ORÍ 9
“Èmi Yóò Mú Kí Ọkàn Wọn Ṣọ̀kan”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ọ̀rọ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò àti ọ̀nà tí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì gbà ṣàlàyé rẹ̀
1-3. Báwo làwọn ará Bábílónì ṣe ń fi àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
FOJÚ inú wò ó pé Júù olóòótọ́ kan ni ẹ́, ìlú Bábílónì lo sì ń gbé. Àwọn èèyàn rẹ ti lo nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún nígbèkùn. Bó o ṣe máa ń ṣe lọ́jọ́ Sábáàtì, ò ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti jọ́sìn Jèhófà. Bó o ṣe ń gba ojú ọ̀nà tọ́pọ̀ èrò ń rìn kọjá, ò ń rí àwọn tẹ́ńpìlì ńláńlá àtàwọn ojúbọ tí kò lóǹkà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kóra jọ síbẹ̀, bí wọ́n ṣe ń rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin sí àwọn òrìṣà bíi Mádọ́kì.
2 Nígbà tó o kúrò níbi tọ́pọ̀ èèyàn kóra jọ sí, o dé ibi tí àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ wà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò pọ̀.a Ẹ rí ibì kan tó pa rọ́rọ́ tẹ́ ẹ ti lè gbàdúrà, kẹ́ ẹ kọrin ìyìn, kẹ́ ẹ sì jọ ronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítòsí ọ̀kan lára àwọn ipa odò tó wà ní ìlú náà. Bẹ́ ẹ ṣe ń gbàdúrà lọ, ò ń gbọ́ ìró tó rọra ń dún lára àwọn ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n dè mọ́lẹ̀ létí odò náà. Ara tù ẹ́ pé ibẹ̀ lálàáfíà dé ìwọ̀n kan. O gbà pé àwọn ará ìlú yẹn ò ní wá yín wá láti da ìpàdé yín rú bí wọ́n ṣe sábà máa ń ṣe. Àmọ́ kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?
3 Àwọn ará Bábílónì ti ṣẹ́gun nínú ọ̀pọ̀ ogun, wọ́n sì gbà pé àwọn òrìṣà wọn ló ń fún ìlú wọn lágbára. Lójú àwọn ará Bábílónì, bí wọ́n ṣe pa ìlú Jerúsálẹ́mù run ló mú kí wọ́n máa rò pé Mádọ́kì tó jẹ́ òrìṣà wọn lágbára ju Jèhófà lọ! Bó ṣe wá di pé wọ́n ń fi Ọlọ́run rẹ àti àwọn èèyàn rẹ̀ ṣẹlẹ́yà nìyẹn. Tí wọ́n bá ń fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà míì, wọ́n á sọ pé: “Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa”! (Sm. 137:3) Ọ̀pọ̀ sáàmù ló sọ nípa bí àwọn èèyàn Síónì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn sáàmù yẹn gan-an làwọn ará Bábílónì fẹ́ràn àtimáa fi ṣe yẹ̀yẹ́. Síbẹ̀ àwọn sáàmù kan ṣì wà tó sọ nípa àwọn ará Bábílónì fúnra wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di àwókù. . . . Àwọn tó yí wa ká ń fi wá ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́.”—Sm. 79:1, 3, 4.
4, 5. Ìrètí wo ló wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)
4 Àwọn Júù apẹ̀yìndà tún wà níbẹ̀, ó máa ń yá wọn lára láti fi ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Jèhófà àtàwọn wòlíì rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́. Láìfi gbogbo yẹ̀yẹ́ yìí pè, ìjọsìn mímọ́ ń tu ìwọ àti ìdílé rẹ nínú. Kò sóhun tó dà bíi pé kẹ́ ẹ jọ máa kọrin, kẹ́ ẹ sì jọ máa gbàdúrà. Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń tuni lára gan-an. (Sm. 94:19; Róòmù 15:4) Fojú inú wò ó pé lọ́jọ́ kan, ọ̀kan nínú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà mú ohun pàtàkì kan wá síbi tẹ́ ẹ kóra jọ sí, ìyẹn àkájọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì. Inú rẹ máa ń dùn tó o bá ń gbọ́ ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa dá àwọn èèyàn òun pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ó wú ẹ lórí gan-an nígbà tó o gbọ́ tí wọ́n ń ká irú ìlérí yìí jáde, lo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé lọ́jọ́ kan, ìwọ àti ìdílé rẹ máa pa dà sílé, ẹ sì máa lọ́wọ́ sí bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò!
5 Ìlérí nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò pọ̀ rẹpẹtẹ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìlérí yìí yẹ̀ wò. Báwo làwọn ìlérí yẹn ṣe ṣẹ sára àwọn tó wà nígbèkùn? Ìtumọ̀ wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní lóde òní? Láwọn ibì kan, a tún máa jíròrò bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.
