ORÍ KẸFÀ
Ibo Là Ń Lọ Tá A Bá Kú?
1-3. Àwọn ìbéèrè wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè nípa ikú, ìdáhùn wo sì ni àwọn ẹ̀sìn máa ń fún wọn?
BÍBÉLÌ sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ikú ò ní sí mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Ní Orí 5, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ìràpadà máa mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́ àwọn èèyàn ṣì ń kú lónìí. (Oníwàásù 9:5) Torí náà, a lè máa ronú pé, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó kú?
2 A sábà máa ń béèrè irú ìbéèrè yìí nígbà tí ẹnì kan tá a fẹ́ràn bá kú. A lè máa béèrè pé: Ibo ni ẹni náà lọ? Ṣé ó ń rí wa? Ṣé ó lè ràn wá lọ́wọ́? Ṣé a tún lè pa dà rí i?
3 Onírúurú ìdáhùn ni àwọn ẹ̀sìn máa ń fún àwọn tó bá béèrè irú àwọn ìbéèrè yẹn. Àwọn kan sọ pé tó o bá jẹ́ èèyàn dáadáa, wàá lọ sí ọ̀run rere, àmọ́ tó o bá jẹ́ èèyàn burúkú, wàá jóná nínú ọ̀run àpáàdì. Àwọn míì tún sọ pé téèyàn bá kú, ẹni náà máa di ẹni ẹ̀mí, á sì máa gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti kú. Àwọn kan sì sọ pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, tó sì ti gba ìdájọ́, wọ́n á tún ẹni náà bí sáyé bí èèyàn tàbí bí ẹranko.
4. Kí ni àwọn ẹ̀sìn máa ń kọ́ni nípa ikú?
4 Ohun tó yàtọ̀ síra ni àwọn ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn èèyàn nípa ikú. Àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé èrò kan náà ni gbogbo wọn fi ń kọ́ni. Wọ́n sọ pé tí èèyàn bá kú, ohun kan lára ẹ̀ ṣì máa ń wà láàyè nìṣó. Ṣé òótọ́ ni?
IBO LÀ Ń LỌ TÁ A BÁ KÚ?
5, 6. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú?
5 Jèhófà mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú, ó sì ti jẹ́ ká mọ̀ pé téèyàn bá kú, ẹni yẹn ò sí mọ́ nìyẹn. Ikú ni òdìkejì ìyè. Torí náà tẹ́nì kan bá kú, onítọ̀hún ò mọ nǹkan kan mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò lọ gbé níbòmíì.a Tá a bá kú, a ò lè ríran, a ò lè gbọ́ràn, a ò sì lè ronú mọ́.
6 Ọba Sólómọ́nì sọ pé “àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” Àwọn òkú kò lè nífẹ̀ẹ́ ohunkóhun, wọn ò sì lè kórìíra ohunkóhun. “Kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú.” (Ka Oníwàásù 9:5, 6, 10.) Bákan náà, Sáàmù 146:4 jẹ́ ká mọ̀ pé tẹ́nì kan bá kú, “èrò inú rẹ̀” ti pa rẹ́ nìyẹn.
OHUN TÍ JÉSÙ SỌ NÍPA IKÚ
7. Kí ni Jésù sọ nípa ikú?
7 Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà kú, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti sùn.” Àmọ́, ohun tí Jésù ń sọ kọ́ ni pé Lásárù ń sinmi. Nígbà tó yá, Jésù wá sọ pé: “Lásárù ti kú.” (Jòhánù 11:11-14) Ìyẹn fi hàn pé Jésù fi ikú wé oorun. Kò sọ pé Lásárù wà lọ́run tàbí pé ó wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ tó ti kú. Kò sì sọ pé Lásárù ń jìyà nínú ọ̀run àpáàdì tàbí pé wọ́n máa tún un bí sáyé bí èèyàn tàbí bí ẹranko. Ńṣe ló dà bíi pé Lásárù ń sun oorun àsùnwọra. Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì fi ikú wé oorun. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n pa Sítéfánù, Bíbélì sọ pé “ó sùn nínú ikú.” (Ìṣe 7:60) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn Kristẹni kan ti “sùn nínú ikú.”—1 Kọ́ríńtì 15:6.
8. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn pé ká máa kú?
