ORÍ 17
“Èmi Yóò Bá Ọ Jà, Ìwọ Gọ́ọ̀gù”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Àlàyé nípa ẹni tí “Gọ́ọ̀gù” jẹ́ àti “ilẹ̀” tó gbógun jà
1, 2. Ogun wo là ń retí tó ju gbogbo ogun lọ? Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká wá ìdáhùn wọn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń jagun, wọ́n sì ti fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ ba ayé yìí jẹ́ gan-an. Lára ẹ̀ ni ìpakúpa tó wáyé nígbà ogun àgbáyé méjèèjì tí wọ́n jà ní ọ̀rúndún ogún. Àmọ́ ogun kan ṣì ń bọ̀ tó máa ju gbogbo ogun lọ nínú ìtàn ìran èèyàn. Ogun yìí kì í ṣe ogun láàárín àwọn èèyàn, èyí tí àwọn orílẹ̀-èdè máa ń bára wọn jà nítorí ìfẹ́ tara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìfi. 16:14) Ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀tá agbéraga ló máa fa ogun yìí nígbà tó bá gbógun ja ilẹ̀ kan tó jẹ́ iyebíye lójú Ọlọ́run; ìyẹn máa mú kí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ lo agbára rẹ̀ tó fi ń pa nǹkan run lọ́nà tó kàmàmà jù lọ ní ayé.
2 Torí náà, àwọn ìbéèrè pàtàkì kan wà tó yẹ ká wá ìdáhùn wọn: Ta ni ọ̀tá yìí? Ilẹ̀ wo ló fẹ́ gbógun jà? Ìgbà wo ló fẹ́ gbógun jà á, kí nìdí tó fi fẹ́ gbógun ja ilẹ̀ náà, báwo ló sì ṣe máa gbógun jà á? Ó yẹ kí àwa tá à ń ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Jèhófà mọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí, torí pé àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ yìí máa kàn wá. A máa rí àwọn ìdáhùn náà nínú àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 38 àti 39.
Gọ́ọ̀gù ti Ilẹ̀ Mágọ́gù Ni Ọ̀tá Náà
3. Ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù.
3 Ka Ìsíkíẹ́lì 38:1, 2, 8, 18; 39:4, 11. Ohun tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà ni pé: “Ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn,” ọ̀tá kan tí Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù ti . . . Mágọ́gù” gbógun ja “ilẹ̀” àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àmọ́ bí wọ́n ṣe gbógun ja ilẹ̀ yẹn mú kí Jèhófà ‘bínú gidigidi,’ Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà, ó sì ṣẹ́gun Gọ́ọ̀gù.a Nígbà tí Jèhófà ṣẹ́gun, ó “mú kí onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ àti ẹran inú igbó fi” ọ̀tá náà àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ “ṣe oúnjẹ.” Nígbà tó yá, Jèhófà yan ‘ibì kan tí wọ́n sin Gọ́ọ̀gù sí.’ Tá a bá fẹ́ lóye bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú, àfi ká kọ́kọ́ mọ ẹni tí Gọ́ọ̀gù jẹ́.
4. Kí la lè sọ nípa Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù?
4 Torí náà, ta ni Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù? Tá a bá wo àpèjúwe tí Ìsíkíẹ́lì ṣe, a lè sọ pé ọ̀tá àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ ni Gọ́ọ̀gù. Ṣé Sátánì, olórí gbogbo ọ̀tá àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ ni wọ́n pè ní Gọ́ọ̀gù nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí? Ohun tá a sọ nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa nìyẹn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́, nígbà tá a tún ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì dáadáa, a wá ṣàtúnṣe òye tá a ní tẹ́lẹ̀. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ṣàlàyé pé kì í ṣe áńgẹ́lì tí kò ṣeé fojú rí ni orúkọ náà Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù ń tọ́ka sí, àmọ́ ó ń tọ́ka sí ọ̀tá tó jẹ́ èèyàn tó ṣeé fojú rí, ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tó máa gbéjà ko ìjọsìn mímọ́.b Ká tó jíròrò ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun pàtàkì méjì nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì tó fi hàn pé Gọ́ọ̀gù kì í ṣe áńgẹ́lì.