“Wọn Yóò Lọ sí Ìgbèkùn, Wọ́n Á Kó Wọn Lẹ́rú”
6. Báwo ni Ọlọ́run ṣe kìlọ̀ léraléra fáwọn èèyàn rẹ̀ tó ya ọlọ̀tẹ̀?
6 Jèhófà bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, ó ní kí Ìsíkíẹ́lì sọ fún wọn bí òun ṣe máa fìyà jẹ wọ́n nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù. Jèhófà sọ pé, “wọn yóò lọ sí ìgbèkùn, wọ́n á kó wọn lẹ́rú.” (Ìsík. 12:11) Bá a ṣe rí i ní orí kẹfà ìwé yìí, Ìsíkíẹ́lì tún ṣàfihàn ìdájọ́ náà. Àmọ́, òun kọ́ lẹni àkọ́kọ́ tó máa ṣe irú ìkìlọ̀ yìí. Àtìgbà ayé Mósè, ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún ṣáájú àkókò yẹn, ni Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé tí wọn ò bá jáwọ́ nínú ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ń hù, ṣe ni wọ́n máa lọ sígbèkùn. (Diu. 28:36, 37) Àwọn wòlíì bí Àìsáyà àti Jeremáyà náà ti ṣe irú ìkìlọ̀ yìí.—Àìsá. 39:5-7; Jer. 20:3-6.
7. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀?
7 Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fetí sí àwọn ìkìlọ̀ náà. Nígbà tó yá, inú Jèhófà bà jẹ́ nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ táwọn èèyàn rẹ̀ ń hù, wọ́n ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ya aláìṣòótọ́, wọ́n ń jẹ́ kí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí kò dáa máa mú wọn hùwà ìbàjẹ́. Torí náà, Ọlọ́run jẹ́ kí ìyàn mú nílẹ̀ wọn, àjálù àti ìtìjú ni èyí sì fà fún wọn, torí pé “ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn” ni ilẹ̀ wọn látọdún yìí wá. (Ìsík. 20:6, 7) Bí Jèhófà ṣe sọ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, ó jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà lọ sígbèkùn. Lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Nebukadinésárì ọba Bábílónì gbógun ìkẹyìn jà wọ́n, ó pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ run. Wọ́n sì kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tí ogun yẹn ò pa lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Ibẹ̀ ni ìfiniṣẹ̀sín àti àtakò tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí ti wáyé.
8, 9. Báwo ni Ọlọ́run ṣe kìlọ̀ fún ìjọ Kristẹni nípa àwọn apẹ̀yìndà?
8 Ṣé irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tí wọ́n kó lọ sígbèkùn ní Bábílónì ṣẹlẹ̀ sí ìjọ Kristẹni náà? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ ni! Bíi tàwọn Júù ayé àtijọ́, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n ti kìlọ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tó ń wá sọ́dọ̀ yín nínú àwọ̀ àgùntàn, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n ní inú.” (Mát. 7:15) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣe irú ìkìlọ̀ yìí, ó ní: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn aninilára ìkookò máa wọlé sáàárín yín, wọn ò sì ní fọwọ́ pẹ̀lẹ́ mú agbo, àwọn kan máa dìde láàárín yín, wọ́n á sọ àwọn ọ̀rọ̀ békebèke láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn.”—Ìṣe 20:29, 30.
9 Àwọn Kristẹni gba ẹ̀kọ́ nípa bí wọ́n á ṣe dá àwọn èèyànkéèyàn yìí mọ̀, tí wọ́n á sì máa yẹra fún wọn. Bíbélì fún àwọn alàgbà ní ìtọ́ni pé kí wọ́n yọ àwọn apẹ̀yìndà kúrò nínú ìjọ. (1 Tím. 1:19; 2 Tím. 2:16-19; 2 Pét. 2:1-3; 2 Jòh. 10) Síbẹ̀, bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Júdà ayé àtijọ́, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí í kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ tá a fún wọn tìfẹ́tìfẹ́. Nígbà tí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi máa parí, àwọn apẹ̀yìndà ti fìdí múlẹ̀ nínú ìjọ. Jòhánù tó kẹ́yìn nínú àwọn àpọ́sítélì ṣì wà láàyè ní òpin ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó rí ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n ń hù nínú ìjọ àti ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tó gbalẹ̀ kan níbẹ̀. Òun nìkan ló kù nínú àwọn tí kò gba ìwà burúkú tó ń gbilẹ̀ náà láyè. (2 Tẹs. 2:6-8; 1 Jòh. 2:18) Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jòhánù kú?
10, 11. Báwo ni ohun tí Jésù sọ nínú àkàwé àlìkámà àti èpò ṣe ṣẹ láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni síwájú?
10 Lẹ́yìn tí Jòhánù kú, ohun tí Jésù sọ nínú àkàwé nípa àlìkámà àti èpò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ. (Ka Mátíù 13:24-30.) Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Sátánì gbin “èpò” tàbí àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà sínú ìjọ, bó ṣe di pé ìwà ìbàjẹ́ tàn kálẹ̀ nínú ìjọ nìyẹn. Ẹ wo bó ṣe máa ba Jèhófà nínú jẹ́ tó bó ṣe ń wo ìjọ tí Ọmọ rẹ̀ dá sílẹ̀, tí ìbọ̀rìṣà ti wá sọ dìdàkudà. Àwọn ayẹyẹ àtàwọn àṣà ìbọ̀rìṣà, títí kan ẹ̀kọ́ èké táwọn èèyàn gbà látọ̀dọ̀ àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tí kò mọ Ọlọ́run àti nínú ẹ̀sìn Sátánì, gbogbo ẹ̀ pátá ló kún inú ìjọ! Kí ni Jèhófà wá ṣe? Ohun tó ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ náà ló ṣe fún wọn, ó jẹ́ kí wọ́n mú àwọn èèyàn rẹ̀ nígbèkùn. Láti àkókò kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni síwájú, àwọn ẹni tó dà bí àlìkámà pa rẹ́ mọ́ àárín àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà. Ṣe ni ká kúkú sọ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ wà nígbèkùn Bábílónì Ńlá, ìyẹn gbogbo ìsìn èké àgbáyé, àmọ́ ní ti àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà, ṣe ni ìwàkiwà inú Bábílónì Ńlá wọ̀ wọ́n lẹ́wù pátápátá. Bí àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà ṣe ń gbilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dá ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀.
