Bọla fun Jehofa—Eeṣe ati Bawo?
“Awọn wọnni ti nbọla fun mi ni emi yoo bọla fun, awọn wọnni ti wọn si ntẹmbẹlu mi yoo jẹ alaijamọ nkankan.”—1 SAMUẸLI 2:30, NW.
1. Awọn wo ni a fi ẹbun Nobel ti o lokiki julọ lagbaaye dálọ́lá, bawo si ni ọpọlọpọ ṣe ka awọn ẹbun ìdálọ́lá wọnyi si?
LỌ́DỌỌDÚN eto idasilẹ mẹrin ni Scandinavia maa nfi ẹbun ìdálọ́lá fun awọn wọnni ti wọn ti ‘mu anfaani titobi julọ ba araye laaarin ọdun ti o ba ṣẹṣẹ kọja.’ Awọn ẹbun naa ni a nfi funni fun awọn aṣeyọri ninu awọn papa igbokegbodo ọtọọtọ mẹfa. Ẹbun Nobel ni ọpọlọpọ kasi ọla titobi julọ ti a le bu fun eniyan eyikeyii.
2. Tani awọn olufi ẹbun Nobel jinki ẹni gbojufo da, eesitiṣe ti Oun ni pataki fi lẹ́tọ̀ọ́ si ọla?
2 Nigbati ko si ohunkohun ti ko tọna pẹlu fifi ọla fun awọn eniyan ti wọn lẹtọ sii, njẹ awọn wọnni ti wọn nbu awọn ọla wọnyi funni ha ti ronu nipa bibọla fun Oloore titobi julọ fun araye? Oloore yẹn ni ẹni ti o ti fi aimọye awọn anfaani sori araye lati igba iṣẹda ọkunrin ati obinrin akọkọ rẹ ni nnkan bii 6,000 ọdun sẹhin. Ìkùnà lemọlemọ lati bọla fun un le rán wa leti awọn ọrọ Elihu ọrẹ Jobu ìgbàanì, ẹni ti o sọ pe: “Ṣugbọn ko si ẹni ti o wipe, nibo ni Ọlọrun Ẹlẹdaa mi wa, ti o fi orin fun mi ni oru.” (Jobu 35:10) Oloore wa nla nbaa lọ lati ṣe ‘rere, o nfunni ni òjò lati ọrun wa, ati akoko eso, o nfi ounjẹ ati ayọ kun ọkan.’ (Iṣe 14:16, 17; Matiu 5:45) Jehofa ni olufunni ni “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipe” nitootọ.—Jakọbu 1:17.
Ohun Ti O Tumọsi Lati Funni Ni Ọla
3. Kinni awọn ọ̀rọ̀ Heberu ati Giriiki pataki naa ti a tumọsi “ọlá,” ki si ni awọn itumọ wọn?
3 Ọrọ Heberu pataki naa fun ọla, ka·vohdhʹ, tumọ ni ṣangiliti si “ìwúwo.” Nitori naa ẹnikan ti a bọla fun ni a kasi ẹni ti o tẹwọn, ti o wuyì lọ́lá, tabi jámọ́ nǹkan. Lọna jijamọ pataki, ọrọ Heberu yii, ka·vohdhʹ, ni a tun maa ntumọ niye igba ninu Iwe Mimọ gẹgẹbi “ogo,” ti o nfihan siwaju sii bi a ṣe ka ẹni ti a bọla fun naa si awuyilọla tabi ẹni pataki to. Ọrọ Heberu miiran, yeqarʹ, ti a tumọsi “ọlá” ninu Iwe Mimọ, ni a tun tumọsi “ṣeyebiye” ati “awọn ohun ṣiṣeyebiye.” Nitori naa ninu iwe mimọ lede Heberu, ọrọ naa ọla ni o tanmọ ogo ati iṣeyebiye. Ọrọ Giriiki naa ti a tumọsi “ọla” ninu Bibeli ni ti·meʹ, oun pẹlu si gbe itumọ ti ìgbéníyì, iniyelori, ati iṣeyebiye yọ.
4, 5. (a) Kinni o tumọsi lati fi ọla jinki ẹnikan? (b) Ipo wo ti a rohin ninu Ẹsteri 6:1-9 ni o ṣapejuwe ohun ti fifi ọla jinki ẹni ni ninu?
