Bọla fun Ọmọkunrin naa Olori Aṣoju Jehofa
“Ẹni ti ko ba bọla fun Ọmọkunrin kò bọla fun Baba ti o ran an.”—JOHANU 5:23, NW.
1. Bawo ni igbagbọ Kristẹndọm ninu Mẹtalọkan ṣe tabuku si Jesu?
NINU Kristẹndọm lonii ọpọlọpọ sọ pe wọn nbọla fun Jesu Kristi, sibẹ odikeji gan-an ni wọn nṣe. Bawo ni o ṣe ri bẹẹ? O dara, ọpọlọpọ sọ pe Jesu Kristi ni Ọlọrun Olodumare, ati pe Ọlọrun, Ẹlẹdaa ohun gbogbo, wa si ilẹ-aye o si gbe ayé o si ku gẹgẹbi eniyan. Ifidaloju sọ yii jẹ ara ẹkọ igbagbọ Mẹtalọkan, eyi ti o jẹ ẹkọ ipilẹ ti Kristẹndọm. Ṣugbọn bi Mẹtalọkan ba jẹ eke, bi Jesu ba jẹ, ẹni rirẹlẹ ju niti tootọ, ti o si wa labẹ Ọlọrun, njẹ apejuwe lọna odi yii nipa ipo ibatan rẹ̀ pẹlu Ọlọrun ko ha ni mu ki Jesu jẹ alailayọ bi? Nitootọ, oun yoo ka iru apejuwe lọna odi bẹẹ si abuku si araarẹ̀ ati ohun gbogbo ti oun fi kọni.
2. Bawo ni Iwe Mimọ ṣe fihan pe Jesu jẹ ẹni rirẹlẹ ju Ọlọrun ti o si wa labẹ rẹ̀?
2 Otitọ naa ni pe Jesu ko sọ ri lae pe oun jẹ Ọlọrun, ṣugbọn oun sọrọ araarẹ̀ leralera gẹgẹbi “Ọmọ Ọlọrun.” Ani awọn ọta rẹ paapaa jẹwọ eyi. (Johanu 10:36; 19:7) Jesu wa lojufo lati gbe Baba rẹ̀ ga ati fifi araarẹ̀ sabẹ Rẹ̀ nigbagbogbo, gẹgẹbi oun ti jẹwọ pe: “Ọmọ ko le ṣe ohunkohun fun araarẹ̀, bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe: nitori ohunkohun ti o ba nṣe, iwọnyi ni ọmọ si nṣe bẹẹ gẹgẹ. Emi ko le ṣe ohun kan fun araami . . . nitori emi ko wa ifẹ ti emi tikaraami, bikoṣe ifẹ ẹni ti o ran mi.” Lẹẹkan sii, oun wipe: “Lọdọ rẹ ni mo ti wa, oun ni o sì ran mi.” Oun tun wipe: “Emi ti ọdọ Ọlọrun jade, mo si wa.” (Johanu 5:19, 30; 7:28, 29; 8:42) Ani Jesu ko damọran ri lae pe oun jẹ Ọlọrun tabi dọgba pẹlu rẹ̀. Nitori naa lati kọni ni iru nnkan bẹẹ tabuku si Jesu.
Awọn Ọna Miiran Ti Awọn Kan Gba Tabuku si Jesu
3. (a) Nipa sisẹ kinni nipa Jesu ni awọn kan ninu Kristẹndọm ṣe tabuku si i? (b) Ẹri wo ni Jesu fifunni niti wíwà rẹ̀ ṣaaju ki o to di ẹda eniyan?