11 Ní gbogbo àkókò tí kò sí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sì ń lo agbára lórí àwọn èèyàn, àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ìyẹn àwọn “àlìkámà” tí Jésù sọ nínú àkàwé rẹ̀. Bíi ti àwọn Júù tó wà nígbèkùn, tí Ìsíkíẹ́lì 6:9 sọ nípa wọn, wọ́n rántí Ọlọ́run tòótọ́. Àwọn kan tiẹ̀ fìgboyà ta ko àwọn ẹ̀kọ́ èké tó kúnnú ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn èèyàn fi wọ́n ṣẹ̀sín, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wọn. Àmọ́, ṣé Jèhófà máa fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá nínú ìgbèkùn tẹ̀mí ni? Ká má rí i! Bíi ti ọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà fi ìbínú hàn dé ìwọ̀n tó yẹ, kò sì jẹ́ kó pẹ́ jù kí ìbínú náà tó rọlẹ̀. (Jer. 46:28) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ò fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ láìní ìrètí. Ẹ jẹ́ ká wá pa dà sọ́dọ̀ àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì àtijọ́, ká sì wo bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n nírètí pé wọ́n á bọ́ nígbèkùn lọ́jọ́ kan.
‘Mi Ò Ní Bínú Mọ́’
12, 13. Kí nìdí tí inú tó ń bí Jèhófà sí àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì fi máa rọlẹ̀?
12 Ohun tó tọ́ ni Jèhófà ṣe nígbà tó fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, àmọ́ ó tún fi dá wọn lójú pé ìbínú òdodo òun ò ní wà títí láé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ tó sọ, ó ní: ‘Mi ò ní bínú mọ́, inú mi ò ní ru sí wọn mọ́, màá ti tẹ́ ara mi lọ́rùn. Nígbà tí mo bá ti bínú gidigidi sí wọn tán, wọ́n á mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ti sọ pé èmi nìkan ni mo fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn.’ (Ìsík. 5:13) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi ní bínú mọ́?
13 Àwọn Júù olóòótọ́ wà lára àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn tí wọ́n kó lọ sígbèkùn. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé lára àwọn èèyàn òun máa ronú pìwà dà nígbèkùn tí wọ́n wà. Àwọn Júù tó ronú pìwà dà yìí máa sọ àwọn ohun ìtìjú tí wọ́n ṣe tó fi hàn pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n á bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí ji àwọn, kó sì fojúure wo àwọn. (Ìsík. 6:8-10; 12:16) Ìsíkíẹ́lì wà lára àwọn Júù olóòótọ́ yẹn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wòlíì Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Kódà, Dáníẹ́lì pẹ́ láyé débi tó fi rí ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ìgbèkùn náà. Àdúrà àtọkànwá tó gbà wà nínú Dáníẹ́lì orí 9, ìyẹn àdúrà tó fi bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jì wọ́n. Ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Dáníẹ́lì náà ló rí lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó wà nígbèkùn, tí wọ́n ń fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wọ́n, kó sì bù kún wọn. Ẹ wo bí ìlérí tí Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti sọ nípa ìtúsílẹ̀ àti ìmúbọ̀sípò ṣe máa dùn mọ́ wọn tó!
14. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ dá àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn?
14 Àmọ́, ohun pàtàkì míì tún wà nínú ọ̀rọ̀ ìtúsílẹ̀ àti ìmúbọ̀sípò àwọn èèyàn Jèhófà. Ìyẹn ni pé, wọ́n máa kúrò nígbèkùn lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, kì í ṣe torí pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ìtúsílẹ̀, àmọ́ torí ó tó àkókò lójú Jèhófà láti ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè. (Ìsík. 36:22) Àwọn ará Bábílónì yẹn máa gbà dájú pé àwọn òrìṣà wọn, irú bíi Mádọ́kì, kò lè dúró rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò ìlérí márùn-ún tí Jèhófà mí sí Ìsíkíẹ́lì pé kó sọ fún àwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ohun tí ìlérí kọ̀ọ̀kan máa túmọ̀ sí fáwọn olóòótọ́ yẹn. Lẹ́yìn náà, a máa rí bí àwọn ìlérí náà ṣe ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò.
15. Àwọn ìyípadà wo ló máa bá ọ̀nà tí àwọn tó dé láti ìgbèkùn gbà ń jọ́sìn?