4 Nipa bayi ẹnikan bọla fun ẹnikeji nipa fifi ọwọ jijinlẹ ati igbeniyi han fun ẹni yẹn. Gẹgẹbi àpèjúwe, gbe ọran ti a sọ ninu Bibeli nipa Júù oluṣotitọ naa Mọdekai yẹwo. Ni akoko iṣẹlẹ kan Mọdekai ti tudii aṣiri ìdìmọ̀lù kan lodisi ẹ̀mí ọba Ahasuerusi ti Persia igbaani. Lẹhin naa, laaarin oru nigba ti ọba ko lè sùn, igbesẹ Mọdekai ni a mu wa si afiyesi ọba. Nitori naa oun bere lọwọ iranṣẹ onitọju rẹ: “Iyin ati ọla wo ni a fifun Mọdekai nitori eyi?” Wọn dahun pe: “A ko ṣe nnkankan fun un.” Bawo ni eyi ti bani lọkanjẹ to! Mọdekai ti gba ẹ̀mí ọba la, sibẹ ọba si ti kuna lati fi imọriri han.—Ẹsteri 6:1-3.
5 Nitori naa ni akoko ti o yẹ Ahasuerusi beere lọwọ olori ijoye rẹ, Hamani, bi o ti darajulọ tó lati bọla fun ẹnikan ti ọba ni inudidun si. Ni kiakia Hamani ronu ninu ọkan rẹ pe: “Tani inu ọba le dun si lati bọla fun ju emi tikalaami lọ?” Nitori naa Hamani wipe ẹni naa ni a nilati wọ ni “aṣọ ọba ti ọba maa ńwọ̀” ki o si gun “ẹṣin ti ọba maa ńgùn.” Oun pari ọrọ pe: ‘Ki wọn mú un gẹṣin la igboro ilu, ki wọn si maa kigbe niwaju rẹ̀ pe, bayi ni a o ṣe fun ọkunrin naa ẹni ti inu ọba dun si lati bọla fun.’ (Ẹsteri 6:4-9) Ẹni ti a bọla fun lọna yii ni a o gbeniyi lọna giga nipasẹ gbogbo awọn eniyan naa.
Idi Ti Jehofa Fi Lẹtọọsi Ọla
6. (a) Tani o lẹtọọsi ọla wa ju gbogbo awọn ẹlomiran lọ? (b) Eeṣe ti ọ̀rọ̀ naa “atobilọla” fi ṣapejuwe Jehofa lọna yiyẹrẹgi?
6 Jakejado ọrọ-itan awọn ẹda-eniyan ni a ti fi ọla fun, ti a ṣe bẹẹ niye igba lailẹtọsii. (Iṣe 12:21-23) Sibẹ bori gbogbo awọn miiran tani o lẹtọọsi ọlá? Họwu, Jehofa Ọlọrun ni dajudaju! Oun lẹtọọsi ọla wa nitori pe oun ní dajudaju tobilọla. Ede isọrọ naa “tobilọla” ni a saba maa nlo fun un. Oun ni Ẹni Atobilọla, Atobilọla Oluṣẹda, Atobilọla Ẹlẹdaa, Atobilọla Ọba, Atobilọla Olukọni, Atobilọla Ọga. (Saamu 48:2; Oniwaasu 12:1; Aisaya 30:20; 42:5; 54:5; Hosea 12:14, NW) Ẹni ti o tobilọla jẹ ọlọlanla, oniyi ọla, agbegasoke, ọlọla, aniyi-lokiki, ati amuni kun fun ibẹru ọlọwọ. Jehofa kọja afiwe, oun ko ni alabaadọgba kankan, oun tayọ ni ogo. Oun funraarẹ jẹrii si otitọ yẹn, ni wiwipe: “Tani ẹyin yoo fi mi we, ti yoo si ba mi dọgba, ti ẹ o si fi mi jọ, ki awa le jẹ ọ̀gbà?”—Aisaya 46:5.
7. Ni ọna ọtọọtọ meloo o keretan ni a le sọ pe Jehofa Ọlọrun jẹ aláìlẹ́gbẹ́, eesitiṣe ti a fi le sọ pe oun jẹ alailafiwe niti ọla-aṣẹ?
