ORÍ 20
“Pín Ilẹ̀ Náà bí Ogún”
OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ìtumọ̀ ilẹ̀ tí wọ́n pín
1, 2. (a) Kí ni Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
ÌSÍKÍẸ́LÌ ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìran kan tó dájú pé á mú kó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) ọdún sẹ́yìn, ìyẹn nígbà ayé Mósè àti Jóṣúà. Lákòókò yẹn, Jèhófà sọ bí ààlà Ilẹ̀ Ìlérí ṣe rí fún Mósè, ó sì tún sọ fún Jóṣúà nígbà tó yá nípa bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. (Nọ́ń. 34:1-15; Jóṣ. 13:7; 22:4, 9) Àmọ́, lọ́dún 593 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn pé kí wọ́n tún pín Ilẹ̀ Ìlérí náà fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì!—Ìsík. 45:1; 47:14; 48:29.
2 Kí ni Ọlọ́run fi ìran yìí sọ fún Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn? Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìran yẹn ń fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí lóde òní? Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú ìran yìí máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú?
Ìran Tó Mú Kí Ohun Mẹ́rin Dájú
3, 4. (a) Ohun mẹ́rin wo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí kẹ́yìn mú kó dá àwọn tó wà nígbèkùn lójú? (b) Nínú orí yìí, èwo nínú àwọn ìlérí tó mú kó dá wọn lójú la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Ìran tó kẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì rí ló wà nínú odindi orí mẹ́sàn-án nínú ìwé tó kọ. (Ìsík. 40:1–48:35) Ìran yìí mú kí ohun mẹ́rin dá àwọn tó wà nígbèkùn lójú, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa pa dà bọ̀ sípò. Kí làwọn ohun tó mú kó dá wọn lójú yẹn? Àkọ́kọ́ ni pé, ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run. Ìkejì, àwọn àlùfáà àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olódodo lá máa darí orílẹ̀-èdè tó pa dà bọ̀ sípò náà. Ìkẹta, gbogbo àwọn tó máa pa dà sí Ísírẹ́lì máa ní ilẹ̀ tiwọn. Ìkẹrin sì ni pé, Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, á sì máa bá wọn gbé bíi ti tẹ́lẹ̀.
4 Orí 13 àti 14 ìwé yìí sọ bí méjì àkọ́kọ́ lára ìlérí yẹn ṣe máa ṣẹ, ìyẹn bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò àti bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olódodo á ṣe máa darí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Nínú orí yìí, ohun kẹta tó mú kó dá wọn lójú la máa fún láfiyèsí, ìyẹn ìlérí nípa bí àwọn èèyàn ṣe máa jogún ilẹ̀ náà. Ní orí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tó dá lórí bí Jèhófà ṣe máa wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.—Ìsík. 47:13-21; 48:1-7, 23-29.
‘Mo Pín Ilẹ̀ Yìí fún Yín Láti Jẹ́ Ogún Yín’
5, 6. (a) Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ilẹ̀ wo ni wọ́n máa pín? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.) (b) Kí lohun tí ìran nípa pínpín ilẹ̀ náà wà fún?
5 Ka Ìsíkíẹ́lì 47:14. Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì rí ilẹ̀ kan nínú ìran, ìyẹn ilẹ̀ tó máa tó dà bí “ọgbà Édẹ́nì.” (Ìsík. 36:35) Jèhófà wá sọ pé: “Ilẹ̀ tí ẹ máa yàn bí ogún fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá (12) nìyí.” (Ìsík. 47:13) “Ilẹ̀” tí wọ́n máa pín ni ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó ti pa dà bọ̀ sípò, èyí tí àwọn tó wà nígbèkùn máa pa dà sí. Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ààlà tó wà ní eteetí ilẹ̀ náà, bó ṣe wà nínú Ìsíkíẹ́lì 47:15-21.