15 ÌLÉRÍ KÌÍNÍ. Kò ní sí ìbọ̀rìṣà tàbí iṣẹ́ tó ń ríni lára ti ìsìn èké mọ́. (Ka Ìsíkíẹ́lì 11:18; 12:24.) Bá a ṣe sọ nínú Orí 5 ìwé yìí, àṣà ẹ̀sìn èké, irú bí ìbọ̀rìṣà, ti sọ Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ di ẹlẹ́gbin. Àwọn èèyàn ti wá yàyàkuyà, wọ́n sì ti kẹ̀yìn sí Jèhófà. Jèhófà gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé kí àwọn tó wà nígbèkùn máa retí ìgbà tí wọ́n tún máa láǹfààní láti máa ṣe ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì lábààwọ́n. Ohun pàtàkì tí gbogbo ìbùkún tó kù nípa ìmúbọ̀sípò yìí dá lé ni: bí ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò.
16. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa ìlú ìbílẹ̀ àwọn èèyàn rẹ̀?
16 ÌLÉRÍ KEJÌ. Wọ́n máa pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Jèhófà sọ fún àwọn tó wà nígbèkùn pé, ‘Màá fún yín ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.’ (Ìsík. 11:17) Ìlérí àgbàyanu ni ìlérí yìí, torí àwọn ará Bábílónì tí wọ́n ń pẹ̀gàn àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n mú lẹ́rú kò fún wọn ní ìrètí kankan pé wọ́n máa pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n fẹ́ràn. (Àìsá. 14:4, 17) Yàtọ̀ síyẹn, tí àwọn tó pa dà dé náà bá ṣì ń jẹ́ olóòótọ́, ilẹ̀ wọn á máa lọ́ràá, á sì máa méso jáde, èyí á jẹ́ kí wọ́n rí oúnjẹ jẹ, wọ́n á sì rí iṣẹ́ gidi ṣe. Ìtìjú àti ìbànújẹ́ tó bá wọn torí ìyàn tó mú náà máa dohun àtijọ́.—Ka Ìsíkíẹ́lì 36:30.
17. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Jèhófà?
17 ÌLÉRÍ KẸTA. Wọ́n á tún bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ Jèhófà. Bá a ṣe sọ ní Orí 2 ìwé yìí, ohun tí Òfin sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ipa pàtàkì ni ẹbọ àti ọrẹ kó nínú ìjọsìn mímọ́. Tí àwọn tó dé láti ìgbèkùn bá ṣáà ti jẹ́ onígbọràn, tó sì jẹ́ pé Jèhófà nìkan ni wọ́n ń sìn, ọrẹ tí wọ́n bá mú wá máa ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ìgbà yẹn ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn máa ní ìdáríjì, tí wọ́n á sì sún mọ́ Ọlọ́run wọn. Jèhófà ṣèlérí pé: “Gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò . . . sìn mí ní ilẹ̀ náà, gbogbo wọn pátá. Inú mi yóò dùn sí wọn níbẹ̀, èmi yóò sì béèrè ọrẹ yín àti àwọn àkọ́so ẹ̀bùn yín, gbogbo ohun mímọ́.” (Ìsík. 20:40) Ó dájú pé ìjọsìn tòótọ́ máa pa dà bọ̀ sípò, èyí sì máa mú ìbùkún bá àwọn èèyàn Ọlọ́run.
18. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ̀?
18 ÌLÉRÍ KẸRIN. Ó máa yọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn burúkú dà nù. Olórí ohun tó mú kí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣìnà pátápátá ni ipa tí àwọn ọkùnrin oníwàkiwà tó ń darí wọn ní lórí wọn. Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣàtúnṣe síyẹn. Ó sọ nípa àwọn olùṣọ́ àgùntàn burúkú yẹn pé: “Mi ò ní jẹ́ kí wọ́n bọ́ àwọn àgùntàn mi mọ́ . . . Màá gba àwọn àgùntàn mi sílẹ̀ ní ẹnu wọn.” Àmọ́, ní ti àwọn èèyàn Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà fi dá wọn lójú, pé: “Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi.” (Ìsík. 34:10, 12) Báwo ló ṣe máa ṣe é? Ó máa lo àwọn ọkùnrin olóòótọ́, á fi wọ́n ṣe olùṣọ́ àgùntàn.
19. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa ìṣọ̀kan àwọn èèyàn rẹ̀?
19 ÌLÉRÍ KARÙN-ÚN. Àwọn tó ń sin Jèhófà máa wà níṣọ̀kan. Ẹ fojú inú wo ẹ̀dùn ọkàn tó máa bá àwọn olóòótọ́ tó ń sin Jèhófà bí wọ́n ṣe ń wo ìpínyà tó wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run kí wọ́n tó lọ sígbèkùn. Àwọn wòlíì èké àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn tó ti di oníwà ìbàjẹ́ ló kéèràn ran àwọn èèyàn náà, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sáwọn wòlíì olóòótọ́ tó ń ṣojú fún Jèhófà; kódà wọ́n dá àwọn ẹgbẹ́ tó ń ta ko ara wọn sílẹ̀. Torí náà, ọ̀kan lára apá tó tuni lára jù lọ nínú ọ̀rọ̀ bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò náà ni ìlérí tí Ọlọ́run gbẹnu Ìsíkíẹ́lì ṣe pé: “Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan, màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn.” (Ìsík. 11:19) Tí àwọn Júù tó dé láti ìgbèkùn bá ti lè wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, tí ìṣọ̀kan sì tún wà láàárín àwọn fúnra wọn, kò sí ọ̀tá náà tó lè borí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ á lè mú ògo bá Jèhófà dípò ẹ̀gàn àti ojútì.