5, 6. Kí la rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì tó jẹ́ ká mọ̀ pé Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù kì í ṣe áńgẹ́lì?
5 “Màá mú kí onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ àti ẹran inú igbó fi ọ́ ṣe oúnjẹ.” (Ìsík. 39:4) Tí Ìwé Mímọ́ bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹyẹ aṣọdẹ tó ń jẹ òkú, ó sábà máa ń fi ṣe ìkìlọ̀ nípa ìdájọ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run ṣe irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti fún àwọn orílẹ̀-èdè míì. (Diu. 28:26; Jer. 7:33; Ìsík. 29:3, 5) Ẹ kíyè sí pé, àwọn áńgẹ́lì kọ́ ni Ọlọ́run ń kìlọ̀ fún, àwọn èèyàn tó ní ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara ni. Ó ṣe tán, ẹran ara ni àwọn ẹyẹ aṣọdẹ àtàwọn ẹran inú igbó máa ń jẹ, wọn kì í jẹ ara ẹ̀mí. Torí náà, ìkìlọ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì yìí fi hàn pé Gọ́ọ̀gù kì í ṣe áńgẹ́lì.
6 “Èmi yóò yan ibì kan . . . ní Ísírẹ́lì tí wọn yóò sin Gọ́ọ̀gù sí.” (Ìsík. 39:11) Ìwé Mímọ́ ò sọ pé wọ́n máa ń sin àwọn áńgẹ́lì sórí ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní wọ́n máa ju Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún, lẹ́yìn náà, wọ́n á jù wọ́n sínú adágún iná tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé. (Lúùkù 8:31; Ìfi. 20:1-3, 10) Torí pé Ọlọ́run sọ nípa Gọ́ọ̀gù pé wọ́n máa ‘yan ibi tí wọn yóò sin ín sí’ lórí ilẹ̀ ayé, a lè sọ pé kì í ṣe áńgẹ́lì.
7, 8. Ìgbà wo ni “ọba àríwá” máa pa run, báwo nìyẹn sì ṣe jọra pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù?
7 Tí Gọ́ọ̀gù kì í bá ṣe áńgẹ́lì, ta wá ni tàbí kí wá ni Gọ́ọ̀gù tó jẹ́ ọ̀tá tó máa gbéjà tó kẹ́yìn ko àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́? Ẹ jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ méjì kan nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ẹni tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù jẹ́.
8 “Ọba àríwá.” (Ka Dáníẹ́lì 11:40-45.) Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn agbára ayé tó máa wà látìgbà ayé rẹ̀ títí di àsìkò wa yìí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún mẹ́nu ba àwọn ìjọba tí wọ́n á jọ máa figagbága, ìyẹn “ọba gúúsù” àti “ọba àríwá,” ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yí pa dà bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, bí oríṣiríṣi ìjọba ayé ṣe ń jà láti borí ara wọn. Dáníẹ́lì sọ nípa ìjà tí ọba àríwá máa jà kẹ́yìn “ní àkókò òpin,” ó ní: “Ó sì máa fi ìbínú tó le gan-an jáde lọ láti pani rẹ́ ráúráú, kó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run.” Àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà gangan ni ọba àríwá máa dájú sọ.c Àmọ́ bíi ti Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ọba àríwá máa “pa run,” nígbà tí kò bá lè ṣẹ́gun àwọn èèyàn Ọlọ́run.
9. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù ṣe jọra pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé”?
9 “Àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Ka Ìfihàn 16:14, 16; 17:14; 19:19, 20.) Ìwé Ìfihàn sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí “àwọn ọba ayé” ṣe máa gbéjà ko “Ọba àwọn ọba,” ìyẹn Jésù tó ti wà ní ọ̀run. Àmọ́ nígbà tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí bá rí i pé àwọn ò lè dé ọ̀run, wọ́n á gbéjà ko àwọn tó ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn ọba ayé á wá rí i pé àwọn ò lè borí nínú ogun táwọn ń jà ní Amágẹ́dọ́nì. Ẹ kíyè sí pé lẹ́yìn tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn èèyàn Jèhófà ni wọ́n máa pa run. Ìyẹn bá ohun tí Bíbélì sọ nípa Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù mu.d
