ORÍ KEJE
Àjíǹde Máa Wà!
1-3. Kí ló sọ gbogbo wa di èrò ẹ̀wọ̀n, báwo sì ni Jèhófà ṣe máa tú wa sílẹ̀?
KÁ SỌ pé wọ́n jù ẹ́ sẹ́wọ̀n gbére nítorí ọ̀ràn tí o kò mọ ohunkóhun nípa ẹ̀, kò sì sí ìrètí pé wọ́n máa tú ẹ sílẹ̀. O ti gbà pé kò sọ́nà àbáyọ kankan mọ́. Àmọ́, o wá gbọ́ pé ẹnì kan wà tó ní agbára láti tú ẹ sílẹ̀, ẹni náà sì ṣèlérí pé òun á ràn ẹ́ lọ́wọ́! Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ?
2 Ikú ti sọ gbogbo wa di èrò ẹ̀wọ̀n. A ò rí ọgbọ́n kankan dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀nà àbáyọ fún wa. Àmọ́ Jèhófà ní agbára láti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Ó sì ti ṣèlérí pé “ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
3 Fojú inú wo bí ara ṣe máa tù ẹ́ tó, tó o bá mọ̀ pé àwa èèyàn ò ní máa kú mọ́. Àmọ́ kì í ṣe pé Jèhófà máa mú ikú kúrò nìkan ni, ó tún máa jí àwọn tó ti kú dìde. Ronú nípa ohun tí ìyẹn máa túmọ̀ sí. Jèhófà ṣèlérí pé “àwọn tí ikú ti pa” máa tún pa dà wà láàyè. (Àìsáyà 26:19) Ohun tí Bíbélì pè ní àjíǹde nìyẹn.
TÍ ẸNI TÁ A FẸ́RÀN BÁ KÚ
4. (a) Kí ló lè tù wá nínú tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa bá kú? (b) Àwọn wo ló wà lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù?
4 Nígbà tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa bá kú, ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn wa máa ń pọ̀ gan-an. Ayé á wá sú wa, torí kò sí ohun tá a lè ṣe tẹ́ni náà á fi pa dà wà láàyè. Àmọ́ Bíbélì fún wa ní ìtùnú gidi. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.) Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ kan tó fi hàn pé ó ń wu Jèhófà àti Jésù gan-an láti jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ Lásárù àtàwọn arábìnrin rẹ̀ Màtá àti Màríà. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Bíbélì sọ pé: “Jésù fẹ́ràn Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” Àmọ́, lọ́jọ́ kan, Lásárù kú.—Jòhánù 11:3-5.
5, 6. (a) Kí ni Jésù ṣe nígbà tó rí i pé àwọn ẹbí Lásárù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀? (b) Kí nìdí tó fi tuni nínú láti mọ̀ pé ó máa ń dun Jésù téèyàn bá kú?
5 Jésù lọ tu Màtá àti Màríà nínú. Nígbà tí Màtá gbọ́ pé Jésù ń bọ̀, ó lọ sẹ́yìn odi ìlú láti lọ pàdé ẹ̀. Inú ẹ̀ dùn láti rí Jésù, àmọ́ ó sọ fún un pé: “Ká ní o wà níbí ni, arákùnrin mi ì bá má kú.” Màtá rò pé Jésù ti pẹ́ jù. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù rí Màríà tó ń sunkún. Bí Jésù ṣe rí i tí ìbànújẹ́ dorí wọn kodò, ó dùn ún, ó sì sunkún. (Jòhánù 11:21, 33, 35) Ó máa ń dun Jésù gan-an tí èèyàn wa bá kú.
6 Ìtùnú ló jẹ́ fún wa bá a ṣe mọ̀ pé ó máa ń dun Jésù náà tí èèyàn wa bá kú. Jésù sì fi ìyẹn jọ Baba rẹ̀. (Jòhánù 14:9) Jèhófà ní agbára láti mú ikú kúrò títí láé, ohun tó sì máa ṣe láìpẹ́ nìyẹn.
“LÁSÁRÙ, JÁDE WÁ!”
7, 8. Kí nìdí tí Màtá kò fi fẹ́ kí wọ́n gbé òkúta náà kúrò ní ibojì Lásárù, àmọ́ kí ni Jésù ṣe?