20, 21. Báwo ni ìlérí Ọlọ́run ṣe ṣẹ sára àwọn tó dé láti ìgbèkùn?
20 Ṣé àwọn ìlérí márààrún ṣẹ sára àwọn Júù tó dé láti ìgbèkùn? Ká má gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Jóṣúà, ọkùnrin olóòótọ́ ìgbà àtijọ́ sọ pé: “Kò sí ìkankan nínú gbogbo ìlérí tó dáa tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe fún yín tí kò ṣẹ. Gbogbo wọn ló ṣẹ fún yín. Ìkankan nínú wọn ò kùnà.” (Jóṣ. 23:14) Bí Jèhófà ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nígbà ayé Jóṣúà, bẹ́ẹ̀ náà ló máa mú un ṣẹ fún àwọn tó dé láti ìgbèkùn sí ìlú ìbílẹ̀ wọn.
21 Àwọn Júù jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà àtàwọn ohun ìríra inú ẹ̀sìn èké tó mú kí wọ́n kẹ̀yìn sí Jèhófà. Wọ́n pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, bó tiẹ̀ dà bíi pé kò lè ṣẹlẹ̀, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í dá oko, wọ́n sì ń gbádùn ayé wọn. Ọ̀kan lára ohun tí wọ́n kọ́kọ́ tún ṣe ni pẹpẹ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ tó ní ìtẹ́wọ́gbà lórí rẹ̀. (Ẹ́sírà 3:2-6) Jèhófà fi àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí tó dáa jíǹkí wọn, irú bí Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ, Nehemáyà àti Serubábélì tí wọ́n jẹ́ gómìnà, Jóṣúà Àlùfáà Àgbà àtàwọn wòlíì onígboyà bíi Hágáì, Sekaráyà àti Málákì. Tí àwọn èèyàn náà bá ti ń ṣe ohun tí Jèhófà sọ, tí wọ́n sì ń jẹ́ kó darí wọn, wọ́n á wà níṣọ̀kan, irú ìṣọ̀kan tí wọn ò ní láti ọjọ́ tó ti pẹ́.—Àìsá. 61:1-4; Ka Jeremáyà 3:15.
22. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣì máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò?
22 Ó dájú pé inú àwọn Júù máa dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí bí Jèhófà ṣe mú apá àkọ́kọ́ lára ìlérí rẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò ṣẹ. Síbẹ̀, ìmúṣẹ yẹn wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó gbòòrò jù bẹ́ẹ̀ lọ tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Àwọn èèyàn náà gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan kan. Wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé ìtọ́ni, ìgbà yẹn nìkan ni Jèhófà máa tó mú àwọn ìlérí náà ṣẹ. Ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá, àwọn Júù yìí tún ya aláìgbọràn àti ọlọ̀tẹ̀. Àmọ́ bí Jóṣúà ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà ò lè lọ láìṣẹ. Torí náà, àwọn ìlérí náà máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò, tó sì máa wà pẹ́ títí. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀.
‘Inú Mi Yóò Dùn sí Yín’
23, 24. Ìgbà wo ni ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?
23 Àwa tá a jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ọdún 1914 ni ètò nǹkan búburú yìí wọ àkókò òpin, ìyẹn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́ èyí kì í ṣe àkókò ìbànújẹ́ fún àwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Kódà, Bíbélì fi hàn pé ohun ìdùnnú kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914, ìyẹn “àkókò ìmúbọ̀sípò gbogbo ohun tí Ọlọ́run sọ.” (Ìṣe 3:21) Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó dáa, kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914? Ọlọ́run gbé Jésù Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba! Báwo lóhun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe jẹ́ ìmúbọ̀sípò? Ká má gbàgbé pé Jèhófà ti ṣèlérí fún Ọba Dáfídì pé títí láé ni wọ́n á máa jọba nínú ìdílé rẹ̀. (1 Kíró. 17:11-14) Àmọ́ àkóso ọ̀hún dáwọ́ dúró fúngbà díẹ̀ lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, tí wọ́n sì fòpin sí àkóso àwọn ọba tó wá láti ìdílé Dáfídì.
24 Àtọmọdọ́mọ Dáfídì ni Jésù tí Bíbélì pè ní “Ọmọ èèyàn,” torí náà, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti jọba ní ìdílé Dáfídì. (Mát. 1:1; 16:13-16; Lúùkù 1:32, 33) Nígbà tí Jèhófà gbé Jésù gorí ìtẹ́ lọ́run lọ́dún 1914, ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ bẹ̀rẹ̀! Ọ̀nà wá ṣí sílẹ̀ fún Jèhófà láti lo Ọba pípé yìí pé kó máa bá iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò lọ.
25, 26. Ìgbà wo ni ìgbèkùn Bábílónì Ńlá táwọn èèyàn ti wà tipẹ́tipẹ́ dópin, báwo la sì ṣe mọ̀ pé ìgbà yẹn ni? (Tún wo àpótí náà, “Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919”) (b) Kí ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ látọdún 1919 síwájú?