3 Awọn kan tun wà, bi o tilẹ jẹ pe eyi ṣajeji, ninu Kristẹndọm lonii ti wọn tabuku si Jesu nipa sísẹ́ pe oun ti wà ṣaaju ki o to di eniyan. Bi o ti wu ki o ri, kiki bi awa ba mọriri pe Jesu wá lati ọrun sori ilẹ-aye niti gidi ni awa to le bọla fun un lọna ti o bojumu. Jesu funraarẹ sọ ni asọtunsọ pe oun ní iwalaaye ṣaaju ki oun to di eniyan. Oun wipe, “Kò si si ẹni ti o goke re ọrun, bikoṣe ẹni ti o ti ọrun sọkalẹ wa, ani ọmọ-eniyan.” Lẹhin naa oun wipe: “Emi ni ounjẹ iye ti o ti ọrun sọkalẹ wa: . . . Njẹ, bi ẹyin ba si ri i ti ọmọ-eniyan goke lọ si ibi ti o gbe ti wa ri nkọ?” Ati lẹẹkan sii pe: “Ẹyin ti isalẹ wa: emi ti òkè wa. . . . Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, ki Abrahamu to wà, emi niyii.” (Johanu 3:13; 6:51, 62; 8:23, 58) Jesu tun tọkasi wiwa rẹ̀ ki o to di eniyan ninu adura rẹ si Baba rẹ ọrun ni òru ti a dà á.—Johanu 17:5.
4. (a) Ni ọna wo siwaju sii ni ọpọlọpọ ṣe ntabuku si Jesu? (b) Ẹri wo ni o nilati pọ̀ to lati fidi rẹ mulẹ pe Jesu ti gbe ayé rí, eesitiṣe?
4 Ani awọn kan ninu Kristẹndọm tilẹ rekọja ààlà debi pe wọn sẹ pe Jesu jẹ ẹni gidi kan ní ìgbà ti o ti kọja, pe oun gbe láyé gẹgẹbi eniyan kan ri. Bi oun kò ba wà niti tootọ, ko ni si koko kankan ninu jijiroro idi ati bi awa ti nilati bọla fun un. Sibẹ ọpọ yanturu ẹri awọn ti ọran ṣoju wọn ti a pamọ sinu Iwe Mimọ ti nilati jẹ ẹri ti o pọ to lati fidi rẹ̀ mulẹ rekọja iyemeji pe Jesu gbe ori ilẹ-aye niti gidi. (Johanu 21:25) Ni pataki ni eyi jẹ ootọ niwọnbi awọn Kristian ijimiji ti maa nkọni nipa Jesu pẹlu ẹ̀mí ati ominira tiwọn gan-an labẹ ewu. (Iṣe 12:1-4; Iṣipaya 1:9) Bi o ti wu ki o ri, yatọ si ohun ti awọn ọmọlẹhin rẹ̀ kọ nipa rẹ̀, njẹ a le fi ẹri wíwà Jesu hàn?
5, 6. Kinni ẹri ti ọrọ itan, yatọ si ti inu Iwe Mimọ, fihan niti wíwà Jesu Kristi niti gidi?
5 The New Encyclopædia Britannica (1987) wipe: “Awọn akọsilẹ ọtọọtọ fi ẹri han pe ni awọn igba laelae ani awọn ti wọn tako isin Kristian ko ṣiyemeji ri si jijẹ ti Jesu jẹ ẹni gidi nigba ti o ti kọja.” Kinni awọn akọsilẹ ọtọọtọ wọnyi? Gẹgẹbi ọmọwe akẹkọọjinlẹ Júù naa Joseph Klausner ti wi, ẹri awọn ikọwe ti Talmud ijimiji wà. (Jesus of Nazareth, oju-iwe 20) Ẹri ti opitan Júù ọrundun kin-inni naa Josephus tun wà pẹlu. Fun apẹẹrẹ, oun ṣapejuwe sisọ Jakọbu lokuta ti o fi han yatọ gẹgẹbi “arakunrin Jesu ẹni ti a npe ni Kristi.”—Jewish Antiquities, XX, [ix, 1].