7 Nígbà tí Jésù dé ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Lásárù sí, wọ́n ti fi òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Àmọ́, Màtá ò fẹ́ kí wọ́n gbé e kúrò. Ìdí sì ni pé ọjọ́ mẹ́rin ni òkú Lásárù ti wà nínú ibojì. (Jòhánù 11:39) Màtá ò sì mọ ohun tí Jésù máa tó ṣe láti ran arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́.
8 Jésù sọ fún Lásárù pé: “Jáde wá!” Ohun tí Màtá àti Màríà rí lẹ́yìn náà jẹ́ ìyàlẹ́nu gbáà fún wọn. “Ọkùnrin tó ti kú náà jáde wá, tòun ti aṣọ tí wọ́n fi dì í tọwọ́tẹsẹ̀ àti aṣọ tí wọ́n fi di ojú rẹ̀.” (Jòhánù 11:43, 44) Lásárù ti jí dìde! Òun àtàwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tún pa dà ríra. Wọ́n fọwọ́ kàn án, wọ́n dì mọ́ ọn, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Iṣẹ́ ìyanu gbáà ni èyí jẹ́! Jésù ti jí Lásárù dìde.
“ỌMỌBÌNRIN, MO SỌ FÚN Ọ, ‘DÌDE!’”
9, 10. (a) Ta ló fún Jésù ní agbára láti jí àwọn èèyàn dìde? (b) Kí nìdí tí àwọn àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde fi wúlò fún wa?
9 Ṣé agbára Jésù ló fi jí àwọn èèyàn dìde? Rárá o. Jésù gbàdúrà sí Jèhófà kó tó jí Lásárù dìde, Jèhófà sì fún un lágbára. (Ka Jòhánù 11:41, 42.) Kì í ṣe Lásárù nìkan ni Jésù jí dìde. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìlá (12) kan tó ń ṣàìsàn tó le gan-an. Jáírù bàbá rẹ̀ ń wá bí ara ọmọ rẹ̀ ṣe máa yá lójú méjèèjì, ló bá bẹ Jésù pé kó wò ó sàn. Òun nìkan sì ni ọmọ tó bí. Bó ṣe ń bá Jésù sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn ọkùnrin kan wá sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Kí ló dé tí o ṣì ń yọ Olùkọ́ lẹ́nu?” Àmọ́ Jésù sọ fún Jáírù pé: “Má bẹ̀rù, ṣáà ti ní ìgbàgbọ́, ara ọmọ náà sì máa yá.” Ni Jésù bá tẹ̀ lé Jáírù lọ sí ilé rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ilé náà, Jésù rí àwọn èèyàn tó ń sunkún. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má sunkún mọ́, torí kò kú, ó ń sùn ni.” Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù ń sọ má yé àwọn òbí ọmọ náà. Jésù wá sọ pé kí gbogbo wọn jáde síta, ó wá mú bàbá àti ìyá ọmọ náà lọ sínú yàrá tí wọ́n tẹ́ ọmọ náà sí. Jésù wá di ọwọ́ ọmọ náà mú, ó sì sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, mo sọ fún ọ, ‘dìde!’” Wo bí inú àwọn òbí rẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó dìde tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn! Jésù jí ọmọbìnrin wọn dìde. (Máàkù 5:22-24, 35-42; Lúùkù 8:49-56) Láti ọjọ́ yẹn lọ, bí wọ́n ṣe ń rí ọmọdébìnrin wọn ni wọ́n á máa rántí ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn nípasẹ̀ Jésù.a
10 Òótọ́ ni pé àwọn tí Jésù jí dìde tún pa dà kú. Àmọ́ ohun tá a kà nípa àwọn èèyàn yìí fún wa ní ìrètí tó dájú. Ó wu Jèhófà láti jí àwọn èèyàn dìde, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀.
OHUN TÁ A RÍ KỌ́ NÍNÚ ÀKỌSÍLẸ̀ NÍPA ÀJÍǸDE
11. Kí ni Oníwàásù 9:5 kọ́ wa nípa Lásárù?
11 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” Lásárù náà ò mọ nǹkan kan nígbà tó kú. (Oníwàásù 9:5) Bí Jésù ṣe sọ, ńṣe ló dà bíi pé Lásárù ń sùn. (Jòhánù 11:11) Nígbà tí Lásárù wà nínú sàréè, kò mọ “nǹkan kan rárá.”
