Orin 144
Wọ́n Á Rí Ìgbàlà
Lákòókò àánú
Ọlọ́run yìí, ká sọ fáyé
Pé ọjọ́ ìbínú
rẹ̀ yóò dé, ó ti dé tán.
(ÈGBÈ)
Jáà yóò gbà wọ́n, ṣáwọn nìkan?
Àwa náà máa rígbàlà.
Wọ́n á rígbàlà, tí wọ́n bá gbọ́,
Dandan ni ká sọ fáráyé;
Dandan ni.
Iṣẹ́ kan wà tó,
yẹ ká jẹ́ fún gbogbo ayé.
À ń pe gbogbo èèyàn
kí wọ́n dọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Jáà yóò gbà wọ́n, ṣáwọn nìkan?
Àwa náà máa rígbàlà.
Wọ́n á rígbàlà, tí wọ́n bá gbọ́,
Dandan ni ká sọ fáráyé;
Dandan ni.
(ÌSOPỌ̀)
Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì,
Kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n bàa lè yè.
À ń kọ́ wọn, à ń sọ fún wọn;
À ń kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ ìyè.
(ÈGBÈ)
Jáà yóò gbà wọ́n, ṣáwọn nìkan?
Àwa náà máa rígbàlà.
Wọ́n á rígbàlà, tí wọ́n bá gbọ́,
Dandan ni ká sọ fáráyé;
Dandan ni.
(Tún wo 2 Kíró. 36:15; Aísá. 61:2; Ìsík. 33:6; 2 Tẹs. 1:8.)