7 Jehofa Ọlọrun jẹ alailafiwe ni o kere tan ọna meje ọtọọtọ, eyi ti o fun wa ni awọn idi ṣiṣe pato lati bọla fun un. Akọkọ ninu gbogbo rẹ, Jehofa Ọlọrun lẹtọọsi ọla titobi julọ nitori pe oun jẹ alailẹgbẹ ninu ọlá-àṣẹ. Oluwa Jehofa ni Ọba-alaṣẹ Agbaye—oun jẹ onípò àjùlọ. Oun ni onidaajọ, afunni lofin, ati ọba wa. Gbogbo awọn eniyan ni ọrun ati lori ilẹ-aye yoo jihin fun Un; sibẹ oun ki yoo jihin fun ẹnikẹni kankan. A ṣapejuwe rẹ dardara gẹgẹbi “titobi, alagbara, ati ẹlẹru.”—Deuteronomi 10:17; Aisaya 33:22; Daniẹli 4:35.
8. Eeṣe ti a fi le wipe Jehofa jẹ alailẹgbẹ (a) niti ipo rẹ̀? (b) niti wíwà ayeraye rẹ̀?
8 Ekeji, Jehofa Ọlọrun lẹtọọsi ọla titobijulọ nitoripe oun jẹ alailẹgbẹ niti ipo rẹ. Oun ni “Ẹni Giga, ati Ẹniti A Gbegasoke,” Ẹni Gigajulọ naa. Oun ga jinna lori gbogbo awọn ẹda rẹ ti ilẹ-aye lọna ti ko ṣee finumoye! (Aisaya 40:15; 57:15; Saamu 83:18) Ẹkẹta, a nilati bọla fun Jehofa ju gbogbo awọn ẹni yooku lọ nitoripe oun jẹ ẹni ti ko lojugba niti wíwà ayeraye rẹ. Oun nikanṣoṣo ni ko ni ibẹrẹ, ti o ti wa lati ainipẹkun de ainipẹkun.—Saamu 90:2; 1 Timoti 1:17.
9. Ni ọna wo ni Jehofa fi jẹ aláìláfiwé (a) niti ògo rẹ̀? (b) niti awọn animọ ipilẹ rẹ̀?
9 Ẹkẹrin, Jehofa Ọlọrun lẹtọọsi ọla titobijulọ nitori itobilọla ogo ara ẹni rẹ̀. Oun ni “Baba imọlẹ.” Oun funraarẹ ní imọlẹyòò debi pe ko si ẹda eniyan kankan ti o lè rii ki o ṣi walaaye sibẹ. Oun nitootọ jẹ amuni kun fun ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. (Jakọbu 1:17; Ẹksodu 33:22; Saamu 24:10) Ẹkarun, awa jẹ Jehofa Ọlọrun ni gbèsè ọla titobijulọ nitori awọn animọ agbayanu rẹ. Oun ni alagbara gbogbo, alainipẹkun ni agbara; ọlọgbọn gbogbo, alainipẹkun ni ọgbọn; oun jẹ pipe patapata ni idajọ-ododo; oun si ni apẹẹrẹ pipe ti ifẹ.—Jobu 37:23; Owe 3:19; Daniẹli 4:37; 1 Johanu 4:8.
10. Ni ọna wo ni Jehofa fi jẹ ẹni ti kò lójúgbà (a) niti awọn iṣẹ iṣẹda ati ohun ini? (b) niti orukọ ati okiki rẹ̀?
10 Ẹkẹfa, Jehofa Ọlọrun lẹtọọsi ọla titobijulọ ti o ṣeeṣe fun awọn iṣẹ iṣẹda titobi rẹ̀. Gẹgẹbi Ẹlẹdaa ohun gbogbo ni ọrun ati lori ilẹ-aye, oun ni igba kannaa ni Atobilọla Ẹni ti o ni ohun gbogbo. Awa ka ni Saamu 89:11 pe: “Ọrun ni tirẹ, aye pẹlu ni tirẹ.” Ikeje, Jehofa Ọlọrun wa lẹtọọsi ọla ju gbogbo awọn ẹlomiran nitoripe oun jẹ alailẹgbẹ, ẹni ti ko lójúgbà niti orukọ ati okiki rẹ. Oun nikan níí jẹ́ orukọ naa Jehofa, ti ntumọsi “O Mu Ki O Wà.”—Wo Jẹnẹsisi 2:4, akiyesi ẹsẹ-iwe.