6 Ni afikun, ẹri awọn opitan Romu ìjímìjí tun wà, paapaa ti Tacitus ti a kàsí lọna giga. Oun kọwe ni ibẹrẹ ọrundun keji nipa “ẹgbẹ kan ti a koriira fun awọn irira ẹgbin wọn, ti awọn eniyan gbáàtúù npe ni awọn Kristian. Christus [Kristi], lati inu ẹni ti orukọ naa [Kristian] ni ipilẹṣẹ rẹ, jiya iku nigba ijọba Tiberius ni ọwọ ọkan lara awọn aṣoju ọba wa.” (The Annals, XV, XLIV) Ni wiwo ẹri naa pe Jesu jẹ ẹni gidi kan nigba ti o ti kọja gẹgẹ bi eyi ti o pọ rẹpẹtẹ, ara France akọnilẹkọọ nipa iwarere lọna imọ-ọran ni ọrundun kejidinlogun, ti njẹ Jean-Jacques Rousseau, jẹrii pe: “Ọ̀rọ̀ itan Socrates, eyi ti ẹnikẹni ko gbiyanju lati ṣiyemeji rẹ̀, ni a kò jẹrii si daradara gẹgẹbi ti Jesu Kristi.”
Awọn Idi fun Bibọla Fun Ọmọkunrin Naa
7. (a) Ẹri Iwe Mimọ wo ni o fi wa sabẹ aigbọdọmaṣe lati bọla fun Jesu Kristi? (b) Bawo ni Jehofa ṣe bọla fun Ọmọkunrin rẹ̀ siwaju sii?
7 Nisinsinyi a wa sori ọran ti bibọla fun Jesu Kristi. Pe awọn ọmọlẹhin Jesu wa labẹ aigbọdọmaṣe lati bọla fun un ni a ri ninu awọn ọrọ rẹ̀ ni Johanu 5:22, 23: “Nitori pe Baba kii ṣe idajọ ẹnikẹni, ṣugbọn o ti fi gbogbo idajọ le ọmọ lọwọ: ki gbogbo eniyan ki o le maa fi ọla fun ọmọ gẹgẹ bi wọn ti nfi ọla fun Baba. Ẹni ti ko ba fi ọla fun ọmọ ko fi ọla fun Baba ti o ran an.” Lati igba ajinde Kristi, Jehofa ti bọla fun Ọmọkunrin rẹ̀ ani de aye titobi ju paapaa ‘ni fifi ògo ati ọla de e ni ade nitori ijiya iku.’ (Heberu 2:9; 1 Peteru 3:22) Ni pataki julọ, awa ni awọn idi lati bọla fun Jesu nitori iru ẹni ti oun nṣe ati nitori ohun ti oun ti ṣe.
8. Nitori awọn otitọ alailẹgbẹ wo nipa Jesu Kristi ni oun fi lẹtọọ si ọla?
8 Jesu Kristi lẹtọọsi ọla nitori oun, gẹgẹbi Logos naa, tabi Ọ̀rọ̀, ni olubanisọrọpọ ọlọla julọ ti Jehofa. Lati inu Iwe Mimọ o han gbangba pe ifunlorukọ “Ọ̀rọ̀ naa” tọkasi Jesu ṣaaju ki oun to wa si ori ilẹ-aye ati lẹhin ti oun gòkè re ọrun. (Johanu 1:1; Iṣipaya 19:13) Ni Iṣipaya 3:14 oun sọrọ nipa araarẹ̀ gẹgẹbi “olupilẹṣẹ ẹda Ọlọrun.” Kii ṣe kiki pe oun jẹ “akọbi gbogbo ẹda” ni ṣugbọn oun jẹ “Ọmọkunrin bibi kanṣoṣo” oun ni ẹnikan ṣoṣo ti a da ni taarata lati ọwọ Jehofa Ọlọrun. (Kolose 1:15; Johanu 3:16, NW) Ni afikun, “nipasẹ rẹ ni a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da.” (Johanu 1:3) Nitori naa, nigbati a ka ni Jẹnẹsisi 1:26 pe, “Jẹ ki a da eniyan ni aworan wa, gẹgẹbi ìrí wa,” “wa” yẹn ní Logos, tabi Ọ̀rọ̀ naa nínú. Dajudaju, otitọ naa pe nigbati Jesu wà ṣaaju ki o to di ẹda-eniyan ó ní anfaani agbayanu ti ṣiṣajọpin pẹlu Jehofa Ọlọrun ninu iṣẹda mu ki o yẹ fun ọla titobi.
