Eeṣe Ti O Fi Pẹ Tobẹẹ Lati Yanju Ariyanjiyan Naa?
NI NNKAN bii 6,000 ọdun sẹhin, ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun ni ko si ninu ariyanjiyan. Ni pipari awọn iṣẹ agbayanu rẹ̀ ti iṣẹda, “Ọlọrun si ri ohun gbogbo ti o dá, si kiyesi i, daradara ni.” (Jẹnẹsisi 1:31) Lẹhin naa oun wọnu saa “isinmi” gigun kan; dajudaju, kii ṣe pe o rẹ̀ ẹ́ niti ara iyara. Kaka bẹẹ, oun sinmi niti pe oun dawọ awọn iṣẹ iṣẹda rẹ̀ lori ilẹ-aye duro, pẹlu igbọkanle pe ète rere rẹ̀ nipa iwọnyi yoo yọrisi rere delẹ.—Jẹnẹsisi 2:1-3; Aisaya 55:11.
Ki ni ète yẹn? Jehofa fi tọkọtaya ẹda eniyan akọkọ si ibi kan ti a npe ni ọgba Edeni. Ẹru iṣẹ wọn ní ipilẹṣẹ ni lati bikita fun ile paradise wọn, papọ pẹlu oniruuru iwalaaye ẹranko pupọ. Pẹlupẹlu, wọn nilati mu awọn ọmọ jade ki wọn sì tọ́ wọn dagba. Laipẹ, gẹgẹ bi idile wọn ti npọ ni iye, wọn nilati mu Paradise gbooro titi de opin ilẹ-aye ni igbọran si aṣẹ Ọlọrun lati ‘ṣe ikawọ ilẹ-aye.’ Nipa bayii, ilẹ-aye yoo di ile ologo ẹwa ni asẹhinwa-asẹhinbọ, ti a fi idile alayọ, ti a sopọṣọkan ti wọn nṣiṣẹsin Baba wọn ọrun kún inu rẹ̀. Iyẹn ni ète Ọlọrun ní ipilẹṣẹ.—Jẹnẹsisi 1:27, 28; 2:8, 15, 20-22.
Njẹ Adamu ati Efa yoo ha ṣajọpin ninu mimu ète titobilọla yii ṣẹ titi de opin rẹ̀? Iyẹn sinmi lori ifọwọsowọpọ wọn ti nbaa lọ pẹlu rẹ̀ nipa ṣiṣegbọran si Ẹlẹdaa wọn. Iṣegbọran wọn ni kò nilati jẹ ti òpònú eyi ti a ṣe laironu. A fun wọn ni ominira ifẹ-inu, nitori pe Ọlọrun fẹ ki wọn ṣiṣẹsin oun lati inu ọkan-aya onimọriri. Gẹgẹ bi irannileti ẹtọ ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ti a lè fojuri, oun pese idanwo rirọrun kan. Wọn le ṣalabaapin ninu ipese eyikeyii ninu ọgba naa ayafi ọkanṣoṣo. Igi eleso kan wà nipa eyi ti Ọlọrun wipe: “Ọjọ́ ti iwọ ba jẹ ninu rẹ̀ kíkú ni iwọ yoo ku.”—Jẹnẹsisi 2:16, 17.
Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi sọ fun wa pe Adamu ati Efa ni a kò da lati dagba di arugbo ki wọn sì ku. Iku yoo wá kiki bi wọn ba ṣaigbọran si aṣẹ rirọrun yii. Bi Adamu ati Efa ba ti wà ni onigbọran si Ọlọrun, wọn yoo ṣì walaaye lori ilẹ aye lonii gẹgẹ bi awọn òbí idile yika agbaye ti o kun fun iru-ọmọ pipe.—Wo ilana naa ti a kọ si Saamu 37:29.
Bi o ti wu ki o ri, ọkan lara awọn ẹda angẹli ti Ọlọrun, ti a pè ni Satani, nisinsinyi, di alariiwisi si ọna ti Ọlọrun ńgbà ṣakoso. O rọ Efa lati jẹ ninu eso ti a kaleewọ naa, ni didabaa lọna itanjẹ pe nipa didaduro lominira kuro lọwọ ipo ọba-alaṣẹ ti Ọlọrun, oun yoo wà ni ipo anfaani didara ju. Bi o ti wu ki o ri, ète isunniṣe gidi ti Satani ni ifẹ ọkan lati jẹ́ ọlọrun idile araye lọ́la.—Jẹnẹsisi 3:1-5; Matiu 4:8, 9; Johanu 8:44.
