Ẹ̀KỌ́ 53
Yan Eré Ìnàjú Táá Múnú Jèhófà Dùn
“Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà. (1 Tímótì 1:11) Ó fẹ́ ká máa láyọ̀, ká sì gbádùn ayé wa. Inú rẹ̀ máa ń dùn sí wa tá a bá ń wá àyè láti sinmi. Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè fọgbọ́n lo àsìkò tá a fi ń sinmi lọ́nà táá mú ká gbádùn ara wa, ká sì múnú Jèhófà dùn.
1. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ yan eré ìnàjú tá a máa ṣe?
Kí ló máa ń wù ẹ́ láti ṣe nígbà tọ́wọ́ ẹ bá dilẹ̀? Àwọn kan máa ń fẹ́ dá wà nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, kí wọ́n lè máa kàwé, gbọ́ orin, wo fíìmù tàbí wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn míì máa ń fẹ́ wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wọn, kí wọ́n lè gbafẹ́ jáde, kí wọ́n lọ lúwẹ̀ẹ́ lódò, kí wọ́n ta ayò, tàbí gbá géèmù. Bóyá a fẹ́ máa dá nìkan wà ni o àbí a fẹ́ máa wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa, ó yẹ ká rí i dájú pé eré ìnàjú tá à ń ṣe wà lára “ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà.” (Éfésù 5:10) Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì, torí pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn eré ìnàjú tó wà lónìí ló máa ń ní àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra nínú, irú bí ìwà ipá, ìṣekúṣe tàbí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn. (Ka Sáàmù 11:5.) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ eré ìnàjú?
Tá a bá mú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́ nípa eré ìnàjú. Bá a ṣe rí i nínú ẹ̀kọ́ tó ṣáájú èyí, “ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àwọn tí ò mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run la mú lọ́rẹ̀ẹ́, a máa “rí láburú.”—Òwe 13:20.
2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré ìnàjú?
Tí eré ìnàjú tá a fẹ́ràn bá tiẹ̀ bójú mu, a gbọ́dọ̀ kíyè sára kó má di pé àá máa lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀. Torí tá ò bá ṣọ́ra, a lè má ráyè fáwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Bíbélì sọ pé ká máa “lo àkókò [wa] lọ́nà tó dára jù lọ.”—Ka Éfésù 5:15, 16.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa ṣèpinnu tó tọ́ nípa eré ìnàjú.
3. Sá fún eré ìnàjú tí kò dáa
Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú dáadáa ká tó pinnu eré ìnàjú tá a máa ṣe? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Báwo làwọn eré ìnàjú òde òní ṣe jọra pẹ̀lú ohun táwọn tó ń ja ìjàkadì ń ṣe nílẹ̀ Róòmù àtijọ́?
Nínú fídíò yẹn, kí ni Danny kọ́ nípa eré ìnàjú?
Ka Róòmù 12:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè yan eré ìnàjú tó dáa?
Kí ni díẹ̀ lára nǹkan tí Jèhófà kórìíra? Ka Òwe 6:16, 17 àti Gálátíà 5:19-21. Lẹ́yìn tó o bá ka ẹsẹ Bíbélì kọ̀ọ̀kan, dáhùn ìbéèrè yìí:
Èwo nínú àwọn nǹkan tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ló wọ́pọ̀ nínú eré ìnàjú òde òní?
Bó o ṣe lè yan eré ìnàjú tó dáa
Bi ara ẹ pé:
Irú eré wo ni? Ṣé ó ní ohunkóhun tí Jèhófà kórìíra nínú?
Ìgbà wo ni? Ṣé kò ní bọ́ sí àsìkò tó yẹ kí n ṣe àwọn nǹkan pàtàkì?
Àwọn wo la jọ fẹ́ ṣe é? Ṣé kò ní jẹ́ kí n máa bá àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà da nǹkan pọ̀, kí n sì máa lo àkókò tọ́ pọ̀ jù pẹ̀lú wọn?
Ohun tó dáa jù ni pé ká jìnnà pátápátá sí ohun tó lè kó wa sí wàhálà. Torí náà, ó yẹ ká máa sá fún àwọn eré ìnàjú tó lè ṣàkóbá fún wa
4. Máa fọgbọ́n lo àkókò rẹ
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò tọ́ kọ́ ni arákùnrin tá a rí nínú fídíò yẹn ń wò, kí ló fi hàn pé kò fọgbọ́n lo àkókò rẹ̀?
Ka Fílípì 1:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fọgbọ́n lo àkókò wa tá a bá fẹ́ ṣe eré ìnàjú?
5. Yan eré ìnàjú tó dáa
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn eré ìnàjú kan wà tí Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan la lè ṣe láti gbádùn ara wa láìrú òfin Jèhófà. Ka Oníwàásù 8:15 àti Fílípì 4:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn eré ìnàjú wo lo fẹ́ràn láti máa ṣe?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò sóhun tó burú níbẹ̀ tí mo bá ń wo eré ìnàjú tí wọ́n ti ń hùwà ipá, tí wọ́n ti ń ṣèṣekúṣe tàbí èyí tó láwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn, tí mi ò bá ṣáà ti ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe.”
Kí lèrò ẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe eré ìnàjú tó dáa kára lè tù wá.
Kí lo rí kọ́?
Àwọn eré ìnàjú wo ni kò yẹ káwa Kristẹni máa ṣe?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí eré ìnàjú?
Kí nìdí tó o fi gbà pé ó bọ́gbọ́n mu kó o máa ṣe eré ìnàjú táá múnú Jèhófà dùn?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ẹni tó yẹ kó pinnu irú eré ìnàjú tó o máa ṣe.
“Ṣé Ó Láwọn Fíìmù, Ìwé Tàbí Orin Tẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ò Gbọ́dọ̀ Gbádùn?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan eré ìnàjú tó dáa.
“Ṣé Eré Ìtura Tó O Yàn Máa Ṣe Ẹ́ Láǹfààní?” (Ilé Ìṣọ́, October 15, 2011)
Ka ìtàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Mo Jáwọ́ Nínú Ẹ̀tanú Tí Mo Máa Ń Ṣe Sáwọn Aláwọ̀ Funfun Pàápàá,” kó o lè rí ohun tó mú kí ọkùnrin kan ṣàtúnṣe lórí irú eré ìnàjú tó ń wò.
“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, February 1, 2010)
Wo fídíò yìí kó o lè rí ohun tó ran ìyá kan lọ́wọ́ láti yẹra fún eré ìnàjú tó ní ìtàn nípa àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn.
Yẹra fún Eré Ìnàjú Tó Ní Ìtàn Nípa Àwọn Ẹlẹ́mìí Òkùnkùn (2:02)