6 Kí lohun tí ìran nípa pínpín ilẹ̀ yìí wà fún? Ohun tí Ọlọ́run sọ nípa àwọn ibi tí ààlà ilẹ̀ náà dé mú kó dá Ìsíkíẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ wà nígbèkùn lójú pé ilẹ̀ wọn tí wọ́n fẹ́ràn máa pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Fojú inú wo bí ìdánilójú tí Jèhófà fún àwọn tó wà nígbèkùn ṣe máa rí lára wọn, ó dájú pé inú wọn máa dùn sí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Jèhófà ṣe lọ́nà tó ṣe kedere! Ṣé àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́ gba ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn pé kí wọ́n jogún lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, wọ́n gbà á.
7. (a) Àwọn nǹkan wo ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, kí nìyẹn sì rán wa létí? (b) Ìbéèrè wo la máa kọ́kọ́ dáhùn?
7 Lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) lẹ́yìn tí Ìsíkíẹ́lì rí ìran, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó wà nígbèkùn bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Àwọn ohun mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn yẹn rán wa létí pé irú ohun kan náà ti ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní. Lọ́nà kan, àwọn náà gba ilẹ̀ tí wọ́n pín fún wọn. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Jèhófà jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wọ ilẹ̀ tẹ̀mí kan, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Torí náà, Ilẹ̀ Ìlérí ayé àtijọ́ tó pa dà bọ̀ sípò kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan nípa bí ilẹ̀ tẹ̀mí àwọn èèyàn Ọlọ́run òde òní ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Àmọ́ ká tó gbé àwọn ẹ̀kọ́ náà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ dáhùn ìbéèré yìí, “Kí nìdí tá a fi gbà pé ilẹ̀ tẹ̀mí kan wà lóde òní lóòótọ́?”
8. (a) Orílẹ̀-èdè wo ni Jèhófà fi rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tara? (b) Kí ni ilẹ̀ tẹ̀mí tàbí párádísè tẹ̀mí túmọ̀ sí? (d) Ìgbà wo ló wáyé, àwọn wo ló sì ń gbé lórí ilẹ̀ náà?
8 Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì kọ́kọ́ rí, Jèhófà jẹ́ kó rí i pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Ísírẹ́lì ṣe máa pa dà bọ̀ sípò máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lẹ́yìn tí “Dáfídì ìránṣẹ́” rẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi, bá bẹ̀rẹ̀ sí í jọba. (Ìsík. 37:24) Ọdún 1914 Sànmánì Kristẹni ni èyí ṣẹlẹ̀. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà yẹn ni Ọlọ́run ti fi orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tara tí wọ́n jẹ́ èèyàn Ọlọ́run. (Ka Mátíù 21:43; 1 Pétérù 2:9.) Àmọ́, kì í ṣe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí nìkan ni Jèhófà fi rọ́pò orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nípa tara, ó tún fi ilẹ̀ tẹ̀mí tàbí párádísè tẹ̀mí rọ́pò ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́. (Àìsá. 66:8) Bá a ṣe rí i ní Orí 17 ìwé yìí, ilẹ̀ tẹ̀mí yẹn ni àyíká tẹ̀mí tó ní ààbò tàbí ibi tá a ti ń gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí, níbi tí àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti ń sin Jèhófà látọdún 1919. (Wo àpótí 9B, “Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún 1919”) Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn tó nírètí láti gbé láyé, ìyẹn àwọn “àgùntàn mìíràn,” bẹ̀rẹ̀ sí í gbé orí ilẹ̀ tẹ̀mí yìí. (Jòh. 10:16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé párádísè tẹ̀mí ń tura sí i, ó sì ń gbèrú, ó di ẹ̀yìn Amágẹ́dọ́nì ká tó gbádùn ìbùkún ibẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Wọ́n Pín Ilẹ̀ Náà Lọ́gbọọgba, Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ
9. Kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ni Jèhófà sọ nípa bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà?
