Ẹ̀KỌ́ 52
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Múra Lọ́nà Tó Bójú Mu
Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló nírú aṣọ tó fẹ́ràn láti máa wọ̀, ọ̀nà tá à ń gbà múra sì yàtọ̀ síra. Jèhófà fún wa láwọn ìlànà tó rọrùn láti lóye nípa bá a ṣe lè múra. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí, àá máa wọ aṣọ tó bójú mu, àá sì máa múnú Jèhófà dùn. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìlànà yẹn.
1. Àwọn ìlànà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra?
Ó yẹ ká máa wọ “aṣọ tó bójú mu . . . pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀,” ká sì máa wà ní mímọ́ tónítóní nígbà gbogbo káwọn èèyàn lè rí i pé à ń “sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.” (1 Tímótì 2:9, 10) Ronú nípa àwọn ìlànà mẹ́rin yìí: (1) Ó yẹ ká máa wọ aṣọ tó “bójú mu.” Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé àwa èèyàn Jèhófà máa ń múra lọ́nà tó yàtọ̀ síra láwọn ìpàdé wa, síbẹ̀ ìmúra wa àti bá a ṣe ń ṣerun máa ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tá à ń sìn. (2) Tá a bá fẹ́ kí ìmúra wa fi hàn pé a ‘mọ̀wọ̀n ara wa’ a ò ní máa wọ aṣọ tá a mú káwọn èèyàn máa ronú nípa ìṣekúṣe, a ò sì ní máa múra torí káwọn èèyàn lè rí bá a ṣe lówó tó tàbí kí wọ́n lè máa kan sárá sí wa. (3) A máa fi hàn pé a ní “àròjinlẹ̀” tá a bá ń kíyè sára ká má bàa fara mọ́ gbogbo aṣọ àti ìmúra tó wà lóde. (4) Gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa múra lọ́nà táá fi hàn pé à ń “sin Ọlọ́run tọkàntọkàn” àti lọ́nà táá jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ là ń sìn.—1 Kọ́ríńtì 10:31.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀?
Òótọ́ ni pé a lómìnira láti múra lọ́nà tó wù wá, síbẹ̀ ó yẹ ká máa ro tàwọn míì tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀. Kò yẹ ká máa múnú bí àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ ká máa “ṣe ohun tó wu ọmọnìkejì [wa] fún ire rẹ̀, láti gbé e ró.”—Ka Róòmù 15:1, 2.
3. Báwo ni ìmúra wa ṣe lè mú kó wu àwọn èèyàn láti wá sin Jèhófà?
Gbogbo ìgbà la máa ń fẹ́ wọ aṣọ tó bójú mu, àmọ́ a tún máa ń kíyè sára ní pàtàkì tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé ìjọ àtìgbà tá a bá fẹ́ lọ wàásù. Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a ò fẹ́ káwọn èèyàn fojú àbùkù wo ìhìn rere tá à ń wàásù torí ìmúra wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, à ń múra lọ́nà táá mú kó wu àwọn èèyàn láti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ká sì “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa . . . lọ́ṣọ̀ọ́.”—Títù 2:10.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tá a lè ṣe ká lè máa wọ aṣọ tó bójú mu, ká sì máa múra lọ́nà tó máa fi hàn pé Kristẹni ni wá.
4. À ń bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tá a bá ń múra lọ́nà tó bójú mu
Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká máa múra lọ́nà tó bójú mu? Ka Sáàmù 47:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Tá a bá ń rántí pé à ń ṣojú fún Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra wa?
Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu ká máa ronú nípa aṣọ àti ìmúra wa tá a bá ń lọ sípàdé tàbí nígbà tá a bá fẹ́ lọ wàásù? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
5. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa wọ aṣọ tó dáa, ká sì máa múra lọ́nà tó bójú mu?
Kò pọn dandan kí aṣọ wa jẹ́ olówó ńlá, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká máa wọ aṣọ tó mọ́ tónítóní, táá sì buyì kún ohun tá à ń ṣe. Ka 1 Kọ́ríńtì 10:24 àti 1 Tímótì 2:9, 10. Lẹ́yìn náà, kó o ronú lórí ìdí tí kò fi yẹ ká máa wọ aṣọ . . .
tó rí wúruwùru tàbí aṣọ tí kò bá ohun tá a fẹ́ ṣe mu.
tó fún mọ́ra, tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí aṣọ èyíkéyìí tó lè mú káwọn èèyàn máa ronú nípa ìṣekúṣe.
Kò pọn dandan káwa Kristẹni máa tẹ̀ lé Òfin Mósè, àmọ́ òfin náà lè jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe ń ronú. Ka Diutarónómì 22:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa wọ aṣọ tó máa ń jẹ́ kí ọkùnrin jọ obìnrin tàbí èyí tó máa ń jẹ́ kí obìnrin jọ ọkùnrin?
Ka 1 Kọ́ríńtì 10:32, 33 àti 1 Jòhánù 2:15, 16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sí ohun tí àwọn aládùúgbò àtàwọn ará lè máa rò nípa ìmúra wa?
Báwo làwọn èèyàn ṣe sábà máa ń múra ládùúgbò yín?
Ṣé o rò pé gbogbo ìmúra yẹn ló bójú mu fún Kristẹni? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Aṣọ tó bá wù mí ni mo lè wọ̀.”
Ṣé èrò tìẹ náà nìyẹn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
A máa fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tá a bá ń múra lọ́nà tó bójú mu, ìyẹn á tún fi hàn pé a gba tàwọn míì rò.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀?
Àwọn ìlànà wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ pinnu irú aṣọ tá a máa wọ̀ àti bá a ṣe máa múra?
Kí ni ìmúra wa máa jẹ́ káwọn èèyàn rò nípa ìjọsìn tá à ń ṣe?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ohun tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn máa rò nípa rẹ torí aṣọ tó ò ń wọ̀.
Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ìdí tó fi yẹ kó o ronú dáadáa kó o tó pinnu bóyá wàá fín àmì sára.
“Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fínfín Àmì sí Ara?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn ìlànà míì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá fẹ́ ṣèpinnu lórí aṣọ tó o máa wọ̀ àti ìmúra rẹ.
“Ǹjẹ́ Ìmúra Rẹ Ń Fògo fún Ọlọ́run?” (Ilé Ìṣọ́, September 2016)
Kí ló ran obìnrin olóòótọ́ kan lọ́wọ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í gba tàwọn míì rò lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra?
“Ìmúra àti Ìwọṣọ Ni Kò Jẹ́ Kí N Tètè Rí Òtítọ́” (Jí!, March 8, 2004)