10. Kí la lè sọ nípa ẹni tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù jẹ́?
10 Tá a bá wo àwọn ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, kí la lè sọ nípa ẹni tí Gọ́ọ̀gù jẹ́? Àkọ́kọ́ ni pé, Gọ́ọ̀gù kì í ṣe áńgẹ́lì. Ìkejì ni pé, àwọn orílẹ̀-èdè ayé tó máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà ni Gọ́ọ̀gù. Ó ṣe kedere pé àwọn orílẹ̀-èdè máa kóra jọ, ìyẹn ni pé wọ́n á lẹ̀dí àpò pọ̀ lọ́nà kan tàbí òmíì. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwa èèyàn Ọlọ́run wà káàkiri ayé, torí náà àwọn orílẹ̀-èdè máa fẹ́ kí èrò wọn ṣọ̀kan lórí bí wọ́n ṣe fẹ́ gbéjà kò wá. (Mát. 24:9) Ẹ má gbàgbé pé, Sátánì ni òṣìkà tó máa rúná sí gbogbo ìgbéjàkò yẹn. Ó ti pẹ́ tó ti máa ń kó sí àwọn orílẹ̀-èdè ayé lórí kí wọ́n lè máa gbéjà ko ìjọsìn mímọ́. (1 Jòh. 5:19; Ìfi. 12:17) Àmọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù dá lórí bí àwọn orílẹ̀-èdè ayé ṣe máa gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà.e
Kí Ni “Ilẹ̀” Náà?
11. Báwo ni Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe “ilẹ̀” tí Gọ́ọ̀gù máa gbógun jà?
11 Bá a ṣe rí i ní ìpínrọ̀ 3, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù máa mú kí Jèhófà bínú gidigidi nígbà tó bá gbógun ja ilẹ̀ tó ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ilẹ̀ wo nìyẹn? Ẹ jẹ́ ká pa dà sínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:8-12.) Ó sọ pé Gọ́ọ̀gù “gbógun ja [ilẹ̀] àwọn èèyàn tó ti bọ́” àti “àwọn èèyàn tí wọ́n tún kó jọ láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè.” Ẹ tún kíyè sí ohun tó sọ nípa àwọn olùjọsìn tí a mú pa dà bọ̀ sípò tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà, ó ní: ‘Ààbò wà lórí gbogbo wọn’; “agbègbè tí kò ní ògiri, ọ̀pá ìdábùú tàbí àwọn ẹnubodè” ni wọ́n ń gbé; wọ́n sì ‘ń kó ọrọ̀ jọ.’ Ilẹ̀ yìí ni àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Jèhófà kárí ayé ń gbé. Báwo la ṣe lè mọ ilẹ̀ náà?
12. Báwo ni nǹkan ṣe pa dà bọ̀ sípò nílẹ̀ Ísírẹ́lì láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
12 Ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá ronú nípa bí nǹkan ṣe pa dà bọ̀ sípò ní Ísírẹ́lì àtijọ́, nílẹ̀ táwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run gbé, tí wọ́n ti ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì ti jọ́sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya aláìṣòótọ́, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Ìsíkíẹ́lì pé ilẹ̀ wọn máa pa run, ó sì máa di ahoro. (Ìsík. 33:27-29) Àmọ́ Jèhófà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àṣẹ́kù tó bá ronú pìwà dà máa pa dà láti ìgbèkùn Bábílónì, wọ́n sì máa dá ìjọsìn mímọ́ pa dà sí ilẹ̀ náà. Ìbùkún Jèhófà máa mú kí nǹkan yí pa dà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì máa gbèrú “bí ọgbà Édẹ́nì.” (Ìsík. 36:34-36) Ọdún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni nǹkan pa dà bọ̀ sípò fún wọn, nígbà tí àwọn Júù tó wà nígbèkùn pa dà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè dá ìjọsìn tòótọ́ pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n fẹ́ràn gan-an.
13, 14. (a) Kí ni ilẹ̀ tẹ̀mí náà? (b) Kí nìdí tí ilẹ̀ yìí fi ṣeyebíye sí Jèhófà?