9. Eeṣe ti a fi pari-ero si pe Jesu ni Maikẹli olu angẹli naa, bawo sì ni Maikẹli ṣe bọla fun Jehofa ni isopọ pẹlu ara Mose?
9 Jesu Kristi lẹtọọsi ọla siwaju sii nitori pe oun ni olori angẹli Jehofa, tabi olu angẹli. Lori ipilẹ wo ni a fi de ipari ero yẹn? O dara, ọrọ iṣaaju naa “olu,” ti o tumọsi “olori” tabi “ògúnná gbòǹgbò,” tumọsi pe olu angẹli kanṣoṣo ni o wà. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ nipa rẹ̀ ni ìtọ́kasi Oluwa Jesu Kristi ti a ji dide. A kà pe: “Oluwa tikaraarẹ yoo sọkalẹ lati ọrun wa ti oun ti ariwo, pẹlu ohun olori awọn angẹli [“olu angẹli,” NW], ati pẹlu ìpè Ọlọrun; awọn oku ninu Kristi ni yoo sì kọ jinde.” (1 Tẹsalonika 4:16) Olu angẹli yii ni orukọ kan, gẹgẹbi a ṣe kà á ni Juuda 9: “Ṣugbọn Maikẹli, olori awọn angẹli [“olu angẹli,” NW], nigbati o nba Eṣu jà, ti o nṣe ọpẹ́ aláyé nitori oku Mose, ko si gbọdọ sọ ọrọ odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa [“Jehofa,” NW] ni yoo ba ọ wi.” Nitori aiyara ṣiwaju Jehofa nipa fifi ìkùgbù mu idajọ wa lodisi Satani Eṣu, Jesu tipa bayii bọla fun Baba rẹ ọrun.
10. (a) Bawo ni Maikẹli ṣe mu ipo iwaju ninu jija nitori Ijọba Ọlọrun? (b) Ipa wo ni Maikẹli ko ninu ọran orilẹ-ede Israẹli?
10 Maikẹli olu angẹli jà nitori Ijọba Ọlọrun, ni mímú ipo iwaju ninu lile Satani ati ẹgbẹ̀fúlú awọn ẹmi eṣu rẹ̀ raurau kuro ninu awọn ọrun. (Iṣipaya 12:7-10) Wolii Daniẹli si wipe ‘o dide lati gbèjà awọn eniyan rẹ̀.’ (Daniẹli 12:1) Nitori naa, o farahan, pe Maikẹli ni “angẹli Ọlọrun naa ti o ṣaaju ogun Israẹli” ati pe oun ni ẹni naa ti Ọlọrun lò lati mu awọn ènìyàn rẹ̀ wa sinu Ilẹ Ileri naa. “Kiyesi ara lọdọ rẹ̀, ki o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ,” ni Ọlọrun pàṣẹ. “Maṣe bi i ninu; . . . nitori orukọ mi nbẹ lara rẹ̀.” (Ẹksodu 14:19; 23:20, 21) Laisi iyemeji olu angẹli Jehofa ti gbọdọ ni ifẹ ọkan titobi ninu awọn eniyan afiṣapẹẹrẹ ti wọn jorukọ mọ Ọlọrun. Lọna yiyẹ rẹ́gí julọ oun wa si iranlọwọ angẹli miiran ti a ran lati tù wolii Daniẹli nínú, ẹni ti ẹmi eṣu alagbara kan ti dè lọna. (Daniẹli 10:13) O le ba ọgbọn ironu mu nigba naa lati pari ero pe angẹli naa ti o pa 185,000 awọn jagunjagun Senakerubu kii ṣe ẹlomiran bikoṣe Maikẹli olu angẹli naa.—Aisaya 37:36.
