Orí Kẹfà
Ọ̀ràn Tó Kan Gbogbo Wa
1, 2. (a) Ọ̀ràn wo ni Sátánì gbé dìde ní Édẹ́nì? (b) Látinú ohun tó sọ, báwo ni ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe wé mọ́ ọ̀ràn náà?
Ọ̀RÀN kan tó ṣe pàtàkì gan-an, tó sì kan gbogbo aráyé kò yọ ìwọ náà sílẹ̀ o. Ìhà tó o bá dúró sí ló máa pinnu bóyá o máa wà títí ayé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ọ̀ràn yìí jẹ yọ nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ wáyé ní Édẹ́nì. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Sátánì béèrè lọ́wọ́ Éfà pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Ó dá a lóhùn pé igi kan wà ti Ọlọ́run ti sọ nípa rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀ . . . kí ẹ má bàa kú.” Ni Sátánì bá sọ pé irọ́ ni Jèhófà ń pa, pé ìwàláàyè Éfà tàbí ti Ádámù kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run. Sátánì sọ pé ohun dáradára kan wà tí Ọlọ́run fi ń du àwọn ẹ̀dá rẹ̀, ohun náà ni pé, fúnra wọn ló yẹ kí wọ́n máa gbé ìlànà kalẹ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. Sátánì tẹ́nu mọ́ ọn pé: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5.
2 Lẹ́nu kan, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé nǹkan á túbọ̀ ṣẹnuure fún ẹ̀dá èèyàn bí wọ́n bá ń fúnra wọn ṣèpinnu dípò ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run. Pẹ̀lú ohun tó sọ yìí, ńṣe ló ń ṣe àríwísí nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso. Èyí ló fa ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ náà, ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, tó ní í ṣe pẹ̀lú bóyá Ọlọ́run ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso. Ìyẹn ló fa ìbéèrè náà pé: Èwo ló dára jù lọ fún èèyàn, ṣé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso ni àbí ìṣàkóso tí kò lọ́wọ́ sí? Lóòótọ́, Jèhófà lágbára láti pa Ádámù àti Éfà run lójú ẹsẹ̀, àmọ́ ìyẹn kọ́ lọ̀nà tó tẹ́ni lọ́rùn láti yanjú ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ náà. Nípa fífún ẹ̀dá èèyàn ní àkókò tó pọ̀ tó láti gbèrú, Ọlọ́run á jẹ́ kí wọ́n mọ ohun náà gan-an tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ bí wọn kò bá gbára lé òun àtàwọn òfin òun.
3. Kí ni ọ̀ràn kejì tí Sátánì gbé dìde?
3 Títakò tí Sátánì ta ko ẹ̀tọ́ Jèhófà láti ṣàkóso kò mọ sórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Édẹ́nì o. Ó dá iyèméjì sílẹ̀ nípa ohun tó ń mú káwọn mìíràn máa fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà. Èyí jẹ́ kókó pàtàkì kejì nínú ọ̀ràn náà. Àríwísí rẹ̀ yìí nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà àti gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí Ọlọ́run pátá, kódà kò yọ àkọ́bí Ọmọ Jèhófà tó nífẹ̀ẹ́ gan-an sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Jóòbù, Sátánì jiyàn pé kì í ṣe nítorí pé àwọn tó ń sin Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso ló jẹ́ kí wọ́n máa sìn ín, àmọ́ nítorí ohun tí wọ́n máa rí gbà níbẹ̀ ni. Ó sọ pé, tí wọ́n bá rí ìṣòro, gbogbo wọn pátá ló máa jáwọ́ nítorí ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan tí wọ́n ní.—Jóòbù 2:1-6; Ìṣípayá 12:10.
Ohun Tí Ìtàn Fi Hàn
4, 5. Kí ni ìtàn fi hàn pé ó ti jẹ́ àbájáde dídarí tí èèyàn ń fúnra rẹ̀ darí ìṣísẹ̀ ara rẹ̀?