13 Bákan náà, Ọlọ́run mú kí nǹkan pa dà bọ̀ sípò fáwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ lóde òní. Bá a ṣe rí i ní Orí 9 nínú ìwé yìí, lọ́dún 1919, Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn ọlọ́jọ́ pípẹ́ nínú Bábílónì Ńlá. Lọ́dún yẹn, Jèhófà mú àwọn olùjọsìn rẹ̀ tó pa dà dé wá sórí ilẹ̀ tẹ̀mí. Párádísè tẹ̀mí ni ilẹ̀ yẹn, ìyẹn ibi tó láàbò, tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù nípa tẹ̀mí tàbí ibi tá a ti ń gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí, níbi tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Ní ilẹ̀ yìí, ààbò wà lórí wa bá a ṣe jọ ń gbé, ọkàn wa balẹ̀, àyà wa ò sì já. (Òwe 1:33) À ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ tẹ̀mí, a sì ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn láti ṣe, èyí tó jẹ mọ́ kíkéde Ìjọba Ọlọ́run. Ní tòótọ́, ọ̀rọ̀ òwe yìí ń ṣẹ sí wa lára pé: “Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” (Òwe 10:22) Ibi yòówù ká máa gbé ní ayé, ilẹ̀ yẹn la wà, ìyẹn párádísè tẹ̀mí, tá a bá ṣáà ti ń fìtara gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa.
14 Ilẹ̀ tẹ̀mí yìí ṣeyebíye lójú Jèhófà. Kí nìdí? Ìdí ni pé lójú rẹ̀, àwọn tó ń gbé ibẹ̀ jẹ́ “ohun iyebíye nínú gbogbo orílẹ̀-èdè,” ìyẹn àwọn tó mú jáde lẹ́nì kọ̀ọ̀kan wá sínú ìjọsìn mímọ́. (Hág. 2:7; Jòh. 6:44) Wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tó ń gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí kò láfiwé yọ. (Éfé. 4:23, 24; 5:1, 2) Ìjọsìn mímọ́ tí wọ́n ń ṣe sí Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n máa lo ara wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, wọ́n ń ṣe é láwọn ọ̀nà tó ń fògo fún un, tó sì ń fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Róòmù 12:1, 2; 1 Jòh. 5:3) A ò lè mọ bínú Jèhófà ṣe máa ń dùn tó bó ṣe ń wo bí àwa olùjọsìn rẹ̀ ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ilẹ̀ tẹ̀mí yìí túbọ̀ rẹwà. Rò ó wò ná: Bó o ṣe ń ka ìjọsìn mímọ́ sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé rẹ, bẹ́ẹ̀ lò ń mú kí párádísè tẹ̀mí yìí rẹwà sí i, tó o sì ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀!—Òwe 27:11.
Ìgbà Wo Ni Gọ́ọ̀gù Máa Gbógun Ja Ilẹ̀ Náà, Kí Nìdí Tó Fi Máa Gbógun, Báwo Ló sì Ṣe Máa Ṣe É?
15, 16. Ìgbà wo ni Gọ́ọ̀gù ti Ilẹ̀ Mágọ́gù máa gbógun ja ilẹ̀ tẹ̀mí wa tí Ọlọ́run mú pa dà bọ̀ sípò?
15 Kì í múnú wa dùn tá a bá rántí pé láìpẹ́, àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè ayé máa gbógun ja ilẹ̀ tẹ̀mí wa tó ṣeyebíye yìí. Torí pé àwa tá à ń ṣe ìjọsìn mímọ́ sí Jèhófà ni wọ́n fẹ́ gbéjà kò, ó wù wá pé ká mọ púpọ̀ sí i nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Ẹ jẹ́ ká dáhùn ìbéèrè mẹ́ta kan lórí kókó yìí.
16 Ìgbà wo ni Gọ́ọ̀gù ti Ilẹ̀ Mágọ́gù máa gbógun ja ilẹ̀ tẹ̀mí wa tí Ọlọ́run mú pa dà bọ̀ sípò? Àsọtẹ́lẹ̀ náà dáhùn pé: “Ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn, ìwọ yóò gbógun ja” ilẹ̀ náà. (Ìsík. 38:8) Ìyẹn ń tọ́ka sí àkókò tó sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí. Ká má gbàgbé pé ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké ayé. Lẹ́yìn tí àwọn ìsìn èké bá pa run, ṣáájú kí Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀, Gọ́ọ̀gù máa fi gbogbo agbára rẹ̀ gbéjà ko àwa tá à ń ṣe ìjọsìn tòótọ́, ogun àjàkẹ́yìn ló sì máa jẹ́ fún un.
