ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wcg orí 1 ojú ìwé 16-19
  • Ó Bá Ọlọ́run Rìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Bá Ọlọ́run Rìn
  • Fìgboyà Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀
  • Kí La Rí Kọ́?
  • Ronú Jinlẹ̀
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Sí I
  • “Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Énọ́kù—Onígboyà Láìka Gbogbo Àtakò Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Fìgboyà Ṣe Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́
wcg orí 1 ojú ìwé 16-19

1 ÉNỌ́KÙ

Ó Bá Ọlọ́run Rìn

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

ÉNỌ́KÙ mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá dá wà. Nígbà tó wà láyé, ìwà ẹ̀ yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn tó wà láyìíká ẹ̀. Láàárín gbogbo àwọn tí wọ́n jọ gbé ayé nígbà yẹn, òun nìkan ni Bíbélì sọ nípa ẹ̀ pé: “[Ó] ń bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Ṣé ó ṣeé ṣe kéèyàn bá Ọlọ́run rìn ṣá? Kí la lè rí kọ́ lára Énọ́kù táá jẹ́ ká nígboyà?

Ó kéré tán, Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn ní ọ̀nà méjì. Àkọ́kọ́, nínú ohun tí kò ṣe. Énọ́kù ò hùwà burúkú bíi tàwọn tí wọ́n jọ gbé ayé. Ìran keje látọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà ni. Ádámù ṣì wà láyé nígbà yẹn, àmọ́ ó ti darúgbó. (Wo àtẹ náà “Ìgbà Ayé Énọ́kù Sígbà Ayé Àwọn Onídàájọ́.”) Látìgbà tí Ádámù àti Éfà ti ṣọ̀tẹ̀, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ló ń ṣe bíi tiwọn. Ébẹ́lì àbúrò Kéènì ló kọ́kọ́ fi hàn pé òun nígbàgbọ́, àmọ́ ńṣe ni Kéènì pa á. Àwọn kan lára àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ Kéènì náà burú bíi tiẹ̀, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn kan burú jù ú lọ. (Jẹ́n. 4:23, 24) Láìka ìwà ìkà tó kún ayé nígbà yẹn, Énọ́kù jẹ́ onígboyà kò sì ṣe bíi tiwọn. Ó ń bá a lọ láti hùwà rere, ó lẹ́mìí àlàáfíà, èyí sì múnú Ọlọ́run dùn.

Ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Énọ́kù làwọn “èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́n. 4:26) Àmọ́, kì í ṣe torí pé wọ́n fẹ́ yin Ọlọ́run ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n ń lo orúkọ náà láti pẹ̀gàn ẹ̀. Ṣùgbọ́n, Énọ́kù ò bá wọn lọ́wọ́ sí nǹkan tí wọ́n ń ṣe yìí. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ ẹ̀, èyí sì mú kó yàtọ̀ sáwọn tí wọ́n jọ gbé ayé.

Nígbà táwọn tí Énọ́kù wàásù fún fẹ́ pa á, Jèhófà dáàbò bò ó

Ọ̀nà kejì tí Énọ́kù gbà bá Ọlọ́run rìn ni pé ó ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Jèhófà fẹ́ kó jíṣẹ́ kan fáwọn èèyàn burúkú yẹn, ó sì gbọ́dọ̀ nígboyà kó tó lè jẹ́ iṣẹ́ náà. Ohun tí Jèhófà ní kó sọ rèé: “Wò ó! Jèhófà dé pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, láti ṣe ìdájọ́ gbogbo èèyàn àti láti dá gbogbo àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lẹ́bi torí gbogbo ìwà búburú wọn àti gbogbo ọ̀rọ̀ tó burú jáì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ti sọ sí i.”

Énọ́kù ń kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn lójú pópó táwọn èèyàn pọ̀ sí. Àwọn kan ń bínú, àwọn mí ì sì mú ohun ìjà dání.

Ó gbàfiyèsí pé ńṣe ni Énọ́kù sọ̀rọ̀ bíi pé Jèhófà ti fìyà jẹ àwọn ẹni ibi yẹn. Ọ̀nà tó gbà sọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ó dá a lójú pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ ló máa ṣẹ. Ọ̀rọ̀ tó sì sọ fi hàn pé Jèhófà ń bínú sáwọn èèyàn yẹn gan-an torí ìwà burúkú tí wọ́n ń hù. Nínú ìdájọ́ tí Énọ́kù kéde yẹn, ó lo àwọn gbólóhùn bí “àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run,” “àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run” àti “ìwà búburú wọn.” Ó dájú pé ìdájọ́ tí Énọ́kù kéde yẹn á múnú bí àwọn èèyàn yẹn gan-an. Síbẹ̀, ó fìgboyà jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an.