4 Kókó pàtàkì kan rèé o nípa ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ: Ọlọ́run kò dá èèyàn láti máa gbé kí nǹkan sì ṣẹnuure fún wọn láìsí ìṣàkóso rẹ̀. Fún àǹfààní wọn ló fi dá wọn lọ́nà tí wọ́n á fi gbára lé àwọn òfin òdodo rẹ̀. Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, Jèhófà.” (Jeremáyà 10:23, 24) Nítorí náà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” (Òwe 3:5) Bí Ọlọ́run ṣe ṣe àwọn òfin àdánidá láti máa darí aráyé kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó, bẹ́ẹ̀ ló tún pèsè àwọn òfin ìwà rere, tó jẹ́ pé bí wọ́n bá ṣègbọràn sí i, yóò mú ìrẹ́pọ̀ wà láwùjọ.
5 Ní kedere, Ọlọ́run mọ̀ pé ìdílé ẹ̀dá èèyàn kò lè darí ara wọn lọ́nà tó máa yọrí sí rere láìjẹ́ pé òun ṣàkóso wọn. Bí àwọn èèyàn ti ń gbìyànjú lórí asán pé kí Ọlọ́run má ṣàkóso àwọn, wọ́n ti dá oríṣiríṣi ètò ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé àti ìsìn sílẹ̀. Àwọn ètò tó yàtọ̀ síra wọ̀nyí ti mú kí aáwọ̀ máa wà láàárín àwọn èèyàn nígbà gbogbo, èyí tó ń yọrí sí ìwà ipá, ogun, àti ikú. “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn látìgbà tí ìtàn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ti ń bá a nìṣó láti máa “tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tímótì 3:13) Ní ọ̀rúndún ogún tó kọjá, tí ìran èèyàn mókè nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti iṣẹ́ ẹ̀rọ, kò tíì sígbà kan tí ìyọnu pọ̀ tó ti ọ̀rúndún náà rí. Ẹ̀rí ti fi hàn lọ́nà tí kò ṣeé sẹ́ pé, òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tó wà ní Jeremáyà 10:23 pé a kò dá àwọn èèyàn láti darí ìṣísẹ̀ ara wọn.
6. Láìpẹ́, báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe yanjú ọ̀ràn kíkọ̀ tí ẹ̀dá èèyàn kọ̀ láti gbara lé e?
6 Àwọn àbájáde oníbànújẹ́, èyí tó ti wà látọjọ́ pípẹ́ nítorí àìsí lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run ti fi hàn gbangba láìkù-síbì-kan pé, ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn kò lè yọrí sí rere. Ìṣàkóso Ọlọ́run nìkan ló lè mú ayọ̀, ìṣọ̀kan, ìlera àti ìwàláàyè wá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì fi hàn pé gbígbà tí Jèhófà fàyè gba ìjọba èèyàn tí kò fi tirẹ̀ ṣe ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin báyìí. (Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5) Láìpẹ́, yóò dá sí ọ̀ràn aráyé láti fi ìṣàkóso rẹ̀ hàn gbangba lórí ayé. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [àwọn ìjọba èèyàn tó ń ṣàkóso lọ́wọ́lọ́wọ́] Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn [àwọn èèyàn kò tún ní ṣàkóso ayé mọ́]. Yóò fọ́ ìjọba [òde òní] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Lílàájá Sínú Ayé Tuntun Ọlọ́run
7. Nígbà tí ìjọba Ọlọ́run bá mú òpin dé bá ìjọba èèyàn, àwọn wo ló máa ṣẹ́ kù?
7 Àwọn wo ló máa ṣẹ́ kù nígbà tí ìjọba Ọlọ́run bá mú òpin bá ìjọba èèyàn? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn adúróṣánṣán [àwọn tó fara mọ́ ọn pé Ọlọ́run ló ní ẹ̀tọ́ láti máa ṣàkóso] ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú [àwọn tí kò fara mọ́ ọn pé Ọlọ́run ló ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso], a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” (Òwe 2:21, 22) Bákan náà, onísáàmù náà sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:10, 29.
8. Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ rẹ̀ láre lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?
8 Tí Ọlọ́run bá ti pa ètò Sátánì run tán, yóò mú ayé tuntun rẹ̀ wá, èyí tó máa mú òpin pátápátá bá àwọn ohun tí ń bani nínú jẹ́ bí ìwà ipá, ogun, ipò òṣì, ìyà, àìsàn àti ikú tó ti di aráyé nígbèkùn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Ọ̀nà tó lẹ́wà ni Bíbélì gbà ṣàpèjúwe àwọn ohun dídára tó ń dúró de àwọn èèyàn onígbọràn. Ó sọ pé: ‘[Ọlọ́run] yóò nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ (Ìṣípayá 21:3, 4) Nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run lábẹ́ Kristi, Ọlọ́run yóò dá ẹ̀tọ́ Rẹ̀ láre (fi ẹ̀rí hàn) lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pé Òun ló yẹ kó jẹ́ Ọba Aláṣẹ wa, ìyẹn Alákòóso wa.—Róòmù 16:20; 2 Pétérù 3:10-13; Ìṣípayá 20:1-6.
Bí Àwọn Kan Ṣe Fi Hàn Pé Jèhófà Làwọ́n Fara Mọ́
9. (a) Ojú wo ni àwọn tó ti dúró ṣinṣin ti Jèhófà fi wo ọ̀rọ̀ rẹ̀? (b) Báwo ni Nóà ṣe fi ìdúróṣinṣin rẹ̀ hàn, báwo la sì ṣe lè jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
9 Látìgbà ìwáṣẹ̀ làwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́ ti wà, tí wọ́n ń fẹ̀rí hàn pé àwọ́n dúró ṣinṣin ti Jèhófà, pé òun ni Ọba Aláṣẹ. Wọ́n mọ̀ pé ìwàláàyè àwọn sinmi lórí títẹ́tí sí Ọlọ́run àti ṣíṣègbọràn sí i. Irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Nóà. Èyí ló mú kí Ọlọ́run sọ fún Nóà pé: “Òpin gbogbo ẹlẹ́ran ara ti dé iwájú mi . . . Ṣe áàkì kan fún ara rẹ.” Nóà tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn ò ka ìkìlọ̀ tí wọ́n fún wọn sí, ńṣe ni wọ́n ń bá ìgbésí ayé wọn lọ bí ẹni pé nǹkan àrà kankan kò ní ṣẹlẹ̀. Àmọ́ Nóà kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò kan ó sì ń bá a lọ ní wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ọ̀nà òdodo Jèhófà. Àkọsílẹ̀ yẹn ń bá a lọ ní sísọ pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:13-22; Hébérù 11:7; 2 Pétérù 2:5.
10. (a) Báwo ni Ábúráhámù àti Sárà ṣe ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lẹ́yìn? (b) Ọ̀nà wo la lè gbà jàǹfààní látinú àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti Sárà?
10 Ábúráhámù àti Sárà tún jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára gan-an nínú dídúró ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, gbogbo ohun tó pa láṣẹ fún wọn ni wọ́n ṣe. Ìlú Úrì àwọn ará Kálídíà tó jẹ́ ìlú aláásìkí ni wọ́n ń gbé. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kó ṣí lọ sí ibòmíràn tí kò mọ̀, Ábúráhámù “lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún un.” Kò sí àní-àní pé ìgbésí ayé ìdẹ̀ra ni Sárà á ti máa gbé tẹ́lẹ̀, táá ní ilé, ọ̀rẹ́ àti ẹbí. Síbẹ̀, ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti sí ọkọ rẹ̀ ó sì lọ sí ilẹ̀ Kénáánì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò mọ bí nǹkan ṣe máa rí bóun bá débẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 11:31–12:4; Ìṣe 7:2-4.