11. Fun lilepa ọna igbesẹ wo lori ilẹ-aye ni Jesu fi lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa?
11 Kii ṣe kiki pe Jesu Kristi lẹtọọ si ọla nitori ẹni ti oun jẹ nikan ni, oun tun lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa nitori ohun ti oun ti ṣe. Fun apẹẹrẹ, oun ni ẹda eniyan kanṣoṣo ti o tii gbe igbesi-aye pipe. Adamu ati Efa ni a da ni pipe, ṣugbọn ijẹpipe wọn ni kò tọ́jọ́. Bi o ti wu ki o ri, Jesu Kristi wa titilọ gẹgẹbi ‘aduroṣinṣin, alailẹgan, ti a yasọtọ kuro lara awọn ẹlẹṣẹ’ laika gbogbo ohun ti Eṣu le muwa sori rẹ̀ si ni ọna awọn adanwo ati inunibini. La gbogbo rẹ̀ já ‘oun kò dẹṣẹ, bẹẹ ni a kò sì ri arekereke ni ẹnu rẹ̀.’ Lọna titọ oun le pe awọn alatako onisin rẹ̀ níjá: “Tani ninu yin ti o tii da mi ni ẹbi ẹ̀ṣẹ̀?” Kò si ẹnikan ti o lè dahun! (Heberu 7:26; 1 Peteru 2:22; Johanu 8:46) Ati nitori pipa iwatitọ alailẹṣẹ mọ́, oun da Baba rẹ̀ ọrun lare gẹgẹbi Ọba alaṣẹ agbaye titọ o sì fi ẹri Eṣu han gẹgẹbi òpùrọ́ patapata ati aláìníláárí.—Owe 27:11.
12. (a) Iru eniyan wo ni Jesu, kinni oun ṣe ti oun sì jìyà rẹ̀ nitori awọn miiran? (b) Eeṣe ti iwọ yoo fi wipe Jesu lẹtọọ si ọla wa nitori ohun ti o ṣe ati nitori ohun ti o jiya rẹ̀?
12 Jesu Kristi lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa, kii ṣe kiki nitori pe oun gbe igbesi-aye pipe, alailẹṣẹ nikan ni ṣugbọn nitori pe oun tun jẹ ẹni rere, alaimọtara-ẹni-nikan, ati olufara-ẹni-rubọ. (Fiwe Roomu 5:7.) Oun ṣeranṣẹ laiṣaarẹ fun aini tẹmi ati ti ara awọn eniyan. Iru itara wo ni oun fihan sode fun ile Baba rẹ̀, iru suuru wo ni oun sì fihan sode ninu biba awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lò! Iru irora wo ni oun muratan lati farada ninu ṣiṣe ifẹ-inu Baba rẹ̀! Niti iriri onirora rẹ ninu ọgba ọgbin Gẹtisemani, Bibeli wipe: “Bi o si ti wa ni ìwàyá ija o gbadura si i kikankikan: òógùn rẹ̀ si dabi iro ẹjẹ nla, o nkan silẹ.” Bẹẹni, o “fi ẹkunrara ati omije gbadura.” (Luuku 22:44; Heberu 5:7) Bawo ni wolii Aisaya ti sọ asọtẹlẹ iriri onirora rẹ lọna pipe perepere ni Aisaya 53:3-7 to!
13. Apẹẹrẹ rere wo ni Jesu filelẹ fun wa ni bibọla fun Baba rẹ ọrun?
13 Jesu tun lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa nitori apẹẹrẹ rere ti oun filelẹ fun wa ninu bibọla fun Baba rẹ ọrun. Oun tun le wipe: “Emi nbọla fun Baba mi.” (Johanu 8:49) Ni gbogbo igba oun nmu ọla bá Jehofa Ọlọrun nipa awọn ọ̀rọ̀ ati iṣe rẹ̀. Nipa bayii, nigba ti o wo ọkunrin kan sàn, akọsilẹ Bibeli wipe, kii ṣe pe awọn eniyan nfi ògo fun Jesu, ṣugbọn pe “wọn sì yin Ọlọrun logo.” (Maaku 2:12) Nitori naa, ni opin iṣẹ ojiṣẹ rẹ̀ ti ori ilẹ-aye, Jesu le sọ ninu adura si Baba rẹ ọrun lọna titọ pe: “Emi ti yìn ọ logo ni aye, emi ti pari iṣẹ ti iwọ fifun mi lati ṣe.”—Johanu 17:4.