Bi A Ṣe Le Bọlafun Jehofa
11. (a) Kinni awọn ọna diẹ ti awa lè gba bọla fun Jehofa? (b) Bawo ni awa ṣe le fihan pe awa nbọla fun Jehofa niti gidi nipa nini igbẹkẹle ninu rẹ̀?
11 Ni oju-iwoye awọn animọ Jehofa, bawo ni awa ṣe le bọla fun un? Gẹgẹbi awa yoo ṣe rii, awa le bọla fun un nipa fifi ẹ̀rù ati ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ han fun un, nipa ṣiṣegbọran si i, nipa jijẹwọ rẹ̀ ninu gbogbo awọn ọna wa, nipa ṣiṣe itọrẹ, nipa ṣiṣafarawe rẹ̀, ati nipa gbigbadura ẹ̀bẹ̀ si i. Awa tun le bọla fun un nipa nini igbagbọ ninu rẹ, nipa gbigbẹkẹle e laika ohunkohun ti o le ṣẹlẹ si. “Gbẹkẹle le Oluwa [“Jehofa,” NW] pẹlu gbogbo ọkàn rẹ,” ni a rọ wa. Nitorinaa awa bọla fun Jehofa nipa gbigba ọrọ rẹ gbọ. Fun apẹẹrẹ, oun wipe: “Iwọ ma bẹru, nitori mo wa pẹlu rẹ; ma foya, nitori emi ni Ọlọrun rẹ: Emi o fun ọ ni okun; nitootọ, emi o ran ọ lọwọ.” (Owe 3:5; Aisaya 41:10) Kikuna lati gbẹkele e patapata yoo jẹ ṣiṣai bọla fun un.
12. Ipa wo ni ìgbọràn ati ìbẹ̀rù kó ninu bibọla fun Jehofa?
12 Ọna ti o tan mọ́ ọn lọna pẹkipẹki ti awa le gba bọla fun Jehofa Ọlọrun ni nipa ṣiṣegbọran si. Oun ti o si ṣe pataki fun igbọran ni ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun, bẹẹni, ibẹru mimu Ọlọrun binu. Ni fifi isopọ ti o wa laaarin bibẹru ati ṣiṣegbọran han ni awọn ọrọ Jehofa si Abrahamu lẹhin ti Abrahamu ti fi igbọran gbidanwo lati fi Isaaki ọmọkunrin rẹ rubọ. Jehofa wipe, “Nisinsinyi emi mọ pe iwọ bẹ̀rù Ọlọrun.” (Jẹnẹsisi 22:12) Nigbati o njiroro ohun tí awọn ọmọ jẹ awọn obi wọn, apọsteli Pọọlu tun fihan pe igbọran ati ọla lọ ni ifẹgbẹkẹgbẹ. (Efesu 6:1-3) Nitorinaa nipa ṣiṣe gbọran si awọn ofin Ọlọrun, eyi ti ko nira, awa nbọla fun Jehofa. Laisi iyemeji kankan nipa rẹ̀, lati ṣaigbọran si Jehofa Ọlọrun yoo jẹ ṣiṣaibọla fun un.—1 Johanu 5:3.
13. Bibọla fun Ọlọrun yoo mu wa ni ẹmi ironu ero ori wo niti awọn igbokegbodo ati iwewee wa?
13 Siwaju sii, awa le mu ọla ti o yẹ wa fun Jehofa Ọlọrun nipa kikọbiara si imọran ti o wa ni Owe 3:6: “Mọ ọ nigbogbo ọna rẹ [bẹẹni, mọ ọ ni amọjẹwọ], oun o si maa tọ ipa ọna rẹ.” Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu fun wa ni amọran rere ni ibamu pẹlu eyi. Dipo titẹsiwaju pẹlu ìdára ẹni loju lati ọjọ de ọjọ, nini igbẹkẹle ninu agbara tiwa funraawa, o yẹ ki awa wipe: “Bi Oluwa [“Jehofa,” NW] ba fẹ, awa o walaaye, a o si ṣe eyi tabi eyiini.” (Jakọbu 4:15) Ni ọpọ ọdun sẹhin o jẹ aṣa awọn Akẹkọọ Bibeli Jakejado awọn Orilẹ-ede [International Bible Students] lati fi ọrọ ikekuru naa D.V. kun gbolohun eyikeyii ti o niiṣe pẹlu ẹhin-ọla, eyi ti o duro fun Deo volente, ti o tumọsi “bi Ọlọrun ba fẹ.”