25 Ọ̀kan lára ohun tí Kristi kọ́kọ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba ni pé ó dara pọ̀ mọ́ Bàbá rẹ̀ láti ṣàyẹ̀wò ètò tí wọ́n ṣe fún ìjọsìn mímọ́ lórí ilẹ̀ ayé. (Mál. 3:1-5) Bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nínú àpèjúwe àlìkámà àti èpò, tipẹ́tipẹ́ ni kò ti ṣeé ṣe láti mọ ìyàtọ̀ láàárín àlìkámà àti èpò, ìyẹn àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró àti àwọn afàwọ̀rajà.b Àmọ́ nǹkan ti yí pa dà báyìí, àkókò ìkórè ti dé lọ́dún 1914, ìyàtọ̀ àárín àlìkámà àti èpò sì ti wá ṣe kedere. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú 1914 ni àwọn olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń túdìí ẹ̀kọ́ èké táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni, wọ́n sì ti ń ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ètò ṣọ́ọ̀ṣì tó ti dìdàkudà. Àkókò ti wá tó lójú Jèhófà láti mú wọn pa dà bọ̀ sípò pátápátá. Torí náà, lọ́dún 1919, ìyẹn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí ‘ìgbà ìkórè’ bẹ̀rẹ̀, a tú àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ pátápátá nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá. (Mát. 13:30) Bí ìgbèkùn náà ṣe dópin nìyẹn!
26 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò ju èyí táwọn èèyàn Ọlọ́run rí nígbà àtijọ́. Ẹ jẹ́ ká wá wo bí àwọn ìlérí márùn-ún tá a mẹ́nu bà ṣáájú ṣe ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò.
27. Báwo ni Ọlọ́run ṣe wẹ ìbọ̀rìṣà kúrò lára àwọn èèyàn rẹ̀?
27 ÌLÉRÍ KÌÍNÍ. Ìbọ̀rìṣà àtàwọn àṣà ẹ̀sìn míì tó ń ríni lára máa dópin. Lápá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún sí ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, àwọn Kristẹni olóòótọ́ ń kóra jọ, wọ́n sì ń yọ àwọn àṣà ẹ̀sìn èké dà nù. Irú bí ìjọsìn Ọlọ́run mẹ́talọ́kan, ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn àti ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì, gbogbo ẹ̀ pátá ni wọ́n yọ dà nù pé kò bá Bíbélì mu àti pé inú ẹ̀sìn èké ló ti wá. Wọ́n jẹ́ kó ṣe kedere pé ìbọ̀rìṣà gbáà ni lílo ère nínú ìjọsìn. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn Ọlọ́run wá rí i pé ìbọ̀rìṣà náà ni lílo àgbélébùú nínú ìjọsìn.—Ìsík. 14:6.
28. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà ti pa dà sí ilẹ̀ wọn?
28 ÌLÉRÍ KEJÌ. Àwọn èèyàn máa pa dà sí ilẹ̀ wọn nípa tẹ̀mí. Bí àwọn Kristẹni olóòótọ́ ṣe kúrò nínú àwọn ìsìn Bábílónì, wọ́n bára wọn ní ilẹ̀ tẹ̀mí tó yẹ kí wọ́n wà, ìyẹn ipò tàbí àyíká tó tura, níbi tí ìyàn tẹ̀mí ò ti ní mú mọ́. (Ka Ìsíkíẹ́lì 34:13, 14.) Bá a ṣe máa rí àlàyé síwájú sí i nínú Orí 19 ìwé yìí, Jèhófà ti fi ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí bù kún ilẹ̀ yẹn lọ́nà tó kọjá àfẹnusọ.—Ìsík. 11:17.
29. Báwo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù látọdún 1919?
29 ÌLÉRÍ KẸTA. Wọ́n á tún bẹ̀rẹ̀ sí í mú ọrẹ wá sórí pẹpẹ Jèhófà. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn Kristẹni kẹ́kọ̀ọ́ pé wọ́n máa rúbọ sí Ọlọ́run, àmọ́ kì í ṣe ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú, ẹbọ tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ni, ìyẹn ọ̀rọ̀ ẹnu wọn tí wọ́n fi ń yin Jèhófà, tí wọ́n sì fi ń wàásù nípa Ọlọ́run fáwọn míì. (Héb. 13:15) Ní gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún táwọn èèyàn Ọlọ́run fi wà nígbèkùn, kò sí ètò kankan tó mú kí irú ẹbọ yìí ṣeé ṣe. Àmọ́, nígbà tí ìgbèkùn náà ń parí lọ, àwọn èèyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ ìyìn yìí sí Ọlọ́run. Wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń fi ayọ̀ yin Ọlọ́run nínú àwọn ìpàdé wọn. Látọdún 1919, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti túbọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù láfiyèsí, wọ́n sì ń bójú tó iṣẹ́ náà kó lè túbọ̀ wà létòlétò. (Mát. 24:45-47) Bó ṣe di pé àwọn tó ń yin orúkọ Ọlọ́run ń pọ̀ sí i nìyẹn, gbogbo ìgbà ni wọ́n sì ń fi ẹbọ kún orí pẹpẹ Jèhófà!