11. (a) Lábẹ́ àwọn ipò wo ni Mósè ti dúró ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Mósè ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
11 Ẹlòmíràn tó tún gbárùkù ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ni Mósè. Ó sì ṣe èyí lábẹ́ ipò tó ṣòro gan-an, ìyẹn lójúkojú pẹ̀lú Fáráò ọba Íjíbítì. Mósè kò dá ara rẹ̀ lójú. Ó tiẹ̀ tún ń ṣiyèméjì nípa ara rẹ̀ pé òun ò mọ̀rọ̀ọ́ sọ tó. Síbẹ̀, ó ṣègbọràn sí Jèhófà. Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Jèhófà àti ìrànlọ́wọ́ arákùnrin rẹ̀, Áárónì, Mósè jẹ́ iṣẹ́ tí Jèhófà rán an léraléra fún Fáráò olóríkunkun. Kódà àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí Mósè. Àmọ́ Mósè fi ìdúróṣinṣin ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pàṣẹ pé kó ṣe, ipasẹ̀ rẹ̀ sì ni a fi dá Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì.—Ẹ́kísódù 7:6; 12:50, 51; Hébérù 11:24-27.
12. (a) Kí ló fi hàn pé ìdúróṣinṣin sí Jèhófà ju ṣíṣe kìkì ohun tí Ọlọ́run là lẹ́sẹẹsẹ sínú àkọsílẹ̀ lọ? (b) Báwo ni níní ìmọrírì fún irú ìdúróṣinṣin yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 2:15 sílò?
12 Àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láyé ọjọ́un kò ronú pé gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń béèrè kò ju pé káwọn sáà ti ṣègbọràn sí ohun tó kọ sílẹ̀. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì gbìyànjú láti tan Jósẹ́fù láti bá òun hùwà panṣágà, kò tíì sí òfin kankan lákọọ́lẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó ka panṣágà léèwọ̀. Àmọ́ o, Jósẹ́fù mọ̀ nípa ètò ìgbéyàwó tí Jèhófà dá sílẹ̀ ní Édẹ́nì. Ó mọ̀ pé níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyàwó oníyàwó kò lè dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Jósẹ́fù kò ní in lọ́kàn láti dán Ọlọ́run wò, kó máa wo ibi tó lè gba òun láyè dé láti dà bí àwọn ará Íjíbítì. Ó rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀nà Jèhófà nípa ríronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run ti sọ tàbí tó ti ṣe nínú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó sì wá fi tọkàntọkàn ṣe ohun tó wòye pé ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12; Sáàmù 77:11, 12.
13. Báwo ni a ṣe fi Èṣù hàn ní òpùrọ́ nínú ọ̀ràn (a) Jóòbù? (b) àwọn Hébérù mẹ́ta?
13 Àní, tí àwọn tó mọ Jèhófà lóòótọ́ bá tiẹ̀ bára wọn nínú ìdánwò líle koko, wọn kì í fi Ọlọ́run sílẹ̀. Sátánì sọ pé tí Jóòbù bá pàdánù gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ tàbí ìlera rẹ̀, Jóòbù ọ̀hún pàápàá tí Jèhófà ṣì ń sọ pé òún tẹ́wọ́ gbà, yóò pa Ọlọ́run tì. Àmọ́ Jóòbù fi Èṣù hàn ní òpùrọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gan-an ò mọ ìdí tí òjò ìyọnu fi ń rọ̀ lé òun lórí. (Jóòbù 2:9, 10) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Sátánì ṣì ń gbìyànjú láti fi hàn pé òótọ́ lòún sọ, ó sún ọba Bábílónì kan tí inú ẹ̀ ń ru fùfù láti fi iná ìléru halẹ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta tí wọ́n kọ̀ láti forí balẹ̀ kí wọ́n sì jọ́sìn níwájú ère kan tí ọba náà gbé kalẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fipá mú wọn láti yàn yálà láti ṣe ìgbọràn sí àṣẹ ọba tàbí ṣe ìgbọràn sí òfin Jèhófà, èyí tó lòdì sí ìbọ̀rìṣà, wọ́n jẹ́ kó di mímọ̀ pé Jèhófà ni àwọn ń sìn àti pé òun ni Ọba Aláṣẹ Gíga Jù Lọ fún àwọn. Ìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì fún wọn ju ìwàláàyè wọn lọ!—Dáníẹ́lì 3:14-18.
14. Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún wa láti fi hàn pé lóòótọ́ la dúró ṣinṣin ti Jèhófà?
14 Ṣé ká wá gbà pé ohun táwọn àpẹẹrẹ yìí ń sọ ni pé, kéèyàn tó lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni pípé tàbí pé ẹni tó bá ti ṣàṣìṣe ti kùnà pátápátá nìyẹn? Rárá o! Bíbélì sọ fún wa pé àwọn ìgbà kan wà tí Mósè ṣàṣìṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kò múnú Jèhófà dùn, kò torí ẹ̀ kọ Mósè sílẹ̀. Àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi náà ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn. Bí Jèhófà ti ń ro ti àìpé tá a jogún mọ́ wa lára, inú rẹ̀ máa ń dùn tí a kò bá mọ̀ọ́mọ̀ dágunlá sí ìfẹ́ rẹ̀ lọ́nà èyíkéyìí. Tá a bá hu ìwà àìtọ́ kan nítorí kùdìẹ̀-kudiẹ wa, ó ṣe pàtàkì pé ká fi tọkàntọkàn ronú pìwà dà ká má sì tún àṣìṣe yẹn ṣe mọ́. Lọ́nà yìí, à ń fi hàn pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jèhófà sọ pé ó dára àti pé a kórìíra ohun tó sọ pé ó burú. Nítorí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìtóye ẹbọ Jésù, a lè ní ìdúró tó mọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Ámósì 5:15; Ìṣe 3:19; Hébérù 9:14.
15. (a) Èwo nínú gbogbo ẹ̀dá èèyàn pátá ló pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run láìkù síbì kan, kí lèyí sì fi hàn? (b) Ọ̀nà wo ni ohun tí Jésù ṣe gbà ràn wá lọ́wọ́?
15 Àmọ́, ṣé ohun tá à ń sọ ni pé kò ṣeé ṣe rárá àti rárá fún ẹ̀dá èèyàn láti ṣègbọràn láìkù síbì kan sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ni? Láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn ni ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ti dà bí “àṣírí ọlọ́wọ̀.” (1 Tímótì 3:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a dá Ádámù ní ẹni pípé, kò fi àpẹẹrẹ pípé sílẹ̀ nípa fífi gbogbo ọkàn sin Ọlọ́run. Ta ló wá lè ṣe é nígbà náà? Ó dájú pé kò sí ọ̀kankan nínú àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tó lè ṣe é. Èèyàn kan ṣoṣo tó lè ṣe é ni Jésù Kristi. (Hébérù 4:15) Ohun tí Jésù gbé ṣe fi hàn pé Ádámù lè pa ìwà títọ́ mọ́ délẹ̀délẹ̀ ká ní ó fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé ipò nǹkan sàn nígbà tiẹ̀ ju ti Jésù lọ. Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run kọ́ ló ní àbùkù. Nítorí ìdí yìí, Jésù Kristi ni àpẹẹrẹ tí a fẹ́ láti tẹ̀ lé nínú ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run àti nínú fífọkànsin Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run pẹ̀lú.—Diutarónómì 32:4, 5.
Kí Ni Ìdáhùn Tiwa Fúnra Wa?
16. Kí ni ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò ní gbogbo ìgbà nípa ọwọ́ tá a fi mú ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ?