12. Báwo la ṣe mọ̀ pé Lásárù jíǹde lóòótọ́?
12 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde. Àwọn ọ̀tá Jésù náà mọ̀ pé ó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí. Bí Lásárù ṣe pa dà wà láàyè jẹ́ ẹ̀rí pé àjíǹde náà ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. (Jòhánù 11:47) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló lọ kí Lásárù, èyí sì jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló rán Jésù lóòótọ́. Inú àwọn ọ̀tá Jésù ò dùn sí èyí, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù àti Lásárù.—Jòhánù 11:53; 12:9-11.
13. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde?
13 Jésù sọ pé “gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí” ló máa jíǹde. (Jòhánù 5:28) Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Jèhófà ló máa pa dà wà láàyè. Àmọ́ kí Jèhófà tó lè jí ẹnì kan dìde, ó gbọ́dọ̀ rántí gbogbo nǹkan nípa ẹni náà. Àmọ́, ṣé Jèhófà lè rántí gbogbo nǹkan nípa àwọn tó máa jí dìde? Rò ó wò ná, àìmọye ìràwọ̀ ló wà lójú ọ̀run. Bíbélì sọ pé Jèhófà mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ yìí. (Ka Àìsáyà 40:26.) Tó bá lè rántí orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀, ó dájú pé ó máa rọrùn fún un láti rántí gbogbo nǹkan nípa àwọn tó máa jí dìde. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jèhófà ló dá ohun gbogbo, torí náà a mọ̀ pé ó ní agbára láti jí àwọn tó ti kú dìde.
14, 15. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Jóòbù sọ nípa àjíǹde?
14 Jóòbù tó jẹ́ ọkùnrin olóòótọ́ gbà pé Ọlọ́run lè jí àwọn òkú dìde. Ó béèrè pé: “Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?” Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèhófà pé: “O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn. Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” Ó dá Jóòbù lójú pé Jèhófà ń dúró de àsìkò tó máa jí àwọn òkú dìde.—Jóòbù 14:13-15.
15 Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe rí lára ẹ? O lè máa ronú pé, ‘Ṣé àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ mi tó ti kú ṣì máa jíǹde?’ Ìtùnú ló jẹ́ fún wa bá a ṣe mọ̀ pé ó wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó máa jíǹde àti ibi tí wọ́n á máa gbé.
WỌ́N ‘MÁA GBỌ́ OHÙN RẸ̀, WỌ́N Á SÌ JÁDE WÁ’
16. Irú ìgbésí ayé wo ni àwọn tó bá jíǹde máa gbádùn?
16 Orí ilẹ̀ ayé ni àwọn tó kú nígbà àtijọ́ jíǹde sí, tí wọ́n sì tún rí ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọn pa dà. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ó tún máa dáa jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn tó máa jíǹde máa ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé, wọn ò sì ní kú mọ́. Wọ́n á sì máa gbé inú ayé kan tó yàtọ̀ gan-an sí èyí tí à ń gbé lónìí. Kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn àti àìsàn mọ́.
17. Àwọn wo ló máa jíǹde?
17 Àwọn wo ló máa jíǹde? Jésù sọ pé ‘gbogbo àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí máa gbọ́ ohùn rẹ̀, wọ́n á sì jáde wá.’ (Jòhánù 5:28, 29) Bákan náà, Ìfihàn 20:13 sọ pé: “Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn.” Ìyẹn fi hàn pé àìmọye èèyàn ló máa jíǹde. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn “olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” ló máa jíǹde. (Ka Ìṣe 24:15.) Kí ni èyí túmọ̀ sí?
18. Àwọn wo ni “olódodo” tó máa jíǹde?
18 Lára “àwọn olódodo” tó máa jíǹde ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n gbé ayé kí Jésù tó wá sáyé. Àwọn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sérà, Mósè, Rúùtù àti Ẹ́sítà wà lára àwọn tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé níbí. O lè kà nípa díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin àti obìnrin yìí nínú Hébérù orí 11. Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó bá kú lóde òní ńkọ́? Àwọn náà wà lára àwọn “olódodo,” torí náà Ọlọ́run máa jí wọn dìde.
19. Àwọn wo ni “aláìṣòdodo”? Àǹfààní wo ni Jèhófà máa fún wọn?
19 Àwọn kan wà tí wọn kò ní àǹfààní láti mọ Jèhófà títí wọ́n fi kú, àwọn ni “àwọn aláìṣòdodo” tó máa jíǹde. Bí wọ́n tiẹ̀ ti kú, Jèhófà ò gbàgbé wọn. Ó máa jí wọn dìde, wọ́n á ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ kí wọ́n sì máa sìn ín.
20. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó ti kú ló máa jíǹde?
20 Ṣé ìyẹn túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó ti kú ló máa jíǹde? Rárá o. Jésù sọ pé àwọn kan ò ní jíǹde. (Lúùkù 12:5) Ta ló máa pinnu bóyá ẹnì kan máa jíǹde àbí kò ní jíǹde? Jèhófà ni adájọ́ tó ga jù lọ, àmọ́ ó ti fún Jésù ní ọlá àṣẹ láti jẹ́ “onídàájọ́ alààyè àti òkú.” (Ìṣe 10:42) Torí náà, tó bá dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ pé ó jẹ́ ẹni burúkú tí kò ṣe tán láti yí pa dà, kò ní jí irú ẹni bẹ́ẹ̀ dìde.—Wo Àlàyé Ìparí Ìwé 19.
ÀJÍǸDE SÍ Ọ̀RUN
21, 22. (a) Kí ni àjíǹde sí ọ̀run túmọ̀ sí? (b) Ta ló kọ́kọ́ jíǹde sí ọ̀run?
21 Bíbélì tún sọ pé àwọn èèyàn kan máa gbé ní ọ̀run. Tí Ọlọ́run bá jí ẹnì kan dìde sí ọ̀run, kò ní jíǹde bí èèyàn ẹlẹ́ran ara. Ọ̀run ló máa jíǹde sí bí ẹni ẹ̀mí.
22 Jésù ni ẹni àkọ́kọ́ tó jíǹde sí ọ̀run. (Jòhánù 3:13) Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta tí wọ́n pa Jésù, Jèhófà jí i dìde. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 13:34, 35) Àmọ́, Jésù kò jí dìde pẹ̀lú ara èèyàn. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù, ó ní: “Wọ́n pa á nínú ẹran ara, àmọ́ a sọ ọ́ di ààyè nínú ẹ̀mí.” (1 Pétérù 3:18) Ọlọ́run jí Jésù dìde ní ẹni ẹ̀mí alágbára! (1 Kọ́ríńtì 15:3-6) Àmọ́ Bíbélì sọ pé Jésù nìkan kọ́ ló máa jíǹde sí ọ̀run.
23, 24. Àwọn wo ni Jésù pè ní “agbo kékeré,” mélòó sì ni wọ́n?
23 Nígbà tó ku díẹ̀ kí Jésù kú, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Mò ń lọ kí n lè pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 14:2) Èyí túmọ̀ sí pé díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa jíǹde tí wọ́n á sì máa gbé pẹ̀lú rẹ̀ lọ́run. Mélòó ni wọ́n? Jésù pè wọ́n ní “agbo kékeré,” tó túmọ̀ sí pé wọ́n kéré níye. (Lúùkù 12:32) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ iye tí wọ́n jẹ́ gangan nínú ìran tí Ọlọ́run fi hàn án, tí Jésù ‘dúró lórí Òkè Síónì [ti ọ̀run], tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) sì wà pẹ̀lú rẹ̀.’—Ìfihàn 14:1.
24 Ìgbà wo ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí máa jí dìde? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé èyí máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Kristi bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 15:23) Àkókò yẹn la wà báyìí, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ló sì ti jí dìde sí ọ̀run. Tí èyíkéyìí lára wọn bá sì kú lónìí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa jíǹde sí ọ̀run. Àmọ́ lọ́jọ́ iwájú, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló máa jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
25. Kí la máa kọ́ nínú orí tó kàn?
25 Láìpẹ́, Jèhófà máa gba gbogbo èèyàn lọ́wọ́ ikú, kò sì ní sí ikú mọ́ títí láé! (Ka Àìsáyà 25:8.) Àmọ́ kí ni àwọn tó ń lọ sọ́run á máa ṣe níbẹ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba kan. A máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìjọba yẹn ní orí tó kàn.
a Nínú àwọn àkọsílẹ̀ míì, Bíbélì sọ nípa àjíǹde ọmọdé àti àgbà, ọkùnrin àti obìnrin àti tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì. O lè kà nípa wọn nínú 1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37; 13:20, 21; Mátíù 28:5-7; Lúùkù 7:11-17; 8:40-56; Ìṣe 9:36-42; 20:7-12.