8 Ṣé Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà láti gbé ayé fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n sì kú? Rárá o! Jèhófà dá wọn kí wọ́n lè wà láàyè títí láé nínú ìlera pípé. Nígbà tí Jèhófà dá àwa ẹ̀dá èèyàn, ó fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sí wa lọ́kàn. (Oníwàásù 3:11) Àwọn òbí kì í fẹ́ káwọn ọmọ wọn dàgbà, kí wọ́n darúgbó, kí wọ́n sì kú lójú ẹ̀mí wọn, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ wa ṣe rí lára Jèhófà. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run dá wa láti wà láàyè títí láé, kí wá nìdí tá a fi ń kú?
KÍ NÌDÍ TÁ A FI Ń KÚ?
9. Kí nìdí tí òfin tí Jèhófà fún Ádámù àti Éfà fi bọ́gbọ́n mu?
9 Nígbà tí Ádámù wà nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà sọ fún un pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn. Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16, 17) Òfin yẹn yé wọn dáadáa, kò sì nira rárá àti pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa fún Ádámù àti Éfà. Tí wọ́n bá ṣègbọràn sí Jèhófà, wọ́n á fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ rẹ̀. Á tún fi hàn pé wọ́n mọrírì àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wọn.
10, 11. (a) Báwo ni Sátánì ṣe tan Ádámù àti Éfà jẹ? (b) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà kò fi ní àwíjàre fún ohun tí wọ́n ṣe?
10 Ó ṣeni láàánú pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà. Sátánì sọ fún Éfà pé: “Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso gbogbo igi inú ọgbà?” Éfà wá dáhùn pé: “A lè jẹ lára àwọn èso igi inú ọgbà. Àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wa nípa èso igi tó wà láàárín ọgbà pé: ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́, kódà, ẹ ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án; kí ẹ má bàa kú.’”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-3.
11 Lẹ́yìn náà Sátánì sọ pé: “Ó dájú pé ẹ ò ní kú. Torí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ tí ẹ bá jẹ ẹ́ ni ojú yín máa là, ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ẹ sì máa mọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4-6) Sátánì fẹ́ kí Éfà ronú pé ó lè pinnu ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa fúnra rẹ̀. Àmọ́, ó tún parọ́ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí Éfà bá ṣàìgbọràn. Sátánì sọ pé Éfà ò ní kú, torí náà Éfà jẹ lára èso náà, lẹ́yìn náà ó fún ọkọ rẹ̀ jẹ. Ádámù àti Éfà mọ̀ pé Jèhófà ti sọ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso náà. Bí wọ́n ṣe jẹ èso yẹn fi hàn pé wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí àṣẹ tó yéni dáadáa tó sì mọ́gbọ́n dání yẹn. Ó tún fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Baba wọn ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wọn. Kò sí àwíjàre fún ohun tí wọ́n ṣe yẹn.
12. Kí nìdí tó fi dùn wá pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Jèhófà?
12 Ó dùn wá gan-an pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ kò bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wọn! Wo bó ṣe máa rí lára ẹ tó o bá ṣiṣẹ́ kára láti tọ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ dàgbà, àmọ́ tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ẹ, tí wọn ò sì ṣe ohun tó o ní kí wọ́n ṣe. Ṣé kò ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ?
13. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Jèhófà sọ pé “ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀”?
13 Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, wọ́n pàdánù àǹfààní láti wà láàyè títí láé. Jèhófà wá sọ fún Ádámù pé: “Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.” (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:19.) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Ádámù á pa dà di erùpẹ̀, bí ẹni pé kò wà láàyè rí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Lẹ́yìn tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀, ó kú, kò sì sí mọ́.
14. Kí nìdí tá a fi ń kú?
14 Ká ní Ádámù àti Éfà ṣègbọràn sí Ọlọ́run ni, wọ́n ṣì máa wà láàyè títí dòní. Àmọ́ nígbà tí wọ́n ṣàìgbọràn, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú. Ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ dà bí àrùn burúkú tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, ìdí nìyẹn tá a fi ń kú. (Róòmù 5:12) Àmọ́, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwa èèyàn kọ́ nìyẹn. Ọlọ́run kò fìgbà kankan fẹ́ kí àwa èèyàn máa kú, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe ikú ní “ọ̀tá.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