14. (a) Ẹmi ironu wo ti o tanmọ awọn isapa wa ni a gbọdọ ni bi awa yoo ba bọla fun Ọlọrun? (b) Ẹmi ironu wo ni a fihansode ni isopọ pẹlu itẹjade awọn iwe ikẹkọọ ti Watch Tower Society?
14 Awa tun bọla fun Jehofa Ọlọrun nipa fifi ẹmi ironu onirẹlẹ han, ni bibuyin fun Ọlọrun lori awọn aṣeyọrisirere eyikeyii ti awa le gbadun. Apọsteli Pọọlu ṣakiyesi nipa iṣẹ-ojiṣẹ rẹ lọna bibojumu pe: “Emi gbìn, Apolo bomirin, ṣugbọn Ọlọrun ni nmu ibisi wa. Njẹ kii ṣe ẹni ti ngbin nkankan, bẹẹni kii ṣe ẹni ti nbomirin; bikoṣe Ọlọrun ti o nmu ibisi wa.” (1 Kọrinti 3:6, 7) Nitootọ, Pọọlu daniyan pẹlu mimu ọla ti o yẹ wa fun Ọlọrun, kii ṣe fun ara rẹ tabi fun ẹda-eniyan eyikeyii miiran. Nipa bayii, lonii awọn itẹjade Watch Tower Society kii fi awọn wọnni ti wọn kọ wọ́n han, awọn onkọwe si yẹra fun jijẹ ki awọn ẹlomiran mọ ohun ti wọn ti pese fun titẹ. Ni ọna yii afiyesi ni a fi sori isọfunni naa, eyi ti a pete lati fi bọla fun Jehofa, kii sii ṣe fun ẹda-eniyan eyikeyii.
15. Iriri wo ni o ṣakawe iṣoro ti awọn eniyan kan ni ninu liloye ẹmi irẹlẹ awọn Ẹlẹrii Jehofa?
15 Ilana eto yii ti kikori afiyesi jọ sọdọ Jehofa, ti a si tipa bayii nbọla fun un, nya awọn kan lẹnu. Ni awọn ọdun diẹ sẹhin, nigba ti wọn mura ẹrọ agbohunjade silẹ fun asọye kan fun gbogbo eniyan ni Central Park ti New York City, awọn Ẹlẹrii ngbọ awọn téépù Kingdom Melodies fun didan igbekalẹ ẹrọ naa wò. Tọkọtaya kan ti wọn mura daradara beere lọwọ ọkan lara awọn Ẹlẹrii naa ohun ti ohùn orin naa jẹ. Ni rironu pe tọkọtaya naa jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii, oun dahun pe: “Iyẹn ni Kingdom Melodies No. 4.” “Bẹẹni, ṣugbọn tani ẹni ti o ṣakojọ ohùn orin yẹn?” wọn beere. Ẹlẹrii naa fesipada pe: “Óò, a kò sọ orukọ ẹni ti o ṣakojọ rẹ̀.” Awọn tọkọtaya naa fesipada: “Awọn eniyan ti wọn maa nṣakojọ iru ohùn orin yẹn kii ṣe e laijẹ pe a forukọ mọ̀ wọn.” Ẹlẹrii naa fesipada pe: “Ṣugbọn awọn Ẹlẹrii Jehofa nṣe e.” Bẹẹni, wọn ṣe eyi ki gbogbo ọla ba le lọ sọdọ Jehofa Ọlọrun!
16. Awọn oniruuru ọna wo ni awa le gbà lo ohùn wa lati bọla fun Jehofa Ọlọrun?
16 Ọna miiran lati bọla fun Jehofa ni nipa lilo awọn ètè wa lati jẹrii nipa rẹ̀. Bi awa ba daniyan pẹlu mimu ọla wa fun un loootọ, nigba naa awa yoo maa fi tọkàntọkàn tan ihinrere Ijọba naa kalẹ̀. Awa le ṣe eyi nipa lilọ lati ile de ile ati nipa awọn ọna eyikeyii miiran ti o wa larọọwọto fun wa, laigboju fo awọn anfaani lati jẹrii lọna aijẹ bi àṣà dá. (Johanu 4:6-26; Iṣe 5:42; 20:20) Ni afikun, awa ni awọn anfaani lati bọla fun Ọlọrun wa pẹlu ohùn wa ni awọn ipade ijọ wa, nipa lilohunsi awọn ọ̀rọ̀ ati nipa didarapọ ninu kikọ awọn orin atọkanwa ti Ijọba wa. (Heberu 2:12; 10:24, 25) Ninu ijumọsọrọpọ wa ojoojumọ, awa tun le bọla fun Jehofa Ọlọrun pẹlu awọn ètè wa. Pẹlu iwọnba isapa, awa le yi awọn ijumọsọrọpọ si awọn ọna tẹmi agbeniro, eyi yoo si yọrisi mimu ọla wa fun Jehofa Ọlọrun.—Saamu 145:2.