17, 18. Báwo ni Jèhófà ṣe máa darí àwọn nǹkan nígbà ìpọ́njú ńlá?
17 Kí nìdí tí Gọ́ọ̀gù fi máa gbógun ja ilẹ̀ tí Jèhófà mú pa dà bọ̀ sípò fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀? Àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì sọ ohun méjì tó máa mú kó ṣe bẹ́ẹ̀, àkọ́kọ́ ni bí Jèhófà ṣe máa darí ọ̀rọ̀ náà, ìkejì sì ni èrò ibi tó wà lọ́kàn Gọ́ọ̀gù.
18 Bí Jèhófà ṣe máa darí ọ̀rọ̀ náà. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:4, 16.) Ẹ kíyè sí ohun tí Jèhófà sọ fún Gọ́ọ̀gù pé: “Màá fi ìwọ̀ kọ́ ọ lẹ́nu,” àti pé, “èmi yóò mú kí o wá gbéjà ko ilẹ̀ mi.” Ṣé ọ̀rọ̀ yìí wá túmọ̀ sí pé Jèhófà máa fipá mú àwọn orílẹ̀-èdè láti gbéjà ko àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀? Rárá o! Jèhófà ò ní mú kí ohun búburú ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ̀ láé. (Jóòbù 34:12) Àmọ́ Jèhófà mọ àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó mọ̀ pé wọ́n máa kórìíra àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́ àti pé ṣe ni wọ́n á máa wá gbogbo ọ̀nà láti pa àwọn olùjọ́sìn Jèhófà rẹ́. (1 Jòh. 3:13) Jèhófà máa darí ọ̀rọ̀ náà bíi pé ó fi ìwọ̀ kọ́ Gọ́ọ̀gù lẹ́nu, tó sì ń mú un lọ, kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà lè wáyé lọ́nà tó bá ìfẹ́ Rẹ̀ mu ní àkókò tó fẹ́. Láàárín kan lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá ti pa run, ó ṣeé ṣe kí Jèhófà ṣe àwọn ohun kan lọ́nà kan tàbí òmíì láti mú kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn. Jèhófà máa tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n gbára dì láti gbéjà kò wá, ìyẹn ló sì máa yọrí sí Amágẹ́dọ́nì, ogun tó máa rinlẹ̀ jù lọ ní ayé. Nígbà náà, Jèhófà máa gba àwọn èèyàn rẹ̀, ó máa gbé ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ ga, ó sì máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́.—Ìsík. 38:23.
Àwọn orílẹ̀-èdè á wá bí wọ́n ṣe máa kó ìjọsìn mímọ́ lẹ́rù, torí wọ́n kórìíra ìjọsìn mímọ́ àti gbogbo àwọn tó ń gbé e lárugẹ
19. Kí ló máa mú kí Gọ́ọ̀gù fẹ́ láti kó ìjọsìn mímọ́ lẹ́rù?
19 Èrò ibi tó wà lọ́kàn Gọ́ọ̀gù. Àwọn orílẹ̀-èdè máa “gbìmọ̀ ibi.” Wọ́n á máa wá ọ̀nà láti fìkanra mọ́ àwa tá à ń sin Jèhófà, torí inú tó ti ń bí wọn tipẹ́ àti bí wọ́n ṣe kórìíra wa látẹ̀yìn wá. Wọ́n á rò pé ṣìnkún lọwọ́ máa tẹ̀ wá, bí àwọn tó “ń gbé agbègbè tí kò ní ògiri, ọ̀pá ìdábùú tàbí àwọn ẹnubodè.” Ara àwọn orílẹ̀-èdè máa wà lọ́nà láti ‘rí ẹrù tó pọ̀, kí wọ́n sì kó o’ látọ̀dọ̀ àwọn ‘tó ń kó ọrọ̀ jọ.’ (Ìsík. 38:10-12) “Ọrọ̀” wo nìyẹn? Àwa èèyàn Jèhófà ní ọrọ̀ tó pọ̀ rẹpẹtẹ nípa tẹ̀mí; ìjọsìn mímọ́ wa tí à ń ṣe sí Jèhófà nìkan, ni ohun ìní tó ṣeyebíye jù lọ tá a ní. Àwọn orílẹ̀-èdè á wá bí wọ́n ṣe máa kó ìjọsìn mímọ́ lẹ́rù, kì í ṣe torí pé wọ́n mọyì rẹ̀, àmọ́ torí wọ́n kórìíra ìjọsìn mímọ́ àti gbogbo àwọn tó ń gbé e lárugẹ.