Kí làwọn èèyàn yẹn wá ṣe? Bíbélì ò sọ ohun tí wọ́n ṣe gangan. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan wà tí ẹ̀mí Énọ́kù wà nínú ewu. Báwo la ṣe mọ̀? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tó yá, Énọ́kù ò sí mọ́, torí Ọlọ́run mú un lọ.” Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Énọ́kù? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn burúkú yẹn ń ṣenúnibíni sí i. Àmọ́, torí pé Jèhófà ò fẹ́ káwọn ẹni ibi náà ṣe Énọ́kù ọ̀rẹ́ ẹ̀ léṣe tàbí kí wọ́n pa á ní ìpa ìkà, ó yọ ọ́ nínú ewu, ó sì “mú un lọ,” ìyẹn ni pé ó rọra jẹ́ kó sùn nínú oorun ikú. Èyí jẹ́ kí Énọ́kù wà nínú ìrántí Jèhófà, níbi tí ẹnì kankan ò ti lè ṣe é níkà.

Àmọ́, kí Énọ́kù tó kú, Jèhófà fún un lẹ́bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ká tó ṣí i nípò pa dà, ó rí ẹ̀rí pé ó ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà fi ìran kan han Énọ́kù nípa ohun tó máa gbádùn nígbà tó bá jíǹde sínú ayé tuntun! Èyí fi hàn pé kí Énọ́kù tó kú, ó dá a lójú gan-an pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun, ó sì bù kún òun torí pé òun nígboyà àti ìgbàgbọ́ tó lágbára!

Ka ìtàn yìí nínú Bíbélì:

  • Jẹ́nẹ́sísì 5:21-24

  • Hébérù 11:5

  • Júùdù 14, 15

Ìjíròrò:

Àwọn nǹkan wo ni Énọ́kù ṣe tó fi hàn pé ó nígboyà?

Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀

  1. 1. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn gbà bẹ̀rẹ̀ sí í “pe orúkọ Jèhófà”? (Jẹ́n. 4:26; w01 9/15 29 ¶3)

  2. 2. Isẹ́ pàtàkì wo ló jẹ́ pé Énọ́kù lẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà fún? Kí ló jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí? (w01 9/15 31 ¶5)

  3. 3. Kí Énọ́kù tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí ló fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó mọ̀ pé òun máa rí àdánwò torí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó ní? (w06 10/1 19 ¶13-14) A

    Àwòrán: Énọ́kù ń ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn baba ńlá ẹ̀. 1. Àwọn kérúbù méjì ń ṣọ́ ọgbà Édẹ́nì, idà oníná sì ń yí láàárín wọn. 2. Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n ti darúgbó. 3. Kéènì pa Ébẹ́lì àbúrò ẹ̀, ó sì ń wo òkú ẹ̀.

    Àwòrán A

  4. 4. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kẹ́nì kan rí i pé ọ̀run kọ́ ni Énọ́kù lọ báwọn kan ṣe rò? (Jòh. 3:13; Héb. 11:5, 13)

Kí La Rí Kọ́?

  • Ìgbà wo la lè túbọ̀ nílò ìgboyà ká tó lè wàásù? Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ bíi ti Énọ́kù? B

    Arákùnrin kan ń ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tún mọ́tò ṣe, ó fẹ́ lọ fún ará ibiṣẹ́ ẹ̀ kan ní ìwé ìkésíni wá sí ìpàdé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú onítọ̀hún le. Àwọn ará ibiṣẹ́ tó kù ń fi arákùnrin náà ṣe yẹ̀yẹ́.

    Àwòrán B

  • Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tá a bá jẹ́ onígboyà? (Òwe 27:11; Héb. 11:5)

  • Báwo lo ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi ti Énọ́kù?

Ronú Jinlẹ̀

  • Kí ni ìtàn yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Báwo ni ìtàn yìí ṣe jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà máa ṣe àwọn nǹkan tó ní lọ́kàn fún ayé àtàwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú?

  • Kí ni màá béèrè lọ́wọ́ Énọ́kù nígbà tó bá jíǹde?

Kẹ́kọ̀ọ́ Sí I

Táwọn èèyàn bá ń hùwà ìkà láyìíká ẹ, báwo ni àpẹẹrẹ Énọ́kù ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Ní Ìgbàgbọ́, Kì Í Ṣe Àwọn Tí Kò Nígbàgbọ́—Tẹ̀ Lé Énọ́kù, Má Tẹ̀ Lé Lámékì (2:53)

Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí Énọ́kù nígbàgbọ́.

“Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo Yìí” (w05 9/1 13-17)

    Yorùbá Publications (1987-2026)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́