ÒTÍTỌ́ SỌ WÁ DI ÒMÌNIRA
15. Báwo ni òtítọ́ nípa ikú ṣe sọ wá di òmìnira?
15 Òtítọ́ nípa ikú sọ wá di òmìnira lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké. Bíbélì kọ́ wa pé àwọn tó ti kú kì í jẹ ìrora, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sí nínú ìbànújẹ́. A ò lè bá wọn sọ̀rọ̀, àwọn náà ò sì lè bá wa sọ̀rọ̀. A ò lè ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn náà ò lè ràn wá lọ́wọ́. Wọn ò lè ṣe wá ní jàǹbá, torí náà kò yẹ ká máa bẹ̀rù wọn. Àmọ́, ńṣe ni ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ni pé àwọn tó ti kú wà láàyè, wọ́n sì ń gbé níbòmíì. Wọ́n tún sọ pé a lè ran àwọn òkú lọ́wọ́ tá a bá ń fún àwọn àlùfáà lówó tàbí àwọn tí wọ́n ń pè ní ẹni mímọ́. Ṣùgbọ́n, tá a bá mọ òtítọ́ nípa ikú, wọn ò ní máa fi irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ tàn wá jẹ.
16. Irọ́ wo ni ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi ń kọ́ni nípa àwọn tó ti kú?
16 Sátánì ń lo ẹ̀sìn èké láti jẹ́ ká rò pé àwọn òkú ṣì wà láàyè. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé tí èèyàn bá kú, ohun kan nínú ẹni yẹn ṣì máa ń wà láàyè nìṣó níbòmíì. Ṣé ohun tí ẹ̀sìn tìẹ kọ́ ẹ nìyẹn, àbí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì ló fi ń kọ́ ẹ? Sátánì máa ń lo irọ́ láti fa àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà.
17. Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ náà pé àwọn èèyàn máa jóná nínú ọ̀run àpáàdì fi tàbùkù sí Jèhófà?
17 Ohun tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ni bani lẹ́rù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń kọ́ni pé àwọn èèyàn burúkú máa jóná títí láé nínú ọ̀run àpáàdì. Irọ́ nìyẹn, ó sì tàbùkù sí Jèhófà. Ìdí ni pé Jèhófà ò lè gbà kí irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ èèyàn láé! (Ka 1 Jòhánù 4:8.) Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá rí ẹnì kan tó ń ti ọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ iná láti fìyà jẹ ẹ́? Ó dájú pé ìkà lo máa pe irú ẹni bẹ́ẹ̀, o ò sì ní fẹ́ sún mọ́ ọn. Irú ẹni tí Sátánì fẹ́ ká gbà pé Jèhófà jẹ́ nìyẹn!
18. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ máa bẹ̀rù àwọn tó ti kú?
18 Àwọn ẹ̀sìn kan ń kọ́ni pé tí èèyàn bá kú, ó máa pa ara dà di ẹni ẹ̀mí. Ohun tí irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ ń dọ́gbọ́n kọ́ni ni pé a gbọ́dọ̀ máa bọlá fún àwọn ẹni tó ti kú tàbí ká máa bẹ̀rù wọn, torí pé wọ́n ti di alágbára tó lè ranni lọ́wọ́ tàbí ọ̀tá tó lè ṣe wá ní jàǹbá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gba irọ́ yìí. Wọ́n ń bẹ̀rù àwọn tó ti kú, torí náà wọ́n ń jọ́sìn àwọn òkú dípò Jèhófà. Àmọ́, máa rántí pé ẹni tó ti kú ò mọ nǹkan kan mọ́, kò sì yẹ ká máa bẹ̀rù wọn. Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa. Òun ni Ọlọ́run tòótọ́, òun nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa jọ́sìn.—Ìfihàn 4:11.
19. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe mọ òtítọ́ nípa ikú?
19 Tá a bá mọ òtítọ́ nípa ikú, a máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ni. Òtítọ́ yìí á jẹ́ ká lóye àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe nípa ìgbésí ayé wa àti ọjọ́ ọ̀la wa.
20. Kí la máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú orí tó kàn?
20 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Jóòbù béèrè pé: “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?” (Jóòbù 14:14) Ṣé ẹni tó ti kú lè tún pa dà wà láàyè? Ìdáhùn tí Ọlọ́run fún wa nínú Bíbélì máa mú inú wa dùn gan-an. A máa rí i nínú orí tó kàn.
a Àwọn kan máa ń sọ pé tí ẹnì kan bá kú, ọkàn rẹ̀ tàbí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì máa ń wà láàyè nìṣó. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo Àlàyé Ìparí Ìwé 17 àti 18.