20. Báwo ni Gọ́ọ̀gù ṣe máa gbógun ja ilẹ̀ tàbí Párádísè tẹ̀mí?
20 Báwo ni Gọ́ọ̀gù ṣe máa gbógun ja ilẹ̀ tàbí párádísè tẹ̀mí? Ó ṣeé ṣe kí àwọn orílẹ̀-èdè fẹ́ dí wa lọ́wọ́, kí wọ́n má sì fẹ́ ká jọ́sìn Ọlọ́run. Wọ́n á fẹ́ fìyẹn dí oúnjẹ tẹ̀mí lọ́wọ́, wọn ò ní fẹ́ ká ṣèpàdé wa, wọ́n á fẹ́ da ìṣọ̀kan àárín wa rú, wọ́n á sì fẹ́ dá wa dúró bá a ṣe ń fìtara jíṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn nǹkan yìí ló sì para pọ̀ di párádísè tẹ̀mí. Sátánì máa tan àwọn orílẹ̀-èdè láti hùwà òmùgọ̀, wọ́n á fẹ́ pa àwọn olùjọsìn tòótọ́ rẹ́ ráúráú, kí wọ́n sì mú ìjọsìn mímọ́ kúrò láyé pátápátá.
21. Kí nìdí tó o fi dúpẹ́ pé Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀?
21 Ìgbéjàkò látọ̀dọ̀ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù yìí máa kan gbogbo àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ lórí ilẹ̀ tẹ̀mí tí Ọlọ́run fún wọn. A dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá pé Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀! Àmọ́, bá a ṣe ń retí ìpọ́njú ńlá, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní fi ìjọsìn mímọ́ sílẹ̀, àá sì máa fi sípò àkọ́kọ́ láyé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa mú kí ilẹ̀ tí Ọlọ́run mú pa dà bọ̀ sípò yìí máa rẹwà sí i báyìí. Àá sì lè wà lára àwọn tó máa fojú ara wọn rí ohun àgbàyanu lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà: Ìyẹn bí Jèhófà ṣe máa gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ àti orúkọ mímọ́ rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì, bá a ṣe máa rí i nínú orí tó kàn.
a Nínú orí tó kàn, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe máa bínú sí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ìgbà tó máa bínú àti ohun tí èyí máa túmọ̀ sí fún àwọn tó ń ṣe ìjọsìn mímọ́.
b Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2015, ojú ìwé 29 sí 30.
c Dáníẹ́lì 11:45 fi hàn pé ọba àríwá máa dájú sọ àwọn èèyàn Ọlọ́run, torí ó sọ pé ọba náà “máa pa àwọn àgọ́ ọba rẹ̀ sáàárín òkun ńlá [ìyẹn òkun Mẹditaréníà] àti òkè mímọ́ Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́ [ìyẹn ibi tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wà tẹ́lẹ̀, táwọn èèyàn Ọlọ́run sì ti ń jọ́sìn].”
d Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbéjàkò látọ̀dọ̀ “àwọn ará Ásíríà” òde òní tí wọ́n á wá ọ̀nà láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. (Míkà 5:5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun kan náà ni ìgbéjàkò mẹ́rin tí Bíbélì lo orúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún, tó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa bá àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tọ́ka sí, ìyẹn ìgbéjàkò látọ̀dọ̀ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, látọ̀dọ̀ ọba àríwá, látọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé àti látọ̀dọ̀ àwọn ará Ásíríà.
e Wo Orí 22 nínú ìwé yìí fún àlàyé nípa ẹni tí Bíbélì pè ní “Gọ́ọ̀gù àti Mágọ́gù” nínú ìwé Ìfihàn 20:7-9.