30. Kí ni Jésù ṣe kó lè pèsè àwọn olùṣọ́ àgùntàn rere fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó nílò olùṣọ́ àgùntàn?
30 ÌLÉRÍ KẸRIN. Ó yọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn burúkú dà nù. Kristi gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn èké tó wà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà, tí wọn ò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ. Nínú agbo Kristi, wọ́n yọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ń ṣe bíi tàwọn olùṣọ́ àgùntàn burúkú yẹn nípò. (Ìsík. 20:38) Jésù tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà rí i dájú pé àbójútó wà fún àwọn àgùntàn òun. Lọ́dún 1919, ó yan ẹrú rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ àti olóye. Àwọn Kristẹni kéréje tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ẹni àmì òróró yìí ló ń múpò iwájú nínú pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí kí àwọn èèyàn Ọlọ́run lè rí àbójútó tó yẹ gbà. Nígbà tó yá, àwọn alàgbà bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa ṣèrànwọ́ láti bójú tó “agbo Ọlọ́run.” (1 Pét. 5:1, 2) Àpèjúwe tí Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti kọ sílẹ̀ nínú Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16 la sábà máa fi ń rán àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn létí ìlànà tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi gbé kalẹ̀.
31. Báwo ni Jèhófà ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 11:19 ṣẹ?
31 ÌLÉRÍ KARÙN-ÚN. Àwọn tó ń sin Jèhófà máa wà níṣọ̀kan. Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún wa ni àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí oríṣiríṣi ṣọ́ọ̀ṣì, ẹnu wọn ò sì kò lórí àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́ ohun àgbàyanu gidi ni Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó mú pa dà bọ̀ sípò. Ìlérí tó gbẹnu Ìsíkíẹ́lì ṣe ti ṣẹ lọ́nà tó wúni lórí, ìyẹn pé, “Èmi yóò mú kí ọkàn wọn ṣọ̀kan.” (Ìsík. 11:19) Kárí ayé ni Kristi ti ní ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ọmọlẹ́yìn tí wọ́n wá látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà, ẹ̀sìn àti àṣà tó yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan náà ni gbogbo wọn ń kọ́, ọ̀nà tí wọ́n sì gbà ń ṣe iṣẹ́ tí Kristi gbé fún wọn bára mu délẹ̀délẹ̀. Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kó tó kú, ó gbàdúrà taratara pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa wà níṣọ̀kan. (Ka Jòhánù 17:11, 20-23.) Lóde òní, Jèhófà ń dáhùn àdúrà yẹn lọ́nà tó gbòòrò jù lọ.
32. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò ṣe rí lára rẹ? (Tún wo àpótí náà, “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìgbèkùn àti Ìmúbọ̀sípò.”)
32 Ohun ayọ̀ gbáà ló jẹ́ láti máa gbé ní àkókò alárinrin tí ìjọsìn mímọ́ ti pa dà bọ̀ sípò yìí! À ń rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe ń ṣẹ lónìí ní gbogbo apá tí ìjọsìn wa pín sí. Ó dá wa lójú pé inú Jèhófà ti ń dùn sí àwọn èèyàn rẹ̀ báyìí, bó ṣe gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Inú mi yóò dùn sí yín.” (Ìsík. 20:41) Ṣé o mọyì àǹfààní tó o ní pé o wà lára àwọn èèyàn tó wà níṣọ̀kan, tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí ní àjẹtẹ́rùn, tí wọ́n ń yin Jèhófà kárí ayé, àwọn tí Ọlọ́run tú sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún nígbèkùn tẹ̀mí? Àmọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣì wà, tí Ìsíkíẹ́lì sọ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, tó ṣì máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò.
“Bí Ọgbà Édẹ́nì”
33-35. (a) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 36:35 túmọ̀ sí fáwọn Júù tó wà nígbèkùn? (b) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ náà túmọ̀ sí fáwọn èèyàn Jèhófà lóde òní? (Tún wo àpótí náà, ‘Àkókò Ìmúbọ̀sípò Ohun Gbogbo.’)
33 Bá a ṣe rí i, ‘àwọn àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ìjọba ìlà ìdílé Dáfídì pa dà bọ̀ sípò, ìyẹn ìgbà tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914. (Ìsík. 37:24) Lẹ́yìn náà, Jèhófà fún Kristi lágbára láti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò fáwọn èèyàn Rẹ̀, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún tí wọn ti wà nígbèkùn tẹ̀mí. Àmọ́, ṣe ibẹ̀ ni iṣẹ́ Kristi láti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò máa parí sí? Rárá o! Iṣẹ́ yẹn máa tẹ̀ síwájú lọ́nà tó gadabú lọ́jọ́ iwájú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ sì fún wa ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ń múnú ẹni dùn.