9 Ka Ìsíkíẹ́lì 48:1, 28. Lẹ́yìn tí Jèhófà sọ ibi tí ààlà ilẹ̀ náà lódindi máa dé, ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe pín in. Ó ní kí ogún tí wọ́n máa pín fún ẹ̀yà méjìlá (12) náà jẹ́ ọgbọọgba, kó sì jẹ́ láti àríwá sí gúúsù. Kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ pínpín náà látorí ẹ̀yà Dánì tó wà ní ìkángun àríwá ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì parí rẹ̀ sọ́dọ̀ ẹ̀yà Gádì ní ìkángun ààlà gúúsù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ogún méjìlá (12) náà ló ní ilẹ̀ tó tẹ́jú pẹrẹsẹ, ó lọ láti ààlà ilẹ̀ náà tó wà ní ìlà oòrùn títí dé Òkun Ńlá tàbí Òkun Mẹditaréníà, ní ìwọ̀ oòrùn.—Ìsík. 47:20.
10. Kí ló wà nínú apá tá a gbé yẹ̀ wò nínú ìran yìí tó ṣeé ṣe kó fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀?
10 Ó ṣeé ṣe kí apá tá a jíròrò nínú ìran yìí fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀, lọ́nà wo? Ó dájú pé kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Ìsíkíẹ́lì ṣe nípa bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà máa mórí àwọn tó wà nígbèkùn wú gan-an, wọ́n á rí i pé ètò tó dáa ti wà lórí bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ náà. Yàtọ̀ síyẹn, bí wọ́n ṣe sọ ìpín tó máa kan ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà mú kó dá wọn lójú pé gbogbo àwọn tó dé láti ìgbèkùn ló máa gba ogún lórí ilẹ̀ tí wọ́n pa dà sí. Gbogbo wọn ló máa ní ilẹ̀ àti ilé tiwọn.
11. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìran tó sọ bí wọ́n á ṣe pín ilẹ̀ náà? (Wo àpótí náà, “Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà.”)
11 Ẹ̀kọ́ tó ń fúnni lókun wo la lè kọ́ látinú ìran yẹn lónìí? Kì í ṣe àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti àwọn olórí nìkan ló jadùn Ilẹ̀ Ìlérí tó pa dà bọ̀ sípò, gbogbo àwọn tó wà nínú ẹ̀yà méjìlá (12) ló jadùn rẹ̀. (Ìsík. 45:4, 5, 7, 8) Bákan náà ló rí lónìí, kì í ṣe àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn tó ń múpò iwájú lára “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” nìkan ló ń jadùn párádísè tẹ̀mí, gbogbo àwọn tó wà nínú ogunlọ́gọ̀ èèyàn náà ń jadùn rẹ̀.a (Ìfi. 7:9) Kò sí bí ipa tá à ń kó nínú ètò Ọlọ́run ṣe rẹlẹ̀ tó, àyè wà fún wa lórí ilẹ̀ tẹ̀mí náà, iṣẹ́ tó ṣeyebíye sì wà fún wa láti ṣe. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Báwo Ni Ìlànà Méjì Tó Yàtọ̀ Síra Ṣe Kàn Wá?
12, 13. Ìtọ́ni tó ṣe pàtó wo ni Jèhófà fi lélẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì?
12 Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára ohun tí Jèhófà sọ nípa bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ náà rú Ìsíkíẹ́lì lójú, torí wọ́n yàtọ̀ sí ohun tí Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kó ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo méjì lára ìyàtọ̀ yẹn. Ọ̀kan jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀; èkejì sì ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn tó máa gbé ibẹ̀.
13 Àkọ́kọ́, ilẹ̀ náà. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé kí ilẹ̀ tó máa pín fún àwọn ẹ̀yà tó tóbi pọ̀ ju èyí tó máa pín fún àwọn ẹ̀yà tí kò tóbi. (Nọ́ń. 26:52-54) Àmọ́, nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà ní kí wọ́n pín ilẹ̀ fún gbogbo ẹ̀yà, kí “ìpín kálukú . . . sì dọ́gba [“kálukú bí arákùnrin rẹ̀,” àlàyé ìsàlẹ̀].” (Ìsík. 47:14) Torí náà, nínú gbogbo ẹ̀yà méjìlá (12) tí wọ́n pín ogún fún, kò sí ẹni tí ogún tiẹ̀ kéré sí tẹni kejì, ọgbọọgba ni, láti ààlà tó wà ní àríwá títí dé ààlà tó wà ní gúúsù. Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì pátá, láìka ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí, gbogbo wọn ló jọ máa nípìn-ín nínú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tó ń jáde láti Ilẹ̀ Ìlérí tó jẹ́ ilẹ̀ tó lómi dáadáa.