Niwọnbi Jehofa ti fun tọkọtaya ẹda eniyan akọkọ ni ohun gbogbo ti wọn nilo, Efa iba ti ṣetilẹhin fun ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ki o si ṣá idamọran eke Satani tì. Ṣugbọn, lọna ti o banininujẹ, o tẹsiwaju o sì ru ofin Ọlọrun. Lẹhin naa, Adamu yàn lati darapọ mọ aya rẹ̀ ninu ipa ọna ailọgbọn rẹ̀. Nipa bayii tọkọtaya oluṣe ti inu ara-ẹni naa, pẹlu Satani, ṣọ̀tẹ̀ lodisi Ọlọrun, ariyanjiyan ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun ni a sì gbé dide.—Jẹnẹsisi 3:6.
A Nilo Akoko lati Yanju Awọn Ariyanjiyan Pataki
Jehofa iba ti pa awọn ọlọtẹ mẹtẹẹta naa run nibẹ ati nigba naa. Ṣugbọn iyẹn kì bá tí yanju awọn ibeere ti a gbe dide nipasẹ iṣọtẹ wọn tan patapata. Njẹ eniyan le ṣakoso ara rẹ̀ pẹlu aṣeyọrisirere laisi Ọlọrun bi? O ha jẹ idajọ ododo ni iha ọdọ Ọlọrun lati fi dandangbọn beere itẹriba fun ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀? Ju bẹẹ lọ, ni oju iwoye ìwà tọkọtaya akọkọ, ẹda eniyan eyikeyii ha lè yàn laini imọtara ẹni nikan lati ṣiṣẹsin Ọlọrun tinutinu bi—ani nigba ti a ba tilẹ dán wọn wò lati ọwọ Satani paapaa? (Joobu 1:7-11; 2:4) Yoo gba akoko lati dahun awọn ibeere wọnyi. Pẹlupẹlu, yoo gba akoko lati ṣẹ́pá awọn iyọrisi iṣọtẹ ipilẹṣẹ yẹn ati lati mu ète Ọlọrun ṣẹ lati sọ ilẹ-aye di Paradise tí iran ẹda eniyan alailẹṣẹ kun inu rẹ̀. Awa ṣì nduro de ipinnu ikẹhin fun awọn ariyanjiyan wọnyi.
Ni ibamu pẹlu òfin rẹ̀, Ọlọrun fawọ anfaani wiwalaaye titilae kuro lọdọ Adamu ati Efa. Oun kò tun yẹ mọ lati ṣajọpin ninu imuṣẹ ète titobi nla rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, ṣaaju ki wọn to ku, a yọnda fun wọn lati mu iru ọmọ jade ki wọn sì tọ wọn dagba. Loootọ, ko ṣeeṣe fun Adamu ati Efa mọ lati ta àtaré iwalaaye dídáṣáṣá, ti o si jẹ alailẹṣẹ sori iru ọmọ wọn. (Roomu 5:12) Ṣugbọn bi o tilẹ jẹ pe awọn iran ti o tẹle e ni a bi ninu aipe ti wọn si nilati ku, ọpọlọpọ awọn ẹni kọọkan ni anfaani lati fi ibi ti wọn duro si hàn niti ariyanjiyan pataki ti ipo ọba-alaṣẹ naa.
Yiyanju Ariyanjiyan Naa
Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe yanju awọn ọran wọnyi ti wọn niiṣe pẹlu ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀? Lọna kan awọn ibeere naa ti a gbe dide padasẹhin ni Edeni ni a ti dahun nisinsinyi. Ẹgbẹẹgbẹrun ọdun itan ẹda eniyan ti fi i han gbangba lọna ti nronilara pe ẹ̀sùn Satani pe Efa yoo wà ni ipo anfaani didaraju bi o ba daduro lominira si Ọlọrun jẹ èké. Iṣakoso ẹda eniyan ti o pa Ọlọrun tì ti jẹ ikuna ti o wa titi. Gẹgẹ bi Bibeli ti wi: “Ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.”—Oniwaasu 8:9.