Ohun Ti O Ti Ṣe fun Wa
14. Kinni iku Jesu ṣaṣepari fun wa ti o mu ki o lẹtọọ si ọla?
14 Bawo si ni Jesu Kristi ti lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa to lọna titobi nitori gbogbo ohun ti oun ti ṣaṣepari fun wa! Oun kú fun awọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ki awa baa le ba Jehofa Ọlọrun làjà. Jesu wi nipa araarẹ pe: “Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] eniyan kò wa, ki a le ṣe iranṣẹ fun un, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ funni ati lati fi ẹmi rẹ ṣe irapada ọpọlọpọ eniyan.” (Matiu 20:28) Nipa bayii, iku rẹ mu ki gbogbo ohun ti Ijọba naa yoo ṣaṣepari fun awọn ẹda eniyan ṣeeṣe: iye aileku ninu awọn ọrun fun 144,000 ti wọn parapọ jẹ iyawo rẹ ati iye ayeraye ninu paradise ilẹ aye fun araadọta ọkẹ awọn miiran ti o fi ẹri igbagbọ ati igbọran wọn hàn labẹ idanwo.—Saamu 37:29; Iṣipaya 14:1-3; 21:3, 4.
15. Kinni apẹẹrẹ Jesu kan ti nṣipaya akopọ iwa Baba rẹ̀ fun wa?
15 Jesu Kristi tun lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa nitoripe, gẹgẹ bi Olukọ Nla naa, oun ti ṣipaya ifẹ inu ati akopọ ìwà Baba rẹ fun wa lọna pipe. Fun apẹẹrẹ, ninu Iwaasu rẹ lori Oke, oun tọkasi iwa ọlawọ Baba rẹ̀ ni jijẹ ki oòrùn ràn ki òjò sì rọ̀ sori ati ẹni buburu ati rere bakannaa o si fihan lẹhin naa pe: “Nitori naa ki ẹyin ki o pe, bi Baba yin ti nbẹ ni ọrun ti pe.”—Matiu 5:44-48.
16. Bawo ni aposteli Pọọlu ṣe ṣakopọ ọna igbesẹ Jesu ti o lẹtọọ si ọla?
16 Apọsteli Pọọlu ṣakopọ ọna igbesẹ Jesu ti o lẹtọọ si ọla nigba ti oun kọwe pe: “Bi o tilẹ wa ni aworan irisi Ọlọrun, [oun] ko fi iṣaro kankan fun ìjá nǹkan gbà, eyiini ni, pe oun nilati ba Ọlọrun dọgba. Bẹẹkọ, ṣugbọn o sọ araarẹ̀ dòfo o si gbe aworan irisi ẹru o sì wá wà ni jijọ eniyan. Ju eyiini lọ, nigba ti o ri ara rẹ̀ ninu awọ ẹda bi eniyan, oun rẹ araarẹ̀ silẹ o si di onigbọran titi de iku, bẹẹni, iku lori opo igi idaloro.”—Filipi 2:5-8, NW.
Bawo Ni Awa Ṣe Lè Bọla fun Ọmọkunrin Naa
17, 18. Ni oniruuru ọna wo ni awa le gba mu ọla wa fun Jesu Kristi?
