlóye nínú Bíbélì wá sójú táyé lóde òní? (Mátíù 24:45) Nígbà tá a bá fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a gbé karí Ìwé Mímọ́, ṣé mo máa ń gbìyànjú láti fi í sílò, tí kì í ṣe pé kìkì ohun tó wà nínú òfin ni mo máa ń pa mọ́ bí kò ṣe àwọn ìlànà tó wà fún ohun tó fẹ́ ká ṣe gan-an? (1 Kọ́ríńtì 14:20) Ǹjẹ́ mo máa ń fi sùúrù dúró de Jèhófà nígbà tí mi ò bá tètè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń dà mí láàmú?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká lo oúnjẹ tẹ̀mí tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa lónìí dáadáa, “kí a má bàa sú lọ láé.” (Hébérù 2:1) Nígbà tí Jèhófà bá pèsè ìtọ́sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, ẹ jẹ́ ká fetí sílẹ̀ dáadáa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò fi ìgbésí ayé aláyọ̀, tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ jíǹkí wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Pétérù ṣèbẹ̀wò sí Síríà Áńtíókù, ó gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin tó ní pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n jẹ́ Kèfèrí. Àmọ́, nígbà táwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù dé láti Jerúsálẹ́mù, Pétérù “wá ń fà sẹ́yìn, ó sì ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, ní ìbẹ̀rù ẹgbẹ́ àwọn tí ó dádọ̀dọ́.” A lè fojú inú wo bó ṣe máa dun àwọn Kèfèrí tó yí padà yẹn tó, nígbà tí àpọ́sítélì tí wọn bọ̀wọ̀ fún gidigidi kọ̀ láti bá wọn jẹun.—Gálátíà 2:11-13.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ọ̀nà wo ni Òfin Mósè gbà jẹ́ ‘akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi?
• Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà nínú ìhà tí Pétérù àti “àwọn alátìlẹyìn ìdádọ̀dọ́” kọ sí ìyípadà tó wáyé nínú òye òtítọ́?
• Kí lo ti kọ́ nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣí òtítọ́ payá lóde òní?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Pọ́ọ̀lù Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Kojú Ìdánwò
Lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì tó kẹ́sẹ járí, Pọ́ọ̀lù gúnlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù ní ọdún 56 Sànmánì Tiwa. Ibẹ̀ ni ìdánwò kan dúró sí dè é. Ìròyìn pé ó ti ń kọ́ àwọn èèyàn pé a ti pa Òfin tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ti dé inú ìjọ. Ẹ̀rù ń ba àwọn àgbà ọkùnrin pé àwọn tó jẹ́ ẹni tuntun lára àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù lè kọsẹ̀ nítorí bí Pọ́ọ̀lù ò ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá lórí ọ̀ràn Òfin àti pé wọ́n lè máa rò pé àwọn Kristẹni ò bọ̀wọ̀ fún ètò tí Jèhófà ṣe. Àwọn Kristẹni mẹ́rin tó jẹ́ Júù wà nínú ìjọ náà, tí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́, bóyá láti di Násírì. Wọ́n ní láti lọ sí tẹ́ńpìlì láti lọ parí ohun tí ẹ̀jẹ́ náà béèrè lọ́wọ́ wọn.
Àwọn àgbà ọkùnrin wá ní kí Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé àwọn mẹ́rin náà lọ sí tẹ́ńpìlì kó sì bójú tó ọ̀ràn ìnáwó wọn. Ìwé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ onímìísí ni Pọ́ọ̀lù ti kọ, nínú èyí tó ti sọ pé kò pọn dandan kéèyàn pa Òfin mọ́ kó tó lè rí ìgbàlà. Àmọ́ ṣá o, ó gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò. Ó sì ti kọ̀wé tẹ́lẹ̀ pé: “Fún àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin mo dà bí ẹni tí ń bẹ lábẹ́ òfin, kí n lè jèrè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin.” (1 Kọ́ríńtì 9:20-23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sóhun tó lè mú kí Pọ́ọ̀lù juwọ́ sílẹ̀ nígbà tọ́rọ̀ bá dórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ṣe pàtàkì, síbẹ̀ ó rí i pé òun lè tẹ̀ lé ohun tí àwọn àgbà ọkùnrin dámọ̀ràn yìí. (Ìṣe 21:15-26) Kò sóhun tó burú nínú ohun tó ṣe náà. Kò sóhun tí ò bá Ìwé Mímọ́ mu nínú ètò ẹ̀jẹ́ jíjẹ́, ìjọsìn mímọ́ gaara ni wọ́n sì ń lo tẹ́ńpìlì náà fún, wọn ò lò ó fún ìbọ̀rìṣà. Kí Pọ́ọ̀lù má bàa ṣe ohun tó lè mú kí ẹnikẹ́ni kọsẹ̀, ó ṣe ohun táwọn àgbà ọkùnrin sọ pé kó ṣe. (1 Kọ́ríńtì 8:13) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù ti ní láti lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí, kókó yẹn sì jẹ́ ká túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún un gan-an.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ọdún bíi mélòó kan làwọn Kristẹni fi lérò tó yàtọ̀ síra nípa Òfin Mósè