Orin 120
Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Táa bá gbọ́rọ̀ Kristi, kí ló yẹ ká ṣe?
Ẹ̀kọ́ rẹ̀ ńtànmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa.
A ńláyọ̀ báa ṣe ń gbọ́ọ táa sì ń mọ̀ọ́n,
Aó ríbùkún tí a bá ṣègbọràn.
(ÈGBÈ)
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún
Tí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀.
Kóo lè láyọ̀, kóo wọ ìsinmi rẹ̀,
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún.
2. Ààbò yóò wà fún wa nígbèésí ayé
Táa bá kọ́lé wa sórí àpáta.
Tí a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù,
Àpáta ni ìpìlẹ̀ ayé wa.
(Ègbè)
3. Bí igi tó fìdí múlẹ̀ sípadò
Tó ńso èso rẹ̀ lákòókò tó yẹ,
Bẹ́ẹ̀ ni ìbùkún wa yóò rí títí láé
Táá bá gbọ́ ti Ọlọ́run bí ọmọ.
(ÈGBÈ)
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún
Tí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀.
Kóo lè láyọ̀, kóo wọ ìsinmi rẹ̀,
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún.
(Tún wo Diu. 28:2; Sm. 1:3; Òwe 10:22; Mát. 7:24-27.)