17 Niwọnbi Jesu Kristi ti lẹtọọ si ọla lati ọ̀dọ̀ wa laisi iyemeji, awa wa sori ibeere naa: Bawo ni awa ṣe le bọla fun Ọmọkunrin naa? Awa lè ṣe bẹẹ nipa mimu igbagbọ lo ninu ẹbọ irapada rẹ̀, ki a si fi ẹri igbagbọ yẹn han nipa gbigbe awọn igbesẹ pipọndandan ti ironupiwada, iyilọkanpada, iyasimimọ, ati baptism. Nipa wiwa sọdọ Jehofa ninu adura ni orukọ Jesu awa bọla fun Jesu, awa bọla fun un siwaju sii nigba ti a ba nkọbiara si awọn ọrọ rẹ̀: “Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ mi lẹhin, jẹ ki o kọ araarẹ̀ silẹ ki o sì gbe opo igi idaloro rẹ ki o si maa tọ mi lẹhin deedee.” (Matiu 16:24, NW) Awa bọla fun Jesu Kristi nigba ti a ba kọbiara si awọn itọni rẹ lati maa lepa Ijọba Ọlọrun ati ododo rẹ̀ lakọọkọ, awa sì tun bọla fun un nigba ti a ba kọbiara si aṣẹ rẹ lati ṣajọpin ninu iṣẹ sisọni di ọmọ ẹhin. Lẹẹkan sii, awa bọla fun Jesu nigba ti a ba fi ifẹ ará han sode ti oun wipe yoo fi awọn ọmọlẹhin oun tootọ han yatọ.—Matiu 6:33; 28:19, 20; Johanu 13:34, 35.
18 Siwaju sii, awa mu ọla wa fun Ọmọkunrin naa nipa biba a jẹ́ orukọ, ni pipe araawa ni Kristian, ati lẹhin naa nipa gbigbe ni ibamu pẹlu orukọ yẹn nipa iwarere wa. (Iṣe 11:26; 1 Peteru 2:11, 12) Apọsteli Peteru wipe awa nilati tẹle awọn ipasẹ Jesu timọtimọ. (1 Peteru 2:21) Nipa ṣiṣafarawe rẹ̀ lọna yii ninu gbogbo iwa wa, awa tun bọla fun un. Ati ni dajudaju, nigba ti awa ba ṣayẹyẹ Iṣe Iranti iku Kristi lọdọọdun, awa nbù ọla akanṣe fun un.—1 Kọrinti 11:23-26.
19, 20. (a) Awọn ere wo ni Jesu nawọ rẹ̀ si awọn ọmọlẹhin rẹ̀ fun bibọla fun un, nisinsinyi ati ni ẹhin-ọla? (b) Igbọkanle wo ni awa le ni ni isopọ pẹlu Ọmọkunrin naa?
19 Awọn èrè wo ni Jesu nawọ rẹ̀ sí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fun titọ ipa ọna kan ti o bọla fun un? Oun wipe: “Loootọ ni mo wi fun yin, ko si ẹni ti o le fi ile silẹ, tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, nitori mi ati nitori ihinrere, ṣugbọn nisinsinyi ni aye yii oun yoo si ri ọgọrọọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati ni aye ti nbọ iye ainipẹkun.”—Maaku 10:29, 30.
20 Nitori eyi, bi awa ba ṣe awọn irubọ nititori Jesu, oun yoo ri sii pe a san ere fun wa. Jesu mu da wa loju pe: “Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju eniyan, oun ni emi yoo jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti nbẹ ni ọrun.” (Matiu 10:32) Nitori naa ani gẹgẹbi Baba ọrun ti bọla fun awọn wọnni ti wọn bọla fun un, awa le ni igbọkanle pe Ọmọkunrin bibi kanṣoṣo ti Jehofa yoo ṣafarawe Baba rẹ̀ ninu ọ̀ràn yii, ani gẹgẹbi Ọmọkunrin ti ṣe ninu awọn ọran miiran.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni ọpọlọpọ ninu Kristẹndọm ṣe tabuku si Ọmọkunrin naa?
◻ Ẹri wo ni Jesu fifunni nipa wíwà rẹ̀ ṣaaju ki oun to di ẹda-eniyan?
◻ Kinni awọn idi diẹ ti a ni fun bibọla fun Jesu?
◻ Kinni awọn ọna diẹ ti awa lè gba bọla fun Jesu?
◻ Bibọla fun Jesu Kristi yọrisi awọn ere wo?