17. (a) Isopọ wo ni iwa ti o tọ ní lori bibọla ti a nbọla fun Jehofa? (b) Ipa wo ni iwa aitọ ní?
17 Gẹgẹ bi o ti dara lati bọla fun Jehofa Ọlọrun pẹlu awọn ètè wa, o tun pọndandan lati bọla fun un nipa iwa wa. Jesu dẹbi fun awọn wọnni ti, nigba ti wọn nbọla fun Ọlọrun pẹlu ètè wọn, wọn ni ọkan aya ti o jinna sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. (Maaku 7:6) Iwa aitọ ni o daju pe yoo mu abuku wa fun Jehofa Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, ni Romu 2:23, 24, a kà pe: “Iwọ ti nṣogo ninu òfin, ni riru ofin iwọ bu Ọlọrun ni ọla kù, nitori orukọ Ọlọrun sa di isọrọ buburu si ninu awọn Keferi nitori yin.” Ni awọn ọdun lọwọlọwọ yii, ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ni a nyọ lẹ́gbẹ́ lọdọọdun kuro ninu awọn ijọ awọn eniyan Jehofa. O ṣeeṣe pe, iye pupọ sii ti lọwọ ninu iwa abunikù ṣugbọn ti a ko yọ wọn lẹgbẹ nitori pe wọn fi ẹmi onironupiwada tootọ han. Gbogbo awọn eniyan wọnyi ti nbọla fun Jehofa tẹlẹ pẹlu awọn ètè wọn, ṣugbọn wọn kuna lati ṣe bẹẹ nipa iwa wọn.
18. (a) Ìdàníyàn wo ni awọn kan ti a ṣojurere si lọna titobi gbọdọ ní bi wọn ba nilati fi ọla ti o tọ́ han si Jehofa? (b) Bawo ni ipo naa pẹlu ti awọn alufaa ni ọjọ Malaki ṣe ṣakawe aini fun ìdàníyàn?
18 Awọn wọnni ti ọwọ́ wọn di ni oniruuru ẹka iṣẹ-isin alakooko kikun—ibaa jẹ ni Bethel, ninu iṣẹ arinrin-ajo tabi ojihin-iṣẹ Ọlọrun, tabi gẹgẹ bi aṣaaju-ọna—ni a ṣojurere si lọna titobi niti awọn anfaani wọn lati fikun ọla Jehofa. Iṣẹ aigbọdọmaṣe wọn ni lati ṣe gbogbo ohun ti wọn le ṣe gan-an ninu iṣẹ eyikeyii ti a yan fun wọn, ni jijẹ ‘oloootọ ninu ohun kinkinni ati pẹlu ninu ohun pupọ.’ (Luku 16:10) Ni awọn ọna kan ipo ọlọla awọn wọnyi ni awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi ni Israẹli igbaani ṣakawe, bi o tilẹ jẹ pe wọn ko ṣapẹẹrẹ rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, nitori iwa ainaani awọn alufaa kan bayii ni ọjọ Malaki, Jehofa wi fun wọn pe: “Bi emi ba nṣe baba, ọla mi ha dà? Bi emi ba sì nṣe Oluwa, ẹ̀rù mi ha dà?” (Malaki 1:6) Awọn alufaa wọnni ntẹmbẹlu orukọ Ọlọrun nipa fifi awọn ẹran afọju, amukun un, ati alaisan ru ẹbọ. Ayafi bi awọn wọnni ti wọn lanfaani iṣẹ-isin akanṣe lonii ba làkàkà lati ṣe gbogbo ohun ti wọn le ṣe pata, awọn ni pataki le lẹtọọsi idalẹbii ti Jehofa fun awọn alufaa wọnni. Wọn yoo maa kuna niti bibọla fun Ọlọrun.