16 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ní láti dojú kọ ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run yìí. Tá a bá ti lè sọ ọ́ ní gbangba pé ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà, Sátánì á bẹ̀rẹ̀ sí í dájú sọ wá. Á máa kó wàhálà bá wa ní gbogbo ọ̀nà, bẹ́ẹ̀ ni yóò si máa ṣe títí tí òpin á fi dé bá ètò àwọn nǹkan rẹ̀. A gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò nígbà gbogbo. (1 Pétérù 5:8) Ìwà wa ń fi ibi tá a dúró sí hàn nínú ọ̀ràn ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ tó ṣe pàtàkì àtèyí tó pọwọ́ lé e, ìyẹn ọ̀ràn pípa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run lábẹ́ ìdánwò. Ohun tó léwu ni láti máa fojú wo ìwà àìdúróṣinṣin bí ohun tí kò burú nítorí pé ó ti wọ́pọ̀ nínú ayé. Bíbá a lọ ní jíjẹ́ adúróṣinṣin ń béèrè pé ká sapá láti máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sílò nínú gbogbo ọ̀ràn ìgbésí ayé wa.
17. Ibo ni irọ́ pípa àti olè jíjà ti pilẹ̀ṣẹ̀ tó fi yẹ ká yẹra fún un pátápátá?
17 Bí àpẹẹrẹ, a ò ní fara wé Sátánì, ẹni tó jẹ́ “baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) A gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe. Nínú ètò àwọn nǹkan ti Sátánì, àwọn ọ̀dọ́ kì í sábàá jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn òbí wọn. Àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ń yẹra fún èyí, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé irọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run á dáwọ́ jíjẹ́ olóòótọ́ dúró tí ìṣòro bá dé. (Jóòbù 1:9-11; Òwe 6:16-19) Àwọn àṣà ìṣòwò kan tún wà tó lè fi hàn pé ìhà ọ̀dọ̀ “baba irọ́” ni ẹnì kan wà dípò kó jẹ́ ìhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run òtítọ́ náà. A kò gbọ́dọ̀ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. (Míkà 6:11, 12) Bákan náà, kò sí ìgbà kankan tí olè jíjà tọ̀nà, kódà béèyàn tiẹ̀ wà nípò àìní pàápàá tàbí kí ẹni téèyàn jí nǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọlọ́rọ̀. (Òwe 6:30, 31; 1 Pétérù 4:15) Ká tiẹ̀ ní àṣà tó wọ́pọ̀ níbi tí à ń gbé ni tàbí pé ohun tẹ́nì kan jí kéré, síbẹ̀, olè jíjà lòdì sí òfin Ọlọ́run.—Lúùkù 16:10; Róòmù 12:2; Éfésù 4:28.
18. (a) Lópin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, ìdánwò wo ni yóò dé bá gbogbo ìran èèyàn? (b) Irú ìwà wo ló yẹ ká mú dàgbà báyìí?
18 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, wọ́n ò ní lè ṣe nǹkan kan fún aráyé. Ìtura ńláǹlà nìyẹn á mà jẹ́ o! Àmọ́ lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún náà, a óò tú wọn sílẹ̀ fúngbà díẹ̀. Sátánì àtàwọn tó tẹ̀ lé e yóò mú nǹkan le fún ìran èèyàn tí a rà padà tí wọ́n ń pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Ọlọ́run. (Ìṣípayá 20:7-10) Ká ní a láǹfààní láti wà láàyè nígbà yẹn, kí la máa ṣe nípa ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run náà? Níwọ̀n bí gbogbo èèyàn á ti jẹ́ ẹni pípé nígbà yẹn, bí ẹnikẹ́ni bá hùwà àìdúróṣinṣin, ó mọ̀ọ́mọ̀ ni, yóò sì yọrí sí ìparun ayérayé. Ẹ ò ri i pé ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé kí a bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìwà ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà èyíkéyìí tí Jèhófà ń fún wa dàgbà nísinsìnyí, yálà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni o tàbí nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀! Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fi hàn pé tọkàntọkàn wa la fi ń sìn ín, pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Ọ̀ràn ńlá wo ni gbogbo wa ní láti dojú kọ? Báwo ló ṣe kàn wá?
• Kí ló gbàfiyèsí nínú àwọn ọ̀nà táwọn ọkùnrin àti obìnrin ayé ọjọ́un gbà pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Jèhófà?
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìwà wa bọlá fún Jèhófà lójoojúmọ́?