14. Báwo lohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn àjèjì ṣe yàtọ̀ sí ohun tó sọ nínú Òfin Mósè?
14 Èkejì, àwọn tó máa gbé ibẹ̀. Òfin Mósè dáàbò bo àwọn àjèjì, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà, àmọ́ wọn ò pín ilẹ̀ fún wọn. (Léf. 19:33, 34) Àmọ́, ohun tí Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì lọ́tẹ̀ yìí yàtọ̀ sí ohun tó sọ nínú Òfin Mósè. Jèhófà sọ fún un pé: “Agbègbè tó jẹ́ ti ẹ̀yà tí àjèjì náà ń gbé ni kí ẹ ti fún un ní ogún.” Jèhófà lo àṣẹ yìí láti fòpin sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín “ọmọ Ísírẹ́lì” àti àjèjì tó ń gbé ilẹ̀ náà. (Ìsík. 47:22, 23) Nínú ilẹ̀ tó pa dà bọ̀ sípò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ó rí i pé ọgbọọgba làwọn ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì ń jọ́sìn níṣọ̀kan.—Léf. 25:23.
15. Òtítọ́ pàtàkì wo nípa Jèhófà ni ìtọ́sọ́nà nípa ilẹ̀ náà àtàwọn tó máa gbé ibẹ̀ jẹ́ ká mọ̀?
15 Ó dájú pé àwọn ìtọ́sọ́nà pàtàkì méjì tí Ìsíkíẹ́lì gbà nípa ilẹ̀ náà àti àwọn tó máa gbé ibẹ̀ máa fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ gan-an. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà máa pín ilẹ̀ fún wọn lọ́gbọọgba, bóyá ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n, àbí àjèjì tó ń sin Jèhófà. (Ẹ́sírà 8:20; Neh. 3:26; 7:6, 25; Àìsá. 56:3, 8) Àwọn ìtọ́sọ́nà yìí tún jẹ́ ká mọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà pé, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ló ṣeyebíye lójú rẹ̀ bákan náà. (Ka Hágáì 2:7.) Lóde òní, a mọyì òtítọ́ kan náà yẹn, bóyá ìrètí láti gbé lọ́run la ní o, àbí ti orí ilẹ̀ ayé.
16, 17. (a) Àǹfààní wo la rí nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò nípa ilẹ̀ náà àtàwọn tó máa gbé ibẹ̀? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò ní orí tó tẹ̀ lé e?
16 Àǹfààní wo la rí nínú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò nípa ilẹ̀ náà àtàwọn tó máa gbé ibẹ̀? Ohun tá a kọ́ ti rán wa létí pé ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará wa ṣe pàtàkì gan-an lóde òní àti pé a gbọ́dọ̀ máa fi hàn kedere pé kò sí ojúsàájú nínú ètò Ọlọ́run. Jèhófà kì í ṣojúsàájú. Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé èmi náà kì í ṣe ojúsàájú bíi ti Jèhófà? Ṣé mo máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, láìka ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà sí tàbí ipò tí wọ́n bá ara wọn nígbèésí ayé?’ (Róòmù 12:10) Inú wa dùn pé Jèhófà fún gbogbo wa ní àǹfààní kan náà láti máa gbádùn párádísè tẹ̀mí, ibẹ̀ la ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá sí Baba wa ọ̀run, tá a sì ń gbádùn àwọn ìbùkún rẹ̀.—Gál. 3:26-29; Ìfi. 7:9.
17 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ohun kẹrin tí Jèhófà mú kó dá Ìsíkíẹ́lì lójú, ní apá tó parí ìran tó rí kẹ́yìn, ìyẹn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa wà pẹ̀lú àwọn tó wà nígbèkùn. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìlérí náà? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yìí ní orí tó tẹ̀ lé e.