19. (a) Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi ni Owe 3:9, kinni afikun ọna ti a lè gba bọla fun Jehofa? (b) Kinni ọna pataki miiran lati bọla fun Jehofa?
19 Ọna miiran ti awa le bọla fun Jehofa Ọlọrun ni nipa ṣiṣe awọn itọrẹ́ owo fun iṣẹ iwaasu kari aye ti a ti palaṣẹ. “Fi ohun-ini rẹ bọwọ fun Oluwa [“Jehofa,” NW] ati lati inu gbogbo akọbi ibisi oko rẹ,” ni a rọ̀ wa. (Owe 3:9) Anfaani ṣiṣe iru awọn itọrẹ bẹẹ jẹ àyè kan ti o ṣisilẹ lati bọla fun Jehofa Ọlọrun ti ẹnikẹni ko nilati gbojufo da. Awa tun le bọla fun Jehofa Ọlọrun ninu awọn adura wa, ni fifi iyin ati ọpẹ fun un. (1 Kronika 29:10-13) Niti ootọ, nitori pe awa wa sọdọ rẹ pẹlu ẹmi irẹlẹ ati pẹlu ọwọ jijinlẹ, wiwa wa gan-an sọdọ Ọlọrun ninu adura nbu ọla fun un.
20. (a) Awọn wo ni awọn eniyan aye saba maa nbọla fun, bawo si ni? (b) Nipa kikọbiara si ofin wo ni awa fi le bọla fun Jehofa siwaju sii?
20 Lonii ọpọlọpọ eniyan, awọn ọ̀dọ́ ni pataki, nbọla fun awọn wọnni ti wọn gbayì loju wọn nipa ṣiṣafarawe wọn—nipa sisọrọ bii tiwọn ati nipa hihuwa bii tiwọn. Awọn eniyan ti wọn ṣafarawe saba maa njẹ awọn akọni ninu ere idaraya tabi ere inaju. Ni ifiwera, gẹgẹ bi Kristian, awa nilati bọla fun Jehofa Ọlọrun nipa sisakun lati ṣafarawe rẹ̀. Apọsteli Pọọlu rọ̀ wa pe ki a ṣe bẹẹ, ni kikọwe pe: “Ẹ maa ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n ẹ sì maa rìn ní ìfẹ́.” (Efesu 5:1, 2) Bẹẹni, nipa lilakaka lati ṣafarawe Jehofa, awa nbọla fun un.
21. (a) Kinni yoo mura wa silẹ lati fi ogo ati ọla fun Jehofa? (b) Kinni awọn ere ti Jehofa nsan fun awọn wọnni ti wọn bọla fun un?
21 Nitootọ, ọpọlọpọ ọna ni o wa ti awa le ti a si nilati fi ògo ati ọla fun Ọlọrun. Ẹ maṣe jẹ ki a gbagbe lae pe nipa bibọ araawa pẹlu Ọ̀rọ̀ rẹ̀ deedee ati didi ojulumọ pẹlu rẹ daradara sii, awa yoo le tubọ bọla fun un. Kinni o jẹ awọn ere fun ṣiṣe bẹẹ? Jehofa wipe, “Awọn wọnni ti nbọla fun mi ni emi yoo bọla fun.” (1 Samuẹli 2:30, NW) Ni asẹhinwa asẹhinbọ Jehofa yoo bọla fun awọn olujọsin rẹ̀ nipa fifun wọn ni ìyè ainipẹkun ninu ayọ, yala ni ọrun gẹgẹbi alajumọ ṣakoso pẹlu Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, tabi lori Paradise ilẹ-aye.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Awọn wo ni awọn ẹda eniyan nbọla fun ni gbogbogboo, ta si ni wọn ṣainaani lati bọla fun lọna wiwọpọ?
◻ Kinni o tumọsi lati bọla fun ẹnikan, ki si ni awọn ọna ti a le gba ṣe eyi?
◻ Kinni awọn idi ṣiṣekoko diẹ ti Jehofa Ọlọrun fi lẹtọọsi ọlá?
◻ Kinni awọn ọna diẹ ti awa le gba bọla fun Jehofa?
◻ Ni awọn ọna wo ni Jehofa fi nsan ere fun awọn wọnni ti wọn bọla fun un?