Ni idakeji ẹ̀wẹ̀, ọpọlọpọ awọn ohun rere ni a ti kọsilẹ laaarin awọn ọdun gbọọrọ naa lati igba ti Adamu ati Efa ti ṣẹ̀. Ọpọlọpọ ninu iran eniyan ti ṣaṣefihan rírọ̀ timọtimọ mọ́ ipo ọba-alaṣẹ Jehofa, apẹẹrẹ tí ó tayọ julọ ni ti “Ọmọkunrin eniyan,” Jesu Kristi funraarẹ. (Matiu 20:18, NW; Heberu 11:1–12:3) Awọn wọnni ti wọn ti tẹle awọn ofin Ọlọrun ti wọn sì jẹwọ ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ti ri i pe eyi jẹ ọna didara julọ niti gidi. Wọn ti niriiri otitọ owe naa: “Ibukun Oluwa [“Jehofa,” NW] ni nmuni là, kii sii fi làálàá pẹlu rẹ̀.” (Owe 10:22) Ju bẹẹ lọ, ọpẹ ni fun ipese ajinde, ni asẹhinwa asẹhinbọ wọn yoo ṣajọpin ninu imuṣẹ ète titobilọla ti Ọlọrun.—Johanu 5:28, 29.
Jehofa ko tii gbagbe ète rẹ ipilẹṣẹ. Awọn wọnni ti wọn nṣa ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ti ni a ko ni yọnda fun lati jẹgaba lori ilẹ-aye titilae. Bibeli si kilọ pe laipẹ Ọlọrun yoo gbegbeesẹ lodisi wọn. A kà pe: “A fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun.” (Roomu 1:18) Ifihanjade ibinu Ọlọrun ti nbọ yii, ti Bibeli pè ni Armageddon, yoo ṣaṣefihan pe oun wà niti tootọ laiṣi iyemeji. Kiki awọn wọnni ti wọn tẹwọgba ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ni yoo la iṣẹlẹ yẹn ja. “Ẹni iduroṣinṣin ni yoo jokoo ni ilẹ̀ naa, awọn ti o pe yoo sì maa wà ninu rẹ̀. Ṣugbọn awọn eniyan buburu ni a o ke kuro ni ilẹ-aye.”—Owe 2:21, 22.
Ariyanjiyan Nla naa ati Iwọ
Ni oju iwoye awọn otitọ wọnyi, ẹni kọọkan wa—gẹgẹ bi Adamu ati Efa—gbọdọ ṣe yíyàn kan. Awa yoo ha gbiyanju lati gbe igbesi aye lọna idadurolominira si Ọlọrun? Tabi awa yoo ha tẹriba fun ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀? Ranti, eyi ni ariyanjiyan pataki julọ ti o dojukọ ọ lonii. Awọn ariyanjiyan miiran, bi o ti le wu ki wọn jẹ pataki to, nii ṣe pẹlu iwalaaye rẹ ti isinsinyi. Eyi nii ṣe pẹlu iwalaaye rẹ ainipẹkun. Ipinnu ti o ṣe yoo nipa lori ọjọ ọla ayeraye rẹ̀.
Bawo ni iwọ ṣe le fihan pe o tẹwọgba ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun? Nipa fifi taapọn taapọn kẹkọọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, ati wiwa ọna lati ṣegbọran si ifẹ inu rẹ̀ ni ibakẹgbẹpọ pẹlu awọn Kristian tootọ miiran. (Sefanaya 2:2, 3) Bi iwọ ba ṣe bẹẹ, iwọ yoo ni ireti alayọ naa ti riri imuṣẹ ète titobilọla ti Ọlọrun. Iwọ yoo lanfaani lati ri imuṣẹ ileri agbayanu yii: “Nigba diẹ, awọn eniyan buburu ki yoo si . . . ṣugbọn awọn ọlọkan-tutu ni yoo jogun aye; wọn yoo sì maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.” (Saamu 37:10, 11) Iyọrisi agbayanu wo ni eyi jẹ́ fun gbogbo awọn ti wọn tẹriba fun ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun! Iru ìdí alagbara wo ni eyi jẹ fun ṣiṣepinnu pẹlu ọgbọ́n ninu ọran pataki julọ yii!