34 Bí àpẹẹrẹ, gbé àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí yẹ̀ wò: “Àwọn èèyàn á sì sọ pé: ‘Ilẹ̀ tó ti di ahoro náà ti dà bí ọgbà Édẹ́nì.’” (Ìsík. 36:35) Kí ni ìlérí yẹn túmọ̀ sí fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn? Ó dájú pé wọn ò retí pé kí ìlérí yìí ṣẹ ní tààràtà, bíi pé kí ilẹ̀ wọn di ọgbà tí Jèhófà fúnra rẹ̀ kọ́kọ́ dá tàbí kó di Párádísè. (Jẹ́n. 2:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yé wọn pé ṣe ni Jèhófà fi ń dá wọn lójú pé ilẹ̀ wọn tó máa pa dà bọ̀ sípò máa lẹ́wà, á sì máa méso jáde.
35 Kí ni ìlérí yìí túmọ̀ sí fún wa lónìí? Àwa náà ò retí pé kó ṣẹ ní tààràtà báyìí nínú ayé burúkú tí Sátánì Èṣù ń ṣàkóso yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lóye pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ń ṣẹ nípa tẹ̀mí lónìí. Àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbé lórí ilẹ̀ tẹ̀mí tá a mú pa dà bọ̀ sípò, ìyẹn ipò tàbí àyíká tí ìṣẹ́ ìsìn wa ti ń sèso rere, tí ìjọsìn Ọlọ́run sì jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sí wa. Díẹ̀díẹ̀ ni ilẹ̀ tẹ̀mí yìí ń dáa sí i, bó ṣe ń dáa sí i, ló túbọ̀ ń di Párádísè. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
36, 37. Àwọn ìlérí wo ló máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú nínú Párádísè?
36 Lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì, Jésù máa mú kí iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò rẹ̀ nasẹ̀ dé ayé tá à ń gbé yìí. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀, ó máa darí àwọn èèyàn láti sọ gbogbo ayé yìí di ọgbà Édẹ́nì, ìyẹn Párádísè, bó ṣe ń wu Jèhófà nígbà gbogbo pé kó rí! (Lúùkù 23:43) Nígbà yẹn, gbogbo èèyàn pátá ló máa wà níṣọ̀kan, wọ́n á sì nílé tiwọn. Ewu kankan ò ní wu wọ́n, ẹnikẹ́ni ò sì ní halẹ̀ mọ́ wọn. Ẹ tún fojú inú wo bó ṣe máa rí nígbà tí ìlérí yìí bá ṣẹ, pé: “Èmi yóò bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà, èmi yóò sì pa àwọn ẹranko ẹhànnà run ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè máa gbé láìséwu nínú aginjù, kí wọ́n sì sùn nínú igbó.”—Ìsík. 34:25.
37 Fojú inú wo bó ṣe máa rí ná. Wàá lè lọ síbikíbi tó o bá fẹ́ lọ láyé, láìsí pé ohunkóhun ń bà ẹ́ lẹ́rù. Ẹranko kankan ò ní wu ẹ́ léwu. Ohunkóhun ò sì ní bà ẹ́ lẹ́rù. Wàá lè dá nìkan rìn wọnú igbó kìjikìji, wàá rí bí àwọn igbó náà ṣe lẹ́wà tó, kódà wàá lè sùn mọ́jú níbẹ̀ láìséwu, ara rẹ á sì le koko nígbá tó o bá jí!
38. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tí ìlérí tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 28:26 bá ṣẹ?
38 Ìlérí míì tó tún máa ṣẹ nìyí, ó ní: “Wọn yóò máa gbé [ilẹ̀ náà], ààbò yóò sì wà lórí wọn, wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, nígbà tí mo bá ṣèdájọ́ gbogbo àwọn tó yí wọn ká tó ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, ààbò yóò wà lórí wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.” (Ìsík. 28:26) Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọ̀tá Jèhófà bá pa rẹ́, àlàáfíà àti ààbò máa wà níbi gbogbo láyé. Bá a ṣe ń bójú tó ayé, bẹ́ẹ̀ náà ni àá máa ṣìkẹ́ ara wa àtàwọn èèyàn wa, àá máa kọ́lé ìdẹ̀rùn, àá sì máa gbin oríṣiríṣi oúnjẹ sínú ọgbà wa.
39. Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì kọ sílẹ̀ nípa Párádísè máa ṣẹ?
39 Ṣé àwọn ìlérí yìí ò jọ àlá tí kò lè ṣẹ lójú rẹ? Rántí àwọn ohun tó o ti rí ní ‘àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo’ tá a wà yìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sátánì ń gbógun lọ́tùn-ún lósì, Ọlọ́run wa ti fún Jésù lágbára láti mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò lásìkò tí gbogbo nǹkan dojú dé yìí. Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nìyẹn jẹ́ pé gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ pátá ló máa ṣẹ!
a Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Júù tó wà nígbèkùn ló ń gbé níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Bábílónì. Bí àpẹẹrẹ, Ìsíkíẹ́lì wà lára àwọn Júù tó ń gbé nítòsí odò Kébárì. (Ìsík. 3:15) Àmọ́, àwọn Júù mélòó kan wà tó jẹ́ pé inú ìlú yẹn gangan ni wọ́n wà. Lára àwọn tó wà níbẹ̀ ni “àwọn ọmọ ọba àti ọmọ àwọn èèyàn pàtàkì.”—Dán. 1:3, 6; 2 Ọba 24:15.
b Bí àpẹẹrẹ, a ò lè sọ ní pàtó èyí tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró nínú àwọn tó fẹ́ ṣe àtúnṣe sí ìsìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún.